raw_text
stringlengths 2
128k
|
---|
mary durojaye mary adeola temitope asake durojaye tabi nìkan mary durojaye tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá osù keje ọdún 1990 ní ìlú jẹ́ ògbóǹtarìgì agbá bọ́ọ̀lù inú agbọ̀n obìnrin ti ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì tí ó sẹ̀ wá láti orílẹ̀-ède nàìjíríà
|
ileri amukamara promise amukamara tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún osù kẹfà ọdún 1993 jẹ́ agbá bọ́ọ̀lù inú agbọ̀n ti orílẹ̀-ède nàìjíríà-amẹrika fún charnay basket bourgogne sud fra àti ẹgbẹ́ orílẹ̀-ède nàìjíríà ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́ promise ga ní ẹsẹ̀ bàtà marun ó lé inch mẹsan175 cm ó jẹ́ ọmọ ilé-ìwé gíga ti arizona state university ó tún jẹ́ àbúrò fún super bowl xlvi champion new york giants tẹ́lẹ̀ rí cornerback prince amukamara iṣẹ́ tí ó yàn promise jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ d'tigress ẹgbẹ́ agbá bọ́ọ̀lù inú agbọ̀n obìnrin ti orílẹ̀-ède nàìjíríà ó jẹ́ olùsọ́ ààyè ti ẹgbẹ́ tí ó ṣeré níbi ní tokyo ó tún kópa níbi ti ọdún 2018
|
ebenezer andrews ebenezer andrews ni a bini ọjọ mọkan lèèlogun óṣu may ni ọdun 2000 jẹ elere badminton ti ilẹ ghana ni óṣu april ọdun 2019 elere naa jẹ ọkan lara team ilẹ ghana to gba ami ọla ti idẹ ni idije ti gbogbo ilẹ afirica to waye ni port harcourt naigiria igbèsi ayè arakunrin naa andrews wa lati winneba ni ilẹ ghana to si jẹ akẹẹkọ ti ilè iwè giga to da lori ẹkọ ni winneba iṣẹ ati àṣèyọri andrews kopa ninu idije badminton u-19 ti junior gbogbo ilẹ afirica to waye ni algeria ni ọdun 2013 elere na kopa ninu ere ẹlẹkẹwa ti gbogbo ilẹ afirica ni ilè iwè giga ti kenyatta ni nairobi ilẹ kenya ni ọdun 2018 andrews ati akẹgbẹ rẹ daniel doe gba gold ninu ere ti commonwealth to waye ni ilẹ australia ni doubles finals
|
victor mbaoma nigerian footballer victor mbaomati a bini ọjọ ogun óṣu kẹ̀wá ọdun 1996 jẹ ogbon tarigi agbaabọlu ọmọ orílè-èdè nàìjíríà toun ṣèrè fun fc qizilqum gẹ̀gẹbi centre forward igbèsi aye arakunrin naa victor ni a bisi ilu eko arakunrin naa bẹrẹ iṣẹ rẹ pẹlu remo stars fc akwa united lẹyin naa ló lọsi enyimba fc ni ọdun 2019 iṣẹ ati àṣèyọri victor jẹ elere to gba goal julọ ninu league eleyi lo jẹki ko dara pọmọ apapọ team ilẹ naigiria arakunrin naa gba goal mẹrin dinlogun ni ere mọkan lèèlogun ni eyinmba ni ọdun 2022 victor kopa ninu debut ilẹ okun fun órilẹ ede naigiria ni ere to wa larin mexico ati ecuador
|
michael baah michael opoku baah jẹ elere badminton orilẹ ede ghana ti a bini ọjọ keji lèèlogun óṣu july ọdun 1996 igbèsi àyè ati àṣèyọri àràkunrin naa michael wa lati takordia ni órilẹ ede ghana to si jẹ akẹẹkọ ti ile iwe giga cape coast ni óṣu february ọdun 2018 michael ati akẹgbẹ rẹ abraham ayittey emmanuel yaw donkor ati daniel sam gba idẹ ninu idije team ti thomas ati uber ni óṣu april ọdun 2019 elere naa kopa ninu ere ilẹ afirica to waye ni ilu port harcout ni ilẹ naigiria
|
emmanuel botwe emmanuel botwe ni à bini ọjọ ogun óṣu may ọdun 1999 jẹ elere badminton órilẹ ede ghana iṣẹ emmanuel ati àṣèyọri ni ọdun 2010 botwe kopa ninu idije gbogbo ilẹ afirica to waye ni mauritius ni ọdun 2013 elere naa kopa ninu idije junior badminton gbogbo ilẹ afirica to waye ni algeria botwe pẹlu awọn akẹgbẹrẹ andrews ebenezer daniel doe jennifer abitty grace atipaka ati eryram yaa migbodzi kopa ninu idije agbaye lori badminton fun igba akọkọ ni ọdun 2019 emmanuel kopa ninu ere ilẹ africa
|
getaneh kebede getaneh kebede gebeto àmháríkì ጌታነህ ከበደ ti a bi 2 kẹrin 1992 jẹ agbabọọlu alamọdaju ara etiopia kan ti o ṣere bi ikọlu fun ologba premier league ti wolkite city
|
nana abdullahi nana aisha abdullahi tí a bí ní ọdun 1960 tí ó sì fi ayé sílè ní ọjọ́ kàrún-ún oṣù kẹta ọdún 2014 jẹ́ adájọ́ àti agbejọ́rò tẹ́lẹ̀rí ní nàìjíríà ní ọdún 2010 abdullahi di adájọ́ high court ìpínlè jigawa òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tó máa kọ́kọ́ dé ipò náà jigawa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní apá àríwá orílè-èdè nàìjíríà abdullahi jẹ́ solicitor general attorney general àti commissioner for justice láti 2000 sí 2005 a yàn án gẹ́gẹ́ bi adájọ́ àgbà ti ilé-ẹjọ́ gíga ní ìpínlè jigawa ní ọdun 2010 òun sì ni obinrin àkọ́kọ́ tí ó di ipò náà mú òun ni ó di ipò yìí mú títí di ìgbà tí ó fi ayé sílè ní ọdún 2014 justice nana abdullahi fi ayé sílè ní ilé-ìwòsàn aládàáni kan ní dutse ìpínlè jigawa nàìjíríà ní ọjọ́ kàrún-ún oṣù kẹta ọdún 2014 ní ọmọ ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta ó fi ọkọ rẹ̀ abubakar sílẹ̀ sáyé
|
mary odili mary ukaego odili née nzenwa cfr tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kárùn-ún ọdún 1952 jẹ́ adájọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti ìyàwó peter odili tó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ rivers láti ọdún 1999 sí 2007 ààrẹ goodluck jonathan ni ó yàn án gẹ́gẹ́ bíi adájọ́ 'associate' ti ilé-ẹjọ́ gíga ti nàìjíríà jsc àti pé olóyè adájọ́ katsina-alu ni ó ṣètò ìbúra sí ọ́fíìsì fún un ní ọjọ́ kẹta-lé-lógún oṣù kẹfà ọdún 2011 ṣáájú kí ó tó di adájọ́ scn ó ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ́fíìsì pàtàkì pẹ̀lú adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ rivers ní ọdún 1992 sí ọdún 2004 ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ àpéjọ ẹ̀ka abuja ọdún 2004 sí ọdún 2010 àti ìdájọ́ alákoso ilé-ẹjọ́ ti ràwọ̀ ẹ̀ka kaduna ọdún 2010 sí ọdún 2011 ó sìn gẹ́gẹ́ bí ìyáwó ààrẹ ti ìpínlẹ̀ rivers nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà nípò gomina
|
rosaline bozimo nigerian lawyer rosaline patricia irorefe bozimo ọjọ́-ìbí ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 1946 jẹ́ agbẹjọ́ro ọmọ nàìjíríà tí wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ delta láti ọjọ́ kẹta-lé-lógún oṣù kẹta ọdún 2003 ó fẹ̀hìn ipò tì ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 2011 tí honorable justice abiodun smith sì tèlé ẹ̀ nígbà àkókò walter onnoghen gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà ilẹ̀ nàìjíríà cjn ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alákoso national judicial institute nji ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rosaline bozimo ni wọ́n bí ní ọjọ́ kìíní osù kìíní ọdún 1946 ní ìjọba ìbílẹ̀ warri south ní ìpínlẹ̀ delta ó lọ sí ilé-ìwé st maria goretti grammar ìlú benin fún ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́hìn náà urhobo college effurun ní oṣù kẹ́sàn-án ọdún 1970 wọ́n gbà á wọlé sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga ahmadu bello zaria tí ó gba òye nípa òfin ní ọdún 1973 lẹ́hìn náà ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ òfin ti nàìjíríà nigerian law school àti pé wọ́n pè é láti di aṣòfin called to bar ní ọdún 1974 lẹ́hìn tí national youth service ní enugu àti onitsha ní east central state nígbà náà ó di ìkọkọ amòfin ní ọdún 1975 pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ alaowei broderick bozimo ó jẹ́ igbákejì olùdásílẹ̀ ti broderick bozimo co ó jẹ́ ní ṣókí ọmọ ẹgbẹ́ ti ìdájọ́ ti ìpínlẹ̀ bendel àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ ṣáájú kí ó tó padà sí iṣẹ́ òfin aládani ní ọdún 1978 sí ọdún 1983 ní oṣù kejìlá ọdún 1983 wọ́n tún yàn-án májísíreéétì ti ìpínlẹ̀ bendel ó di olóyè adájọ́ ní oṣù kẹjọ ọdún 1988 nígbàtí a ṣẹ̀dá ìpínlẹ̀ delta láti ìpínlẹ̀ bendel àtijọ́ ní ọdún 1991 ó di alága àkọ́kọ́ ti ìgbìmọ̀ tenders ti ilé-ẹjọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ delta àti olóyè alákoso ti ilé-ẹjọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ ní oṣù kẹsàn-án ti ọdún kan náà ní oṣù kejìlá ó ti búra gẹ́gẹ́ bí adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga kan
|
rahila hadea cudjoe onísòfin nàìjíríà justice rahila hadea cudjoe ofr ọjọ́ ìbí jésù ojọ́ kẹfà osù kẹwàá ọdún 1948 jẹ́ onísòfin kan ri to àti adájọ àgbà kan ri ni ìpínlè kaduna o jẹ́ obìnrin àkọkọ́ láti dé ipò adájọ àgbà ní ìpínlè kaduna tí ó sì ṣe ìsìn láti ọdún 1996 títí dé ọdún 2014 ó tún jẹ́ agbẹjọ́rò obìnrin àkọkọ́ ní north western state àti obìnrin àkọkọ́ tí ó jẹ́ agbẹjọ́rò òfin ní ìpínlẹ̀ kaduna ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀ ìgbé ayé àti iṣẹ́ adájọ àgbà rahila jẹ́ ọmọ bíbí ile sáríà ní ìpínlè kaduna tí wọn bí ní ọdún 1948 ó lọsí ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ tí orúko rè ń jẹ́ our ladies high school ní kaduna àti ilé ìwé gíga tí ìjọba government girls college ní dala ní ìpínlè kano lẹ́yìn èyí ní ó wà lọsí fásitì tí ó tí lọ kà nípa òfin ní fásitì ahmadu bello ní ìpínlè zaria rahila léyìn èyí ní wọn pè sí nigerian bar schools ní ọdún 1973 iṣé rahila bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òfin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi olùdámọ̀ràn ìlú ní ilé-iṣẹ́ ìdájọ ti ìpínlè kaduna ní ọdún 1979 wọ́n tún yàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jẹ́ draftsman òfin ti awọn ministry of justice ní ìpínlè kaduna àti olùdámọ̀ràn òfin sí ilé ìgbìmò aṣòfin tí ìpínlè kaduna ní 1983 lẹ́yìn èyí ní wọn yán-àn gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún ilé-ẹjọ́ gíga tí ìpínlè kaduna lábẹ́ ìdarí gómìnà àná ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ lawal laiya tí ìpínlè kaduna ni won tí yan rahila gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà fún ìpínlè náà ó jẹ́ olókìkí àti gbajúmò fún ìdarí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ojà zangon kataf lábẹ ìgbìmọ̀ ìdájọ riots tí ipinle kaduna ní ọdún 1992
|
eberechi wike nigerian judge adájọ́ eberechi suzzette wike tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù karùn-ún ọdún 1972 jẹ́ adájọ́ ní ilé-ẹjọ́-ńlá ti òun ni ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ rivers gómìnà ezenwo nyesom wike láti ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2015
|
saint george sc saint george sports club amharic ቅዱስ ጊዮርጊስ ስፖርት ክለብ kidus giorgis sport club ti inagijẹ rẹ ń jẹ kidus giorgis jẹ ogbontarjgi ẹgbẹ agbabọọlu afẹsẹgba kan ti a da silẹ ni addis ababa ethiopia ẹgbẹ yí ń gba bọọlu ni ipele oke ti bọọlu afẹsẹgba ajumọṣe tí itiopia premier league ethiopia ti a da ni ọdun 1935 ẹgbẹ naa jẹ akọkọ ni itiopia ati pe o ti fi idi mulẹ gẹgẹbi aami àtakò ti orilẹ-ede etiopia tí ó lodi si awọn agbara gbigba tí fási ítálì fascist italy
|
daisy w okocha daisy wotube okocha tí a bí ní ọjọ́ keedogun oṣù kínní ọdun 1951 jẹ́ adájọ́ àgbà ìpínlè rivers òun ni ó ní ìkáwọ́ high court of justice àti judicial service commission gọ́minà ezenwo wike ni ó yàn sípò náà ní ọjọ́ kẹrin oṣù kínní ọdun 2016 ó sì di ipò náà mú títí di ìgbà tí ó fi ipò náà kalẹ̀ ní ọjọ́ meedogun oṣù kínní ọdun 2016 ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bi okocha ní ìlú obio-akpor ìpínlẹ̀ rivers orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní ọjọ́ keedógún oṣù kínní ó jẹ́ ẹ̀yà ikwerre bàbá rẹ̀ jonathan okocha jẹ́ kọmíṣọ́nà ọlọ́pá tẹ́lẹ̀ rí ìyá rẹ̀ helen nonyelum okocha sì ń ta oúnjẹ daisy gba àmì-ẹ̀yẹ ti ìmọ̀ òfin llb hons ní yunifásítì àmọ́dù béllò ní ọdun 1978 ní ọdun tí ó tẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ kàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà wọ́n gba sínú isẹ́ ìmò òfin
|
monica dongban-mensem monica bolna'an dongban-mensem cfr ọjọ́-ìbí ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹfà ọdún 1957 jẹ́ adájọ́ ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ ààrẹ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní nàìjíríà ìpinnu yíyán rẹ̀ jẹ́ ìfọwọ́sí ní ọjọ́bọ̀ oṣù kẹfà ọjọ́ kọkànlá ọdún 2020 àwọn àmì ẹ̀yẹ rẹ̀ ní oṣù kẹwàá ọdún 2022 ọlà orílẹ̀-èdè nàìjíríà kan ti alákoso ti àṣẹ ti ìjọba àpapọ̀ cfr ni a fún monica nípasẹ̀ ààrẹ muhammadu buhari
|
binta fatima nyako ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù karùn-ún ọdún 1959 ni wọ́n bí binta nyako ní ìjọba ìbílẹ̀ remawa ní ìpínlẹ̀ katsina wọ́n bí i sí ilé ẹbí tí wọ́n gbìyànjú láti ṣètò ayé wọn ó dàgbà ó sì lọ sí ilé-ìwé ní bauchi nígbà náà ó gbìyànjú láti gba ẹ̀kọ́ tó yẹ yálà àwọn ìṣòro tó dojú kọ èyí ló sì mú kí iṣẹ́ rẹ̀ gboyè nísìínìn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ìtẹ̀lé ìwọlé rẹ̀ sí queens college ní yaba ní ìpínlẹ̀ èkó nàìjíríà ó gba satífíkéètì àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1976 ó lọ sí fásítì ahmadu bello ní zaria níbi tó ti gba llb dìgírì nígbà tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin ayé binta nyako ọkọ rẹ̀ àti ẹbí rẹ̀ ó jẹ́ ìyàwó ìkẹrin ti vice admiral - murtala nyako gómìnà ológun ti tẹ́lẹ̀ ti ìpínlẹ̀ niger láti oṣù kejì ọdún 1976 sí oṣù kejìlá ọdún 1977 ó tún jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ adamawa ti tẹ́lẹ̀ láti ọjọ́ ọ̀kàn-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2008 sí ọjọ́ karùn-ún dín lógún oṣù keje ọdún 2014 wọ́n sì mú u kúrò nípò lẹ́hìn náà ó bímọ méjì pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní bauchi ṣáájú kí ó tó pàdé murtala tí wọ́n sì wà pẹ̀lú bàbá wọn ó tún ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìyá ìyá ti ọmọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ síi ṣùgbọ́n kò tí ì mẹ́nuba rẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀ nítorí ó n'ífẹ lati tọjú ìgbésí ayé ara rẹ̀ ní ìkọkọ
|
kudirat kekere-ekun nigerian jurist born 1958 kudirat motonmori olatokunbo tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí kudirat kekere-ekun cfrcfr ọjọ́ ìbí ọjọ́ keje oṣù karùn-ún ọdún 1958 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí ó jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí kekere ekun ní ọjọ́ keje oṣù karùn-ún ọdún 1958 ní ìlú london united kingdom ní ọdún 1980 ó gba òye bachelor's degree nípa òfin ní yunifásítì èkó àti pé ó gba ilé-ìgbìmọ̀ nigeria bar ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ọdún 1981 lẹ́hìn tí ó ti jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ òfin nàìjíríà ṣáájú kí ó tó lọ sí 'london school of economics' níbití ó ti gba òye másítà ní òfin ní oṣù kọkànlá ọdún 1983 àmì ẹ̀yẹ ní oṣù kẹwàá ọdún 2022 olá orílẹ̀-èdè nàìjíríà kan ti alákoso ti àṣẹ ti ìjọba àpapọ̀ cfr ni a fún un ní láti ọ̀dọ̀ ààrẹ muhammadu buhari iṣẹ́ òfin kudirat darapọ̀ mọ́ ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ èkó gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà kejì ó sì di ipò adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ náà ó sìn gẹ́gẹ́ bí alága ìgbìmọ̀ ìjà jilè àti ìbọn zone ii ikeja láàrín oṣù kọkànlá ọdún 1996 sí oṣù karùn-ún ọdún 1999 wọ́n yàn án sí ìjókòó ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní nàìjíríà lọ́dún 2004 kí wọ́n tó yàn án gẹ́gẹ́ bí adajọ́ ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ti nàìjíríà ní oṣù keje ọdún 2013
|
olubunmi olateru olagbegi olubunmi olateru olagbegi ofr jẹ́ ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ nàìjíríà àti adájọ́ àgbà tẹ́lẹ̀ ti ìpínlẹ̀ ondo nàìjíríà ó tún jẹ́ olùkàwé ní yunifásítì afe babalola ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ ìdílé omitowoju ní ilé-ifẹ̀ ìlú kan ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ni wọ́n bí adájọ́ olubunmi ìyàwó sínú ìdílé ọlágbẹ́gi ìdílé ọba ní ọ̀wọ̀ ní ìpínlẹ̀ ondo nàìjíríà ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga yunifásítì ti london níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí àti oye òye iṣẹ́ òfin ní ọdún 1990 wọn yàn án sí ibùjókòó ti adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga kan ti ìdájọ́ ìpínlẹ̀ ondo àti ní ọdún 2003 ó di adájọ́ àgbà ti adájọ́ ìpínlẹ̀ náà ọdún méje ló ṣiṣẹ́ yìí kó tó di pé ó fẹ̀yìntì iṣẹ́ náà ní ọjọ́ kẹrin-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 2010 ní ọjọ́ kejì-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2008 ni olóyè olusegun obasanjo ààrẹ orílẹ̀-èdè nàìjíríà nígbà náà fún un ní ọlá ti orílẹ̀-èdè
|
olatokunbo olopade olatokunbo oduyinka olopade con jẹ́ onímọ̀ amòfin lórílẹ̀-èdè nàìjíríà ẹni tí wọ́n yàn sípò àgbà onídàájọ́ ní ìpínlẹ̀ ogun òun ni ìdájọ́ obìnrin àkọ́kọ́ láti ìgbà ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ náà ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ ọdún 1953 ni wọ́n bí olopade ó kẹ́kọ̀ọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ àti gíràmà ní ilé-ìwé queens èdè àti adéọlá odùtọ́lá college ìjèbú-òde lẹ́sẹsẹ̀ ó gba òye nípa òfin ní fásítì ifẹ̀ tí wọ́n sì pè é sí ilé-ìgbìmọ̀ ní ọdún 1976 ó ti ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀ka ètò ìdájọ́ fún ìpínlẹ̀ edo àti èkó ṣáájú yíyàn rẹ̀ bí adájọ́ àgbà ó jẹ́ agbẹjọ́ro ìpínlẹ̀ 1978 olùdarí ti ìbánirojọ́ gbogbo ènìyàn 1993 lẹ́hìn náà adájọ́ àgbà 2011 ní oṣù kẹjọ ọdún 2018 ó fẹ̀hìntì kúrò ní ipò rẹ̀ pẹ̀lú honorable justice mosunmola dipeolu tó rọ́pò rẹ̀ ní agbára iṣẹ́ ó jẹ́ olùgbà ti ọlá orílẹ̀-èdè alákoso àṣẹ ti niger
|
uwani musa abba aji uwani musa abba aji tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù kọkànlá ọdun 1956 jẹ́ adájọ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti adájọ́ ilé-ẹjọ́ àgbà orílẹ̀-èdè ti orílẹ̀-èdè nàíjíríà àárò ayé àti èkó rẹ̀ wọ́n bí aji ní ọjọ́ keje oṣù kọkànlá ọdun 1956 ní ìlú gashua ìpínlè yobe ó tètè bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé central primary school gashua ní ọdun 1961 tí ó sì tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní government girls secondary school maiduguri níbi tí ó ti gba ìwe-ẹ̀rí waec rẹ̀ ni ọdun 1972 ní ọdun 1976 ó gba àmì-ẹyẹ diploma in law ní yunifásítì àmọ́dù béllò ti zaria ní ọdun 1980 àti àmì-ẹyẹ llb hons ní ilé-ìwé kan náà aji bẹ̀rẹ̀ isẹ́ òfin ní ọdun 1981 ìdílé rẹ̀ uwani fẹ́ musa abba-aji àwọn méjèèjì sì bí ọmọ mẹ́ta musa jẹ́ ọ̀gá àgbà borno state civil service tẹ́lẹ̀ rí uwani ní àwọn nnkan tí òun féràn láti ma se ni kí kàwé kí kọ̀wé kí òun máa rin ìrìn-àjò àti kí ó máa tọjú ọgbà
|
fadima murtala aminu fadima murtala aminu jẹ́ ọmọbìnrin tí a bí ní ọjọ́ ógbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 1968 ní zaria ìpínlẹ̀ kaduna ní ilẹ̀ nàìjíríà ó jẹ́ adájọ́ pẹ̀lú ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà
|
toyin bolaji adegoke toyin bolaji adegoke tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún osù ògún ọdún 1964 jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdẹ̀ nàìjíríà ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ní wọ́n bí í sí èkọ́ ó ka ìwé mẹ́wàá rẹ̀ tán ní ojuku grammar school ní ọdún ní ọdún 1981 ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní fásítì maiduguri ní ìpínlẹ̀ maiduguri lọ́dún 1987 láti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì english
|
modupe omo-eboh modupe omo-eboh ọdun 1922 ọjọ́ karúndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdun 2002 jẹ́ agbẹjọ́rò ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti ọ̀jọ̀gbọ́n amòfin tí ó jẹ́ adájọ́bìnrin àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè náà ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ wọ́n bí modupe akingbehin sí ìpínlẹ̀ èkó ní ọdún 1922 ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ-ọmọbìnrin oshodi tapa gbajúgbajà l'èkó àti ọmọọmọ-ọmọbìnrin ti bishop samuel ajayi crowther tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ àwọn ọmọ ọba abiodun ti ọ̀yọ́ herbert macaulay ni arákùnrin ìyá rẹ̀ ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ queen's college ti èkó kí ó tó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀-òfin ní ìlú-ọba
|
nkemdilim izuako nigerian judgenkemdilim amelia izuako jẹ́ adájọ́-bìnrin ti orilẹ̀-èdè nàìjíríà láti ọdún 2009 ó ti wà lára ọ̀kan lára àwọn adájọ́ mẹ́ta àkọ́kọ́ ní united nations dispute tribunal undt ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ izuako gba kẹ́kọ̀ọ́ níoa òfin ó sì gba ìwé-ẹ̀rí ẹ̀kọ́ náà ní obafemi awolowo university ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ìmọ̀-òfin ní nnamdi azikiwe university àti gambia technical institute iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi adájọ́ izuako di adájọ́ ní ọdún 1998 nígbà tí wọ́n yàn án sí ilé-ẹjọ́ ti ipinle anambra wọ́n padà yàn án sí ilé-ẹjọ́ gíga ti orílẹ̀-èdè naijiria ó sì sìn níbẹ̀ títí di ọdún 2003 láti ọdún 2004 wọ 2006 ó sìn gẹ́gẹ́ bíi adájọ́ ní ilẹ́-ẹjọ́ gíga àti ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti orílẹ̀-èdè gambia ní ọdún 2006 wọ́n yàn án sí high court of solomon islands òun sì ni adájọ́bìnrin àkọ́kọ́ tí wọ́n máa kọ́kọ́ yàn sí ilé-ẹjọ́ solomon islands
|
modupe omo-edeh
|
kelvin katey carboo kelvin katey carboo tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹta oṣù ẹrẹ́nà ọdún 2000 ó jẹ́ eléré ìdárayá bọ́ọlù àláfọwọ́gbá volleyball tẹ́lẹ̀ ní orílẹ̀-èdè ghana ìgbèsi ayè ati iṣẹ́ rẹ̀ wọ́n bí carboo ní ìlú accra ní orílẹ̀-èdè ghana ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹta oṣù ẹrẹ́nà ọdún 2000 carboo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gégẹ́ bíi eléré-ìdárayá volleyball ní ọdún 2017 nígbà tí ó kopa nínú eré volleyball àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ nínú ìdíje commonwealth pẹ̀lú akin ẹgbé rẹ̀ eric tsatsu tí wọ́n sì gbé ipò kẹrin nínú ìdíje náà ni óṣu keje ọdun 2018 elere naa kopa ninu ere awon ọdọ ilẹ afirica to waye ni ilẹ algeria ni óṣu kẹfà ọdun 2019 arakunrin naa kopa ninu ere eti odo akọkọ ilẹ afirica pẹlu akin ẹgbẹ rẹ essilfie samuel tetteh ti wọn si gba ipó kèji ni óṣu kiniọdun 2020 elere naa kopa ninu ìfe tí cavb cavb cup ni ilẹ accra pẹlu akin ẹgbẹ rẹ essilfie nibi ti wọn ti gbègba órokè ṣe ipó akọkọ
|
lahcen ahidous moroccan boxer lahcen ahidous ni a bini ọjọ kẹtalaóṣu april ọdun 1945 jẹ̀ afẹṣẹja órilẹ ede morocco àṣèyọri lahcen kopa ninu olympics ti summer ni ọdun 1964 ati 1968
|
àtòjọ àwọn adájọ́bìnrin ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà àwọn adájọ́bìnrin ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà ni
|
kudirat abíọ́lá
|
morenike olasumbo obadina morẹ́nikéjì ọlásùḿbọ̀ ọbádínà tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kẹwàá ọdún 1963 jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ìjọba-ìpínlẹ̀ èkó tí ó wà ní igbóṣeré ní nigeria ìjọba ìpínlẹ̀ èkó yàn án gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lọ́dún 2001
|
hadiza rabiu shagari hadiza dawaiya shagari tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí hadiza shehu shagari ọdun 1940/41 ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ ọdun 2021 jẹ́ gbajúmọ̀ ènìyàn obìnrin àkọ́kọ́ ilẹ̀ nàìjíríà láàrin 1979 to 1983 àti ìyàwó shehu shagari nígbà tí àwọn méjèèjì wà láyé òun àti àwọn ìyàwó shagari tó kù jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ ilẹ̀ nàìjíríà nígbà tí shagari jẹ́ ààrẹ ilẹ̀ nàìjíríà láàrin ọjọ́ kínní oṣù kẹ̀wá ọdun 1979 sí ọjọ́ kanlélógbòn oṣù kejìlá ọdun 1983 ìtàn ayé rẹ̀ hadiza dawaiya pàdé ọkọ rẹ̀ shehu shagari ní ìpínlẹ̀ sókótó wọ́n fẹ́ ara wọn ní ọdun 1957 hadiza shagari kú nítorí ààrùn covid-19 ní gwagwalada abuja ní ago mẹ́ta àárò ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ ọdun 2021 ó jẹ́ ọmọ ọdún ọgọrin ìsìn kún rẹ̀ wáyé ní abuja national mosque ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ ni ago merin ọ̀sán ọkọ rẹ̀ ààrẹ tẹ́lẹ̀rí shehu shagari fi ayé sílè ní ọdun 2018
|
mustapha adnane moroccan weightlifter mustapha adnane ni a bini ọdun 1931 to si ku ni ọjọ keji dinlọgbọn óṣu april ọdun 2006 jẹ àdánù gbigbe ti órilẹ ede morroco àṣèyọri mustapha kopa ninu olympics summer ti ọdun 1960 ati 1964
|
vivian yusuf nigerian olympic judoka vivian aminu yusuf ni a bini ọjọ kẹjọ óṣu kẹjọogún ni ọdun 1983 ó jẹ ọkan ninu awọn óbinrin to kopa ninu ere judo ni órilẹ ede naijiria ninu abala idaji heavyweight àṣèyọri vivian gba ami ọla ti idẹ ni ere ti gbogbo ilẹ afirica ni ọdun 2007 to waye ni algiers ati idije judo ti ilẹ afirica ni ọdun 2008 to waye ni agadir morocco vivian kopa ninu ere olympics ti summer nibi ti arabinrin naa ti ṣóju naigiria ninu xxix olympiad ni beijing china nibi to ti kopa ninu idaji heavyweight 78kg
|
ijeoma lucia ojukwu ijeoma lucia ojukwu jẹ́ ọmọbìnrin tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejìlá ọdún 1966 ní kaduna ní ilẹ̀ nàìjíríà ó kọ́kọ́ gba satífíkéètì òye waec àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1985 ó jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó wá láti ìpínlẹ̀ abia ayé rẹ̀ arábìnrin náà wá láti akuma ní ìjọba ìbílẹ̀ ìwọ̀-oòrùn oru ní ìpínlẹ̀ imo ó sì tì jẹ́ ìyàwó pẹ̀lú ọ̀jọ̀gbọ́n ernest ojukwu san tí ó jẹ́ ọmọ ìlú isuikwuato ní ìpínlẹ̀ abia ó sì ti bímọ márùn-ún ìrìn àjò iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ onídájọ́ ojukwu gbajúgbajà fún bí ó ṣe ṣe ìtọ́jú ẹjọ́ omoyele sowore akòròyìn nàìjíríà àti àpéjọ #revolutionnow àti olùjẹ́jọ́ rẹ̀ olawale bakare ṣe olórí ilé-ẹjọ́ 5 ní agbègbè abuja ti ilé-ẹjọ́ náà a pè é sí ẹgbẹ́ adájọ́ bar ní ọdún 1990 àti pé ó ní òye másítà ní òfin llm ìrìn-àjò rẹ̀ lórí ibùjókòó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú yíyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alákoso àgbà kejì ní ilé-ìgbìmọ̀ ìdájọ́ ìpínlẹ̀ kan ní oṣù kẹfà ọdún 1996 níbití ó ti ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn ipò títí di oṣù kìíní ọdún 2006 nígbà tí a yàn-án ní olóyè mágísíréètì ìtẹ kìíní
|
zainab bage abubakar zainab bage abubakar jẹ́ adájọ́ ní ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà wọ́n bí i ní ọjọ́ ọ̀kàn-dín-lógún oṣù kọkànlá ọdún 1964 ní zuru ní ìlú kebbi
|
joyce obehi abdulmalik hon justice joyce obehi abdulmalik jẹ́ adájọ́ ní ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà a bí i ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù keje ọdún 1968 ní london ní ilẹ̀ united kingdom ó jẹ́ ọmọ ìwọ̀-oòrùn esan ní ìpínlẹ̀ edo
|
dorcas venenge agishi dorcas venenge agishi tí a bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹrin ọdún 1961 jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà a bí i ní wukari ní ìlú taraba ó wá láti ìpínlẹ̀ benue àti pé ó jẹ́ ìyàwó sí solomon agishi tí ó wá jẹ́ ọkọ rẹ̀
|
beni lar beni lar tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ ọdun 1967 jẹ́ olóṣèlú ọmọ ẹgbẹ́ people's democratic party láti ìpínlẹ̀ plateau nàìjíríà ó jẹ́ asojú ìkọ̀ langtang north àti langtang south ti ìpínlẹ̀ plateau ní ilé ìgbìmò asofin kékeré a kọ́kọ́ yán sí ipò náà ní 2007 wọ́n sì tún dìbò yán ni ọdun 2019 fún sáà kẹrin ní ipò náà ìtàn ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ òun ni ọmọbìnrin àkọ́kọ́ solomon lar gómínà ìpínlẹ̀ plateau tẹ́lẹ̀rí àti ọ̀jọ̀gbọ́n mary lar beni wípé “bàbá mi kọ́ mi pé kò sí ìyàtọ̀ láàrin ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ó kó mi láti jẹ́ onísẹ́ takuntakun nítorí náà mo gbìyànjú láti jẹ́ agbẹjọ́rò bi bàbá mi ó gba àwọn ọmọ nàìjíríà níyànjú láti má gbàgbé isẹ́ takuntakun tí bàbá rẹ̀ se láti mú ìsokan àlàáfíà àti ìfẹ́ wà ó ní pe àwọn nkan yìí jẹ́ àwọn ǹkan tí ó se pàtàkì láti mú kí nàìjíríà tẹ̀ síwájú ní ọdun 2007 a dìbò yán sí ilé ìgbìmò aṣòfin kékeré ní ọdun 2008 ilé ìgbìmò asòfin yàn gẹ́gẹ́ bi alága ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kékeré lórí ọ̀rọ̀ obìnrinítí di oṣù keje 2014 update ó jẹ́ asojú ikọ̀ langtang north àti south ó tún jẹ́ alága ilé ìgbìmò aṣòfin lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ènìyàn ó fọwọ́ sí fífi owó ran ààjọ national agency for the prohibition of trafficking in persons naptip lọ́wọ́ fífi owó líle òfin mú àwọn tí ó ń bá ọmọdé ṣe ǹkan àìtó àti dídá ààjọ national child protection and enforcement agency kalẹ̀
|
abdelhak achik moroccan boxer abdelhak achik tí a bí ní ọjọ́ kọkànlá osù kẹta ọdun 1959 jẹ́ afẹ̀ṣẹ́jà órilẹ̀-èdè morocco ìgbà kan rí afẹ̀sẹ́jà náà gba àmì ọlá ti idẹ ní olympic tí summer tó wáyé ní seoul àṣeyọrí abdelhak kópa ninu ére olympic ti ọdun 1988ótoáyé eíni seoulíni round 64 32 16 quarterfinaà ati semifinalíni ií ó o ti gbàmì i ála ti idẹ
|
ezzaki badou moroccan footballer born 1959 ezzaki badou ni a bini ọjọ keji óṣu kerin april ọdun 1959 ti inagijẹ rẹ njẹ zaki jẹ a-ko-ni-mo-o-gba coach ere bọọlu alafẹsẹgba ati elere tẹlẹ ri to ṣèrè gẹgẹbi asole goalkeeper órilẹ ede morocco iṣẹ ezzaki ezzaki ṣoju as salè wydad ac rcd mallorca ati fath union gẹgẹbi elere bọọlu alafẹsẹgba arakunrin naa kopa ninu ife eye ere bolu orile-ede agbaye ti a mo si fifa cup ti ọdun 1986 ati ife eye orile-ede afirica ti a mo si african cup of nation leemẹrin àṣèyọri ni ọdun 1986 ezzaki ni a ọ ni elere bọọlu afẹsẹgba ti ilẹ afirica lẹyin naa ni elere naa yege ninu la liga ni ọdun 1989 nibi to ti gba ife ẹyẹ ti ricardo zamora ezzaki gba elere to pegede julọ ni órilẹ ede morocco ni ọdun 1979 1981 1986 ati 1988 ni ọdun 1986 ezzaki jẹ elere bọọlu afẹsẹgba caf ti ilẹ afirica ni ọdun 2017 badou jẹ coach to pegede julọ ni ilu algeria
|
catherine obianuju acholonu catherine obianuju acholonu tí a bí ní ọjọ́ kẹrindínlógún oṣù kẹ̀wá ọdun 1951 ọjọ́ méjìdínlógún oṣù kẹta ọdun 2014 jẹ́ olùkọ̀wé olóṣèlú àti ajàfẹ́to ẹni ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni senior special adviser ssa sí ààrẹ olusegun obasanjo lórí ọ̀rọ̀ àwòrán àti àsà ó sì tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ association of nigerian authors ana ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí catherine sínú ìdílé chief lazarus emejuru olumba àti josephine olumba ní umuokwara village ti ìlú orlu òun ni àkọ́bí nínú àwọn ọmọ mẹ́rin ó parí ẹ̀kọ́ primari àti sẹ́kọ́ndìrì rẹ̀ ní ilé-ìwé holy rosary school kí wón tó fe fún brendan douglas acholonu nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún douglas jẹ́ onísẹ́ abẹ orílẹ̀-èdè jẹ́mánì sì ló kalẹ̀ sí nígbà náà ní ọdun 1974 catherine tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní yunifásítì ti düsseldorf ó sì kékọ̀ọ́ gboyè ní ilé-ìwé náà lodun 1977 ní ọdun 1982 ó gba àmì-èye phd nínú ìmò èdè igbo ikú rẹ̀ acholonu fi ayé sílè ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta 2014 ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógota nígbà náà ó kú látàrí àìsàn kíndìnrín
|
bilkisu yusuf nigerian journalist bilkisu yusuf tí àwọn ènìyàn tún mọ̀ sí hajiya bilkisu yusuf ọjọ́ kejì oṣù kejìlá ọdun 1952 ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn 2015 jé oníròyìn àti akọròyìn fún àwọn ilé ìròyìn tó gbajúmọ̀ ní abuja kano àti kaduna ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà bilkisu jẹ́ ẹ̀yà ọmọ yorùbá máa mọ́ hausa mùsùlùmí àti ajàfẹ́tọ́ obìnrin òun ni ó ń gba ààrẹ ní ìmọ̀ràn lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó bá pa nàìjíríà papọ̀ mọ́ òkè òkun àti nípa dídá àwọn ààjọ tí kò sí lábé ìdarí ìjọba kalẹ̀ àwọn ààjọ bi women in nigeria win àti the federation of muslim women's association fomwan yusuf fi ayé sílè látàrí ìtẹ̀pa 2015 mina stampede nígbà tí ó wà ní haj ní mecca saudi arabia
|
folashade adekeko adesiyan olubanjo adájọ àgbà ní orílé èdè nàìjíríà chief magistrate folashade adekoke adesiyan olubanjo ọjọ́ ìbí jé ojọ́ kejì osù keje ọdún 1968 jẹ́ adájọ àgbà tí wọn bí sí ìpínlè katsina ní orílé èdè nàìjíríà tí ó sì ṣe ìsìn fún ìjọba láti ọọ́ kíni oṣù kẹjọ odun 2003 tí di ọdún 2009 ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀ ìgbé ayé folashade tí wón bí sí ìlú katsina jẹ́ ọmo ìpínlè oyo ti ó lọ sí ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ tí fásitì ibadan tí wọn pè ní university of ibadan senior staff school ní ọdún 1972 sí 1978 tí ó sì lọ sí ilé ìwé sẹ́kọ́ńdírì queen's school ní àpáta ní ìlú ìbàdàn ní ọdún 1978 sí ọdún 1983 lẹyìn tí ó kúrò ní 1983 ní queen's school ní ó ṣe bẹ́ẹ̀ ó lọ sí international school tí fásitì ìlú ìbàdàn ní ọdún 1983 sí ọdún 1985 folashade kàwé gboyẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga lórí iṣẹ òfin ní fásitì ìlú ìbàdàn ní 1985 sí 1988 bi kò sàì máa lọ sí nigerian law school tí ó wà ní victoria island ní ìlú èkó láti 1988 sí 1989 iṣé folashade jẹ́ agbẹjọro ati barrister nínú ofin tí ó sì gboyè 2nd class upper pẹlu oyè ọlá division honours ni ọdún 1989 èyí tí ó sì bẹrẹ sí ní ṣíṣe ní odún 1990 ní ọdún 1990 oṣù kejì ọdún náà sì oṣù kẹjọ náà ni ọ fí jẹ́ ìrànlọ́wọ́ sí òṣìṣẹ́ amòfin kàn ní ilé ifówopámọ́sí afribank ni orílé èdè nàìjíríà ó jẹ́ oluṣakoso òṣìṣẹ́ nípa òfin fún ilé iṣé epiwit consulting limited ní ìlú ìbàdàn láti oṣù kẹfà ọdún 1991 sí oṣù tí ó gbèyìn ọdún náà ní oṣù kọkànlá ọdún 1993 o jẹ́ alábojútó ilé iṣé durtie holdings limited ní ìlú ìbàdàn tí tí dì oṣù kẹsán ọdún 1996 lẹyìn èyí ni oníṣe òfin legal officer láti ọdún 1997 sí oṣù kàrún-un ọdún 2003 folashade ń ṣiṣẹ gẹgẹbi alakoso agba àbojúto fún ilé igbìmọ̀ ìdájọ ti ìpínlè óyo láti ọdún 2003 ọjọ́ kinní oṣù kẹjọ tí tí ó fí dì adájọ àgbà chief magistrate grade ii
|
mustapha el biyaz moroccan footballer mustapha el-biyaz ni a bini ọjọ kejila óṣu february ni ọdun 1960 ni taza jẹ elere bọọlu afẹsẹgba defender ti órilẹ ede morocco to ti fi ẹhinti el biyaz ṣèrè fun club kac marrakech ninu botola àṣèyọri biyaz kopa ninu olympic summer ti ọdun 1984 ati cup fifa àgbayè ti ọdun 1986 ni ọdun 2006 caf yan mustapha gẹgẹbi ọkan lara awọn igba elere bọọlu afẹsẹgba to dara ju ni ilẹ afirica lati adọta ọdun sẹyin
|
aziz bouderbala moroccan footballer abdelaziz el idrissi bouderbala ni a bini ọjọ kẹrin din lọgbọn óṣu december ni ọdun 1960 jẹ elere bọọlu afẹsẹgba nigba kan ri ni ọdun 2006 elere naa jẹ okan lara awọn igba elere bọọlu afẹsẹgba to dara ju ni ilẹ afirica ti caf yan fun adọta ọdun sẹyin iṣẹ elere naa ati àṣèyọri aziz bẹrẹ iṣẹ rẹ gẹgẹbi àkọṣẹ mọṣẹ elere bọọlu afẹsẹgba ni wydad casablanca kotodipè o lọ si fc sionmatra racing ati french olympique lyon ni ọdun 1986 bouderbala gba ami ẹyẹ gẹgẹbi elere bọọlu afẹsẹgba ti ọdun naa ni ọdun 1986 arakunrin naa ṣèrè ni cup finals agabaye ti fifa ni ọdun 1988 aziz jẹ elere bọọlu afẹsẹgba to dara ju ninu cup nations ti ilẹ afirica ni ọdun 2015 aziz jẹ aṣoju fun satuc cup eleyi lo jẹ idije tutun lori bọọlu afẹsẹgba fun awọn ọmọ órukan u16 ọmọ alaina ati atọrọjẹ
|
felicity okpete ovai felicity okpete ovai tí a bí ní 1961 jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọengineer àti ọ̀mọ̀wé láti degema ti ìpínlè rivers nàìjíríà ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ rivers state people's democratic party òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí a yàn sípò kọmíṣọ́nà fún iṣẹ́ ó dipò náà mú láàrin ọdun 2003 sí 2006
|
noureddine bouyahyaoui moroccan football defender noureddine bouyahiaoui ni èdè larubawa نور الدين البويحياوي ni a bini ọjọ keje óṣu january ọdun 1955 jẹ agbabọọlu afẹsẹgba to ṣèrè gẹgẹbi defender fun órilẹ ede morocco àṣèyọri elere naa ṣèrè fun kac kenitra ni ọdun 1986 noureddine kopa ninu cup agbaye ti fifa
|
mustapha fadli moroccan boxer mustapha fadli jẹ afẹṣẹja ti órilẹ ede morocco fadli kopa ninu idije awọn ọkunrin omi ara to fuyẹmen's lightweight ni summer olympic to waye ni ọdun 1984
|
mustafa el haddaoui moroccan footballer mustafa el haddaoui ni ede larubawa مصطفى الحداوي ni a bini ọjọ keji dinlọgbọn óṣu july ni ọdun 1961 ni ilu casablanca jẹ akọṣẹmọṣẹ agbabọọlu afẹsẹgba to ti fi ẹyinti àṣèyọri mustapha lo ọpọlọpọ igba rẹ gẹgẹbi àkọṣẹmọṣẹ agbabọọlu afẹsẹgba ni ilu france arakunrin naa wa lara awọn elere to kopa ninu cup fifa agbaye to waye ti ọdun 1986 ati 1994 mustapha dije ninu olympic ti summer nibi to ti ṣoju fun órilẹ ede morocco ni ọdun 1984
|
comfort ekpo comfort ekpo tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kọkànlá ọdun 1954 jẹ́ ọ̀mọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó ti fi ìgbàkan jẹ́ adarí yunifásitì ìlú uyo ìtàn ayé rẹ̀ wọ́n bí comfort memfin ekpo ní uyo ní ọdun 1954 àwọn òbí rẹ̀ ni etim udoh isok àti nyong sam akpan comfort ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi olùkọ́ sunday school teacher àti gẹ́gẹ́ bi ẹni tí ó ń ran olùkó lọ́wọ́ ní yunifásítì ìpínlè cross river láàrin ọdun 1983 sí 1991 ekpo ti fi ìgbàkan jẹ́ adarí yunifásítì ìlú uyo òun ni obìnrin àkọ́kọ́ láti di ipò adarí yunifásitì náà mú ní oṣù kejìlá ọdun 2015 wọ́n yan ọ̀jọ̀gbọ́n enefiok essien láti rọ́pò rẹ̀ ṣùgbọ́n ó kọ̀wé sí mínísítà ètò ẹ̀kọ́ adamu adamu láti mú ìfàsẹ́yìn bá àbá láti yàn sípò náà ó kọ̀wé yìí látàrí èsùn ìbáni ṣe ìranù àtilèsùn yí yí ìwé tíeàwọn oníròyìn fi sun essienthe press
|
zaynab alkali zaynab alkali tí a bí ní ọdún 1950 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí wọ́n sínú ìdílé tura-mazila ní ìpínlẹ̀ bọ̀rnó ó lọ ilé-ìwé queen elizabeth secondary school ti ìlú ilorin kí ó tó tẹ̀síwájú ní yunifásítì àmọ́dù béllò abu zaria àti ní yunifásítì bayero ti kano buk láti gba àmì-ẹ̀yẹ dokitaphd nínú ìmò inglisi ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí alkali ní tura-wazila ní ìpínlẹ̀ borno ní ọdun 1950 ó kàwé gboyè ní yunifásítì báyéró ti ìpínlẹ̀ kano pẹ̀lú àmì-ẹ̀yẹ ba ní ọdún 1973 ó gba àmì-ẹ̀yẹ dókítá nínú ìmò nípa ilẹ̀ áfríkà ní yunifásitì kan náà kí ó tó padà di adarí ilé-ìwé shekara girls' boarding school ó padà di olùkọ́ni nínú ìmọ̀ èdè inglisi ní àwọn yunifásitì méjì ní nàìjíríà
|
juice wrld american rapper singer and songwriter 19982019 jarad anthony higgins tí wọ́n bí ní 2 1998 tí ó sì kú ní december 8 2019 tí orúkọ ìnágijẹ rẹ̀ ń jẹ́ juice wrld tí kíkọ sílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ juice world jẹ́ ọmọọmọ olórin ilẹ̀ ìlú america àti akọrin sílẹ̀ ó jẹ́ aṣíwájú fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ emo rap àti soundcloud rap soundcloud rap and genres léyìí tí ó kó ọkàn àwọn ènìyàn ní àárín ọdún 2010 orúkọ eré ìtàgé tí ó jẹ́ ṣíṣe olórí ilé ayé tí ó jẹ́ jáde láti inú eré sinimá àgbéléwò crime thriller film juice 1992
|
labid khalifa moroccan footballer labid khalifa tí a bí ní ọjọ́ àkọ́kọ́ óṣu kìíní ọdún 1955 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tó jẹ́ defender fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè morocco àṣèyọri labid ṣerè fun kac kenitra arákùnrin náà ṣerè fún orílẹ̀-èdè morocco ní cup fifa agbayè ti ọdún 1986
|
abdelmajid lamriss moroccan footballer abdelmajid lamriss tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejì ọdún 1959 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tó jẹ́ defender fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè morocco àṣèyọri abdelmajid ṣeré fún far rabat eléré náà ṣeré fún cup fifa àgbáyé ní ọdún 1986
|
safia abdul rahman safia abdul rahman tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù karùn-ún ọdún 1986 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti àwọn obìnrin ti ilẹ̀ ghana kan tí ó ń mú iwájú fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá àwọn obìnrin ti orílẹ̀-èdè ghana ó díje nínú ìdíje fifa women's world cup ti ọdún 2007 ní ìpele ẹgbẹ́ ó ṣeré fún ghatel ladies ní ghana
|
kulu yahaya kulu yahaya tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlélógún osù kaàrún ọdún 1976 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti orílẹ̀-ède ghana tí ó gbá bọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí olùgbèjà fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti obìnrin ghana ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó kópa ní bi fifa world cup women's world cup ti ọdún 1999 lórí ìpele ẹgbẹ́ ó ṣeré fún ashiaman ladies ní ghana
|
sherifatu sumaila sherifatu sumaila tí a bí ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kọkànlá ọdún 1996 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá agbabọọlu ọmọ orílẹ̀-ède ghana kan tí ó ń ṣeré bíi agbábọ́ọ̀lù ìkọlù olùgbèjà àti olùkọlù fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù primera federación spanish rayo vallecano ó ṣeré tẹ́lẹ̀ fún djurgårdens if fotboll àwọn obìnrin ó tún jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ́ bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ti àwọn obìnrin united united states la galaxy orange county sherifatu jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àwọn obìnrin ti orílẹ̀-ède ghana black queens ẹ̀kọ́ sherifatu jáde ní ilé-ìwé gíga feather river community ní quincy california
|
suzzy teye suzzy dede teye tí a bí ní ọjọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ọdún 2002 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-ède ghana kan tí ó dúró bí alárinà ní orí pápá fún hatayspor ní super league ti turkey àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin ghana isé ẹgbẹ́ teye gbábọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù premier league women's ghana lady strikers fc ní ọdún 2021 wọ́n fún ní orúkọ “player of the month february” ní oṣù kẹẹ̀wá ọdún 2022 ó kó lọ sí turkey ó sì buwọ́ lùwé pẹ̀lú hatayspor láti gbábọ́ọ̀lù ní 202223 sper league isé òkè-òkun wọ́n gba teye wọlé sínú ẹgbẹ́ u-17 àwọn ọmọbìrin ghana láti ṣe eré ní bi 2018 african u-17 women's world cup qualifying tournament àti 2018 fifa u-17 women's world cup ó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ ti u-20 ti obìnrin ghana ní bi fifa u-20 world cup women ti ọdún 2022 ó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ àwọn obìnrin ti orílẹ̀-ède ghana àwọn ìtọ́kasí ẹ̀kaàwọn ènìyàn alààyè ẹ̀kaàwọn ọjọ́ìbí ní 2002
|
faiza ibrahim faiza ibrahim tí a bí ní ọjọ kejìlélógún oṣù kẹta ọdún 1990 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti orílẹ̀-èdè ghana ó gbá bọ́ọ̀lù ní ipò iwájú ó mi àwọ̀n ní bi ayò mẹ́ta sí òdo pẹ̀lú mali ní bi ìdíje àwọn obìrin afirika ti ọdún 2012 ó mi àwọ̀n ní bi ayò mẹ́ta sí òdo pẹ̀lú etiopia ní bi ìdíje àwọn obìrin afirika ti ọdún 2014 ó wà nínú ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lù ghana fún ìdíje àwọn obìnrin fún ọdún 2014 ó kúrò nínú ẹgbẹ́ ti ilẹ̀ ghana ní oṣù keje ọdún 2015 nítorí pé ó ní ìpalára ó wà nínú àwọn tí ó kópa ní ghana fún àwọn eré afirika ti ọdún 2015
|
rumanatu tahiru rumanatu tahiru tí a bí ní ọjọ kẹrin osù kẹfà ọdún 1984 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gba ọmọ orílẹ̀-ède ghana tí ó seré lókè-òkun tí ó mú ipò iwájú lórí pápá ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àwọn obìrin orílẹ̀-ède ghana ó wà lára àwọn tí ó kópa ní bi fifa women's world cup ti ọdún 2007 lórí ìpele ẹgbẹ́ ó ṣeré fún athleta ladies ní ghana
|
ayo ayoola-amale ayo ayoola-amale jẹ́ akéwì àti agbẹjọ́rò ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bí ayo ayoola-amale sí ìlú jos nàìjíríà ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ peace movement nígbà tí ó sì jẹ́ ọmọdé ó sì di adarí ẹgbẹ rotaract club àti girls guide nígbà tí ó sì jé ọ̀dọ́ ọmọbìnrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ obìnrin tí wọ́n dá kalẹ̀ nígbà náà jẹ́ ẹgbẹ́ tí wọ́n dá kalẹ̀ láti takò rírẹ́ àwọn obìnrin jẹ àti láti tako àwọn ìwà àìtọ́ míràn sí obìnrin ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ rotary club àti women in nigeriawin bàbá rẹ̀ ẹni tí ó kàwé gboyè ní yunifásitì ti london jẹ́ agbẹjọ́rò àti òṣìṣẹ́ elétò àbọ̀ national security adviser ẹni tí ó ń gba igbá kejì ààrẹ ní ìyànjú lórí ọ̀rọ̀ ètò àbò àti alága state security service ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹyẹ pẹ̀lú àwọn ẹyẹ míràn láti orílẹ̀-èdè amerika ìyá ayo jẹ́ ọmọ ọba iṣẹ́ òwò sì ni ó ń ṣe ó lọ ilé ìwé st louis secondary school bompai ní ìpínlè kano fún ẹ̀kọ́ primari rẹ̀ ó padà kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmò òfin ní yunifásítì ọbáfẹ́mi awolowo wọ́n sì pé sínú iṣẹ́ òfin ní 1993 ó padà tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní yunifásitì ìlú èkó àti yunifásitì ti ghana
|
elvan abeylegesse ethiopian-born long-distance runner for turkey elvan abeylegesse tó fìgbà kan jẹ́ hewan abeye አልቫን አበይለገሠ ní èdè amharic àti elvan can ní orílẹ̀-èdè turkey ni a bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù september ní ọdún 1982 jẹ́ eléré ìdárayá tó máa ń sáré ọlọ́nà jínjìn ta bí sí orílẹ̀-èdè ethiopia arábìnrin náà ti kópa nínú eré ìdíje ti marathon fún 1500 metres ìgbésí ayé eléré ìdárayá náà abeylegesse ni a bí sí addis ababa ethiopia ní ọdún 2011 oṣù february elvan fẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ ìgbà pípẹ́ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ semeneh debelie ní ọdún 2011 oṣù july arábìnrin náà bímọ obìnrin tí wọ́n sọ ni arsema àṣeyọrí ní ọdún 1999 elvan kópa nínú ìdíje iaff cross ti àgbáyé fún àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ ti ilẹ̀ ethiopia ní belfast northern ireland níbi tó ti parí pẹ̀lú ipò kẹsàn-án ní eré ti evergood bergen bislett games tó wáyé ní norway oṣù june ní ọdún 2004 abeylegesse yege nínú record àgbáyé àwọn obìnrin ti 5000m ní ọdún 2010 abeylegesse gba wúrà ní marathon ti 10000m nínú ìdíje ti eré-ìdárayá ti orílẹ̀-èdè ethiopia níbi tí arábìnrin náà ti parí pẹ̀lú ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lé ní ẹyọ̀kan ìṣẹ́jú àáyá ti 1023
|
arinola olasumbo sanya arinola olasumbo sanya tí a bí ní ọdun 1953 jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní yunifásítì ìlú ìbàdàn àti kọmíṣọ́nà fún ètò-ìlera ara ti ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ orílẹ̀-èdè nàìjíríà arinola di òjògbón ní ọdun 2000 èyí tí ó sọ di obìnrin àkọ́kọ́ láti di ọ̀jọ̀gbón nínú bí a ṣe ń dá isẹ́ ara bọ̀ sípò physiotherapy ní orílẹ̀ afrika àti obìnrin àkọ́kọ́ láti di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmò physiotherapy ní nàìjíríà ó wà lára àwọn ẹni iyì ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ arinola ni igbá kejì adarí yunifásítì ìlú ìbàdàn arinola bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ní salvation army primary school ní surulere ti ìpínlẹ̀ èkó ó tẹ̀síwájú ní queens college yaba ìpínlè èkó níbi tí wọ́n ti fi joyè head girl ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmò physiotherapy ní yunifásítì ìlú ìbàdàn ìsìn ìjọba arinola di kọmíṣọ́nà fún ètò-ìlera ara ti ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní ọdun 2005 ìdílé ọkọ ọ̀jọ̀gbọ́n sanya ní dr yemi sanya onímọ̀ ọ̀gùn òyìnbó àti oníṣòwò ní ìpínlẹ̀ èkó nàìjíríà wọ́n ní ọmọ mẹrin
|
ejgayehu taye ethiopian athlete ejgayehu taye ni a bini ọjọ kẹwa óṣu february ọdun 2000 jẹ elere idaraya ti ọna jinjin ti órilẹ ede ethiopia taye naa gba ami ọla ti idẹ fun 3000 metres ti idije agbaye ti inu ilè to waye ni ọdun 2022 àṣèyọri ni óṣu july ọdun 2018 ejgayehu taye gba ami ọla ti ninu idije u20 iaaf agbaye ti 5000 metres ni ọdun 2019 taye gbe ipo karun ninu ere ilẹ afirica ti 5000m
|
samuel adesina gbadebo alake of abeokuta samuel adesina gbadebo èyí tí a tún mọ̀ sí gbadebo ii jẹ́ ọba ní orílẹ̀-èdè naijiria tí ó di oyè aláké ti ìlú ẹ̀gbá mú ṣáájú kí ó tó di alake gbadebo ṣe àwọn ètò ní ìwọ̀-oòrùn nàìjíríà láti polongo iṣẹ́ àgbẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ a bí gbadebo ní oṣù kẹsàn-án odun 1908 sí ìdílé oba gbadebo i àti esther omolara ó lọ ilé ìwé girama ní abeokuta ó di ọ̀jọ̀gbọ́n láàrin egba native authority níbi tí ó ti ní àǹfààní láti ṣíṣe pẹ̀lú alake ladapo ademola eni tí ó ní fẹ́ sí isẹ́ rẹ̀ lẹ́hìn náà ó darapọ̀ mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ti ilẹ́-iṣẹ́ railway nigeria gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé ó tún ṣiṣẹ́ ní ojú-irin àgbègbè ìlà-oòrùn àti ìwọ-oòrùn nàìjíríà ní ọdun1936 ó padà sí abeokuta ó ń síse pẹ̀lú awon aláṣẹ egbaegba native authority ó kó ẹ̀kọ́ nínú ìmò igbóforestry ní ìbàdàn ó si di olórí àwọn tí ń rí sí ọ̀rọ̀ igbó ní egba láàrin ọdun 1954 sí 1955 ó kẹ́kọ̀ọ́ ní british foresty commission nígbàtí ó padà sí nàìjíríà ó ṣiṣẹ́ fún àgbègbè ìwọ-oòrùn nàìjíríà ní ṣíṣe ìfihàn iṣẹ́-ọ̀gbìn ní ọdun 1963 wọ́n fi jẹ òye alake ti ilẹ̀ egba léyìn ìgbà tí ó dé ipò yí ó dá ìgbìmò ìdámọ̀ràn kalẹ̀ ní agbègbè mẹ́rin abeokuta ake gbagura oke-ona àti owu àwọn ìgbìmò náà a ma fi ìpinu wọn ránṣẹ́ sí ìgbìmọ̀ agbegbe abeokuta bákan náà ni ó gbé ìgbìmọ̀ ìsọ̀kan kan dide láti ṣàkóso àwọn ọ̀ràn ti ìgbìmọ̀ agbegbe ó sowọ́pọ̀ pẹ̀lú egbé nna akintola nígbà tí wàhálà òsèlú ṣẹlẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn ní láàrin ọdun 1964 sí 1966 ó sì fẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún àtìlẹ́yìn wọn fún ilẹ̀ egba ọdun 1971 ló papòdà oba lipede ni ó rọ́pò rẹ̀ òun jẹ àbúrò ọ̀kan lára àwọn òbí oba gbadebo iii
|
serkalem biset abrha serkalem biset abrha ni a bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù march ọdún 1987 arábìnrin náà jẹ́ asáré tó wá láti orílẹ̀-èdè ethiopia tó sì tún kópa nínú oríṣiríṣi ìdíje ọ̀nà jínjìn ìgbésí ayé biset biset kọ́ iṣẹ́ eré-sísá pẹ̀lú bizunesh deba genna tufa àti atalelech asfaw ní ilẹ̀ new york àti albuquerque new mexico ara iṣẹ́ arábìnrin náà ni eré-sísá lọ sí orí-òkè addis ababa ethiopia pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ nínú eré-sísá àṣeyọrí eré-sísá abrha àkọ́kọ́ ní ìta orílẹ̀-èdè ethiopia wáyé ní ilẹ̀ india ní delhi àti lahore 10k láti ọdún 2005 dé ọdún 2007 abrha parí pẹ̀lú ipò kejì nínú ìdajì marathon ní ọdún 2006 níbi tó ti gba owó ẹgbẹ̀rún dollar ní ọdún 2008 abrha yege nínú maas marathon tó wáyé ní visè belgium ní ọdún 2009 arábìnrin náà kópa nínú atlanta marathon ní georgia níbi tó ti ṣáájú àwọn obìnrin tó sì gba ẹ̀bùn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta dollar ní ọdún 2010 arábìnrin náà parí pẹ̀lú ipò kẹta nínú marathon ti las vegas níbi tó ti gba owó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin dollar ní ọdún 2011 abrha yege nínú marathon ti california tó wáyé ní sacramento california ní ọdún 2017 arábìnrin náà gbé ipò kẹta nínú eré-sísá ti france 8k ní oṣù august ọjọ́ ogún ní agogo 3201 ọ̀kan nínú àṣeyọrí arábìnrin náà to ṣè pàtàkì ni pé ó gbé ipò àkọ́kọ́ nínú marathon ti philadelphia ní 21447
|
netsanet achamo netsanet achamo tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù december ọdún 1987 jẹ́ eléré sísá ọ̀nà jínjìn ti orílẹ̀-èdè ethiopia àṣeyọrí netsanet parí pẹ̀lú ipò kẹrin nínú ìdíje àwọn eléré ní ọdún 2006 ní 3000 metres achamo kópa nínú ìdíje àgbáyé ti eré-sísá nínú 300 metres ti steeplechase ní ọdún 2007 arábìnrin náà gba idẹ nínú eré gbogbo ilẹ̀ afirica ti ọdún 2007 lórí 3000 metres ti steeplechase achamo yege nínú ìdajì olomouc marathon ní ọdún 2011 mumbai marathon ti ọdún 2012 àti hamburg marathon ti ọdún 2012
|
kate okikiolu kate adebola okikiolu tí a bí ní ọdún 1965 jẹ́ onímọ̀ máàsì ọmọ orílẹ̀-èdè ilẹ̀ọba aṣọ̀kan àwọn ènìyàn mọ̀ ọ́n fún iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú elliptic differential operators àti inner-city children ìpìlẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí okikiolu ní 1965 ní england bàbá rẹ̀ ni george olatokunbo okikiolu ó jẹ́ onímọ̀ mátì tó gbajúmọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ní nàìjíríà ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè ilẹ̀ọba aṣọ̀kan tí ó ń kó mátì ní ilé-ẹ̀kọ́ kan okikiolu gba àmì-ẹyẹ ba nínú ìmò mátì ní yunifásitì ti cambridge ní ọdun 1987 ní ọdun 1991 ó gba àmì-ẹ̀yẹ phd nínú ìmò mátì ní yunifásitì california ní los angeles
|
ilu owu ẹ̀yà owu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ yorùbá ní ìwọ̀-oòrùn áfíríkà ago-owu ní abeokuta ni ibi ti àwọn owu ti pọ̀jù sí káàkiri ile yoruba ni a sì ti máa ń rí àwọn owu àjọṣepọ̀ ìjọba ilẹ̀ yorùbá gbòòrò kọjá ilẹ̀ nàìjíríà dé orílẹ̀-èdè benin àti togo orísun àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn owu kọ́kọ́ wáyé lẹ́yìn ìtẹ̀dó wọn ní ago-owu ní ọdún 1820 ìtàn àròsọ yorùbá mú wa gbàgbọ́ pé àwọ owu tẹ̀dó sí agbègbè kan tààrà lẹ́ẹ̀bá odò odò ọya ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìṣílọ wọn sí apá gúúsù wáyé látàrí ogun ẹ̀yà tó bẹ́ sílẹ̀ láìfarajọ àwọn ìletò tẹ́lẹ̀ àwọn owu ò gbìyànjú láti bá àwọn ọmọ ogun ìbàdàn jà dípò èyí wọ́n tẹ̀dó pẹ̀lú àlàáfíà nítorí àwọn aláṣẹ ìlú ìbàdàn ti rán àwọn òjíṣẹ́ àlàáfíà sí wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ pé àwọn owu ń bọ̀ láti wá kógun ja ìlú wọn àwọn olórí ìlú ìbàdàn fi ilẹ̀ fún àwọn owu láti máa gbé wọ́n sì tàn láti ita lisa títí dé owu ipole lágbègbè ikire àjọ̀dún ọdún ìbílẹ̀ owu ìdí kan pàtàkì tí wọ́n fi ń ṣàjọyọ̀ àjọ̀dún owu ni láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlódùmarè fún ìpèsè gbogbo àìní wọn àṣà ṣíṣayẹyẹ ọdún yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1999 ó sì ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlọ́wọ́sí àwọn ará owu mọ́ra àti àwọn ènìyàn káàkiri ayé ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹwàá ọdún 2010 olowu ti ilu owu tí ń ṣe adegboyega dosunmu amororo ii ṣe ìkéde ìta gbangba pé òpin ọ̀sẹ̀ kejì ní oṣù kẹwàá ni àwọn yóò máa ṣe àjọyọ̀ àti ìdúpẹ́ lọ́wọ́ olódùmarè ìkéde yìí wáyé láti àjọ̀dún ọdún ìbílẹ̀ owu pẹ̀lú àjọ̀dún ọmọ olówu àjọ̀dú ọmọ olówu yìí dàpọ̀ mọ́ àjọ̀dún iṣu tuntun èyí tí olówu fúnra rẹ̀ sọ tí gbogbo ènìyàn sì tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú àtẹ́wọ́ àwọn ènìyàn tó fi ìjókòó yẹ́ àjọ̀dún ti ọdún 2010 náà sí ni ọọ̀ni ifẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí tí ń ṣe oba okunade sijuade olubuse ii tó ti wàjà ààrẹ ilẹ̀ nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí àti balógun ti owu tí ń ṣe olúṣẹ́gun ọbásanjọ́ chief of staff sí ààrẹ goodluck jonathan olóyè mike oghiedome igbákejì gómìnà ti ipinle ogun nígbà kan rí àti alákòóso ecomog tí ń ṣe rtd general tunji olurin
|
olowu ti ilu owu olowu ti ilu owu jẹ́ ọba aládé ìlú owu àwọn ọmọọba tí wọ́n yàn láti ìdílé ọba mẹ́fa tí ń ṣe amororo otileta ayoloye akinjobi akinoso àti lagbedu ló ń darí ìlú òwu àwọn ògbóni àti àwọn ológun ló máa ń ran ọba lọ́wọ́ balógun ló jẹ́ olórí àwọn ìjòyè lábẹ́ rẹ̀ ni a sì rí otun osi seriki aare ago àti jagunna lára àwọn olóyè ogboni ni akogun obamaja orunto oyega osupori àti omolasin olosi ni adífálà ìlú òwu àti olowu láti ìpìlẹ̀ ìlú òwu ní ìletò mẹ́ta tí ń ṣe eyun owu erunmu àti apomu nínú ìṣẹ̀ṣe àwọn afọbajẹ mẹ́fà ló máa ń yan olówu àmọ́ wọ́n ti fi olóyè méjì kún un ní ọdún 1964 tí ń ṣe balogun àti olosi àṣà ogboni ò sí lára àwọn àṣà ará ìlú òwu tẹ́lẹ̀ ọwọ́ à̀wọn egba ni wọ́n ti ya lẹ́yìn tí àwọn òwu tẹ̀dó sí ìlú abeokuta èyí sì ni ìdí tí àwọn owu ò ní ilédì ilé ògbóni títí dòní ní ọdún 2006 lábẹ́ àsìkò ìjọba olówu ọba olusanya adegboyega dosunmu amororo ii wọ́n ṣàtúntò ètò ìṣèlú wọ́n tún ètò ìṣejọba ògbóni àti ológun tò wọ́n sì yan ìgbìmọ̀ tuntun tí á máa ṣe ìjọba lára ìgbìmọ̀ yìí ni a tí ní olóyè méje kan tí ń ṣe
|
abdul-azeez olajide adediran abdul-azeez olajide adediran tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí jandor jẹ́ olóṣèlú nàìjíríà oniroyin oníṣòwò àti onímọ̀-ẹ̀rọ òun ni alága ẹgbẹ́ lagos4lagos àti olùdíje ipò gómìnà ìpínlẹ̀ èkó lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú people’s democratic party pẹ̀lú olùdíje àti igbákejì rẹ̀ funke akindele ó gba doctorate honorary nínú ètò ìdarí àti ìṣèjọba ní south american university ní ìpínlẹ̀ èkó nàìjíríà ìgbésí ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí jandor sí ìdílé alhaji adeniran àti olóògbé ruth oluwafunmilayo adeniran ni ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1977 ní agbègbè mushin ní ìpínlẹ̀ èkó jandor jẹ́ akékọ̀ọ́-gboyè láti ilé-ìwé gíga ti polytechnic ti ilú ìbàdàn modul university vienna howard university school of business washington dc ní orílẹ̀ èdè america àti oxford university united kingdom iṣẹ́ rẹ̀ jandor bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú iṣẹ́-ìròyìn tí ó sì jẹ́ akọ̀ròyìn fún bíi ogún ọdún ó padà wọ inú òṣèlú ó sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ apc òun ni olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbìmọ̀ ti lagos4lagos ẹgbẹ́ kan lábẹ́ apc níkẹyìn ó padà lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ pdp ó sì jẹ́ olùdíje ipò gómìnà ìpínlẹ̀ èkó tó kọjá ayé rẹ̀ maryam ọlajide adediran ni ìyàwó rẹ̀ wọ́n sì bí ọmọ méji fareedah oluwamayokun amoke àti fadhilulah oluwamurewa adedayo akanniade olajide-adediran
|
akọ̀ròyìn akòròyìn jẹ́ ẹni tí iṣẹ́ rè ní ṣe pẹ̀lú gbígbà ìròyìn yálà ní àkọsílẹ̀ tàbí lórí fọ́nrán tàbí àwòrán ṣíṣe àtòjọ àti àtúntò àwọn ìròyìn náà àti ìpínkárí ìròyìn náà fún àwọn ará-ìlú
|
àtòjọ àwọn akọ̀ròyìn ilẹ̀ nàìjíríà
|
wale aboderin gbadebowale aboderin 1958 30 may 2018 jẹ́ oniroyin láti orílẹ̀-èdè naijiria oníṣòwò àti alábòójútó eré-ìdárayá òun ni alága ìwé-ìròyìn punch títí ìgbà tó kú èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tí bàbá rẹ̀ dá sílè ìwé-ìròyìn vanguard ṣe àpejúwe ìwé-ìròyìn yìí gẹ́gẹ́ bíi òpó kan pàtàkì fún iṣẹ́ ìgbéròyìn jáde ó kàwé ní government college ní ìlú ibadan àti clifton college kó tó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọkọ̀ òfurufú ní burnside-ott flying school nínú eré-ìdárayá ó jẹ́ alága ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù agbábọ́ọ̀lù ìpínlẹ̀ èkó àti igbákejì ààrẹ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù nàìjíríà aboderin kú lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ọkàn tí ó ṣe ní eko aare ilẹ̀ nàìjíríà muhammadu buhari gómìnà èkó tẹ́lẹ̀ rí akinwunmi ambode wà lára àwon tó ṣàánú fún àwọn ẹbí rẹ̀ ní ọdún 1997 ó ṣe ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù inú apẹ̀rẹ̀ aládàáni ti ilẹ̀ nàìjíríà àkọ́kọ́ fún àwọn obìnrin dolphins ikú rẹ̀ wale aboderin kú ní 30 may 2018 ní ikoyi ìpínlẹ̀ èkó ní ẹni ọdún 60
|
kunle ajibade kunle ajibade tí wọ́n bí ní 28 may 1958 jẹ́ akoroyin olóòtú àti òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè naijiria ní ọdún 1995 pẹ̀lú olusegun obasanjo àti àwọn oníròyìn mẹ́ta mìíràn ni wọ́n fi ẹ̀sùn ọ̀tẹ̀ kàn ní ọdún 1998/1999 ó di ọmọ ẹgbẹ́ feuchtwanger ní villa aurora ní los angeles ètò-ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀ ajíbádé gboyèẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì àti masters nínú ìmọ̀ literature-in-english láti obafemi awolowo university ó ti ṣiṣẹ́ bíi akọ̀ròyìn àgbà ní the african concord aṣèrànwọ́ olóòtú ní the african guardian àti bí olóòtú àgbà ní thenews àti pm news
|
adanech zekiros ethiopian long-distance runner zekiros adanech ni a bini ọjọ kẹrin dinlọgbọn óṣu kẹta ni ọdun 1982 jẹ elere sisa ti ọna jinjin órilẹ ede ethiopia lori iṣẹ rẹ gẹgẹbi elere sisa awọn ibi to ti gbegba oroke julọ ni315937 ninu 10000 metres to waye ni sollentuna ni ọjọ keji dinlọgbọn óṣu june ni ọdun 2005 11206 ninu idaji marathon ni addis ababa to waye ni ọjọ keji dinlọgbọn óṣu august ni ọdun 2005 ati 22732 ninu marathon to waye ni rotterdam ni ọjọ kẹtala óṣu april ni ọdun 2008 àṣèyọri ni ọdun 2004 ti idije iaaf agbaye idaji marathon adanech pari pẹlu ipó kẹrin dinlogun ni 11350 lẹyin ti arabinrin naa fojusi ere sisa ti 10000 metres ati idaji marathon fun igba ibẹẹrẹ iṣẹ rẹ adanech foju si marathon odidi ni ọdun 2005 ni ọdun 2006 adanesh pari pẹlu ipo kẹjọ ni marathon ti berlin ni 23648 ati ipo kẹta ni marathon ti rome to waye ni ọdun 2006 ni 22738 ere sisa to ṣè pataki ti adanech kopa ninu rẹ ni marathon ti rotterdam ti ọdun 2008 to si pari pẹlu ipo keji
|
grace ebun delano grace ebun delano tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kọkànlá ọdún 1935 ní kaduna jẹ́ núrsì àti agbẹ̀bí tí ó kópa nínú ètò family planning àti àwọn ǹkan míràn nípa ètò ibí ní nàìjíríà ó wà lára àwọn tó dá ẹgbẹ́ reproductive and family health kalẹ̀ òun sì ni adarí ẹgbẹ́ náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdun ní ọdún 1993 ó gba àmì-ẹ̀yẹ world health organization sasakawa award fún iṣẹ́ ribiribi rẹ̀ ní ètò ìlera ara
|
levi chibuike ajuonuma levi chibuike ajuonuma tí a bí ní ọjọ́ kejì oṣù kejìlá ọdún 1959 tí ó sì kú ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà ọdún 2012 tí a mọ̀ sí livi jẹ́ ọ̀mọ̀wé naijiria o fìgbà kan jẹ́ sọrọ̀sọ̀rọ̀ lórí rédíò àti lórí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán ó sì gbajúgbajà fún ètò rẹ̀ ní alaalẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ open house party lórí raypower 1005fm ajuonuma tún ti ṣiṣẹ́ ní nigerian television authoritynta àti àwọn ìkànní mìíràn níbi tí ó ti jẹ́ olóòtú àti olùdarí the sunday show showtime àti levi ajuonuma live ìgbésí ayé rẹ̀ ọmọ bíbí ìlú ideato south ní ipinle imo ni ajuonuma ti wá ṣùgbọ́n ìlú enugu ni wọ́n bí sí ibẹ̀ ló sì wà títí tó fi dàgbà tó sì ti kọ́ ẹ̀kọ́ alàkọ̀ọ́bẹ̀rẹ́ ó lọ sí orílẹ̀-èdè amẹ́ríkà lọ́dún 1979 láti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ó sì gboyè ba ní ìbánisọ̀rọ̀ láti huntington college indiana àti m a pẹ̀lú phd ni mass communications láti university of minnesota ní ọdún 1983 àti 1987 ó sì tún gboyè mba láti plymouth state university ní ọdún 1989 iṣẹ́ rẹ̀ ajuonuma bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí rédíò ní ọdún 1977 pẹ̀lú imo broadcasting service ibs ní owerri ipinle imo ó kúrò ní nàìjíríà láti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní mass communications ní united states níbi tó ti jáde pẹ̀lú ba ma àti phd ṣáájú kí ó tó padà sí nàìjíríà lẹ́yìn àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ìlú america ajuonuma ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ ní ẹ̀ka ìwé-ìròyìn keene state college of the university system of new hampshire ó padà sí orílẹ̀-èdè nàìjíríà láti tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ rẹ̀ tesiwaju nínú ìgbéròyìnsáfẹ́fẹ́ àti olùgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní oríṣiríṣi àwọn ilé-iṣẹ́ rédíò àti tv ní nàìjíríà lẹ́yìn náà ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi alákòóso gbogboogbò fún corporate affairs of the nigerian national petroleum corporation nnpc níbi tó wà títí tó fi kú igbesi aye ara ẹni ajuonuma ní ìyàwó orúkọ rẹ̀ sì ni josephine ajuonuma tí wọ́n sì jọ bímọ méjì papọ̀ ikú rẹ̀ ajuonuma jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ nnpc mẹ́rin tó sọ ẹ̀mí wọ́n nù ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà ọdún 2012 nínú ìjàmbá oko ofurufu dana air 992 ní iju-ishaga ní ipinle eko minisita tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo ní nàìjíríà nígbà kan rí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ diezani alison-madueke wá síbi ayẹyẹ ìsìnkú tí wọ́n ṣe láti fi yẹ́ ẹ sí wọ́n sin ajuonuma sí ìlú abínibí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ imo
|
beatrice aboyade beatrice aboyade tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹjọ ọdun 1935 jẹ́ olùmójútó ilé ìkàwélibrarian àti ọ̀jọ̀gbọ́n fẹ̀híntì ní nàìjíríà ààjọ world encyclopedia of library and information services se àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ara àwọn tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àmójútó ilé ìkàwé ní nàìjíríà aboyade ti ṣíṣe ní ilé ìkàwé yunifásítì ìlú ìbàdàn àti yunifásítì ọbáfẹ́mi awólọ́wọ̀ ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ aboyade lọ ilé-ìwé christ's church primary school porogun ijebu ode fún ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ ó tẹ̀síwájú ní queen's college ti ìpínlè èkó fún ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì rẹ̀ láàrin ọdun 1948 sí 1951 láàrin 1952 sí 1953 ó tún tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní queen's college ede ó gba àmì-ẹ̀yẹ ba rẹ̀ ní yunifásítì ìlú ìbàdàn ní ọdun 1960 kí ó tó tẹ̀síwájú fún àwọn àmì-ẹyẹ míràn ní yunifásítì ti michigan ní ọdun 1964 ní ọdun 1970 ó parí ẹ̀kọ́ dokita ní yunifásitì ìlú ibadan ó fé ọ̀jọ̀gbọ́n ojetunji aboyade òjògbón nínú ìmò ètò ọrọ ajé láti ọdun 1961 títí di ìgbà ti ó fi ayé sílè ní ọdun 1994 iṣẹ aboyade ko di ile-ikawe lẹsẹkẹsẹ ṣugbọn lo akoko diẹ ni ile-iṣẹ broadcast ti orilẹ-ede naijiria ṣaaju ki o darapọ mọ ile-ikawe university of ibadan gẹgẹbi ile-ikawe iranlọwọ ni ọdun 1962 laipẹ o gba ipo tuntun bi katalogi olori ni university of ife ni ọdun 1965 ọdun mẹta lẹhinna o pada si ile-ẹkọ giga ti ibadan lati ṣe itọsọna awọn iṣẹ oluka wọn ni ọdun 1972 o bẹrẹ si kọ sibẹ nigbati o di olukọni ni university ni ẹka ile-ikawe ikawe ni ọdun 1978 o ti ni igbega lati ọdọ olukọni agba nigbati o jẹ ọjọgbọn ọjọgbọn ti awọn ijinlẹ ile-ikawe ni university of ibadan ati pe o ṣe iranṣẹ bi ẹka ti ile-ikawe awọn ijinlẹ ati alaye ni ile-ẹkọ giga o tun sare eto eto alaye idagbasoke rural rudis eyiti o pọ si iraye alaye si awọn eniyan igberiko ni afirika iṣẹ rẹ pẹlu rudis fi han pe awọn ile-ikawe igberiko naijiria ni akọkọ ṣiṣẹ ibeere iṣẹ kan a lo awọn iwe ile-ikawe lati ṣafihan bi o ṣe le ṣe ilọsiwaju awọn ohun elo bii awọn ọna ina isuna ati omi fifẹ awọn onkawe yoo wa nipa awọn aye oojọ ti agbegbe ati alaye nipa awọn ajile ati awọn aye iṣowo
|
henry akubuiro henry akubuiro jẹ́ akọ̀rọ̀yìn àti àti òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀ akubuiro kàwé gboyè nínú ìmò englisi ni yunifásítì ìpínlẹ̀ ímò owerri ni ọdun 2003 ó bèrè isé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ̀rọ̀yìn nígbà tó sì jẹ́ ọmọ ilé-ìwé yunifásitì ìpínlè imo níbi tí ó ti dá editor of the elite—the student newspaper in imo state university àti the imo star—the newspaper of the student union government kalẹ̀ ó gba àmì-ẹ̀yẹ bbc world service fún olúborí ìdíje láàrín àwọn ọ̀dọ́ akàròyìn àti ní ìdíje ìkọ̀wé tí ẹ̀ka ìjọba fún ètò ẹ̀kọ́ àti eré ìdáyará dá kalẹ̀
|
jerry fisayo bambi jeremiah fisayo bambi jẹ́ akòròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà olùpìlẹ̀ṣẹ̀ òǹkọ̀wé ìròyìn agbàlejò ìròyìn àti showhost lórí africanews àti euronews iṣẹ́ rẹ̀ bambi ṣe àgbéjáde àti àfihàn “inspire africa” ètò tẹlifísàn kan pẹ̀lú àwọn ìtàn ti ìsọdọ̀tun ìyípadà àti ipa ní áfíríkà ó papọ̀ gbàlejò ètò ìròyìn àárọ̀ “the morning call” lórí africanews ètò ìròyìn tẹlifísàn kan lórí ìṣèlú àṣà ètò-ẹ̀kọ́ scitech eré ìdárayá àti ìṣòwò ó ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àwọn olùdarí ìjọba bíi prime minister uk tẹ́lẹ̀ gordon brown lórí ipa britain nínú ìgbéjàkọ ìpaniláyà nàìjíríà àti àwọn ènìyàn láti agbègbè àti aládani ní ìṣòwò àti ṣíṣe ètò ìmúlò ní áfíríkà ó jẹ́ agbọ́rọ̀sọ ní àpéjọ kan ní summit áfíríkà àwọn àmì ẹ̀yẹ bambi jẹ́ olùdíje tí a yàn ti àmì ẹ̀yẹ bbc komla dumor àti pé ó jẹ́ olùdíje fún ẹ̀bùn tẹlifísàn ènìyàn ti ọdún 2020 nigeria achievers awards
|
tunji bello olatunji bello ọjọ́-ìbí ọjọ́ kìíní oṣù keje ọdún 1961 jẹ́ àgbẹjọ́ro onímọ̀ nípa àyíká onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ńsì òṣèlú oníròyìn àti kọmíṣọ́nà tó jókòó fún àyíká àti ọrọ̀ omi lábẹ́ ìṣàkóso babajide sanwo-olu ní ìpínlẹ̀ èkó ó jẹ́ ọmọ eko ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ó ní bsc ìwé gíga yunifásítì ti ìbàdàn níbi tí ó ti kàwé ìmọ̀ òṣèlú tí ó sì gbòye jáde ní ọdún 1984 ó sì gba masters degree ní international law and diplomacy mld ní ọdún 1987 ní yunifásítì ti èkó ó ti gba òye bachelor of laws láti ilé-ìwé gíga yunifásítì ti èkó náà nàìjíríà ní ọdún 2000 iṣẹ́ oníròyìn rẹ̀ tunji bello bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oníròyìn ní ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde concord press ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà níbi tí ó ti dàgbà láti di olóòtú ó bẹ̀rẹ̀ bí ẹ̀yà-ara òǹkọ̀wé ó tún jẹ́ olùrànlọ́wọ́ olóòtú àwọn ẹ̀yà ara iṣẹ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn dàgbà ní kíákíá tó bẹ́ẹ̀ tí ó di olóòtú ìṣèlú ní ọmọ ọdún mẹ́tà-dín-lọ́gbọ̀n lẹ́hìn náà ó gbéga sí olóòtú àkọ́lé sunday àti lẹ́hìn náà olóòtú àkọ́lé ojoojúmọ́ ti concord newspapers group ó tún jẹ́ alága ti ìgbìmọ̀ olóòtú ti ìwé ìròyìn thisday ó jẹ́ òǹkọ̀wé òṣìṣẹ́ kan pẹ̀lú st petersburg times florida usa àti us news world report washington dc ní ọdún 1992 àwọn àmì ẹ̀yẹ ó sì gba oríṣiríṣi àwọn àmì ẹ̀yẹ ó gba alfred friendly press fellowship usa ó gba àmì ẹ̀yẹ concord press fún ìlọsíwájú àti ìgboyà ní ìwé ìròyìn alákoso olóòtú tí ó dára jùlọ ti concord publisher ó jẹ́ ẹni tí ó gba àmì ẹ̀yẹ distinguished alumnus ti yunifásítì ti ìbàdàn àti ẹ̀bùn ọ̀rẹ́ aláṣẹ fásítì ti èkó distinguished alumni achievers àwùjọ àwọn oníṣẹ́-ẹ̀rọ̀ nàìjíríà ikeja èka èkó àti undp lọ́lá fún un fún fífi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún oúnjẹ àyíká ní ìpínlẹ̀ èkó ó ti kọ ìwé kan àti pé ó ṣe alábàpín sí àwọn mẹ́rin mìíràn ayé rẹ̀ ó jẹ́ ọkọ sí ibiyemi olatunji-bello olùdarí èyí tí ó jẹ́ vice-chancellor ti fásítì ìpínlẹ̀ èkó láti oṣù kẹ́sàn-án ọdún 2021 títí di ìsìsiyìn
|
moses da rocha moses da rocha èyí tí a bí ní oṣù kìn-ín-ní ọdún 1875 tí ó sì kú ní oṣù karùn-ún ọdún 1942 jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó akọ̀ròyìn àti olóṣèlú ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ ìṣẹgun òyìnbó bí i africanus horton orisadipe obasa àti john k randle tí wọ́n mú iṣé ìṣègùn mọ́ òṣèlú ní ọdún 1923 nígbà tí ó kù dẹ̀dẹ̀ kí ìdìbò ìgbìmọ̀ lẹjisilétíìfù bẹ̀rẹ̀ ó dá egbẹ́ the union of young nigerians sílẹ̀
|
abebech afework ethiopian long-distance runner abebech afework bekele ni a bini ọjọ kọkanla óṣu december ni ọdun 1990 jẹ akọṣẹmọsẹ elere sisa ti ọna jinjin to dari lori idaji marathon abebech ṣóju fun órilẹ ede ethiopia ninu idije iaaf agbaye cross country ti iadaji marathon ati idije iaaf agbaye ti idaji marathon awọn ere ti arabinrin naa ti yege julọ ni 11030 àṣèyọri abeche bere si ni dije ni ilẹ okun ni ọdun 2009 nibi to ti gbe ipo kẹta ni maraton idaji ti udine ni 11115 ni ọdun naa arabinrin naa yege ninu idaji marathon ti arezzo kekere ni óṣu january ọdun 2011 abebech yege ninu idaji marathon ti egmond nibi to ti sare fun club ti ere sisa defenc ilẹ ethiopia ni ọdun 2012 abebech gbe ipo kẹfa ninu idije cross country ti ilẹ afirica pẹlu ẹgbẹrun mẹwa metres ati iṣẹju ti 314853 ni prefontaine classic ni óṣu july 2012 arabinrin naa gbe ipo kẹta ni idaji marathon ti bogotà ni ọdun 2013 abebech ṣè dada ninu marathon ti rottedam pẹlu wakati 22359
|
ruti aga ethiopian long-distance runner ruti aga ni a bini ọjọ kẹrin dinlogun óṣu january ni ọdun 1994 jẹ elere sisa ti ọna jinjin ti órilẹ ede ethiopia ruti yege ninu ere awọn óbinrin ti ọdun 2019 ninu marathon ti ilẹ tokyo àṣèyọri ni ọdun 2012 aga gba ami ẹ̀yẹ ti silver ninu idije agbaye ti junior ere sisa to waye ni barcelona spain ni ọdun 2013 arabinrin pari pẹlu ipo karun ninu idije ere sisa ti awọn óbinrin ti iaaf agbaye cross country to waye ni bydgoszcz poland ni ọdun 2019 aga kopa ninu idije ere sisa agbaye ayẹyẹ marathon ti awọn obinrin ni ọdun 2022 ruti kopa ninu marathon ti chicago ninu ere sisa fun wakati 22141
|
stephanie busari stephanie busari tí a bí ní ọdún 1977 jẹ́ akọ̀ròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà kan tí ó gbajúmọ̀ fún gbígbá “proof of life” ní ìyasọ́tọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin ilé-ìwé chibok tí ó pàdánù ní àtẹ̀lé agbawi bring back our girls èyí tí ó yọrí sí ìdúnadúrà pẹ̀lú boko haram pé yọrísí ìtúsílẹ̀ tí ó ju ọgọ́run àwọn ọmọbìnrin ilé-ìwé tí a jí gbé ẹ̀kọ́ busari kọ́ ẹ̀kọ́ faransé àti media gbogbogbò ní trinity and all saints college ní leeds àti lẹ́hìn náà lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti rennes fún ètò ìwé-ẹ̀kọ́ gíga diploma iṣẹ́ rẹ̀ busari bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní new nation tí ó ti parẹ́ báyìí ìwé ìròyìn tí ó dá lórí ìlú lọ́ńdọ́nù àti lẹ́hìn náà ó kó lọ sí daily mirror arábìnrin náà ní àkókò kúkurú bí oníròyìn onítumọ̀ ní bbc news ṣáájú kí ó tó lọ sí cnn ní ọdún 2008 àti tún gbé lọ sí èkó nàìjíríà ní ọdún 2016 láti ṣe ìtọsọ́nà ilé-iṣẹ́ oní nọ́mbà àkọ́kọ́ ti cnn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀-ẹ̀rọ ní ọdún 2015 busari jẹ́ àpákan ti ẹgbẹ́ tí ó gba ààmì ẹ̀yẹ peabody fún ìròyìn cnn ti àwọn ọmọbìnrin ilé-ìwé nàìjíríà tí ó pàdánù àti ní ọdún 2017 ó gba ààmì ẹ̀yẹ hollywood gracie àti outstanding woman ní media awards fún ìròyìn jinlẹ̀ ti àwọn ọmọbìnrin ilé-ìwé nàìjíríà tí ó pàdánù ọ̀rọ̀ busari ọdún 2017 tí à ń pè ní ted talk ní gèésì lórí “báwo ni àwọn ìròyìn irọ́ ṣe ìpalárá gidi” ni a ti wò ju àwọn àkókò mílíọ̀nù kan lọ àti pé a túmọ̀ ìwé-kíkọ rẹ̀ sí àwọn èdè mẹ́ta-dín-ogójì jùlọ
|
nasiru l abubakar ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ wọ́n bí nasiru ní ọjọ́ kẹ́rin oṣù kẹsàn-án ọdún 1977 ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ àríwá kaduna ní ìpínlẹ̀ kaduna nasiru kẹ́kọ̀ọ́ gboyè pgd nínú ẹ̀kọ́-ìmọ̀ mass communication ní buk gboyè pgd nínú ẹ̀kọ́-ìmọ̀ ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè àti diplomacy ní àfikún sí ẹ̀kọ́ hnd nínú ẹ̀kọ́-ìmọ̀ mass communication ní kaduna polytechnic ní ìpínlẹ̀ kaduna oníṣẹ́-ìròyìn nasiru bẹ̀rẹ̀ ìṣe ìròyìn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó yàn láàyò ní abg group ó ṣiṣẹ́ fún ìgbà ráńpẹ́ gẹ́gẹ́ bíi òǹkọ́ṣẹ́ lábẹ́ àmójútó pẹ̀lú ksmc ní ìlu kaduna kí ó tó dára pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ oníwé-ìròyìn daily trust lákọ̀ọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ arakẹni ní oṣù mẹ́jọ 2000 kí ó tó wá di òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ gan ní ọdún 2004 ní daily trust ó jẹ́ aṣojú yàn ayẹ̀ròyìn wò ní sátidé ní ọdún 2012 kí wọ́n tó dá a padà sí igbákejì ayẹ̀ròyìn wò daily ní ọdún 2014 kí wọ́n tó bòǹtẹ̀lú gẹ́gẹ́ bíi ayẹ̀ròyìn wò ní ọdún 2016 gẹ́gẹ́ bí ayẹ̀ròyìn wò ó gba àmì-ẹ̀yẹ tí ayẹ̀ròyìn wò jùlọ tí ọdún náà ní ọdún 2016 tí ìwé-ìròyìn daily sì gba àmì-ẹ̀yẹ ìwé-ìròyìn tí ọdún náà ní ọdún 2019 wọ́n yan nasiru gẹ́gẹ́ bíi olùṣàkóso ayẹ̀ròyìn wò tí daily trust ó fi iṣẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 2020 láti lọ dára pọ̀ mọ́ dateline nigeria gẹ́gẹ́ bíi olú-ayẹ̀ròyìn wò ó máa ń kó ìròyìn fún gamjicom láti ọdún 2015 ó sì máa ń dá sí ti àwọn ilé-iṣẹ́ yòókù
|
moses da rocha
|
taiwo abioye taiwo olubunmi abioye jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ englisi ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni obìnrin àkọ́kọ́ láti di ìgbàkejì adarí covenant university ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí taiwo ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gún oṣù kínní ọdun 1958 ní kaduna sínú ìdílé àwọn òbí tó wá láti ìpínlẹ̀ ogun abioye gba àmì-ẹ̀yẹ àkọ́kọ́ nínú ìmò language arts yunifásítì àmọ́dù béllò bákan náà ẹ̀wẹ̀ ó tẹ̀síwájú láti gba àmì-ẹ̀yẹ master àti ti dókítá ní ilé-ìwé kan náà ní ọdun 1992 àti 2004 ní ọdun 1982 abioye gba àmì-ẹ̀yẹ akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé jùlọ ni ẹ̀ka inglisi ti yunifásitì àmọ́dù béllò
|
john payne jackson biography orukọ john payne jackson ọjọ ibi 1848-03-25 ibi ibi cape palmas liberia ọjọ ikú 1915-08-01 ibi iku lagos orilẹ-ede liberia british west african iṣẹ́ ìròyìn ti a mọ fun igbasilẹ ọsẹ ọsẹ ni lagos igbesi aye john payne jackson 25 march 1848 1 august 1915 je onise americo-liberian kan ti a bi ni liberia ti o ni ipa ni lagos nigeria ni ayika ibẹrẹ ti 20th orundun o ṣatunkọ ati ṣe agbejade igbasilẹ ọsẹ ọsẹ 'ilu eko' lati ọdun 1891 titi o fi ku eyi jẹ iwe ti a kọ daradara ati alaye ti o jiroro ati itupalẹ awọn iṣẹlẹ lọwọlọwọ o gba atako-amunisin ipo orilẹ-ede afirika ti o jẹ ki o jẹ ki o ko gbajugbaja pẹlu awọn alaṣẹ ati pẹlu diẹ ninu awọn olokiki naijiria
|
ngozi nwozor-agbo nigerian journalist 1974-2012 ngozi nwozor-agbo ọjọ́ 21 oṣù kẹfà ọdún 1974 sí ọjọ́ 28 oṣù karùn-ún ọdún 2012 jẹ́ oníròyìn orílẹ̀-èdè nàìjíríà òǹkọ̀wé àti akéwì tí gbogbo ènìyàn ń pè ní ‘lady campus’ ó jẹ́ ìlú mọ̀ọ́ká ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà gẹ́gẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó dá ìwé-ìròyìn ọgbà fáṣítì sílẹ̀ tí ó pè ní ìgbésí ayé ọgbà fáṣítì campuslife èyí tí ó jẹ jáde látinú àwọn ìwé-ìròyìn the nation fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti inú ọgbà fáṣítì jákèjádò orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó tún jẹ́ gbajúgbajà nípa kíkọ ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tí orílẹ̀-èdè nàìjíríà láti di àwọn òǹkọ̀ròyìn tí ó gbámúṣẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti iṣẹ́ àyànṣe wọ́n bí ngozi agbo ní ìlú onitsha ní ìpínlẹ̀ anambra ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó lọ sí fáṣítì tí orílẹ̀ èdè nàìjíríà nsukka unn níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì ó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó múnádóko wọ́n sì yàn-án gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ ti ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọba ti unn ní ọdún 1999 ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè másítà nínú ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ìtàn àti ẹ̀kọ́-ìmọ̀ ìbáṣepọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ní fáṣítì èkó unilag ngozi darapọ̀ mọ́ ìwé-ìròyìn the nation ní ọdún 2007 pẹ̀lú pé ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìwé-ìròyìn new age àti àwọn àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba ngo fate foundation
|
pelu awofeso pelu awofeso jẹ́ akọ̀ròyìn ọmọ orílẹ̀-edè nàìjíríà ó jẹ́ ọ̀ǹkọ̀wé nípa ìrìn-àjò àti àṣà tó ń gbé ìlú èkó ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jáwẹ́ olúborí nínú ìdíje ti cnn/multichoice ní africa fún àmì-ẹ̀yẹ ti ẹ̀ka àwọn oníròyìn nípa ìrìn-àjò ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní à ń ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gé bíi aṣáájú òǹkọ̀wé nípa ìrìn-àjò ó tún jẹ́ òǹkọ̀wé tí a ṣatẹ̀jáde ìwé rẹ̀
|
jahman anikulapo jahman oladejo anikulapo ọjọ́ ìbí je ọjọ́ kẹrìndínlọ́gún osù kíní ọdún 1963 ó jẹ́ onísẹ́ ìròyìn àti akọ̀wẹ́ àṣà aníkúlápó jẹ́ ọmọ naijiria ó kẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ tíátà ní yunifásitì tí ìbàdàn ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akọọlẹ iṣẹ ọna rẹ ni the guardian bi iṣẹ ọna ati olóòtú media ni 1993 o ṣiṣẹ bi iṣẹ ọna ati olóòtú media títí di ọdún 2003 lẹ́yìn náà ó ṣiṣẹ́ bi olóòtú ìwé ìròyìn guardian on sunday and the guardianlife lati 2003 si 2013
|
zemzem ahmed ethiopian runner zemzem ahmed deko ni a bini ọjọ kẹta dinlọgbọn óṣu december ni ọdun 1984 ni ilu asella jẹ elere sisa ti steeplechase ati ti óju ọna ti órilẹ ede ethiopia arabinrin naa jẹ ọkan lara awọn elere sisa ti steeplechase to pegede julọ ni ilẹ ethiopia àṣèyọri zemzem ṣoju ethiopia ninu olympics ti summer to waye ni beijing ni ọdun 2008 to si kopa ni steeplechase ti awọn óbinrin ti ẹgbẹrun mẹta metre ni ọdun 2009 arabinrin naa kopa ninu idije agbaye ti ere sisa to si gbe ipo kẹwa ninu steeplechase pẹlu ere ti iṣẹju 92264 ni ọdun 2012 arabinrin naa kopa ninu marathon ti frankfurt nibi to ti gbe ipo kẹfa pẹlu wakati 22712
|
mizan alem ethiopian long-distance runner mizan alem ni a bini keji leelogun óṣu january ni ọdun 2002 jẹ elere sisa lobinrin ti ọna jinjin to gbajumọ ninu metres ti ẹgbẹrun marun ti órilẹ ede ethiopia àṣèyọri ni ọdun 2021 mizan gba ami ẹyẹ idanilọla ti gold ninu idije u20 ere sisa agbaye
|
kola muslim animasaun olóyè kola muslim animasaun tí wọ́n bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù keje ọdún 1939 jẹ́ akọ̀ròyìn orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti alága ẹgbẹ́ olótùú fún ìwé-ìròyìn the vanguard tó ń ṣáájú àwọn ìwé-ìròyìn ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìwé rè from 1939 to the vanguard of moodern journalism ní wọ́n gbé jáde ní nigerian institute of international affairs ní ìpínlẹ̀ èkó ní oṣù keje ọdún 2012 àwọn ènìyàn pàtaàkì tó wà níbi ayẹyẹ nahà ni aṣíwájú bola tinubu olórí ẹgbẹ́ òṣèlú ti gbogbo progressives congress àti abiola ajimobi gómìnà ipinle oyo tó wà ní apá gúùsù mọ́ ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ naijiria
|
elfenesh alemu elfenesh alemu ni a bini ọjọ kẹwa óṣu june ni ọdun 1975 ni lemo arya arsi zone jẹ elere sisa ti ọna jinjin órilẹ ede ethiopia arabinrin naa gbajumọ lori ere ti marathon àṣèyọri elfenesh ṣọju órilẹ ede ethiopia ninu olympics summer ti ọdun 2000 ati 2004 arabirnin naa kopa ninu marathon ti idjije agbaye lori ere sisa lẹmẹrin lati ọdun 1997 de 2003 alemu yege ninu idije marathon agbaye to waye ni ọdun 1994 arabinrin naa gba ami ẹyẹ idanilọla ti idẹ ninu ere gbogbo ilẹ afirica ni ọdun 1995 alemu jẹ óbinrin ilẹ ethiopia akọkọ to yege ninu marathon ti amsterdam ni ọdun 1997 alemu kopa ninu marathon ti nagano olympic ni ọdun 2000 ni ọdun 2002 alemu gbe ipo kẹta ninu marathon ti boston ni ọdun 2003 arabinrin naa yege ninu marathon awọn obinrin agabye to waye ni ilẹ tokyo ni ọdun 2009 alemu gbe ipo kọkanla ninu marathon ti chicago arabinrin naa wa lara marathon ti mumbai ti ọdun 2011 to si gbe ipo kẹta pẹlu wakati 22904
|
femi d amele amele adefemi olubunmi d a bíi ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹ̀wá tí gbogbo ènìyàn mọ sí femi d ó jé olugbohunsafefe rédíò àti tv lorile-ede nàìjíríà alagbasọ ọrọ olupilẹṣẹ ayélujára ati oniroyin òṣèlú awọn kókó ọrọ ti ó jíròrò lori awọn ètò rẹ jẹ́ ìdàgbàsókè ètò imulo orilẹ-ede ọrọ-ajé mikro ìṣàkóso ìjọba àti àwọn ọran àgbáyé ni ọdun 2020 ó wá àwọn ọgọ́rùn-ún ènìyàn oniroyin oke ti ọdun nipasẹ ynaija igbesiaye a bi amele ni ojo kerinla osu kokanla odun 1983 ni orile-ede naijiria o si ni ife si igbohunsafefe ni omo odun merinla ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò fún ilé iṣẹ́ rédíò unizik fm ti yunifásítì nnamdi azikiwe lórí ètò kan tí wọ́n ń pè ní international affairs ifihan ifọrọwerọ akọkọ rẹ ti debuted ni ọdun 2010 ni ile-iṣẹ redio kan ni awka ati dojukọ lori iṣelu ti orilẹ-ede ati ti kariaye nipasẹ asọye tirẹ ati awọn ipe olutẹtisi ni ọdun kanna o fun un ni ẹbun uk lati ṣe iwe-ipamọ kan nipa ipa iyipada oju-ọjọ lori eko fiimu rẹ nigbamii ti yan fun aami eye tv iyipada afefe ni 2011 o darapọ mọ cool fm nigeria ati iwe irohin ti ko ni bayi 234next lakoko ti o wa ni cool fm o ṣe iranlọwọ idasile ati idagbasoke alaye naijiria ni bayi nẹtiwọọki ti awọn ibudo redio ọrọ amele ti ṣiṣẹ ni 1019 jay fm nigeria info amplified radio ati galpha media ni awọn ipo oriṣiriṣi lati ọdọ oludari eto si alaga igbimọ o ti gbalejo awọn ifihan deede gẹgẹbi morning crossfire pẹlu femidlive 2019 nigeria info and let's talk with femi d 951 abuja ati awọn pataki bi ṣetan lati ṣiṣe redio ṣaaju idibo 2019 amele tun jẹ oludasile orin ati ohun elo ifihan ọrọ vibinglive ọmọ ẹgbẹ igbimọ imọran fun iread nigeria project o si ti fi ifọrọwanilẹnuwo fun awọn eniyan bii jerry gana lai mohammed audu maikori ati 2baba lakoko iṣẹ rẹ o ti kọwe fun opera news hub eyiti o jẹ ipilẹ owo ori ayelujara fun awọn onkọwe ni nigeria o tun ti kọwe fun mbele legitng ati vanguard ati pe o ṣe ọpọlọpọ awọn iwe-ipamọ pẹlu ohunkohun fun wa nipa ẹbun ijọba ati ibajẹ ni nigeria pẹlu atilẹyin ti yiaga africa ati macarthur foundation ati high and dry about ilokulo oogun paapaa olubori ti nigeria health watch ati awọn olugba ti 2nd #preventepidemicsnaija journalism fellowship amele jẹ́ akíkanjú ọmọ ẹgbẹ́ #nottooyoungtorun èyí tí ó ṣé àgbè fún ìwé-àṣẹ láti dínkù ọjọ-ori tí ó yẹ fún ìdìbò aláṣẹ nàìjíríà ó kọ ìwé ó sì sọ àsọyé ìwé-pamọ young lawmakers credit 'not too young to run' law for their emergence ni ifowosowopo pẹ̀lú yiaga africa ṣe ti nkọju si idibo ifẹ si ni awọn idibo niwaju idibo 2019 o si ṣe bawo ni awọn ọdọ ṣe gbadun ni idije ni awọn idibo 2019 eyiti o gbejade lori awọn ikanni tv pẹlu atilẹyin ti yiaga africa ati european union o ṣajọpọ ṣetan lati ṣiṣe redio lori alaye naijiria tun ṣaaju idibo 2019 o tun ti ṣe awọn iṣẹ ohun fun igbimọ idibo ti orilẹ-ede olominira ita ìjápọ media related to femi d amele at wikimedia commons
|
samuel aruwa samuel aruwan tí a bí ní ọjọ́ kẹwà osù kárun ọdún 1982 o jẹ́ oníròyìn ọmo orílẹ̀-èdè nàìjíríà ati komisana àkọ́kọ́ fún ilẹ́-iṣẹ àabò abẹ́lé àti ọ̀rọ̀ abẹ́lé ti ipinlẹ kaduna
|
lanre alfred lanre alfred jẹ́ akọ̀ròyìn òǹkọ̀wé àti akéde ọmọ nàìjíríà òun ni olùtèjáde the capital olóòtú awujọ iṣaaju ati akọ̀ròyìn ìwé ìròyìn this day onkọ̀wé ìwé márùn àti ẹni tí ó ni itàkan ni ilu ekò nàìjíríà alfred lanre jẹ́ olóòtú ìwé-ìròyìn celebrity journalism iṣẹ́ rẹ̀ nínú ẹ̀ka ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ náà ni iṣẹ́ oníròyìn láwùjọ òǹkọ̀wé àti òǹkọ̀wé ní ìwé ìròyìn city people ìwé ìròyìn asọ̀ tí ó gbajúmọ̀ ní nàìjíríà jẹ́ tí seye kehinde dá sílẹ̀ lẹhin ọdun meji kan alfred fi iwe irohin ilu awọn eniyan silẹ fun iwe iroyin ọjọ oni yii nibiti o ti kọ spyglass ni ọjọ satidee ati awọn iṣẹlẹ awujọ ni ọjọ ọṣẹ oju-iwe nipasẹ eyiti o ṣe afihan igbesi aye ti awọn awujọ awujọ naijiria ati awọn olokiki olokiki o fi ọjọ yii silẹ gẹgẹbi olootu awujọ ni 2014 lati wa iwe irohin ti ara rẹ lori ayelujara the capital itẹjade lori ayelujara pẹlu idojukọ lori iṣowo iṣelu ati igbesi aye ti awujọ giga ti nigeria ati nouveau riche o si maa wa a idasi columnist si yi day nipasẹ kan osẹ iwe ti a npè ni high life
|
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.