_id
stringlengths
17
21
url
stringlengths
32
377
title
stringlengths
2
120
text
stringlengths
100
2.76k
20231101.yo_2286_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán, tí ó di wí pé wọ́n ń wá ibùjókòó tí wọn yóò tẹ̀dó, àwọn méjèéji-Agígírì àti ajíbogun yìí náà ló jìjọ dìde láti Ilé-Ifẹ. Wọn wá sí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣa láti dó sí kí wọn lè ni àyè ijọba tiwọn. Ajíbogun dúró níbi tí a ń pè ní Iléṣa lónìí yìí, òun sì ni Ọwá Iléṣà kìíní. Agígírì rìn díẹ̀ síwájú kí ó tó dúró. Lákòókó tí ó fi dúró yẹn, ó rò wí pé òun ti rìn jìnnà díẹ̀ sí àbùrò òun kò mọ̀ wí pé nǹkan ibùsọ̀ mẹ́fà péré ni òun tí ì rín. Ṣùgbọ́n, lọ́nà kìíní ná, kò fẹ́ rìn jìnnà púpọ̀ sí àbúrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ìpinnu wọn pé àwọn kò gbọdọ̀ jìnná sára wọn bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn méjèè jì kò jọ fẹ́ gbé ibùdó kan náà. Lọ́nà kejì, ò lè jẹ́ wí pé bóyá nítorí pé ẹsẹ̀ lásán tó fi rín nígbà náà tàbí nítorí pé aginjù tó fi orí là nígbà náà ló ṣe rò wí pè ibi tí òun ti rìn ti nàsẹ̀ díẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àbúrò òun lo ṣe dúró ni ibi tí a ń pè ní Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí.
20231101.yo_2286_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Kì wọn tó kùrò ni Ifẹ̀, wọn mú àádọta ènìyàn pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ìgbà tí wọ́n dé Iléṣà ti Ajíbógun dúró, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fún un ní ọgbọn nínú àádọ́tà ènìyàn náà. Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọn, òun lè dáàbò bo ara òun, ò sí kó ogún tó kù wá sí ibùdo rè ni Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. Ìdí nìyí tí a fi ń ki ìlú náà pé;
20231101.yo_2286_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ìtàn míràn sọ fún wa pé ọmọ ìyá ni Agígírì àti Ajíbógun ni Ilé-Ifẹ̀. Ajíbógun ló lọ bomi òkun wá fún bàbá wọn - ọlọ́fin tí ó fọ́jú láti fi ṣe egbogi fún un kí ó lè ríran padà ó lọ, Ó si bọ̀. Ṣùgbọ́n kí ó tó dé àwọn ènìyàn pàápàá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rò wí pé ó ti kú, wọ́n sì ti fi bàbá wọn sílẹ̀ fún àwọn ìyàwó rẹ fún ìtọ́jú. Kí wọn tó lọ, wọ́n pín ẹrù tàbí ohun ìní bàbá wọn líifi nǹkan kan sílẹ̀ fún àbúro wọn – Ajíbógun. Ìgbà tí ó dé, ó bu omi òkun bọ̀, wọ́n lo omi yìí, bàbá wọn sì ríran.
20231101.yo_2286_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ojú Ajíbógun korò, inú sì bi pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti fi bàbá wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì kó ohun ìnú rẹ̀ lọ. bàbá wọn rí i pé inú bí i, ó sì pàrọwà fún un. “Ọmọ àlè ní í rínú tí kì í bí, ọmọ àlè la ń bẹ̀ tí kì í gbọ́” báyìí ló gba ìpẹ́ (ẹ̀bẹ̀) bàbá rẹ̀. ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ fun un ní idà kan – Idà Ajàṣẹ́gun ni, ó ni kí ó máa lé awọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ pé ibikíbi tí ó bá bá wọn, kí ọ bèèrè ohun ìní tirẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ pa wọ́n. Ajíbógun mú irin-àjò rẹ̀ pọ̀n, níkẹhìn ó bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní padà lọ́wọ́ wọn. Pẹ̀lú iṣẹ́gun lórí àwọn arákùnrin rẹ̀ yìí, kò ní ìtẹ́lórùn, òun náà fẹ́ ní ibùjókòó tí yóò ti máa ṣe ìjọba tirẹ̀.
20231101.yo_2286_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Kò sí ohun tí ó dàbí ọmọ ìyá nítorí pé okùn ọmọ ìyà yi púpọ̀. Agígírí fẹ́ràn Ajíbógun ọwá Obòkun púpọ̀ nítorí pé ọmọ ìyá rẹ̀ ni. Bàyìí ni àwọn méjèèjì pèrò pọ̀ láti fi Ilé - Ifẹ̀ sílẹ̀ kí wọn sì wá ibùjókòó tuntun fún ara wọn níbi tí wọ́n yóò ti máa ṣe ìjọba wọn.
20231101.yo_2286_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Itán sọ pé Ibòkun ni wọ́n kọ́kọ́ dó sí kí wọn tó pínyà. Ọwá gba Òdùdu lọ, Ọna Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà sì gba Ilékéte lọ. Ó kúrò níbẹ̀ lọ si Ẹẹ̀sún. Láti Eẹ̀sún ló ti wá sí Agóró: Agóró yìí ló dúró sí tí ó fi rán Lúmọ̀ogun akíkanju kan patàki nínú àwọn tí ó tẹ̀ lé e pé kí ó lọ sì iwájú díẹ̀ kí ó lọ wo ibi tí ilẹ̀ bá ti dára tí àwọn lè dó sí. Lúmọ̀ogun lẹ títí bí ẹ̀mí ìyá aláró kò padà. Àlọ rámirámi ni à ń rí ni ọ̀ràn Lúmọ̀ogun, a kì í rábọ̀ rẹ̀. Igbà ti Agígírì kò rí Lúmọ̀ogun, ominú bẹ̀rẹ̀sí í kọ́ ọ́, bóyá ó ti sọnù tàbí ẹranko búburú ti pá jẹ. Inú fun ẹ̀dọ̀ fun ni ó fi bọ́ sọ́nà láti wá a títí tí òun ó fi rí i. Ibi tí wọ́n ti wá a kiri ni wọ́n ti gbúròó rẹ̀ ni ibì kan tí a ń pè ní Òkèníṣà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lonìí yìí. Iyàlẹnu ńlánlà lọ́ jẹ́ fún Agígírì láti rí Lúmọ̀ogun pẹ̀lù àwọn ọdẹ mélòó kan, Ó ti para pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ wọ̀nyí ó sì ti gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n rán an nítorí ti ibẹ̀ dùn mọ́ on fún ọwọ́ ìfẹ́ tí àwọn ọdẹ náà fi gbà á. Inú bí Agígírì a sì gbé e bú. Ṣùgbọ́n isàlẹ̀ díẹ̀ ni òun náà bá dúro sí. Eléyìí ni wọ́n ṣe máa ń pe Òkònísà tí wọ́n dó sí yìí ní orí ayé. Wọ́n á ní “Òkènísà orí ayó”.
20231101.yo_2286_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Agbo ilée Bajimọn ní Òkè -Ọjà ni Agígírì sọ́kọ́ fi ṣe ibùjókòó. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́jìn èyí ni ó bá lọ jà ogun kan, ṣùgbọ́n kí ó tó padà dé, ọmọ rẹ̀ kan gbà òtẹ́ ńlá kan jọ tí ó fi jẹ́ wí pé Agígírì kò lè padà sí ilée Bajimọ mọ́. Ìlédè Agígírì kọjá sí láti lọ múlẹ̀ tuntun tí ó sì kọ̀lé sí Ilédè náà ní ibi tí Aàfin Ọba Ijẹ̀bú-jẹ̀ṣà wà títí di òní yìí. Ó jókòó nibẹ̀, ó sí pe àwọn tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí wọ́n múra láti ibé ogun ti ọmọ rẹ̀ náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀. Nikẹhìn, ọmọ náà túnúnbá fún bàbá rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. “Ojú iná kọ́ ni ewùrà ń hurun”. Ẹnu tí ìgbín sì fib ú òrìṣà yóò fi lọlẹ̀ dandan ni” Ọmọ náà tẹríba fún bàbá rẹ́ ó sì mọ̀ àgbà légbọ̀n-ọ́n.
20231101.yo_2286_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ìtàn míràn bí a ṣe tẹ Ijẹ̀bù-Jẹ̀ṣà dò àti bí a ṣe mọ̀ ọ́n tàbí sọ orúkọ rẹ̀ ní Ìjẹ̀bí-Jẹ̀ṣà ni ìtàn àwọn akíkanjú tàbí akọni ọdẹ méje tí wọ́n gbéra láti Ifẹ láti ṣe ọdẹ lọ. Wọ́n ṣe ọdẹ títí ìgbà tí wón dé ibi kan, olórí wọ́n fi ara pa. Wọ́n pẹ̀rẹ̀sì í tọ́júu rẹ̀ ìgbà tí wọ́n ṣe àkíyèsí wí pé ọgbẹ́ náà san díẹ̀, wọ́n tún gbéra, wọ́n mù ọ̀nà-àjò wọn pọ̀n Igbà tí wọ́n dé ibi tí a ń pè ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí yìí ni ẹ̀jẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀sí í sàn jáde láti ojú ọgbẹ́ ọkùnrin náà. Wọ́n bá dúró níbẹ̀ láti máa tọ́jú ogbà náà, wọ́n sì dúró pẹ́ dìẹ̀. Nígbẹ̀hìn, wọ́n fi olórí wọ́n yìí síbẹ̀, wọ́n pa àgó kan síbẹ̀ kí ó máa gbé e. Ìgbà tí àwọn náà bá ṣọdẹ lọ títí, wọn a tún padà sọ́dọ̀ olórí wọn yìí láti wá tójùu rẹ̀ àti láti wá simi lálẹ́. Wọ́n ṣe àkíyèsí pé ìbẹ̀ náà dára láti máa gbé ni wọ́n bá kúkú sọbẹ̀ dilé. Ìgbà tí ara olórí wọn yá tán, tí wọ́n bá ṣọdẹ lọ títí, ibẹ̀ ni wọ́n ń fàbọ̀ sí títí tí ó fi ń gbòrò sí i. Orúkọ tí Olórí wọn –Agígírì sọ ibẹ̀ ni IJẸLÚ nítorí pe ÌJẸ̀ ni Ìjẹ̀sà máa ń pe Ẹ̀JẸ̀. Nigbà tí ìyípadà sì ń dé tí ojú ń là á sí i ni wọ́n sọ orúkọ ìlú da ÌJẸ̀BÚ dípò Ìjẹ̀bú tí wọ́n ti ń pè tẹ́lẹ̀. Agígírì yí ni Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà kiíní, àwọn ìran ọlọ́dẹ méje ìjọ́sí ló di ìdílé méje tí ń jọ́ba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà títí di òní.
20231101.yo_2286_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ṣùgbọ́n Ijẹ̀bú - Ẹrẹ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń pe ìlú yìí rí nítorí ẹrẹ̀ tí ó ṣe ìdènà fún awọn Ọ̀yọ́. Ó ń gbógun ti ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà nígbà kan. Ní ìlú náà ẹrẹ̀ ṣe ìdíwọ́ fún àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ ni wọ́n bá fi ń pe ìlú náà ni Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀. Ní ọdún 1926 ni ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí “Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà Progressive Union” yí orúkọ ìlú náà kúrò láti Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ sí Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nítorí pé ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ìjẹ̀bú yìí wa.
20231101.yo_2286_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
A níláti tọ́ka sí i pé Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀ṣà yí lè ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bu ti Ìjẹ̀bù –Òde. Bí wọ́n kò tilẹ̀ ní orírun kan náà. Ìtàn lè pa wọ́n pọ̀ nipa àjọjẹ́ orúkọ, àjọṣe kankan lè má sí láàárin wọn nígbà kan ti rí ju wí pé orúkọ yìí, tó wu Ògbóni kìíní Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nígbà tí ó bá àbúrò rẹ̀ Ajíbógun lọ bòkun, wọ́n gba ọ̀nà Ìjẹ̀bú-Òde lọ. Ibẹ̀ ló gi mú orúkọ yìí bọ̀ tí ó sì fi sọ ilú tí òun náà tẹ̀dó.
20231101.yo_2286_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Nínú àwọn ìtàn òkè yí àwọn méjì ló sọ bí a ṣe sọ ìlú náà ní Ijẹ̀bú ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé a lè gba ti irúfẹ́ èyí tí ó sọ pé Ìjẹ̀bú – Òde ni Ọba Ijẹ̀bú Jẹ̀ṣà ti mú orúkọ náà wá ní eléyìí ti ó bójú mi díẹ̀. Orúkọ yìí ló wú n tí ó sì sọ ìlú tí òun náà tẹ̀dó ní orúkọ náà. Orúkọ oyè rè ni Ògbóni. Itán sọ fún wa pé ibẹ̀ náà ló ti mú un bọ̀.
20231101.yo_2286_13
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Gẹ́gẹ́ bi ìtàn àtẹnudẹ́nu, oríṣìíríṣìí ọ̀ná ni a máa ń gbà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, Ṣùgbọ́n ó kù sọ́wọ́ àwọn onímọ̀ òde òní láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìtàn wọ̀nyí kí a sì mú eléyìí tí ó bá fara jọ ọ̀ọ́tó jù lọ nínú wọn.
20231101.yo_2286_14
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Nipa pé tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni Ọwá Iléṣà àti Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ láti àárọ̀ ojọ́ wà yìí, sọ wọ́n di kòrí – kòsùn ara wọn. Wọ́n sọ ọ́ di nǹkan ìnira làti ya ara kódà, igbín àti ìkarahun ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Ṣé bí ìgbín bá sì fà ìkarahun rẹ̀ a sẹ̀ lé e ni a máa ń gbọ́. Ìgbà tí ó di wí pé àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò yí máa fi Ifẹ́ sílẹ̀, ìgbà kan náà ni wọ́n gbéra kúrò lọ́hùnún, apá ibì kan náà ni wọ́n sì gbà lọ láti lọ tẹ̀dó sí. Ọ̀rọ̀ wọn náà wà di ti ajá tí kì í lọ kí korokoro rẹ̀ gbélẹ̀. Ibi tí a bá ti rí ẹ̀gbọ́n ni a ó ti rí abúrò. Àjọṣe ti ó wà láàárìn wọ́n pọ̀ gan-an tí ó fi jẹ́ wí pé ní gbogbo ìlẹ̀ Ijẹ̀ṣà, Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jọ ní àwọn nǹkán kan lápapọ̀ bẹ́ẹ̀ náà si ni àwọn ènìyàn wọn.
20231101.yo_2286_15
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Tí Ọwá bá fẹ́ bọ̀gún, ó ní ipa tí Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ kó níbẹ̀, ó sì ní iye ọjọ́ tí ó gbọ́dọ̀ lò ní Ilẹ̀ṣà. Ní ọjọ́ àbọlégùnún, ìlù Ọba Ìjẹ̀bu-Jẹ̀ṣà ni wọ́n máa n lù ní Ilẹ́ṣà fún gbogbo àwọn àgbà Ìjẹ̀ṣà làti jó. Nìgbà tí Ọba Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà bá ń bọ̀ wálé lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí ó ti lọ̀ ni Ilẹ́ṣà fún ọdún ògún, ọtáforíjọfa ni àwọ̀n ènìyàn rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ pàdé rẹ̀. Idí nìyí tí wọ́n fi máa ń sọ pé;
20231101.yo_2286_16
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Oríṣìíríṣìí oyè ni wọ́n máa ń jẹ ní Iléṣà tí wọn sì n jẹ ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà a rí Ògbóni ní Iléṣà bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Ara Ìwàrẹ̀fà mẹfà ni ògbóní méjèejì yí a ni Iléṣà ṣùgbọ́n ògbóni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ni aṣáájú àwọn ìwàrẹ̀fà náà. A rí àwọn olóyè bí Ọbaálá, Rísàwẹ́, Ọ̀dọlé, Léjòfi Sàlórò Àrápatẹ́ àti Ọbádò ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà bí wọ́n ti wà ni Iléṣà.
20231101.yo_2286_17
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Bákan náà, oríṣìíríṣìí àdúgbò ni a rí ti orúkọ wọn bá ara wọn mu ní àwọn ìlú méjèèjì yí fún apẹẹrẹ bí a ṣe rí Ọ̀gbọ́n Ìlọ́rọ̀ ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà náà ni a rí i ní Iléṣà, Òkèníṣà wà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, Òkèṣà sì wà ní ìléṣà. Odò-Ẹsẹ̀ wà ní ìlú jèèjì yí bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹrẹ́jà pẹ́lù.
20231101.yo_2286_18
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Nínú gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, àdè tàbí ohùn ti Iléṣà àti ti Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló bá ara wọn mu jù lọ.
20231101.yo_2286_19
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló máa ń fi Ọwá tuntun han gbogbo Ìjẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bí olórí wọn tuntun lẹ́hìn tí ó bá ti ṣúre fún un tán.
20231101.yo_2286_20
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ní ìgbà ayé ogun, ọ̀tún ogun, ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, wọ́n sì ní ọ̀nà tiwọn yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù.
20231101.yo_2286_21
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Nígbà tí ilẹ̀ Ilèṣà dàrú nígbà kan láyé ọjọ́ún, àrìmọ-kùnrin Ọwá àti àrìmọ-bìnrin Ọba Ìjẹ̀bù-Jẹ̀ṣà ni wọ́n fi ṣe ètùtù kí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó rójù ráyè, kí ó tó tùbà tùṣẹ.
20231101.yo_2286_22
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Nítorí pé Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò látàárọ̀ ọjọ́ wá, àjọṣe tiwọn tún lé igbá kan ju ti gbogbo àwọn ọbà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó kù lọ nítorí pé “Ọwá àti Ògbóni Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà ló mọ ohun tí wọ́n jọ dì sẹ́rù ara wọn”
20231101.yo_2286_23
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ìlù Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà jẹ́ ìlú kan pàtàkì ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà. Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yị́ ní Nàìjéríà. Apá ìwọ́ oòrùn ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ilẹ̀ Yorùbá tàbí káàárọ́ - oò- jíire. Ìlú Ilẹ́ṣà ti ó jẹ́ olú ìlú fun gbogbo ilẹ̀ jẹ̀ṣà jẹ́ nǹkan ibùsọ̀ mẹ́rìnléláàádọ́rin sí ìlú Ìbàdàn tí jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ìlú Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà sì tó nǹkan bí ibùsọ̀ mẹ́fà sí Iléṣà ní apá àríwá ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà.
20231101.yo_2286_24
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ní títóbi, ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ó pọwọ́lé ìlú Iléṣà ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà, òun si ni olú ìlú fún ìjọba ìbílẹ̀ Obòkun ọ́un kí wọn tó tún un pín sí ọ̀nà mẹ́rin; síbẹ̀ náà òun ni olú ìlú fún ìjọba ìbìlẹ́ ààrin gùngùn obòkun.
20231101.yo_2286_25
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Àdúgbò márùnún pàtàkì ni wọ́n pín ìlú yìí sí kí bà lè rọrùn fún ètò ìjọ̀ba síṣe àti fúniṣẹ́ Ìlọ́rọ̀, Ọ̀kènísà àti Òdògo. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àdúgbò yí ló ní Olórí ọmọ tàbí lóógun kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ aṣáájú fún ọmọ àdúgbò rẹ̀ òun ní aṣáájú fún iṣẹ́kíṣẹ́ àti tí ó bá délẹ̀ láti ṣe ni àdúgbó, bẹ́ẹ̀ ni, ó sì tún jẹ́ aṣojú ọba fún àwọn ọmọ àdúgbò rẹ̀. Òdògo nìkan ni kò fi ara mọ́ èlò yí tó bẹ́ẹ̀ nítorí ìtàn tó bí i fi hàn pé ìlú ọ̀tọ̀ gédégédé ni òun. Àwọn ènìyàn ọ̀gbọ́n náà ń fẹ́ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìgbà ìwásẹ̀ ti fi hàn wí pé wọn kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Lòde òní, nǹkan ti ń yàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ nítorí pé àjọṣẹ tí ó péye ti ń wàyé láàárín ọ̀gbọ́n náà àti àwọn ọ̀gbọ́n yòókù.
20231101.yo_2286_26
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ẹ̀rí tí ó fi hàn gbegbe pé àwọn Ìjẹ̀ṣà gba ìlù Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bi ìlú ti ó tẹ̀ lé Iléṣà ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni pé ìjókòó àwọn lọ́balọ́ba ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá ìlẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà máa ń yàn àn lé. Síwájú sí i, nípa ti ìlànà oyè jíjẹ, ó ní iye ọjọ́ tí Ọwá tuntun gbọ́dọ̀ lò ní Ijẹ̀bù - Jẹ̀ṣà láyé ọjọ́un. Ọba Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà ni ó máa ń gbé Ọwá lésẹ̀ tí ó sì máa ń ṣúre fún un kí wọn tó gbà á gẹ́gẹ́ bí ọwá àti olóri gbogbo ọba ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà.
20231101.yo_2286_27
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Láti túnbọ̀ fi pàtàkì ìlú Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà hàn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú ìtàn ìwásẹ̀, ti Ọwá bá fẹ́ ṣe ìdájọ́ fún ọ̀daràn apànìyàn kan, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gbódọ̀ wà níjòkó, bí èyí kò bà rí bẹ́ẹ̀, Ọwá gbódọ̀ sùn irú igbẹ́jọ́ tábi ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ sí ọjọ́ iwájú. Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe máa ń sọ pé
20231101.yo_2286_28
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ pàtàkì jùlọ tí àwọn ènìyàn ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ń ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó jẹ́ àgbẹ̀ alárojẹ, bẹ́ẹ̀ ni a tún rí àwọn tó mú àgbẹ̀ àrojẹ mọ́ àgbẹ̀ agbinrúgbìn tó ń mówó wọlé lọ́dọ́ọdún àti láti ìgbàdégbà. Àwọn irúgbìn tí wọ́n ń gbìn fún àrojẹ ni, iṣu, ẹ̀gẹ́ (gbáàgúdá) ikókó, ìrẹsì, àgbàdo, kọfí, òwù àti obì sì jẹ́ àwọn irù-gbìn tó ń mówó wálé fún wọn.
20231101.yo_2286_29
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
A rí àwọn oniṣẹ-ọwọ́ bíi, alágbẹ̀dẹ, onílù. agbẹ́gilére, àwọn mọlémọlé àti àwọn kanlékanlé. Àwọn obìnrin wọn náà a máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́-ọwọ́, lára wọn ni aró dídá, apẹ ati ìkòkò mímọ àti aṣọ híhun pẹ̀lú.
20231101.yo_2286_30
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Bákan náà, wọ́n tún jẹ́ oníṣowò gidi. Ọmọ ìyá ni ẹlẹ́dẹ̀ àti ìmọ̀dò, bẹ́ẹ̀ náà sì ni inàki àti ọ̀bọ, gbogbo ibi tí a bá ti dárúkọ Ìjẹ̀ṣà ni a á ti máa fi ojú oníṣòwo gidi wò wọ́n. Elèyìí ni a fi ń pè wọ́n ní “Òṣómàáló” nítorí kò sí ibi tí a kó ti lè rí Ìjẹ̀ṣà ti ọ̀rọ̀ ìṣòwò bá délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí irúfẹ́ owo tí wọn kò lè ṣe, ohun tí ó kó wọn ni irìnra ni olé àti ọ̀lẹ. “Alápà má ṣiṣẹ́” ni àwọn Ìjẹ̀ṣà máa ń pe àwọn ti kò bá lè ṣiṣẹ́ gidi. Wọn ko sì fẹ́ràn irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ràrá. Ìjẹ̀ṣà kò kọ̀ láti kọ ọmọ wọn lọ́mọ tí ó bá jalè tàbí tí kò níṣẹ́ kan pàtàkì lọ́wọ́. Wọ̀n á sí máa fi ọmọ wọn tí ó bá jẹ́ akíkanjú tàbí alágbára yangàn láwùjọ. “Òkóbò nìkan ni kìí bímọ sí tòsí, a ní ọmọ òun wà ní òkè-òkun” Bákan náà ni pé “arúgbó nìkan ni ó lè parọ́ ti a kò lè já a nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ti kú tán” Purọ́ n níyì, ẹ̀tẹ́ ní ń mú wá, bi irọ́ ni, bí òótọ́ ni pé àwọn Ìjèṣà jẹ́ akíkanjú, ẹ wo jagunjagun Ògèdèngbé “Agbógungbórò” Ọ̀gbóni Agúnsóyè, “Ologun abèyìngọgọú, ó pẹ̀fọ̀n tán, ó wojú ìdó kọ̀rọ̀, Ọ̀dọ̀fin Arówóbùsóyè, Ọ̀gbọ́kọ̀ọ́ǹdọ̀ lérí odi kípàyẹ́ bì yẹ̀ẹ̀yẹ̀ẹ̀ séyìn” Ológun Arímọrọ̀ àti àwọn Olórúkọ ńláńlá ni ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà láyé ọjọ́un. Tí a bá tún wo àwọn oníṣòwò ńláńlá lóde òní nílẹ̀ Yorùbá jákèjádò, “Ọkan ni ṣànpọ̀nná kó láwùjọ èpè” ni ọ̀rọ̀ ti Ìjẹ̀ṣà. Nínú wọn ni a ti rí Àjànàkú, Erinmi lókun, Ọmọ́le Àmúùgbàǹgba bíu ẹkùn, S.B. Bákàrè Olóye méjì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo àti Onìbọnòjé àtàri àjànàkù tí kì í ṣẹrù ọmọdé. Mé loòó la ó kà lẹ́hín Adépèlé ni ọ̀rọ̀ wọn.
20231101.yo_2286_31
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Àwọn ọmọ Ìjèbú -Jẹ̀ṣà jẹ́ aláfẹ́ púpọ̀ pàápàá nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Àwọn ènìyàn ti o fẹ́ràn àlàáfíà, ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ láàárin onílé àti àlejò sì ni wọ́n pẹ̀lú. Wọn máa ń pín ara wọn sí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ìlú láti jọ kẹ́gbẹ́ àjùmọ̀ṣe lẹ́nu iṣẹ́ àti oríṣìíríṣìí ayẹyẹ nílùú pẹ̀lú. “Àjèjé ọwọ́ kan kò gbẹ́rù dóri” àjùmọ̀ṣè wọn yìí mú ìlọsíwájú wá fún ìlú náà lọ́pọ̀lọ́pọ̀ “Abiyamọ kì í gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀ kò má tatí were” ni ti àwọn ọmọ Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà sí ohunkóhun tí wọ́n bá gbọ́ nípa ìlú wọn. Bí ọ̀rọ̀ kan bá délẹ̀ nípa iṣẹ́ ìlú, wọn máa ń rúnpá-rúnsẹ̀ sí i, wọ́n á sì mú sòkòtò wọn wọ̀ láti yanjú irú ọ̀rọ̀ náà. Ọmọ ọkọ ni àwọn ọmọ ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ní tòótọ̀.
20231101.yo_2286_32
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80b%C3%BA-J%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Síwájú sí i, oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó bá òde òní mu ni wọ́n ti là sí àárín ilú láìní ọwọ́ ìjọba kankan nínú fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ìlú wọn. Fún àpẹẹrẹ Ilé - Ẹ̀kọ́ gíga (Grammar Schoo) méji tí ó wà ní ilú náà, òógùn ojú wọn ni wọ́n fi kọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Modern School wọn. Ọjà ilú, ilé-ìfìwé rànṣẹ́ àti gbàngàn ìlú ti o nà wọn tó àádọ́ta àbọ̀ ọ̀kẹ́ naira: Àwọn ọ̀nà títí tí wọ́n bójú mu tí wọ́n sì bá ti òde òní mu náà ni wọ́n ti fi òógùn ojú wọn là láìsí ìrànlọ́wọ́ ìjọba kankan.
20231101.yo_2291_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Nínú àwọn ìwé ti mo yẹ̀ wò. kò sí èyí tó sọ pàtó ìgbà tàbí àkókò tí a dá ìlú Ẹ̀fọ̀m-Aláayè sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti àbúdá ìtàn ìwáṣẹ̀. púpọ̀ nínú ìtàn yìí ló máa ń rújú pàápàá tó bá jẹ́ ìtàn ìtẹ̀lúdó ni ìlẹ Yorùbá. (Akínyẹmí 1991:121) Ìlànà ìtàn àròsọ ìwásẹ̀ ní a gbé ìtàn wọ̀nyí lé. Ní ìgbà ìwáṣè kò sí pé a ń kọ nǹkan sílẹ̀. Nítorí àìkọ sílẹ̀ ìtàn yìí, kò jẹ́ kì a rí àkọsílẹ̀ gidi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá nínú ibi tí ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè ti jé ọ̀kan nínú awọn ìlú bẹ́ẹ̀. Ìtàn ti a rí jójọ kò kọjá ìtàn atẹnúdẹnu. ìtàn ìwáṣẹ̀ ìlú Ẹ̀fọ̀n Aláayé kò yàtọ̀ sí èyí. Oríṣìí òpìtàn ni a rí, ìtàn wọn máa ń yàtọ̀ sí ara wọn, bí kò ní àfikún yóò ni àyọkúro ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí àwọn òpìtàn ti ṣiṣẹ́ lé lórí nípa ìtàn ilẹ̀ Aáfíríkà ni ìyànjú wọn lati wo ìtàn ìwáṣẹ̀, kí wọ́n tó lè fa òótọ́ yọ jáde. Ṣàṣà ni onímọ̀ kan tó ṣiṣẹ́ lórí ìtàn ìlú kan tàbí àdúgbò kan tí kò mú ìlànà ìtàn ìwáṣẹ̀ ló láti ṣàlàyé to bojumu nípa orírun ìlú kan (Johnson 1921;3).
20231101.yo_2291_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn ilẹ̀ Yorùbá, àwọ òpìtàn ìlú Ẹ̀fọ̀n Aláayè gbà pé ọ̀dọ̀ odùduwà ni wọ́n tí ṣẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀. Lára àwọn òpìtàn yìí tilẹ̀ lérò pé ẹni tó tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè dó rọ̀ lati ojú ọ̀run sílé ayé. Ìlú tó sọ̀kalẹ̀ sí ní Ilé-Ifẹ̀ tó jẹ́ orírun àwọn Yorùbá. Ìtàn yìí ṣòro láti gbàgbọ́, nítorí kò ri ìdí múlẹ̀. Kò tí ì sí ẹni tí a rí tó wọ̀ láti ojú ọ̀run rí. Nínú ìtàn ìwáṣẹ̀, òrìṣà àti odù mẹ́rìndínlógún ni a gbọ́ pé wọ́n rọ̀ láti ìsálọ̀run wá sí ìsálayé (Abimbọla, W. 1968:15). Awọn òpìtàn yìí lè rò pé bóyá nítorí tí a ti ń pe àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá ni ìgbákejì òrìṣà ni àwọn náà ṣe rò pé Aláayè àkọ́kọ́ rọ̀ sílẹ́ ayé lati ọ̀run.
20231101.yo_2291_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Nínu ìtàn ìwáṣẹ̀ mìíràn, a gbọ́ pé Ọbàlùfọ̀n Aláyémore ni ọba àkọ́kọ́ ti o tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè dó. Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ yìí jẹ́ ọmọ Ọbàlùfọ̀n Ogbógbódirin tí í ṣe àkọ́bí Odùduwà tí ó jẹ́ Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀ ni àkókó ìgbà kan. Lẹ́yìn Ikú rẹ̀, Ọ̀rànmíyàn lò yẹ kí ó jẹ ọba ní Ilé-Ifẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti lọ sílùú àwọn ọmọ rẹ̀, Eweka ni Eìní ati Aláàfin ni Ọ̀yọ́. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ti jẹ oyè Ọọ̀ni kí Ọ̀rànmíyàn tó dé.
20231101.yo_2291_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Nígbà tí Ọ̀rànmíyàn dé, Aláyẹ́mọrẹ sá kúrò lórí oyè nítorí pé ní ayé àtijọ́ wọn kì í fi ẹni ìṣááju sílẹ̀ láti fi àbúrò joyè. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ rìn títí ó fi dé orí òkè kan. Wọn pe ibẹ̀ ni Ọba-òkè. Èyí ni ọba tó tẹ̀dó sorí òkè ṣùgbọ́n lónìí ọ̀bàkè ni wọn ń pe ibẹ̀.
20231101.yo_2291_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Ni orí òkè yìí, Ọbàlùfọ̀n ṣe àkíyèsí pé ẹranko búburú pọ̀ ní agbègbè tó tẹ̀dó sí, èyí tó pọ̀jù ni ẹfọ̀n. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ẹfọ̀n yìí ni àparun. Awọn ẹfọ̀n kékeré níbẹ̀ ni wọn kójọ sínu ọgbà, ti wọn so wọn mọ́lẹ̀ títí wọ́n fi kú. Ọmọdé tó bá lọ sì igbó ibi tí wọ́n kó ẹfọ̀n kékeré sí, ni awọn òbí wọn a ké pé: ‘Kọ́ ọ̀ yàá ṣe lúgbó ẹfọ̀n alaayè’
20231101.yo_2291_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Nibi yìí ni Ẹ̀fọ̀n ti kún orúkọ Ọbalufọn Aláyémọrẹ. Lára Aláyémọrẹ ni wọn tí yọ Aláayè to fid i: Ẹ̀fọ̀n-Aláayè títí dí òní. Nígbà tí ó ṣe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ránṣẹ́ sí Ọ̀rànmíyàn kí o fi nǹkan ìtẹ̀lúdó ṣọwọ́ sí òun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi nǹkan yìí ránṣẹ́ sí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ; kò pẹ́ ti Ọ̀rànmíyàn kú. Àwọn ará Ilé-Ifẹ̀ wá ránṣẹ́ si Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ láti wá jọba lẹ́ẹ̀kejì. Kí o tó lọ, ó fí ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀. Ìyàwó mẹ́ta ni Aláyémọrẹ ni kí ó tó kúrò ní Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Àwọn ni Adúdú Ọ̀ránkú tí ì ṣe ìran àwọn Obólógun; Aparapára ọ̀run ìran awọn Aṣemọjọ, ẹ̀ẹ̀kẹta ni Èsùmòrè-gbé-ojú-ọ̀run-sàgá-ìjà. Ìtàn sọ pé lásìkò tí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ padà sí Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọọ̀ni, bọ́ sí àkókò ti Ọba Dàda Aláàfin Ọ̀yọ́ wá lórí oyè ni nǹkan bí 1200-1300AD.
20231101.yo_2291_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Bí ìtàn ìwáṣẹ̀ yìí ìbá ṣe rọrún tó láti gbàgbọ́ awọn àskìyèsí kan ní a rí tọ́ka sí tí ó jẹ́ kí ìtàn náà rú ènìyàn lójú. Nínú ìtàn yìí, wọn sọ pé Ọbàlùfọ̀n Ògbógbódirin ni àkọ́bí Odùduwa, èyí tó tako ìtàn tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa Odùduwa. Ọ̀kànbí ni àkọ́bí Odùduwa. Bó bá tilẹ̀ ṣe orúkọ ló yípadà, àwọn ọmọ Ọkànbí ni ọba méje pàtàkì ni ilẹ̀ Yorùbá tí kò sí Ọbàlùfọ̀n nínú wọn. Ohun tí òpìtàn ìbá sọ fun wa nip é ìran Odùduwà ni Ọbàlùfọ̀n jẹ́.
20231101.yo_2291_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ rú ni lójú púpọ̀. Nínú ìtàn yìí a ri i pe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ mọ àsìkò ti Ọ̀rànmíyàn wà láyé. A rí i pé ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ni wọn. Kó yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kó jẹ ọmọ àti bàbá. Lóòótọ́ ni Ọ̀rànmíyàn jẹ ọba ni Òkò, tó tún wá sí Ilé-Ifẹ̀. Àwọn ará Ọ̀y;ọ ló fi Àjàká jẹ ọba sí Òkò. Aláàfin Dada tí òpìtàn fẹnu bà pé ó jẹ ọba ní Ọ̀yọ́ da ìtàn rú. Johnson (1921:144) gbà pé Àjàká ló wá lórí oyè gẹ́gẹ́ bí Aláàfin Ọ̀yọ́ nígbà tí Ọ̀rànmíyàn kú. Tó bá jẹ́ òtítọ́ ní Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ tún wa jọba lẹ́ẹ̀kejì ní Ilé-Ifẹ̀ a jẹ́ pé àsìkò Aláàfin Àjàkáló jẹ ọba.
20231101.yo_2291_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Awọn òtìtọ́ kọ̀ọ̀kan farahàn nínú ìtàn yìí. Lóòótọ́ ni Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ kan wá ni Ilé-Ifẹ̀. Títí dí oní ọ̀gbọ́n Ọbàlùfọ̀n wa ní Ilé-Ifẹ̀. Àdúgbò Aláayè si wa ní Ilé-Ifẹ̀ títí dí òní. Kò sí irọ́ níbẹ̀ pé Ẹ̀fọ̀n Aláayè bá Ilé-Ifẹ̀ tan. Nínú ìtàn mìíràn, a gbọ pé àwọn oríṣìí ènìyàn bí i mẹ́fà ni wọ́n tẹ̀dó lásìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Nínú ìtàn yìí, a gbọ́ pé Èkúwì ló kọ́kọ́ dé sílùú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, igbó-àbá ni Èkúwì tẹ̀dó sí. Ọdẹ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oríkin náà tẹ̀dó sí Igbó àayè. Lọ́jọ́ kan, lásìkò tí oríkin tẹ̀dó, ó rí iná tó ń rú ni Igbó-Àbá. Ó ṣe ọ̀dẹ lọ sí igbó yìí. Oríkin rọ àwọn tó wa ni Igbó àbá kí wọn jọ má gbé ní Igbó-Àayè. Wọ́n gbà bẹ́ẹ̀. Lásìkò tí wọn jọ ń gbé ni wọn fí Ọbàlùfọ̀n jẹ ọba. Igbákejì Ọbàlùfọ̀n tí wọ́n jọ wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní wọn fi jẹ igbákejì ọba tí a mọ̀ sí Ọbańlá. Bàbá Igbó Àbá ọjọ́sí ni wọn fi jẹ baba ọlọ́jà tí a mọ sí Ọbalọ́jà. Ọbàlùfọ̀n àti Ọbalọ́jà jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nígbà náà. Bí ọba ṣe ń pàṣẹ fún àayè ní Ọbalọ́jà ṣe n pàṣẹ ní Ọ̀bàlú láyé ìgbà náà. Lónìí, Ọbalọ́jà jẹ Olóyè pàtàkì ní ìlú Ẹ̀fọ̀n. Ọbalọ́jù ní olórí àwọn Ọ̀bàlú. Àjọṣe wá láàrìn Ọba àti Ọbalọ́jà. Bí ọba kan bá wàjà ní ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, iwájú ilé ọba-ọlọ́ja ni wọn yóò kó ọjà lọ.
20231101.yo_2291_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Nínú ìtàn mìíran a gbọ́ pé ààfin Odùduwà ni wọ́n bí Aláayè sí. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọba obinrin ló bii. O jẹ́ arẹwà okùnrin ti ènìyàn púpọ̀ fẹ́ràn rẹ̀ pàápàá àwọn babaláwo tó ń wá sí ààfin. Ìtàn yìí tẹ̀síwájú pé ọkùnrin yìí ní aáwọ̀ ni ààfin, èyí ló mú kí Odùduwà ṣe fún Aláayè ní ilẹ̀ sí ìráyè tí a mọ̀ sì Modákẹ́kẹ́ lónìí. Odùduwà fún un ni adé tó sì n jẹ́ Ọba Láayè. Nínú ìtẹ̀sìwájú, Ìtàn mìíràn tó fara jọ ìtàn òkè yìí, a gbọ́ pé àwọn ọmọọba méjì ló fẹ́ lọ tẹ ìlú dó. Bó ba rí bẹ́ẹ̀ á jẹ́ pé ìlú Ẹ̀fọ̀n tí wá kí Modákẹ́kẹ́ tó dáyé. Àtàdá ati Johnson tilẹ̀ maa ń to Aré àti Ẹ̀fọ̀n tẹ̀lé ara wọn.
20231101.yo_2291_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Ni pàtàkì, ogun kò ṣẹgún Ẹ̀fọ̀ Aláayè rí àyàfi Ogun Ọdẹ́rinlọ (1852-54). Ọdẹ́rìnlọ jẹ ọmọ Ìrágberí, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀fọ̀n-Aláayè ni ìrágberí ti kúrò. A le sọ pe ọmọ bíbi Ẹ̀fọ̀n ló kó Ẹ̀fọ̀n-Aláayè kì í ṣe ọ̀tá nítorí òkè to yí wọ́n ká jẹ ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ fún ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, ó sì jẹ wàhálà fun ọ̀tá. Àwọn ọ̀tá to fẹ jà wọn lógun nígbó Òòyè, wọn ṣe lásán ni. Ogun yìí fà á ti Aláayè kì í fi jẹ osun ògògó titi dòní. Ohun àrífàyọ nínú ìtàn yìí nip é ọdẹ ló tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n dó gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú mìíran ni ilẹ̀ Yorùbá. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn mìíràn ń tẹ̀lé e wá sí ibi ìtẹ̀dó. Ó ṣe é ṣe bẹ́ẹ̀ nitori ibi ti ọdẹ máa ń tẹ̀dó sí kò ní jìnnà sí omit i ń sàn; àtipé yóò ti kó àwọn ẹran rẹ̀ jọ sí ojú ibi ìdáná. Ọja ló ṣéyọ láti ibẹ̀. A tún rí i pé ẹni tó jẹ ọba Ẹ̀fọ̀n gbé adé rẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀; ṣùgbọ́n àsìkò tó dé sí ibùdó yìí ni a kò mọ̀. Lóòótọ́, ẹni tó bá jẹ́ alágbára láyé àtijọ, tó sì ní àmúyẹ ni wọn fi i jọba, lẹ́yìn ti Ifá bá ti fọre. Kò yá wá lẹ́nu pé wọ́n fi ẹni tí adé ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ jẹ ọba nítorí àwọn ohun àmúyẹ ọba wà ni sàkání rẹ̀.
20231101.yo_2291_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
…they (myths) depict the deeds of human rather then supernatural heroes and deal with or allude to, events such as migrations, war, or the establishment of ruling dynasties.
20231101.yo_2291_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
Èyí ni pé ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ti pẹ́, ó ń sọ nípa ènìyàn akọni àti awọn nǹkan to yi i ka bí ìrìnàjò láti ibi kan sí èkejì, ogun jíjà ati bí wọn ṣe tẹ ìlú dó. Encyclopaedia Britanica (1960:54) ṣàlàyé pé ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ ìtàn nípa àṣà tí ó ń ṣàlàyé nípa ènìyàn, ẹranko, òrìṣà àti ẹ̀mí àìrí. Irú ìtàn yìí kì í sọ àkókò gan-an tí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣẹ́ ṣùgbọ́n wọn jẹ́ kí ìtàn ní kókó àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò lò rí nínú ìtàn lásán. Ìtàn ìwáṣẹ̀ máa ń jẹ ọ̀nà kan pàtàkì láti ṣàlàyé ìgbé ayé tó ti kọjá. Ò máa ń sọ nípa bí àwọn ènìyàn ṣe dé sí ilẹ̀ kan ati ìdí tí àwọn kan fi jẹ gàba lórí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Volume Library (267) tilẹ̀ sọ pé o yẹ kí ìgbàgbọ́ wa rọ̀ mọ́ ìtàn ìwáṣẹ̀ nítorí ó jẹ́ mọ́ àṣà bí o tilẹ jẹ́ pé kò sí ẹni tó mọ ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ohun ti a mọ̀ nip é ìtàn ìwáṣẹ̀ ti wáyé lásìkò tó ti pẹ́.
20231101.yo_2291_13
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8f%E1%BB%8D%CC%80n-Al%C3%A0%C3%A0y%C3%A8
Ẹfọ̀n-Alààyè
A kò lè fọ́wọ́ rọ́ ìtàn ìwáṣẹ̀ ìlí Ẹ̀fọ̀n-Alàayè ṣẹ́yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú àwọn ìtàn tí àwọn òpìtàn sọ fún wa, ìdáṣọró okùn-ìtàn wà níbẹ̀ ṣùgbọ́n nǹkan tó ṣe pàtàkì ní pé ẹni tó tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n Alàayè dó wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní àsìkò ìgbà kan tí a kò mọ̀. Ìlú ibi ti wọ́n tẹ̀dó sí tù wọn lára, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí dí òní.
20231101.yo_2292_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ponna
Ponna
J.A Ògúnwálé (1992), ‘Àyẹ̀wò Àwọn Afọ̀ Onítumọ̀ Pọ́n-na nínú Àwọn Ìwé kan nínú Èdè Yorùbá.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyé Ẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria.
20231101.yo_2292_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ponna
Ponna
Pọ́n-na inú àwọn àṣàyàn ìwé Yorùbá kan ni kókó ohun tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí. Iṣẹ́ yìí tún ṣe àlàyé lórí àjọṣepọ̀ ààrin Ṣàkání-Ìtumọ̀, afọ̀ àti ìtumọ̀ nítorí pé bí atọ́nà ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Bákan náà ni a pín àwọn Pọ́n-na tí a rí nínú àwọn ìwé Yorùbá díẹ̀ sí ìsọ̀rí. Ẹ̀yìn èyí ni a wá ṣe àfiwé pọ́n-na pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Ìtumọ̀ mìíràn tó ń bá a ṣé orogún.
20231101.yo_2292_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ponna
Ponna
A fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ọmọ Yorùbá tó ń lo èdè náà lẹ́nu wò kí ìtumọ̀ tí a ń fún afọ̀ tí àwa kà sí pọ́n-na má baà dà bí àtorírò tiwa lásán. A wo àwọn ìwé tí ó jẹ mọ́ ewì, ọ̀rọ̀ geere àti eré onítàn kí a lè baà kó gbogbo ẹ̀yà ìwé Yorùbá já. Orí òṣùwọ̀n àjùmọ̀ṣe Kress àti Odell lórí ìṣẹ̀dà òye-ọ̀rọ̀ ni a gbé iṣẹ́ yìí kà.
20231101.yo_2292_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ponna
Ponna
A kíyèsí I wí pé àwọn àkíyèsí tí ó jẹ mọ́ ti gírámà àti sẹ̀máńtììkì máa ń pa ìtumọ̀ afọ̀ kan dà. A sì tún kíyèsí i wí pé ìlò àfikún ẹ̀yán wà lára aáyan elédè láti pèsè ṣàkání-ìtumọ̀. Iṣẹ́ yìí tún pín pọ́n-na sí ìsọ̀rí. Òṣùwọ̀n tí a lò ni àyè tí a bá àwọn ibùba pọ́n-na, Ìrísí Ṣàkání-ìtumọ̀, Ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ àti àbùdá odo ìtumọ̀ onípọ́n-na. a rí i wí pé àbùdá pọ́n-na kì í ṣe ohun tó yé tawo-tọ̀gbẹ̀rì, a wá fi wé àwọn oríṣìí ẹ̀yà-ìtumọ̀ mìíràn bíi gbólóhùn aláìlárògún, ẹ̀dà òye-ọ̀rọ̀, ààrọ̀ àti gbólóhùn aláìnítumọ̀-pàtó. Iṣẹ́ yìí rí i wí pé ara àbùdá èdè ni àwọn pọ́n-na kan jẹ́, ó lè má jẹ́ àmì àìgbédè-tó olùsọ̀rọ̀. Èyí mú kí a tọ́ka àkọtọ́ tó péye, Ìṣẹ̀dà òyè ọ̀rọ̀ àti ìlò ṣàkání-ìtumọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ìyọní-pọ́n-na.
20231101.yo_2292_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ponna
Ponna
A fi orí iṣẹ́ yìí tì si ibi wí pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni pọ́n-na máa ń jẹ́ àkómẹ́rẹ̀ fún àsọyé àti àgbọ́yé. Èyí ló sún wa dé ibi pé kí a ṣe àlàyé díẹ̀ lórí ìlò tí a ń lo pọ́n-na láwùjọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú àwọn ìwé tí a ṣàyàn
20231101.yo_2294_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/If%E1%BA%B9%CC%80w%C3%A0r%C3%A0
Ifẹ̀wàrà
Gẹ́gẹ́ bí a sọ ṣaájú, ìwádìí lórí iṣẹ́ yìí dé Ìjọba Ìbílẹ̀ Àtàkúmọ̀sà tí ó ní ibùjókòó rẹ̀ ní Òṣú. Ní ìjọba ìbìlẹ̀ yìí, gbogbo àwọn ìlú àti abúlèko tí ó wà ní ibẹ̀ ló jẹ́ ti Ìjẹ̀ṣà. Ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀ṣà ni wọ́n sì ń sọ àfi Ifẹ̀wàrà tí ó jẹ́ ẹ̀yà ẹ̀kà-èdè Ifẹ̀ ni wọ́n ń sọ. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn tí gbọ́, Ifẹ̀ ni àwọn ará Ifẹ̀wàrà ti ṣí lọ sí ìlú náà láti agboolé Arùbíìdì ní òkè Mọ̀rìṣà ní Ilé-Ifẹ̀1 . Ìwádìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ oyè ló dá ìjà sílẹ̀ ní ààrin tẹ̀gbọ́ntàbúrò. Ẹ̀gbọ́n fẹ́ jẹ oyè, àbúrò náà sì ń fẹ́ jẹ oyè náà. Ọ̀rọ̀ yìí dá yánpọn-yánrin sílẹ̀ ní ààrin wọn. Lórí ìjà oyè yìí ni wọ́n w`atí ẹ̀gbọ́n fi lọ sí oko. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀gbọ́n tó ti oko dé, ipè láti jẹ oyè dún. Àbúrò tí ó wà ní ilé ní àsìkò náà ló jẹ́
20231101.yo_2294_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/If%E1%BA%B9%CC%80w%C3%A0r%C3%A0
Ifẹ̀wàrà
Ipé náà. Ipè ti sé ẹ̀gbọ́n mọ́ oko. Èyí bí ẹ̀gbọ́n nínú nígbà tí ó gbọ́ pé àbúrò òun ti jẹ òyé, ó sì kọ̀ láti padà wá sí ilé nítorí pé kò lè fi orí balẹ̀ fún àbúrò rẹ̀ tí ó ti jẹ oyè. Ọ̀rọ̀ yìí di ohun tí wọn ń gbé ogun ja ara wọn sí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n yìí wá ń gbé ogun ja àbúrò rẹ̀ ní Ifẹ̀ lemọ́lemọ́, ni àwọn Ifẹ̀ bá fi ẹ̀pà ṣe oògùn sí ẹnu odi ìlú ní Ìlódè. Wọ́n sì fi màrìwò ṣe àmì sì ọ̀gangan ibi tí wọ́n ṣe oògùn náà sí. Láti ìgbà yìí ni ogun ẹ̀gbọ́n kò ti lè wọ Ifẹ̀ mọ. Àwọn Ìjẹ̀ṣà ní ó ni kí ẹ̀gbọ́n tí ó ń bínú yìí lọ tẹ̀dó sí Ìwàrà. Nígbà tí wọ́n dé Ìwàrà, wọ́n fi mọ̀rìwò ọ̀pẹ gún ilẹ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́ mọ̀rìwò kọ̀ọ̀kan ti di igi ọ̀pẹ kọ̀ọ̀kan.Ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀lẹ̀, wọ́n sì pinnu pé àwọn kò níí lè bá àwọn àlejò náà gbé nítorí pé olóògùn ni wọn. Èyí ló mú kí àwọn ara Ìwàrà lé àwọn àlejò náà sí iwájú. Ibi tí àwọn àlejò náà tẹ̀dó sí lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Ìwàrà ni a mọ̀ sí Ifẹ̀wàrà lónìí. Lóòótọ́ orí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ifẹ̀wàrà wà ṣùgbọ́n kò sí àjọṣepọ̀ kan dàbí alárà láàrin Ifẹ̀wàrà, Iléṣà àti Ìwàrà títí di òní pàápàá nípa ẹ̀ka-èdè tí wọn ń sọ.
20231101.yo_2294_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/If%E1%BA%B9%CC%80w%C3%A0r%C3%A0
Ifẹ̀wàrà
Àkíyèsí fi hàn pé gbogbo orúkọ àdúgbò tí ó wà ní Ifẹ̀ náà ni ó wà ní Ifẹ̀wàrà. A rí agboolé bí Arùbíìdì, Mọ̀ọ̀rẹ̀, Òkèrèwè, Lókòrẹ́ àti Èyindi ní Ifẹ̀wàrà.
20231101.yo_2294_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/If%E1%BA%B9%CC%80w%C3%A0r%C3%A0
Ifẹ̀wàrà
Bákan náà ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ nì wọ́n ń sọ ní Ifẹ̀wàrà. Àsìkò tí wọ́n bá sì ń ṣe ọdún ìbílẹ̀ ní Ifẹ̀ náà ni àwọn ará Ifẹ̀wàrà máa ń ṣe tiwọn.
20231101.yo_2294_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/If%E1%BA%B9%CC%80w%C3%A0r%C3%A0
Ifẹ̀wàrà
Ìwádìí nípa ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ìlú tí iṣẹ́ yìí dé fi hàn gbangba pé mọ̀lẹ́bí ni Ifẹ̀, Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó pẹ̀lú Òkè-Igbo, àti Ifẹ̀wàrà. Wọ́n jọra nínú ìṣesí wọn. Ẹ̀ka-èdè wọn dọ́gba, orúkọ àdúgbò wọn tún bára mu, bákan náà ni ẹ̀sìn wọn tún dọ́gba. Àkókó tí wọ́n ń ṣe ọdún ìbílẹ̀ kò yàtọ̀ sí ara wọn. Bí ẹrú bá sì jọra, ó dájú pé ilé kan náà ni wọ́n ti jáde.
20231101.yo_2295_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ife
Ife
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣiwájú nínú ìmọ̀ ni wọ́n ti sọ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ifẹ̀. Bákan náà Johnson1, Gugler, àti Flanagan2 tó fi mọ́ Fáṣọgbọ́n3 sọ ìtàn Ifẹ̀ nínú iṣẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí, ọ̀nà méjì ni ìtàn Ifẹ̀ pín sí. Èkíní jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ nípa pé láti ìpilẹ̀sẹ̀ ni Ifẹ̀ ti wà. Ìtàn kejì ni èyí tí ó sun jáde láti ara Odùduwà1. Ìtàn àkọ́kọ́ ni ti Ifẹ̀ Oòdáyé2 Ìtàn ìwásẹ̀ náà sọ pé Olódùmarè pe àwọn Òrìṣà láti lọ wo ilé ayé wá nígbà ti ó fẹ́ dá ayé. Ó fún wọn ní èèpẹ̀ tí ó wà nínú ìkarahun ìgbín, adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún, àti ọ̀ga. Nígbà tí wọ́n dé ilé ayé, wọ́n rí i pé omi ní ó kún gbogbo rẹ̀, àwọn òrìṣà da eèpẹ̀ tí Ooódùmarè fún wọn sí orí omi náà, adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún sì tàn án. Bí adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún ṣe ń tan ilẹ̀ yìí bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ ń fẹ̀ sí i èyí náà ló bí orúkọ Ifẹ̀.
20231101.yo_2295_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ife
Ife
Ìtàn kejì ni pé láti ìlú mẹ́kà ni Lámurúdu tí ó jẹ́ baba Odùduwà ti wá sí Ifẹ̀. Ogun Mohammed tí ó jà láàrin kèfèrí àti mùsùlùmí ìgbà náà ló ká Lámúrúdu mọ́. Èyí ti Lámurúdu ìbá fi gbà, ó fi ìlú Mẹ́kà sílẹ̀, ó sì tẹ Ifẹ̀ dó.3 Lẹ́yìn ikú Lámurúdu ni Odùduwà gba Ipò. Ilé Ọ̀rúntọ́ ti wà ní Ifẹ̀ kí Lámurúdu tó dé. àwọn ará ilé Ọ̀rúntọ́ ni ó gba Lámurúdu àti Odùduwà ní àlejò4. Àwọn ará ilé Ọ̀rúntọ́ gbà fún Odùduwà láti jẹ́ olórì wọn nítorì pé alágbára ni.
20231101.yo_2295_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ife
Ife
Ìtàn ti akọkọ yìí ló sọ bí Olódùmarè ṣe ran àwọn oriṣa láti wá dá ayé. Lẹ́yìn tí àwọn oriṣa dá ayé tan, ti wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ ni Odùduwà tó wá sí Ile-Ifẹ̀ láti ìlú Mẹka. Abẹ́nà ìmọ̀ itan kejì yìí tilẹ̀ fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Lámurúdu àti Odùduwà bá àwọn kan ni Ilé-Ifẹ̀ nígbà ti wọ́n dé Ifẹ̀. Ohun tí èyí èyí ń fi yé wa nip é nibi tí ìtàn akọkọ parí si ni ìtàn kejì ti bẹrẹ.
20231101.yo_2296_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/If%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81t%E1%BA%B9%CC%80d%C3%B3
Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó
Dérìn Ọlọ́gbẹ́ńlá nì orúkọ ẹnì tí ó tẹ Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó dó1. Ọmọ ìlú Ifẹ̀ nì Ọlọ́gbẹ́ńlá, ó sì jẹ́ akíkanjú àti alágbára ènìyàn. Ìwádìí fi hàn pe, ọba Òṣemọ̀wé Oǹdó ló ránṣẹ́ sí Ọọ̀nì Abewéelá pé, kí ó rán àwọn ọmọ-ogun wá, kí wọ́n lè ran òun lọ́wọ́ latí ṣẹ́gun àwọn tí ó ń bá òun jà. Ọdún 1845 ni ọba Abewéelá rán Ọlọ́gbẹ́ńlá àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ jẹ́ ìpè ọba Òṣemọ̀wé ti Oǹdó2
20231101.yo_2296_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/If%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81t%E1%BA%B9%CC%80d%C3%B3
Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó
Wọ́n sì tẹ̀dó sí Òkè-Igbó. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ní ọdún 1845 yìí kan náà, Ọlọ́gbẹ́ńlá kò padà sí Ifẹ̀ mọ́, ó kúkú fi Òkè-Igbó ṣe ibùjókòó rẹ̀. Gbogbo aáyan àwọn Ifẹ̀ láti mú kí Ọlọ́gbẹ́ńlá padà sí Ifẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti ṣẹ́gun ní Oǹdó ló já sí pàbó. Ní ọdún 1880 ní wọn fi jẹ Ọba èyí ni Ọọ̀ni ti Ifẹ̀, ṣùgbọ́n kò wá sí Ifẹ̀ wá ṣe àwọn ètùtù tí ó rọ̀ mọ́ ayẹyẹ ìgbádé ọba, Òkè-Igbó ni ó jókòó sí1 Òkè-Igbó yìí ní ó wà tí ọlọ́jọ́ fi dé bá a ní ọdún 18922.
20231101.yo_2296_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/If%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81t%E1%BA%B9%CC%80d%C3%B3
Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó
Ní ọdún 1982 ni àwọn ara Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó kan fi ibinu ya kúrò lára Òkè-Igbó3, nítorí ọ̀rọ̀ ìlẹ̀. Oko-àrojẹ àwọn Òǹdó ni Òkè-Igbó kí ó tó dip é Ọlọ́gbẹ́ńlá àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fi ibẹ̀ ṣe ibùjókòó wọn4. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé lórí ilẹ̀ Òǹdó ni Òkè-igbó wà ṣùgbọ́n àwọn Ifẹ̀ ni ó ń gbé ìlú náà. Nígbà tí àwọn Òyìnbó ń pín ilẹ̀ Yorùbá sí ẹlẹ́kùnjẹkùn, wọ́n pín Òkè-Igbó mọ́ Òǹdó. Ohun tí ó ṣẹ́lẹ̀ lẹ̀yín náà nip è àwọn Òǹdó ń fẹ kí àwọn tí ó wà lórì ilẹ̀ àwọn ní Òkè-Igbó máa san owó-orì wọn sí àpò ìjọba ìbílẹ̀ Oǹdó. Bákan náà ni àwọn Ifẹ̀ ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó wà ní Òkè-Igbó san owó-orí wọn sí àpò ìjọba ìbílẹ̀ Ifẹ̀ nítorí pé Ifẹ̀ ni wọ́n1. Yàtọ̀ sí àríyànjiyàn tí ó wà lórí ibi tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn Òkè-Igbó san owó-orí sí, àwọn akọ̀wé agbowó-orí tún máa ń ṣe màgòmágó sí iye owó-orí tí àwọn èniyàn bá san2. Èyí ni pé ọ̀tọ̀ ni iye owó tí ó máa wà ní ojú rìsíìtì tí àwọn akọ̀wé agbowó-orí ń fún àwọn tí ó san owó-orí, ọ̀tọ̀ ni iye tí wọ́n máa kó jíṣẹ́. Gbogbo èyí ló dá wàhálà sílẹ̀ ní Òkè-Igbó ní àkókò náà. Ọba Ọọ̀ni Adérẹ̀mí ni ó pa iná ìjà náà nígbà tí ó pàṣẹ ni oḍún 1932 pé kí ẹni tí ó bá mọ̀ pé Ifẹ̀ ni òun, kúrò ní Òkè-Igbó, kí ó fo odò Ọọ̀ni padà sẹ́yìn kí ó tó dúró. Àwọn tí ó padà sí òdìkejì odò Ọọ̀ni ní oḍún 1928 ati ọdún 1932 ni a mọ̀ sí Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó lónìí.
20231101.yo_2296_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/If%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81t%E1%BA%B9%CC%80d%C3%B3
Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó
Ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó, àwọn àdúgbò wọ̀nyí ló wà níbẹ̀: Ilé Badà, Oríyangí, Kúwólé, Aṣípa-Afolúmọdi, Mọ̀ọrẹ̀, balágbè, Fáró, Ìta-Akíndé, Odò-Odi, Òkè-Ẹ̀ṣọ̀, Òkèèsodà, Olú-Òjá àti Ọdọ́. Díẹ̀ lára àwọn àdúgbò wọ̀nyí wà ní Ifẹ̀, fún àpẹrẹ, Oríyangí, Mòọ̀rẹ̀, Òkè-Ẹ̀ṣọ̀, àti Òkèèsodà. Bákan náà ló jẹ́ pé gbobgo ọdún ìbílẹ̀ tí wọ́n ń ṣe ní Ifẹ̀ náà ni wọ́n ń ṣe ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó. Bí a bá tún wo ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó, ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ni. Nítorí náà a gba orin èébú ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó.
20231101.yo_2297_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cgb%C3%B3m%C3%ACn%C3%A0
Ìgbómìnà
Igbomina Ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà jẹ́ ẹ̀yà èdè Yorùbá tí àwọn Ìgbómìnà ń sọ. Ní ilẹ̀ Yorùbá lóde òní, àwọn Ìgbómìnà wà ní ìpìnlẹ̀ Ọṣun àti Kwara. Àwọn ìlú tí wọn tí ń sọ ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣùn ní ìlá Ọ̀ràngún Òkè-Ìlá àti Ọ̀rà. Ní ìpínlẹ̀ Kwara, àwọn ìlú yìí pọ̀ jut i Ọ̀ṣun lọ. Ìjọba Ìbílẹ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọn ti ń sọ Ìgbominà. Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Ìfẹlodun, Ìrẹ́pọdun, Òkè-Ẹ̀rọ́ àti Isis. Ìlú tí wọ́n ti n sọ èka-èdè Igbómìnà ni ìjọba Ìbílẹ̀ Ìfẹ́lódun ni Ìgbàjà, Òkèyá, Òkè-Ọdẹ, Babáńlá, Ṣàárẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní Ìjọba ìbílẹ̀ Irẹpọ̀dun, lára àwọn Ìlú tí wọ́n ti ń sọ ẹ̀kà-èdè Igbómìnà ni Àjàṣẹ́, Òró, Òmù-Àrán, Àrán-Ọ̀rin. Ní ìjọba ìbílẹ̀ Òkè-Ẹ̀rọ̀ ẹ̀wẹ̀, wọn a máa sọ Ìgbómìnà ni Ìdọ̀fin. Ní ti ìjọba Ìbílẹ̀ Isis, a rí ìlú bíì Òkè-Onigbin-in, Òwù-Isis, Èdìdi, Ìjárá, Ọwá kájọlà, Ìsánlú-Isis, Ọ̀là àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
20231101.yo_2297_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cgb%C3%B3m%C3%ACn%C3%A0
Ìgbómìnà
Olúmuyiwa (1994:2) wòye pé ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀ka-èdè ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ní ẹ̀yà. Èyí náà rí bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà. Lóòótọ́, àwọn ìlú tí a dárúkọ bí ìlú tí a ti ń sọ ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà máa ń gbọ́ ara wọn ni àgbọ́yé bí wọ́n ba ń sọ̀rọ̀ síbẹ̀ oríṣiríṣI ni ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà tí wọn ń sọ láti ìlú kan sí èkejì. Ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà Òrò sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà tí wọn ń sọ ni ẹkùn Òrò.
20231101.yo_2305_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/F%C3%AD%C3%ACm%C3%B9
Fíìmù
C. O. Ọdẹjọbi (2004), ‘Àyẹ̀wò Ìgbékalẹ̀ Ìwà Ọ̀daràn nínú fíìmù Àgbéléwò Yorùbá’., Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria.
20231101.yo_2305_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/F%C3%AD%C3%ACm%C3%B9
Fíìmù
Iṣẹ́ yìí ṣe àyẹwò sí bí isẹlẹ inú àwùjo se jé òpákùtèlè ìwà òdaràn nínú ìsòwó àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá kan, b.a. ‘Ogun Àjàyè’, ‘Owọ́ Blow’, ‘Aṣéwó Kánò’, ‘Agbo Ọ̀dájú’, ‘Ṣaworoidẹ’, ‘Ìdè’, abbl. Àlàyé wáyé lórí ọ̀nà ìgbékalè ọ̀ràn nínú fíìmù àgbéléwò Yorùbá, bákan náa ni a sì tún se àyèwò ipa tí fíìmù àgbéléwò ajemọ́ ọ̀ràn dídá ń ní lórí àwọn òǹwòran, òsèré lọ́kùnrin-lóbìnrin àti àwùjo lápapọ̀. Iṣẹ́ yìí ṣe àyèwò ohun tó ń mú kí àwọn asefíìmù ó máa ṣe àgbéjáde fíìmù Yorùbá ajemó òràn dídá tó lu ìgboro pa báyìí, a sì tún wo orísirísi ìjìyà tí àwọn ọ̀daràn máa ń gbà.
20231101.yo_2305_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/F%C3%AD%C3%ACm%C3%B9
Fíìmù
Tíọ́rì ìmò ìfojú ìbára-eni-gbépò ni a lò kí a lè fi òràn dídá inú fíìmù wé tí ojú ayé. Ìfọ̀rọ̀ wá àwọn aṣefíìmù lénu wò wáyé láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń gbé fíìmù ajẹmó òràn dídá jáde. A tún fi ọ̀rọ̀ wá àṣàyàn àwọn òṣèré lókùnrin àti lóbìnrin àti ònwòran lénu wò láti mo ìhà tí wón ko sí fíìmù ajemó òràn dídá àti ipa tí wíwo irúfé fíìmù béè lè ní lórí àwọn ènìyàn nínú àwùjo.
20231101.yo_2305_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/F%C3%AD%C3%ACm%C3%B9
Fíìmù
Àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá tó jẹ mọ́ iṣẹ́ yìí ni a wò tí a sì tú palè. Ní àfikún. Olùwádìí tún lọ sí ilé ìkàwé láti ka ọ̀pọ̀ ìwé bíi jọ́nà, átíkù, ìwé iṣé àbò-ìwádìí láti lè mo àwọn isé tó ti wà nílè.
20231101.yo_2305_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/F%C3%AD%C3%ACm%C3%B9
Fíìmù
Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn pé ìyàgàn àti àìní tó je mó owó, ipò, obìnrin àti àwọn nǹkan mìíràn tí ẹ̀dà lépa ló ń ti àwon ènìyàn sínú ìwà ọ̀daràn. Iṣẹ́ yìí se àkíyèsí pé lára àwọn tó ń lówó nínú ìwà ọ̀daràn ni a ti rí òré, ebí àti àwọn agbófinró. Bákan náà ni isẹ́ yìí tún se àfihàn onírúurú ọ̀nà tí àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí ń gbà dá ọ̀ràn.
20231101.yo_2305_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/F%C3%AD%C3%ACm%C3%B9
Fíìmù
Ní ìparí. iṣé yìí gbà pé àwọn ìwà ọ̀daràn tó ń ṣelè ni a lè kà sí ọ̀kan lára ohun tí ìsẹ̀lẹ̀ àwùjọ bí àti pé ìjìyà ti a ń fún ọ̀daràn máa ń ní ipa nínú ẹbí wọn nígbà mìíràn.
20231101.yo_2354_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cl%C3%BA%20%C3%8Cr%C3%A8l%C3%A8
Ìlú Ìrèlè
Ilu Irele Akinyomade (2002), ‘Ìlú Ìrèlè’, láti inú ‘Ipa Obìnrin nínú Ọdún Èje ní Ìlú Ìrèlè.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria, ojú-ìwe 3-12.
20231101.yo_2354_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cl%C3%BA%20%C3%8Cr%C3%A8l%C3%A8
Ìlú Ìrèlè
Ìlú Ìrèlè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì àti èyí tí ó tóbi jù nínú Ìkálẹ̀ Mẹ̀sàn-án (Ìrèlè, Àjàgbà, Ọ̀mi, Ìdèpé-Òkìtipupa, Aye, Ìkọ̀yà, Ìlú tuntun, Ijudò àti Ijùkè, Erínjẹ, Gbodìgò-Ìgbòdan Líṣà). Ìlú yìí wà ní ìlà-oòrùn gúṣù Yorùbá (SEY) gẹ́gẹ́ bí ìpínsí-ìsọ̀rí Oyelaran (1967), Ó sì jẹ ibìjókòó ìjọba ìbílẹ̀ Ìrèlè. Ìlú yìí jẹ́ ọkan lára àwọn ìlú tí ó ti wà ní ìgbà láéláé, àwọn olùgbé ìlú yìí yòó máa súnmọ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbàá. Ní apá ìlà-oòrun, wọ́n bá ilú Sàbọmì àti Igbotu pààlà, ní apá ìwọ̀-oòrùn ìlú Ọ̀rẹ̀ àti Odìgbó pààlà, ní àriwá tí wọ́n sì ba ìlú Okìtìpupa-Ìdèpé àti Ìgbòbíní pààlà nígbà tí gusu wọ́n bá ìlú Ọ̀mì pààlà. Ìrèlè jẹ́ ìlú tí a tẹ̀dó sórí yanrìn, tí òjò sì máa ń rọ̀ ní àkókò rẹ̀ dáradára. Eléyìí ni ó jẹ́ kì àwọn olùgbé inú ìlú yìí yan iṣẹ́ àgbẹ̀ àti iṣẹ́ ẹja pípa ní àyò gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òòjọ́ wọ́n ṣé wọ́n ní oko lèrè àgbẹ̀. Ohun tí wọ́n sábà máa ń gbìn ni ọ̀pẹ, obì tí ó lè máa mú owó wọlé fún wọn. Wọ́n tún máa ń gbin iṣu, ẹ̀gẹ́ kókò, kúkúǹdùkú àti ewébẹ̀ sínú oko àrojẹ wọn. Nígbà tí ó dip é ilẹ̀ wọn kò tó, tí ó sì tún ń ṣá, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i, àwọn mìíràn fi ìlú sílẹ̀ láti lọ mú oko ní ìlú mìíràn. Ìdí èyí ló fi jẹ́ pé àwọn ará ìlú yìí fi fi oko ṣe ilé ju ìlú wọn lọ. Lára oko wọn yìí ni a ti ri Kìdímọ̀, Lítòtó, Líkànran, Òfò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀làjú dé, àwọn ará ìlú yìí kò fi iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ẹja pípa nìkan ṣe iṣẹ́ mọ́, àwọn náà ti ń ṣe iṣẹ́ ayàwòrán, télọ̀, bíríkìlà, awakọ̀, wọ́n sì ń dá iṣẹ́ sílẹ̀. Wọ́n ní ọjọ́ tí wọ́n máa ń kó èrè oko wọn lọ láti tà bíi ọjà Arárọ̀mí, Ọjà Ọba, àti Ọjà Kónyè tí wọ́n máa ń kó èrè oko wọn lọ láti tà bíi ọjà Arárọ̀mí, Ọjà Ọba, àti Ọjà Kóyè tí wọn máa ń ná ní ọrọọrín sira wọn. Àwọn olùsìn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ pọ̀ ni Ìrèlè. Wọ́n máa ń bọ odò, Ayélála, Arẹdẹ-lẹ́rọ̀n bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n máa ń ṣe ọdún egúngún, Ṣàngó, Ògún, Ọrẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀sìn àjòjì dé wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ń yi padà lati inú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wọ́n sí ẹ̀sìn mùsùmùmí àti ẹ̀sìn kirisitẹni.
20231101.yo_2354_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cl%C3%BA%20%C3%8Cr%C3%A8l%C3%A8
Ìlú Ìrèlè
Bí ojú ṣe ń là si náà ni ìdàgbàsókè ń bá ìlú yìí. Oríṣìíríṣìí ohun amúlúdùn ni ó wà ní ìlú Ìrèlè, bíi iná mọ̀nà-mọ́ná, omi-ẹ̀rọ, ọ̀dà oju popo, ile ìfowópamọ́, ilé ìfiwé-ránṣẹ́, ilé-ìwé gígá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
20231101.yo_2354_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cl%C3%BA%20%C3%8Cr%C3%A8l%C3%A8
Ìlú Ìrèlè
Ìrèlè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ilẹ̀ Yorùbá tí m bẹ ni ìha “Òǹdó Province” ó sì tún jẹ́ ọ̀kan kókó nínú àwọn ilẹ̀ mẹ́ta pàtàkì tí ń bẹ ni “Ọ̀kìtìpupa Division” tàbí tí a tún ń pè ní ìdàkeji gẹ́gẹ́ Ẹsẹ̀ Odò tí ọwọ́ òwúrò ilẹ̀ Yorùbá. Ìwádìí fí yé wa wí pé ọmọ ọba Benin tó jọba sí ìlú Ugbò1 tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ Olúgbò-amẹ̀tọ́2 bí Gbáǹgbá àti Àjànà. Gbáǹgbá jẹ́ àbúrò Àjànà ṣùgbọ́n nígbà tí Olúgbò-amẹ̀tọ́ wàjà, àwọn afọbajẹ gbìmọ̀pọ̀ lati fi Gbáǹgbà jẹ ọba èyí mú kí Àjànà bínú kuro ní ìlú, ó sì lọ tẹ ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́3 pẹ̀lú Gbógùnrọ́n arakunrin rẹ̀. Láti ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́ ní Àjànà tí lọ sí ìlú Benin, ò sí rojọ́ fún Ọba Uforami4 bí wọ́n ṣe fí àbúrò oùn jọba, àti pé bí oùn náà ṣe tẹ ibikan dó. Oùn yóò sì jẹ Ọba “Olú Orófun”5 sí ìbẹ. Ọba Uforami sì fún Àjànà ní adé, Àjànà padà sí Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, ó bí Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún àti Ògèyìnbó, ọkùnrin sì ni àwọn mejeeji. Kò pẹ́, kò sí jìnà, Àjànà wàjà. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji lọ si Benin lati jọba. Ògèyìnbó lọ sí Benin lati jọba. Ó dúró sí ọ̀dọ̀ Oba Benin pé baba òun tí wàjà, òun yóò sí jọba. Ọ̀rúnbẹ̀mékún náà lọ sí ọ̀dọ̀ Ìyá Ọba Benin pé òun náà fẹ jọba nígbà tí baba òun ti kú. Ọba Benin ń ṣe orò ọba fún Ògèyìnbó nígba tí Ìyá ọba ń ṣe orò fún Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún. Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún mu Olóbímítán ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí akọ́dà Ọba Benin tí yóò wà gbé oúnjẹ fún Ìyá Ọba, rí í wí pé ọrọ̀ tí ọba ń ṣe fún alejo ọdọ̀ rẹ̀ náà ní Ìyá ọba ń ṣe fún ẹni yìí. Èyí mú kí akọ́dá ọba fi ọ̀rọ̀ náà tó kabiyesi létí. Ní ọba ni ọmọ kì í bí ṣáájú iyaa rẹ, ó pe Ògèyìnbò kó wá máa lọ. Nígbà tí àwọn méjèéjì fí lọ sí Benin, Gbógùnrọ̀n tí gbe “Àgbá Malokun”6 pamọ́ nítorí ó tí fura pé wọn kò ní ba inú dídùn wá. Ògèyìnbó dé Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, kò rí Àgbá Malòkun mọ́, ó wa gbé Ùfùrà, ó wọ inú ọkọ ojú omi, o sí tẹ isalẹ̀ omi lọ, oùn ní ó tẹ ìlú Erínjẹ dó. Ní àkókò tí Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún fí wà ní ìlú Benin, Òlóbímitán, ọmọ rẹ̀ máa lọ wẹ̀ lódò Ìpòba7 àwọn ẹrú ọba sí màa ń ja lati fẹ èyí ló fá ìpèdè yìí “Olóbímitán máa lọ wẹ̀ lódì kí ẹru ọba meji máa ba jìjà ku tori ẹ”. Èyí ní wọ́n fi ń ṣe ọdún Ìjègbé ní ìlú Benin. Ní ìgbà tí ó ṣe Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún àti Olóbímitán padà sí ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, ṣùgbọ́n Gbógùnrọ̀n sọ fún wí pe àbúrò rẹ̀ (Ògèyìnbó) i ba ibi jẹ́ kò sì dára fún wọn lati gbé, wọ́n kọja sí òkè omi wọn fi de Ọ̀tún Ugbotu8, wọn sọkalẹ, Olóbímitán ní òun…àbàtà wọ́n wá tẹ́ igi tẹ́ẹ́rẹ́ lorí rẹ̀ fún, èyí ní wọn fí ń kí oríkì wọn báyìí: “Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún a hénà gòkè” .
20231101.yo_2354_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cl%C3%BA%20%C3%8Cr%C3%A8l%C3%A8
Ìlú Ìrèlè
Àgbá Malòkun tí gbógùnrọ̀n gbé pa mọ́ kò le wọ inú ọkọ́ ojú omi, wọn sọ ọ́ sínú omi, títí dì òní yìí tí wọ́n bá ti ń sọdún Malòkun ní ìlú Ìrèlè, a máa ń gbọ́ ìró ìlù náà ní ọ̀gangan ibi wọ́n gbé sọ ọ́ somi. Wọ́n tẹ̀dó sí odó Ohúmọ. Oríṣìíríṣìí ogun ló jà wọ́n ní odí Ohúmọ, lára wọn ní Ogun Osòkòlò10, Ogun Ùjọ́11, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Olumisokun ọmọ ọba Benin, ìyàwò rẹ̀ kò bímọ nígbà tó dé Ìrèlè ó pa àgọ́ sí ibikan, ibẹ̀ ní wọn tí ń bọ Malokun ni ìlú Ìrèlè. Lúmúrè wá dò ní ìlú Ìrèlè, ó fẹ Olóbímitán ṣùgbọ́n Olóbímitán kò bímọ fún un èyí mú kí ó pàdà wa si ọdọ baba rẹ̀, Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún, olúmísokùn wá fẹ Olóbímitán ní odó Ohúmọ. Wọ́n bí Jagbójú àti Oyènúsì, ogun tó jà wọn ní ní odó Ohúmọ pa Oyènúsì èyí mú kí Jagbójú sọ pé “oun relé baba mi”. Mo relé. Bí orúkọ àwọn to kọ́kọ́ jọba ni ìlú Ìrèlè ṣe tẹ̀lé ara wọn nì yìí:
20231101.yo_2357_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
A bí Bámijì Òjó ní ogúnjọ́ oṣù kẹwàá ọdún 1939 ní ìlú ìlọ́ràá, ní ìjọba ìbílẹ̀ Afijió ní ìpínlẹ̀ Ọ̀jọ́. Orúkọ àwọn òbí rẹ̀ ni Jacob Òjó àti Abímbọ́lá Àjọkẹ́ Òjó. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn òbí rẹ̀ ń ṣe.
20231101.yo_2357_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Ojú ti ń là díẹ̀ nígbà náà, ẹni tí ó bá mú ọmọ lọ sí ilé-ìwé ní ìgbà náà, bí ìgbà tí ó fi ọmọ sọ̀fà tí ó mú ọmọ lọ fún òyìnbó ni. Ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ pa ìmọ̀ pọ̀ wọ́n fi sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti ìjọ onítẹ̀bọmi ti First Baptist Day School ìlú Ìlọràá ni ọdún 1946. O ṣe àṣeyẹrí nínú ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́fà, tí ó kà jáde ni ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Nígbà náà wọ́n ti ń dá ilé ẹ̀kọ́ gíga Mọ́dà (Modern School) sílẹ̀. Bámijí Òjó ṣe ìdánwò bọ́ sí ilé-ìwé Local Authority Modern School ní ìlú Fìdítì, ó wà ní ibẹ̀ fún ọdún mẹ́ta (1956-1959).
20231101.yo_2357_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Lẹ́yìn èyí nínú ọdún 1960, Bámijí Òjó ṣe iṣẹ́ díẹ̀ láti fi kówó jọ. Nítorí pé kò sí owó lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ láti tọ́ ọ kọjá ìwé mẹ́jọ. Lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣẹ́ tí ó sì kówó jọ fún ọdún kan pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí “Modern School”, ó tún tíraka láti tẹ̀síwájú lẹ́nu ìwé rẹ̀. Ó lọ sí ilé-ìwé ti àwọn olùkọ́ni ti “Local Authority Teacher Training College” ní ìlú Ọ̀yọ́ láti inú ọdún 1961 di ọdún 1962.
20231101.yo_2357_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Ìgbà tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe iṣẹ́ tí ó wù ú lọ́kàn gan-an láti ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni iṣẹ́ tíṣà. Ó ṣe iṣẹ́ tíṣà káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ bí i Ṣakí, Edé, Ahá. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìròyìn ni ó múmú ní ọkàn rẹ̀.
20231101.yo_2357_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Bámijí Òjó wà lára àwọn méjìlá àkókó tí wọ́n gbà ní ọdún 1969 láti kọ́ Yorùbá ní Yunifásitì Èkó. Nígbà náà ojú ọ̀lẹ ni wọ́n fi máa ń wo ẹni tí ó bá lọ kọ́ Yorùbá ní Yunifásitì.
20231101.yo_2357_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni wọ́n gba Bámijí Òjó sí ilé iṣẹ́ ìròyìn ní ọdún 1970, Àlhàájì Lateef Jákàńdè ni ó gbà á sí iṣẹ́ ìròyìn ní ilé-iṣẹ́ “Tribune”ní ìlú Èkó, gẹ́gẹ́ bí igbá kejì olóòtú Ìròyìn Yorùbá. Ṣùgbọ́n nítorí pé ó tin í ìyàwó nílé nígbà náà wọ́n gbé e padà sí Ìbàdàn. Ilé-iṣẹ́ wọn wà ní Adẹ́ọ̀yọ́. Ní àsìkò yìí kan náà ni Bámijí Òjó ronú pé iṣẹ́ ìròyìn ti orí Rédíò Sáá ní ó wu òun. Ó wá ń bá wọn ṣiṣẹ́ aáyan ògbufọ̀ ni ilé-iṣẹ́ “Radio Nigeria”. Èyí ni ó ń ṣe tí ó fi ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ “Tribune” àti nílé iṣẹ́ “Radio Nigeria”.
20231101.yo_2357_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Ní ọdún 1971 ni wọ́n gba Bámijí Òjó gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ Ìròyìn ní ilé iṣẹ́ “Radio Nigeria”. Àwọn tí wọ́n jìjọ ṣiṣẹ́ ìròyìn nígbà náà ni Alàgbà Ọláòlú Olúmìídé tí ó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀, Olóògbé Àlhàájì Sàká Ṣíkágbọ́ àti Olóògbé Akíntúndé Ògúnṣínà àti bàbá Omídèyí.
20231101.yo_2357_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Nítorí ìtara ọkàn tí Bámijí Òjó ní láti ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ Tẹlifíṣàn ó kúrò ní “Radio Nigeria”, ó lọ sí “Western Nigerian Broadcastint Service” àti “Western Nigerian Televeision Station” WNBS/WNTV tó wà ní Agodi Ìbàdàn, nínú oṣù kọkànlá ọdún 1973. Ni ibẹ̀ ni ọkà rẹ̀ ti balẹ̀ tí àyè sì ti gbà á láti lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti gbé èdè, àṣà àti lítíréṣọ̀ Yorùbá lárugẹ. Ìràwọ̀ rẹ̀ si bẹ̀rẹ̀ sí í tàn gidigidi lẹ́nu iṣẹ́ ìròyìn. Nígbà ti Bámijí Òjó wà ní “Radio Nigeria” kí ó tó lọ sí “Western Nigerian Television Station (WNTV)” ni wọ́n ti kọ́kọ́ ran àwọn oníṣẹ́ ibẹ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ Rédíò. Ilé iṣẹ́ Rédíò ní Ìkòyí ni wọn ti gba idánilẹ́kọ̀ọ́ yìí. Ìdí nip é tí ènìyàn bá máa sọ̀rọ̀ nílé iṣẹ́ “Radio Nigeria”nígbà náà ó gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀kọ́. Lára àwọn ètò tó máa ń ṣe lórí ẹ̀rọ Tẹlifísàn ni “Káàárọ̀-oò-jíire” àti “Tiwa-n-tiwa” túbọ̀sún Ọládàpọ̀, Láoyè Bégúnjọbí àti àwọn mìíràn ni wọ́n jọ wà níbi iṣẹ́ nígbà náà. Gbogbo akitiyan yìí mú kí ìrírí Bámijí gbòòrò si nípa iṣẹ́ ìròyìn àti ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn inú rẹ̀.
20231101.yo_2357_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Ní ọdún 1976 ni Bámijí Òjó lọ fún ìdáni lẹ́kọ̀ọ́ ní Òkè Òkun, ní orílẹ̀ èdè kenyà níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí “Certificate Course In Mass Communication” (Ìlànà Ìgbétèkalẹ̀ lórí afẹ́fẹ́).
20231101.yo_2357_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Nígbà tí ó di oṣù kẹwàá ọdún 1976, ni wọ́n dá àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́ta sílẹ̀, Ọ̀yọ́, Òndó àti Ògùn, Bámijí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó kúrò ni ilé iṣẹ́ “Western Nigerian Broadcasting Services” àti “Western Nigerian Television Station (WNBS/WNTV) tí ó lọ dá Rédíò Ọ̀yọ́ sílẹ̀. Engineer Olúwọlé Dáre ni ó kó wọn lọ nígbà náà, Kúnlé Adélékè, Adébáyọ̀ ni wọ́n jìjọ dá ilé iṣẹ́ Rédíò sí lẹ̀ ni October 1976, wọ́n kó ilé iṣẹ́ wọn lọ sí Oríta Baṣọ̀run Ìbàdàn.
20231101.yo_2357_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Nínú ọdún 1981 ni Bámijì Òjó tún pa iṣẹ́ tì, tí ó tún lọ fún ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ Rédíò ní ilé iṣẹ́ Rédíò tí ó jẹ́ gbajúgbajà ní àgbáyé tí wọn ń pè ní “British Broadcasting Co-operation (BBC) London fún Certificate Course.
20231101.yo_2357_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Ní ọdún 1983 ni ó lọ sí orílẹ̀ èdè Germany fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Olóṣù mẹ́ta ní ilé iṣẹ́ Rédíò tí à ń pè ni “Voice of Germany”. Níbẹ̀ ló ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ Rédíò àti Móhùnmáwòrán. Ìgbà tí Bámijì Òjó dé ni ó jókòó ti iṣẹ́ tí ó yìn láàyò. Èyí ni ó ń ṣe títí tí wọ́n tún fi pín Ọ̀yọ́ sí méjì tí àwọn Ọ̀ṣun lọ, èyí mú kí àǹfààní wà láti tẹ̀ síwájú. Oríṣìíríṣìí ìgbéga ni ó wáyé nígbà náà ṣùgbọ́n ìgbéga tí ó gbẹ̀yìn nínú iṣẹ́ oníròyìn ni “Director of Programmes’ tí wọ́n fún Bámijí Òjó nínú oṣù kẹsàn-án, ọdún 1991, Ó sì wà lẹ́nu iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí olùdarí àwọn ẹ̀ka tí ó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ títí di ọdún 1994. Ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1994 ni ó fẹ̀yìn tì.
20231101.yo_2357_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Ní ọdún tí ó tẹ̀lé, nínú oṣù kìíní ọdún 1995 ni Bámijì Òjó dá ilé iṣẹ́ tirẹ̀ náà sílẹ̀. Èyí tí ó pa orúkọ rẹ̀ ní ‘Bámijí Òjó Communicatio Center’.
20231101.yo_2357_13
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn móríyá àti ìkansáárásí ni Bámijí Òjó gbà nígbà tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ijọba. Fún orí pí pé àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀ tí ó fi hàn ní ilẹ̀ Germany. Ó gba onírúurú ẹ̀bùn fún àṣeyọrí àti àṣeyege ní òpin ẹ̀kọ́ náà. Pẹ̀lú ìrírí àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ ní ‘London’ àti ‘Germany’ó di ọmọ ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí ‘Overseas Broadcasters’ Association’.
20231101.yo_2357_14
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Ní ọdún 1990 ni ọ̀gágun Abudul Kareem Àdìsá fún Bámijí Òjó ní ẹ̀bùn ìkansáárá sí, èyí ni ‘Ọ̀yọ́ State Merit Award for the best producer or the year’. Fún ìmọ rírì ètò tí ó ń ṣe ní orí ‘Television Broadcasting Co-operation Ọ̀yọ́ State (BCOS)’ Ṣó Dáa Bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ń jé àǹfààní rẹ̀, Aláyélúwà Ọba Emmanuel Adégbóyèga Adéyẹmọ Ọ̀pẹ́rìndé 1. ni ó fi oyè Májẹ̀óbà jẹ́ ti ilú Ìbàdàn dá a lọ́lá, nínú oṣù kọkànlá ọdún 1994.
20231101.yo_2357_15
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Ìwé kíkọ jẹ ohun ti Bámijì Òjó nífẹ̀ẹ́ sí. Ọba Adìkúta jẹ́ ọ̀ken lára ìwé méjì sí mẹ́ta tí ó ti kọ jáde.
20231101.yo_2357_16
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Nígbà tí Bámijì Òjó wà ní ilé iṣẹ́ “Radio Nigeria” ni ó ti kọ́kọ́ kọ ìwé kan tí ó pè ní Àṣà Àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá. Ìwé yìí wà lọ́dọ̀ àwọn atẹ̀wétà tí ó gbàgbé sí wọn lọ́dọ̀ tí kò sì jáde di òní olónìí.
20231101.yo_2357_17
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Bámijì Òjó gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí ó ní ìtara ọkàn. ó tún ní àwọn ìwé méjì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí yóò jáde ní àìpẹ́. Àkọ́kọ́ ni Ṣódaa Bẹ́ẹ̀. Ìwé yìí jẹ́ àbájáde ètò kan tí ó ṣe pàtàkì lórí Rédíò.
20231101.yo_2357_18
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
Òmíràn ni ètò Èyí Àrà. Bámijí Òjó ni ó dá ètò náà sílẹ̀¸ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹrin ọdún 1984. Ní ilẹ̀ Yorùbá pàápàá jù lọ “South West”, òun ni ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kò sí ilé iṣẹ́ Rédíò tí ó síwájú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ètò yìí “Phone In” Èyí Àrà.
20231101.yo_2357_19
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1mij%C3%AD%20%C3%92j%C3%B3
Bámijí Òjó
A.O. Adeoye (2000), ‘Ìtàn Ìgbésí Ayé Bámijí Òjó’, láti inú Àtúpelẹ̀ Ìwé Ọba Adìkúta tí Bámijí Òjó ko.’, Àpilẹ̀kọ fún Òyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀ Nigeria.
20231101.yo_2358_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%CC%80gb%C3%A0g%C3%AC
Ọ̀gbàgì
Ìlú Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú pàtàkì tó wà ní agbègbè àríwá Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìlú yìí wà láàárín Ìkàrẹ́ àti Ìrùn tó jẹ́ ààlà àríwá Àkókó àti Èkìtì. Ìlú Ọ̀gbàgì wà ní ojú ọ̀nà tó wá láti Adó-Èkìtì sí Ìkàrẹ́-Àkókó ó sì jẹ́ kìlómítà mẹ́rìnláá sí ìlú Ìkàrẹ́. Láti Ìkàrẹ́, ìlú Ọ̀gbàgì wà ní apá ìwọ̀ oòrùn tí ó sì jẹ́ pé títì tí a yọ́ ọ̀dà sí ló so ó pọ̀ mọ́ ìlú Ìkàrẹ́ tó jẹ́ ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Àkókó.
20231101.yo_2358_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%CC%80gb%C3%A0g%C3%AC
Ọ̀gbàgì
Ìlú Ọ̀gbàgì kò jìnnà sí àwọn ìlú ńlá mìíràn ní agbègbè rẹ̀. Ní ìlà oòrùn Ọ̀gbàgì, a lè rí ìlú bí i Ìkàrẹ́ àti Arigidi àti ní ìwọ̀ oòrùn ìlú yìí ni ìlú Ìrùn wà ní ọ̀nà tó lọ sí Adó-Èkìtì.
20231101.yo_2358_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%CC%80gb%C3%A0g%C3%AC
Ọ̀gbàgì
Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú mẹ́fà tí ó tóbi jùlọ ní agbègbè àríwá Àkókó nírorí ìwádìí sọ fún wa pé gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn, ti ọdún `963, àwọn ènìyàn ìlú yìí ju Ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ nígbà náà ṣùgbọ́n èyí yóò tit ó ìlọ́po méjì rẹ̀ lóde òní. Ìlú yìí jẹ́ ìlú ti a tẹ̀dó sí ibi tí ó tẹ́jú ṣùgbọ́n tí òkè yí i po, lára àwọn òkè wọ̀nyí sì ni a ti rí òkè Oròkè tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ojýbọ Òrìṣà Òkè Ọ̀gbàgì. `
20231101.yo_2358_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%CC%80gb%C3%A0g%C3%AC
Ọ̀gbàgì
Ojú ọ̀nà wọ ìlú yìí láti àwọn ìlú tó yí i pot í ó sì jẹ́ pé èyí mú ìrìnnjò láti Ọ̀gbàgì sí ìlúkílùú ní Ìpinlẹ̀ Oǹdó rọrùn. Àwọn ọ̀nà wọ̀nyí mú un rọrùn láti máa kó àwọn irè oko wọ̀lú láti gbogbo ìgbèríko tó yí ìlú Ọ̀gbàgì ká.
20231101.yo_2358_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%CC%80gb%C3%A0g%C3%AC
Ọ̀gbàgì
Gẹ́gẹ́ bi ó ti jẹ́ pé oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́ àti lóde òní, bẹ́ẹ̀ náà ni a lè rí i ní ìlú Ọ̀gbàgì níbi tó jẹ́ pé púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtijọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá ni wọn ń ṣe. Iṣẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ pàtàkì iṣẹ́ àwọn Yorùbá ló rí àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ mìíràn. Iṣẹ́ àwọn ọkùnrin ni ẹmu-dídá tó tún ṣe pàtàkì tẹ̀lé iṣẹ́ àgbẹ̀. Òwò ṣíṣe, oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tàbí iṣẹ́ ọwọ́ bí i agbọ̀n híhun, irun gígẹ̀, iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ, ilé mímọ àti iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Iṣẹ́ àwọn obìrin sì ni aṣọ híhun, irun dídì, òwò ṣíṣe àti àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìjọba ti ọkùnrin àti obìnrin ń ṣe.