raw_text
stringlengths 2
128k
|
---|
fatuma issa maonyo fatuma issa maonyo tí a bí ní ọjọ́ kẹ̀sán osù kẹrin ọdún 1995 jẹ́ ogbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-ède tanzania tí ó ṣeré ipò olùgbèjà lórí pápá fún simba queens àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tanzania isẹ́ òkè-òkun ní oṣù keje ọdún 2018 maonyo borí ní bi ìdíje cecafa women's championship ti ọdún 2018 pẹ̀lú tanzania lẹ́hìn tí ó ṣẹ́gun etiopia pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin si ọ̀kan 4-1 ní bi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìkẹhìn wọn
|
donisia minja donisia daniel minja tí a bí ní ọjọ́ kẹsán oṣù kẹjọ ọdún 1999 jẹ́ ogbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-ède tanzania tí ó ṣeré ipò iwájú lórí pápá fún yanga princess àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tanzania isẹ́ òkè-òkun ní ọdún 2018 minja mi àwọ̀n pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta ní bi ìdíje cecafa women’s championship ti ọdún 2018 láti gba àmì ẹ̀yẹ ẹni tí ó mi àwọ̀n jùlọ ní bi ìdíje náà
|
olusola momoh olúṣọlá momoh jẹ́ adarí àwọn ilé íròyìn kan ní nàìjíríà ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ àti igbákejì alága ti àwọn channels media group ilé-iṣẹ́ tí ó ń darí channels tv momoh gboyè bsc ní mass communicatio láti yunifásitì ìlú èkó ó tún gba àmì ẹyẹ pí polongo ìròyìn ní yunifásitì ìlú èkó ní ọdún 2014 ó wà lára àwọn women leadership forum program ti ilé-ìwé ìsòwò harvard iṣẹ́-ṣíṣe ṣáájú kí ó tó dá channel television àti channels media group silẹ̀ momoh jẹ́ oníròyìn pẹ̀lú nigeria television authoritynta láàrin ọdún 1979 sí 1987 ní àkókò yìí ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbéjáde lórí bí nàìjíríà ṣe ń sọ epo nù yàtò sí isẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi akàròyìn momoh ṣiṣẹ́ fún ọdún méje ní àwọn ilé-ìfowópamọ́ ó ṣiṣẹ́ ní international merchant bank imb àwọn àmì ẹyẹ ní ọdún 2019 momoh gbà àmì-ẹ̀yẹ doctorate degree nínú ìṣàkóso ìṣòwò ní yunifásitì achievers ọ̀wọ̀ ìpínlẹ̀ oǹdó ní oṣù kọkànlá ọdún 2021 àjọ women in management business and public service wimbiz ká mọ́ ọkàn lára àwọn obìnrin tí ó lókìkí jù àjọ náà tún ká mọ́ ọkàn nínú àwọn obìnrin tí ó lókìkí jù nínú àwọn oníròyìn obìnrin ní nàìjíríà
|
patricia kalesanwo patricia kalesanwo jẹ alamọdaju ibaraẹnisọrọ lorilẹ-ede naijiria oniroyin o tu je obinrin akọkọ ti o forukọsilẹ ti institute of journalism ti naijiria ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú eto ẹkọ agba communication arts lati yunifásítì ìlú ìbàdàn ibadan south west nàìjíríà arabinrin naa jẹ alaṣẹ ọran awọn ọmọ ile-iwe ti ile-ẹkọ naa ṣaaju ipinnu lati pade rẹ bi olufokosilẹ ti ile-ẹkọ naa ni ọjọ ejidinlogbon oṣu kejila ọdun 2020 ati pe lẹhinna jẹrisi bi alakoso pataki ti ile-ẹkọ naa ni oṣu kẹta ọjọ 17 ọdun okan le ni okoo le ni egbaa
|
omololu falobi omololu falobi 1971-oṣù kẹwàá 5 2006 jẹ́ oníṣẹ́ ìròyìn ní orílẹ̀ èdè naijiria ó sì jẹ́ ajìjàgbara àrùn aids ní ọdún 1997 ó ṣe ìdásílẹ̀ jaaids wọ́n ṣe ìdàsílẹ̀ ẹ̀yẹ ọmololu falobi ní orúkọ rè ní ọdún 1998 ó ṣe ìdásílẹ̀ jaaids tí ó jẹ́ àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba pẹ̀lú èròńgbà láti kó àwọn oníṣẹ́ ìròyìn tí ó wà lórílẹ̀ èdè jọ láti kọ́ wọ́n ní ẹ̀kọ́ nípa ìjàmbá àrùn aids àti ọ̀nà dẹ́kun rẹ̀ ní ọdún 2004 àti ọdún 2005 ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣojú joint united nations programme on hiv/aids ó fi ilẹ̀ ṣaṣọbora ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá ọdún 2006 ní ìlú èkó lagos ní dédé ago mẹ́wàá ọ̀sàn-án kò pẹ́ tí ó kúrò ní olú ilé tí ó wà ní èkó ẹni tí ó fẹ́ paá tẹ̀le tí ó sì yín ìbọn fún ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí ó fi ku ẹbí ó fẹ́ arábìnrin aderonke falobi tí ó sì jẹ́ bàbá ọlọ́mọ mẹ́ta tí ṣe ayomide olamide àti aramide falobi
|
sophia mwasikili sophia edward mwasikili tí a bí ní ọjọ́ kẹrin osù kẹrin ọdún 1986 jẹ́ ogbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-ède tanzania tí ó ṣeré ipò olùgbèjà lórí pápá àti asáájú fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tanzania isẹ́ òkè-òkun mwasikili ti sojú orílẹ̀-ède tanzania ní ìpele àgbà ní bi ìdíje africa women cup of nations qualificationti ọdún 2018
|
jaafar jaafar nigerian journalistjaafar jaafar jẹ́ akọ̀ròyìn ilẹ̀ nigerian ọ́ jé ọmọ bíbí ìlú kano state ó sì jẹ́ olùdásílẹ̀ daily nigerian ilé iṣẹ atẹ̀wéjáde orí ẹ̀rọ ayélujára èyí tí ó ṣe àgbéjáde àgbékúrú fídíò tó takọ gómìnà ìpínlẹ̀ kano abdullahi umar ganduje fún gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ 5 million ní october 2018
|
james vivian clinton nigerian journalist james vivian clinton obe láti ọjọ́ kẹfà oṣù kejì ọdún 1902 - sí ọjọ́ kejìdínlógún oṣù karùn-ún ọdún 1973 jẹ́ akọ̀ròyìn ọmọ bíbí ìlú gold coast ní orílẹ̀-ède sierra leone ó jé olùgbé orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí ó wá láti ìdílé sierra leone creole ni apá ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè india àti àwọn ọmọ bíbí europe tí wọ́n ní òmìnira láti lọ sí ibikíbi ní apá ìwọ̀-oòrùn áfíríkà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó padà gbé ní ìlú calabar ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ obe in 1949 ó sì ní ìbáṣẹpọ̀ tó dájú pẹ̀lú orílẹ̀-èdè sierra leone
|
hamza idris hamza idris tí a bí ní 27 july ọdún 1972 jẹ́ akọ̀ròyìn àti asàtúnse ilé-isé ìwé ìròyìn nigeria's daily trust newspapers òkàn lára àwọn ilé-isé ìwé ìròyìn tó ń síwájú ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni aláàmójútó ipò mèta ní ilé isẹ́ ìwé ìròyín tó ti ń sisẹ́ daily trust daily trust saturday and daily trust on sunday
|
eromo egbejule eromo egbejule j́ẹ oníṣẹ́ ìròyìn olùkọ̀wé àti oníṣẹ fíìmù ó j́ẹ́ olókìkí púpọ̀ jùlọ fún iṣẹ́ rẹ lórí ìkọlù boko haram àti àwọn ìjà mì́iràn ní iwọ-oorun àti central africa lọ́wọ́lọ́wọ́ ó jẹ́ olóòtú áfíríkà ní al jazeera english online abẹ́lẹ̀ ìlú sapele ní apá gúúsù nàíjíríà ni wọ́n ti bí egbejule ó ní àwọn ìwọ̀n-òye ní ìmọ̀-ẹ̀rọ media àti àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti àkọ́ọ́lẹ́ dátà láti university of nigeria nsukka university of leicester àti columbia university lẹ́sẹsẹ iṣẹ́ kíkọ ó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́bi akọ̀ròyìn orin kíkọ fún àwọn ìwé nàìjíríà agbègbè ̀bí i the guardian nigeria thisday next àti ynaija ní ọdūn 2014 ó ṣe à̀layé ìdààmú èbólà ní liberia fún àwọn oníròyìn agbègbè naìjíríà ṣùgbọ́n nígbàmíì ọdún yẹn bẹ̀rẹ̀ ṣiṣẹ́ bí ajábọ̀-íròyìn ọ̀fẹ́ àti okùn fún àwọn oníròyìn àjèjì lórí orin àti àṣà láti ìgbàńà ó ti ṣe ì́jabọ̀́ lọpọ̀lọpọ̀ lórí ìṣọ̀tẹ̀ boko haram àwọn ìdìbò jákèjádò ìwọ-oòrùn áfíríkà ìdúróṣinṣin ní amazon peruvian áwọn ìbátan china-áfíríkà ní ìwo áfíríkà àti àwọn àkòrí ́mìíràn nínú ìfọ̀rọ̀wá́nilẹnuwò ọdún 2017 ó sọ pé ó ti sọ pé ọ̀nà kíkọ rẹ̀ dá lórí 'yíyí cube' dípò àtunlò à̀wọn agbegbè ìjábọ̀ ̀lórí áfíríkà
|
mimi fawaz mimi fawaz jẹ́ akọròyìn eléré ìdárayá tí ilẹ̀ nàìjìríà-labanese olùdarí ètò àti olóòtú tí ó ń ṣiṣẹ́ gẹgẹ́ bíi olóòtú eré ìdárayá ní focus on africatí ìròyìn bbc ifètòlède fún bbc world news pẹ̀lú bbc africa àti bbc sports ó ti ṣiṣẹ́ fún cnn espn àti itv television network ní oṣù kìíní ọdún 2017 ó darí ètò ọdún 2016 tí glo-caf awards òun pẹ̀lú òsèré ìlú nàìjíríàrichard mofe damijo
|
farooq kperogi nigerian academic columnist born 1973farooq adamu kperogi a bi ní ọdún 1973 ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ọmọ nàìjíríà àti amẹ́ríkà akọ̀wé born 1973 media scholarọ̀mọ̀wé ìgbóhùngbáwòrán sáfẹ́fẹ́ akọ̀ròyìn bílọ́gà àti ajìjàgbara ó jẹ́ afìròyìn léde àti aṣàtúnṣe ìròyìn ní ọ̀pọ̀ iwé ìròyìn ilẹ̀ nàìjíríà tí ó fi mọ́ daily trust daily triumph àti new nigerian ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i aṣèwádìí ní ẹ̀ka ìwádìí àti ìbánisọ̀rọ̀ tí ààrẹ ní ìgbà ìṣèjọba olusegun obasanjo tí ó sì kọ́ ṣíṣẹ ìròyìn àti sísọ̀ ìròyìn ní ahmadu bello university àti kaduna polytechnic ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbé ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí kperogi ní ọdún 1973 ní okuta baruten tí ń ṣe agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ ìpínlè kwara ní nàìjíríà ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ bariba baatonu people ó lọ sí bayero university láàárín1993 àti 1997 ní bi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní mass communication ó sì ní ìwé ẹ̀rí nínú communication ìyẹn master's degreeuniversity of louisiana at lafayette àti phd ní georgia state university ní united states ní ọdún 2011
|
tony momoh ọmọ oba tony momoh tí a bí ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣu kẹrin ọdún 1939 tó sì kú ní ọjọ́ kínní oṣù kejì ọdún 2021 jẹ́ akọ̀ròyìn nàijíríà àti olóṣèlú kan tí ó jẹ́ mínísítà fún ìfitónilétí àti àṣà nàijíríà láti ọdún 1986 wọ 1990 lákòókò ìjọba ológun ti ọ̀gágun ibrahim babangida ìbí àti ẹ̀kọ́ a bí momoh ní ọjọ́ 27 oṣù kẹrin ọdún 1939 ní auchi ìjọba ìpínlẹ̀ edo ó jẹ́ ọmọ karùn-ún lé lọ́gọ́jọ 165 ti ọba momoh i ti auchi ó lọ sí ilé-ìwé ìjọba auchi 19491954 àti ilé-ìwé anglican okpe 1954 momoh jẹ́ olùkọ́ni akẹ́ẹ̀kọ́ ní ilé-ìwé anglican auchi oṣù kińní- oṣù kejìlá 1955 ati olukọni ni ile-iwe anglican ubuneke ivbiaro ijọba ibile owan january 1958 - kejìlá 1959
|
robert campbell colonist robert campbell tí a bí ní 7 may 1829 19 january 1884 jẹ́ ọmọ bíbí orílè èdè jamaican tí ó fi ìgbà kan gbé ní orílè èdè united states kí ó tó lo sí orílẹ̀ èdè nàìjíríà ní àkókò ó kò ṣe lábẹ́ atèwéjáde kí ó tó kó ṣé láti di olùkọ́ ti èdè spéìn nígbà tí ó ri pé owó osù òun kéré nínú ìdàrúdàpò ọrọ ajé post-abolition jamaica ó kó lo sí orílẹ̀ èdè nicaragua and panama kí ó tó wá tèdó sí orílẹ̀ èdè new york ní ọdún 1853 ó sise bí atèwéjáde kí wọ́n tó gbà sí isẹ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ imọ science lẹ́yìn náà odi igbá kejì oga ilé ìwé institute for colored youth ni philadelphia pennsylvania
|
simon kolawole simon kolawole jẹ́ akọ̀ròyìn aṣọ̀rọ̀-lórí-ìtàgé àti onímídíà aládàáni ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti olùdarí ní cable newspaper limited lábẹ́ the cable iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn orí afẹ́fẹ́ aládàáni ní ọdún 2012 àjọ ètò ọrọ̀-ajé lágbàáyé the world economic forum pe simon kolawole ní ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́darí lágbàáyé èyiun young global leaders gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀yẹ ìdánimọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ àti ìfọkànjìn rẹ̀ sí àwùjọ gẹ́gẹ́ bí daily trust se ṣe àfihàn rẹ̀ nígbà tí kolawole wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó di ẹni tó kéré jù lọ lọ́jọ́ orí tó jẹ́ aṣàtúnṣe sí ìwé ìròyìn àpapọ̀ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní ọdún 2007 ẹ̀wẹ̀ nígbà tí ó di yíyàn gẹ́gẹ́ bíi aṣàtúnṣe fún ìwé ìròyìn this day ó tún jẹ́ ọmọ nàìjíríà tó kéré jù lọ tí ó ní irú àṣeyọrí yìí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ ìlú ilorin ní ìpínlè kwara orílè-èdè nàìjíríà ni wọ́n gbé bí kolawole simon ṣùgbọ́n ó ṣí lọ sí ìlú mopa ní ìpínlẹ̀ kogi láti gbé pẹ̀lú arúgbóbìnrin rẹ̀ lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú ní inú ìjàmbá ọkọ̀ ojú ọ̀nà ní ọdún 1976 ní ọdún 1989 ó padà sí ìlú èkó láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ gbọyè ní inú mass communication ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì tí ìlú èkó èyiun university of lagos
|
wana udobang wana udobang tí a tún mọ̀ sí wana wana jẹ́ akọ̀ròyìn orile-èdè nàìjíríà ó tún jẹ́ akéwì oníròyìn òṣèré àti òṣìṣé amóhùnmáwòran iṣé rẹ̀ ti hàn ní orí bbc al jazeera huffington post bellanaija àti the guardian wọ́n ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ọ̀kan lára àwọn tó dáátọ́ lẹ́nu kí á sọ̀rọ̀ tó múná dóko
|
abidina coomassie nigerian journalist and newspaper publisher abidina coomassie jẹ́ akọ̀ròyìn àti atẹ̀wé-ìròyìn jáde ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìgbésíayé àti iṣẹ́ rẹ̀ coomassie ni ó dá today's communications ltd sílẹ̀ tí ó ń ṣàtẹ̀jáde ìwé-ìròyìn bí́i defunct today ìwé-ìròyìn ojoojúmọ́ ti abuja mirror àti èdè hausa a yau a bí i sí ìdílé ahmadu coomassie tó jẹ́ alábòójútó àti àkọ̀wẹ́ ní apá àríwá nàìjíríà arákùnrin ló jẹ́ ọ̀gá ọlọ́pá tẹ́lẹ̀ ibrahim coomassie gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ ìròyìn ó bẹ̀rẹ̀ ìṣe rẹ̀ ní ghana broadcasting service lásìkò ìjọba kwame nkrumah lẹ́yìn tí ó kúrò ní ghana ó dára pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ radio frcn kaduna lẹ́yìn náà ó sì ṣe ìròyìn nípa ohun abele naijiria níbi tó ti bá ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ológun tí wọn yóò tún gbà òṣèlú àwọn ipa
|
stumai abdalla stumai abdalla jẹ́ agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-ède tanzania tí ó ṣeré ipò iwájú lórí pápá fún ẹgbẹ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tanzania ní ọdún 2019 ó jẹ́ asáájú fún ikọ̀ ẹgbẹ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-ède nígbà tí wọ́n ń jà fún ife ẹ̀yẹ ìdíje
|
tejitu daba ethiopian-born long-distance runner colspan=3 style=text-aligncenter background-color#b0c4de| medal record women's athletics sport tejitu daba chalchissa ni a bini ọjọ ogun óṣu august ọdun 1991 jẹ elere sisa lobinrin to ṣoju fun bahrain daba gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura ninu idije ti ilẹ asia ere sisa ni ọdun 2011 àṣèyọri tejitu kopa ninu idije agbaye ti iaaf ni ọdun 2009 ni óṣu october ọdun 2009 daba yege ninu ere inu ile ti ilẹ asia to si gba ami ẹyẹ ti wura metres ti ẹ̀gbẹrun mẹta tejitu kopa ninu idije to si ṣoju fun bahrain ni metres ni ẹgbẹrun mẹwa to si gbe ipo kẹrin ni ọdun 2010 tejitu kopa ninu idije agbaye to si jẹ ọkan lara awọn mẹwa to pegede ninu ere ti junior ni ọdun 2011 daba kopa ninu idije agbaye ninu ere sisa pẹlu ipo kẹsan ni wakati 151462 ni ọdun 2011 tejitu yege ninu ere ilẹ arab ni metres ti ẹgbẹrun mẹwa tejitu gba ami ẹyẹ ti idẹ ninu idije ere sisa ti inu ile ti ilẹ asia ni ọdun 2012 lori metres ti ẹgbẹrun mẹta
|
matilda kerry matilda kerry jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó àti asọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìmóhùn máwòrán ó wà lára àwọn tí ó ń ṣe ètò the doctors ó gbajúmọ̀ nígbà tí ó gba àmì-ẹ̀yẹ obìnrin tó rẹwà jù ní nàìjíríà ní ọdún 2000 ẹ̀kọ́ kerry lọ ilé ìwé federal girls college ti benin ibẹ̀ ni ó ti gba ìwé ẹrí waec rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì rẹ̀ ó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní yunifásítì ìlú èkó láti kọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó iṣẹ́ rẹ̀ kerry kàwé gboyè ní yunifásitì ìlú èkó ní ọdún 2006 láti di dókítà alábẹ́rẹ́ òun ni ààrẹ george kerry life foundation àjọ tí ó ń kọ́ àwọn ènìyàn nípa àwọn àìsàn tí kò sé kó ràn ó wà lára àwọn young african leaders initiative ètò tí ààrẹ amerika tẹ́lẹ̀rí barack obama dá kalẹ̀
|
firehiwot dado ethiopian long-distance runner firehiwot tufa dado ni a bini ọjọ kẹsan óṣu january ọdun 1984 si assela arsi jẹ elere sisa lóbinrin ti ọna jinjin tufa yege ninu marathon ti new york city pẹlu wakati 22315 dado kopa ninu marathon ti rome city àṣèyọri dado kopa ninu ere awọn óbinrin ti casablanca ni ọdun 2008 ni ọdun 2009 firehiwot kopa ninu marathon ti rome pẹlu wakati 22708 dado kopa ninu marathon ti frankfurt ni bi to ti gbe ipo kẹrin ni ọdun 2010 firehiwot kopa ninu marathon ti mumbai to si gbe ipo karun firehiwot kopa ninu marathon ti florence ninu ọdun 2010 ni ọdun 2011 firehiwot kopa ninu ere ni rome to si gbe ipo kẹta pẹlu wakati 22413 ni ọdun 2011 dado kopa ninu marathon ti new york pẹlu wakati 22314 ni ọdun 2012 dado kopa ninu marathon ti boston to si gbe ipo kẹrin ni ọdun 2014 dado yege ninu marathon ti prague pẹlu wakati 22334
|
birhan dagne birhan dagne ni a bini ọjọ kẹjọ óṣu april ọdun 1978 jẹ elere sisa lóbinrin jẹ ọmọ bibi ilẹ ethiopia ṣugbọn to gbe ni ilẹ british arabinrin naa da lori ere sisa ti ọna jinjin àṣèyọri dagne kopa ninu idije agbaye junior ti iaaf ti ọju ọna ni metres ti ẹgbẹrun mẹta ati metres ti ẹgbẹrun mẹwa birhan ṣoju fun britain to si kopa ninu idije agbaye ti iaaf ni ọdun 1999 ni ọdun 2004 dagne kopa ninu marathon ti london larin iṣẹju aya ẹyọkan
|
mamitu daska ethiopian long-distance runner colspan=3 style=text-aligncenter background-color#b0c4de| medal record colspan=3 | representing ethiopia colspan =3 mamitu daska molisa ni a bini ọjọ kẹrin lèèlogun óṣu october ọdun 1983 ẹ elere sisa lobinrin órilẹ ede ethiopia to da lo ri ti ayẹyẹ ere sisa ti oju ọna daska gba ami ẹyẹ ti ọla lẹẹmeji ninu idije agbaye ti iaaf arabinrin naa yege ninu marathon ti dubai ati marathon ti houston pẹlu wakati 22159 àṣèyọri daska kopa ninu marathon ti houston ni ọdun 2013 pẹlu iṣẹju aya ti 6953 ni ọ̀dun 2013 daska pari pẹlu ipo kejila ninu marathon ti boston mamitu kopa ninu ere sisa ni ọdun 2013 lori marathon ti frankfurt to si pari pẹlu ipo kẹrin pẹlu wakati 22323 ni ọjọ karun óṣu november ọdun 2017 daska kopa ninu marathon ti new york city to si pari pẹlu ipo kẹta pẹlu wakati 22808 ni óṣu may ọdun 2018 daska yege ninu bolder boulder fun igba kẹfa
|
bizunesh deba ethiopian long-distance runner bizunesh deba ni a bini ọjọ kẹjọ óṣu september ọdun 1987 jẹ elere sisa lobinrin ti ilẹ ethiopia to da lori ere sisa ti ọna jinjin arabinrin naa ṣè dada julọ ni ọdun 2014 ninu marathon ti boston pẹlu wakati 21959 àṣèyọri ni ọdun 2004 deba kopa ninu ere sisa ti ilẹ japan pẹlu wakati 155233 fun metres ti ẹgbẹrun maarun lati ọdun 2009 deba ti yege ninu marathon ti california marathon ti san diego marathon ti los angeles marathon ti boston marathon ti twin cities arabinrin naa pari pẹlu ipo ọkan lara mẹwa to dara julọ ni marathon ti new york city ni ọdun 2011 deba kopa marathon ti san diego to si pari pẹlu wakati 22331 deba kopa ninu marathon ti new york city pẹlu wakati 22319 to si pari pẹlu ipo keji ni ọdun 2013 deba kopa ninu marathon ti houston ni wakati 22426 to si pari pẹlu ipo keji ni 2014 deba kopa ninu marathon ti boston to si yege pẹlu wakati 21959 ni ọjọ keji óṣu november ọdun 2014 deba gbe ipo kẹsan lori papa iṣere ti awọn óbinrin ninu marathon ti new york city pẹlu wakati 23140 ni ọdun 2015 deba pari pẹlu ipo kẹta ninu marathon ti boston pẹlu wakati 22509
|
hamza idris
|
ramadan ramadan ramzan ramadhan tàbí ramathan jẹ́ oṣù kẹsàn-án nínú ònkà oṣù ojú ọ̀run ẹ̀sìn ìmàle gbogbo ẹlẹ̀sìn islam ninwọ́n ma ń gba àwẹ̀ nínú oṣù ramadan jákè-jádò agbáyé tí wọ́n sì ma ń kún fún bíbẹ ọlọ́run púpọ̀ jùlọ gbígba awẹ̀ nínú oṣù ramadan lọ́dọọdún jẹ́ ìkan nínú àwọn òpó márùún ìmàle wọ́n ma ń gba awẹ̀ nínú oṣù ramadan fún ọgbọ̀n ọjọ́ tàbí ọjọ́ mọ́kàndílọ̀gbọ̀n bíbẹ̀rẹ̀ awẹ̀ ma ń dá lé bí wọ́n bá ṣe rí ìlétéṣù lójú ọ̀run níparí oṣù sha'abán bí wọ́n bá sì fẹ́ túnu wọn yóò ma wòye ojú ọjọ́ fún lílé oṣù oṣù shawwal tàbí kí won ka àwẹ̀ ramadan pe ọgbọ̀n gbáko kí wọ́n tó dáwọ́ awẹ̀ dúró gbígbàwẹ̀ láti òwúrọ̀ kùtùkùtù tí tí di ìgbà tí oòrùn bá ti wọ̀ tán jẹ́ dan dan fún gbogbo mùsùlùmí tí wọ́n ti bàlágà yí wọ́n kò sì ní ìṣòro àárẹ̀ tàbí àìsàn tó lágbára tí wọn kò sì sí ní inú ìrìn-àjò tó lágbára tí wọn kò sì kìí ṣe arúgbò kùjọ́ kùjọ́ bákan náà tí wọn kò sì kìí ṣe abiyamọ tí wọ́n ń fọmọ lóyàn tàbí ṣe nkan oṣù lọ́wọ́ oúnjẹ tí wọ́n ma ń jẹ ní ìdájí ni wọn ń pe ní sààrì nígbà tí oúnjẹ tí wọ́n ma ń jẹ tí wọ́n fi ń ṣínu ni wọ́n ń pe ní ìṣínu
|
eleanor nwadinobi eleanor nwadinobi jẹ́ dókítà alábẹ́rẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti ajà fún ètò ìlera tó péye fún àwọn obìnrin òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí a kọ́kọ́ yàn gẹ́gẹ́ bi ààrẹ medical women international association ìpìlẹ̀ rẹ̀ bàbá eleanor jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ ábíá nàìjíríà ìyá rẹ̀ sì wá láti orílẹ̀-èdè jamaica àwọn méjèèjì pàdé ní london nígbà tí bàbá rẹ̀ ń kọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó ti àwọn ẹranko ní yunifásítì ti london àti tí ìyá rẹ̀ ń kó nípa iṣẹ́ núrsì eleanor lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé nítorí iṣẹ́ tí bàbá rẹ̀ ń ṣe àti nítorí ìjà abẹ́lé nàìjíríà ó lọ ilé ìwé queen’s school enugu saint louis grammar school ibadan àti international school yunifásitì ìlú ibadan ó kàwé gboyè nínú ìmò ìṣègùn òyìnbó ní yunifásítì ilẹ̀ nàìjíríà ó tẹ̀síwájú láti gba àmì-ẹ̀yẹ master’s degree nínú ìmọ̀ ètọ́ ọmọ ènìyàn ní european inter-university centre venice italy
|
mamman daura mamman daura tí á bí ní ọdún 1939 jẹ́ olóòtù ìròyìn ti nàìjíríà tí ó ṣé àtúnkọ tí ó padà ṣe ìṣàkóso nàìjíríà tuntun láti ọdún 1969 di 1975 ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n sí ààrẹ muhammadu buhari àti ọ̀kan gbòógì ọmọ ẹgbẹ́ kaduna mafia ẹgbẹ́ aláìmúnisìn oníṣòwò òṣìṣẹ́ ìlú ọ̀jọ̀gbọ́n àti olórí ológún láti ilẹ̀-àríwá náìjíríà ìgbésí ayé rẹ̀ a bí mamman daura ní daura ílè aríwà british nigeria ní ọdún 1939 bàbá rẹ̀ alhaji dauda daura dì oyé durbin daura tí daura emirate ó sì jẹ́ ẹ̀gbọ́n muhammadu buhari ó kẹ́ẹ̀kọ́ ní daura elementary school katsina middle school kí ó tó lọ sí provincial secondary school okene ní ọdún 1956 nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ó bẹ̀rẹ̀ síí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú daura native authority fún ọdún díẹ̀ kí ó tó dáràpọ̀ mọ́ nigerian broadcasting corporation ó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ilẹ̀-àríwá mẹ́fà tí sir ahmadu bello yàn láti kẹ́kọ̀ọ́ ní england
|
meseret defar ethiopian long-distance runner meseret defar tola ni a bini ọjọ ọkan dinlọgbọn óṣu november ọdun 1983 jẹ elere sisa lóbinrin to da lori ayẹyẹ ti metres ẹgbẹrun mẹta ati metres ti ẹgbẹrun maarun àṣèyọri ni ọdun 2003 defar gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura ti metres ti ẹgbẹrun maarun ni ọdun 2004 defar kopa ninu olympics ti summer ni athens pẹlu wakati 144565 ni ọdun 2008 defar kopa ninu olympics ti beijing to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver ni ọjọ akọkọ óṣu september ọdun 2007 defar kopa ninu idije agbaye ni osaka ti metres ti ẹgbẹrun maarun to si gba wura pẹlu wakati 145791 ni 2007 defar gba ami ẹyẹ gẹgẹbi obinrin to pegede julọ ninu iaaf agbaye lori ere sisa ninu ọdun naa ni ọdun 2005 meseret kopa ninu idije agbaye to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver to waye ni helsinki ni ọdun 2006 defar kopa ninu idije agbaye ti inule ti metres ti ẹgbẹrun mẹta ni ọdun 2008 defar kopa ninu idije agbaye ti inule ti metres ti ẹgbẹrun mẹta to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura ni ọdun 2009 defar kopa ninu idije agbaye lori ere sisa ti metres ti ẹgbẹrun mẹwa pẹlu wakati 295920 ni ọdun 2009 defar kopa ninu idije agbaye lori ere sisa ti metres ti ẹgbẹrun mẹta pẹlu wakati 83015 ni ọdun 2010 meseret kopa idije ilẹ afirica ti metres ti ẹgbẹrun to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver ni ọdun 2010 defar kopa ninu cup ti iaaf ti metres ti ẹgbẹrun mẹta ni ọdun 2010 defar kopa ninu idaji marathon ti philadelphia pẹlu wakati 10744 ni ọdun 2011 defar kopa ninu idije agbaye lori ere sisa ti metres ti ẹgbẹrun mẹwa ati ẹgbẹrun maarun ni ọdun 2012 meseret kopa ninu idije agbaye ti inule pẹlu ipo keji ni ọdun 2012 defar kopa ninu olympics ti london ti metres ti ẹgbẹrun maarun ni ọdun 2013 meseret yege ninu idaji marathon ti new orleans pẹlu wakati 83528 ti metres ti ẹgberun mẹta defar yege ninu idije agbaye ni moscow pẹlu wakati 145019 ti metres ti ẹgbẹrun maarun
|
worknesh degefa ethiopian long-distance road runner worknesh degefa tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1990 jẹ́ ọmọbìnrin tó ń kópa ní nú eré sísá ti ọ̀nà jínjìn ní orílẹ̀-èdè ethopia arábìnrin náà jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹrin nínú àwọn tó lè sá eré jù àṣeyọrí ní ọdún 2016 worknesh kópa nínú marathon ti ìdajì ti prague tó sì parí láàárín wákàtí 10614 ní ọdún 2017 degefa kópa nínu marathon ti dubai pẹ̀lú wákàtí 21953 ní oṣù january ọdún 2019 worknesh kópa nínú marathon ti dubai pẹ̀lú wákàtí 21741 ní ọjọ́ karùnlélógún oṣù april ọdún 2019 degefa yege nínú marathon ti boston pẹ̀lú wákàtí 22331
|
olayinka koso-thomas olayinka koso-thomas tí a bí ní ọdún 1937 jẹ́ dókítà alábẹ́rẹ́ tí a bí ní nàìjíríà ṣùgbọ́n tí ó ń gbé ní orílẹ̀-èdè sierra leone wọ́n mọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè fún ipa rẹ̀ láti dá sí ṣẹ abẹ ojú ara àwọn ọmọbìnrin jòjòló dúró ní ọdún 1998 ó gba àmì-ẹ̀yẹ prince of asturias award fún iṣẹ́ rẹ̀
|
yihunlish delelecha yihunlish delelecha tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣu kẹwàá ọdún 1981 jẹ́ ọmọbìnrin tó ń kópa nínú eré-ìdárayá ti eré-sísá ní orílẹ̀-èdè ethiópíà arábìnrin náà kópa nínú ìdíje àgbáyé ti eré-sísá tó sì gba àmì-ẹ̀yẹ ti silver fún ilẹ̀ ethiopia àṣeyọrí ní ọdún 1998 delelecha kópa nínú ìdíje ti iaaf tó wáyé ní ìlú marrakesh ní orílẹ̀-èdè morocco níbi tó ti ṣojú fún ilẹ̀ ethiopia ní ọdún 2011 delelecha kópa nínú marathon ti grandma tó sì gbé ipò àkọ́kọ́ láàárín wákàtí 023039 ní ọdún 2012 delelecha kópa nínú marathon ti houston tó sì gbé ipò kẹta ní ọdún 2012 delelecha kópa nínú eré tó wáyé ní washington dc tó sì gbé ipò kẹta láàárín wákàtí 5433 ní ọdún 2012 arábìnrin náà kópa nínù ìdajì marathon ti pittsburgh tó sì gbé ipò kẹrin àsìkò tí delelecha lò ni 23536 ní ọdún 2012 yihunlish kópa nínú ìdajì marathon ti philadelphia tó sì gbé ipò kẹrin ní ọdún 2013 delelecha kópa nínú eré ti pittsburgh tó sì parí pẹ̀lú ipò kẹta
|
shure demise shure demise ware tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kìíní ọdún 1996 jẹ́ ọmọbìnrin tó ń kópa nínú eré-ìdárayá eré-sísá ní orílẹ̀-èdè ethopia tó sì ti kópa nínú ìdíje lóríṣiríṣi àṣeyọrí ní ọdún 2015 demise kópa nínú marathon ti dubai tó sì parí pẹ̀lú ipò kẹrin ní ọdún 2015 demise kópa nínú marathon ti ilẹ̀ boston tó sì parí pẹ̀lú ipò kẹjọ ní ọdún 2019 demise kópa nínú marathon ti àwọn obìnrin ní ìdíje àgbáyé lórí eré sísá tó wáyé ní doha qatar
|
merima denboba merima denboba tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹjọ ọdún 1974 ní ìlú arsi jẹ́ ọmọbìnrin eléré sísá tẹ́lẹ̀ rí tó dá lórí ẹgbẹ̀rúnmárùn-ún mítà àṣèyọri ni ọdun 2003 denboba yege ninu oeiras ti agbaye to si tun yege ninu cross internacional de itàlica ni ọdun naa arabinrin naa pada wa fun àṣèyọri keji ni ọdun 2004
|
birhane dibaba birhane dibaba tí a bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹsàn-án ọdún 1993 jẹ́ ọmọbìnrin eléré sísá ti ọ̀nà jínjìn tó dá lórí ìdíje ti eré sísá ti ojú ọ̀nà àṣeyọrí ní ọdún 2014 dibaba kópa nínú marathon ti tokyo tó sì gbé ipò kejì láàárín wákàtí 22230 ní ọdún 2015 birhane kópa nínú marathon ti tokyo tó sì gbé ipò àkọ́kọ́ láàárín wákàtí 22315 ní ọdún 2015 birhane ni a yàn gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó yege nínú eré sísá ní ìdíje àgbáyé láti ṣojú fún ẹgbẹ́ eré sísá àwọn obìnrin ti ilẹ̀ ethiopia ní ọdún 2017 birhane kópa nínú ìdíje àgbáyé ti eré sísá nínú marathon ti àwọn obìnrin
|
celestial church of christ benin - batism ceremony in cotonoujpg the celestial church of christ tí a tún mọ̀ sí ìjọ mímọ́ ti kristiccc jẹ́ ilé-ìjọsìn tí samuel oshoffa dá sílẹ̀ ní áfríkà ní ọjọ́ 29 oṣù kẹsàn-án ní ìlú porto-novo nih benin ó wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé pẹ̀lú orílẹ̀ èdè america àti àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ ní africa ìtàn oshoffa tí a bí sí dahomey ní ọdún 1909 fìgbà kan jẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà tí ó ti di benin báyìí ìjọ methodist ni ó dàgbà sí ó ní ìṣípayá àtọ̀runwá nígbà tí ó sọnù sínú igbó ní ọjọ́ 23 oṣù karùn-ún ọdún 1947 tí ìṣẹ̀lẹ̀ eclipse ṣẹ̀ ó nímọ̀lára láti gbàdúrà láti mú àwọn aláìsàn lára dá àti láti jí àwọn òkú dìde ó dá ìjọ rẹ̀ sílẹ̀ ní oṣù kẹsàn-án ọdún 1947 lẹ́yìn tí ó ti yan ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì olùṣọ́-àgùtàn àti olùdásílẹ̀ ipò tí ó ga jù lọ ni ó wà nígbà náà ccc gba ìdánimọ̀ àti àṣẹ láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ wọn láti ọwọ́ orílẹ̀-èdè dahomey ní ọdún 1965 láti ọdún 1976 ìjọ náà bẹ̀rẹ̀ ìpolongo ìhìnrere ní orílẹ̀-èdè yẹn tó fìgbà kan jẹ́ french west africa tó ti gba òmìnira ní ọdún 1960 láti òpin ọdún 1960 ìjọ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ẹ̀rọ-ayélujára fún ìpolongo ìhìnrere èyí sì mú kí ìbánisọ̀rọ̀ wà láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka ìjọ náà tó ti wà ní ìdásílẹ̀ káàkiri ilẹ̀ òke-òkun tí ọmọ africa wà bíi united kingdom germany austria france àti united states orílẹ̀-èdè nàìjíríà ni ìjọ yìí gbajúmọ̀ sí lẹ́yìn ikú oshoffa ìjọ náà ń tẹ̀síwájú àmọ́ kò ṣàìrí àwọn ìdojúkọ kọ̀ọ̀kan èyí tó wọ́ pọ̀ jù lọ ní ọ̀rọ̀ olórí àti adarí ìjọ náà lẹ́yìn ikú oshoffa lẹ́yìn bàbá oshoffa alexander abiodun adebayo bada ló jẹ́ adarí ìjọ náà títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹsàn-án ọdún 2000 lẹ́yìn náà ni philip hunsu ajose gorí ipò náà fún ìgbà díẹ̀ torí ikú rẹ̀ ní oṣù kẹta ọdún 2001 awuyewuye ṣẹlẹ̀ lórí arọ́pò ajose àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn kan kéde gilbert oluwatosin jesse gẹ́gẹ́ bíi olórí tuntun nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ reverend emmanuel oshoffa tí ó jẹ́ ọmọ samuel oshoffa bada bíi olórí tuntun lẹ́yìn ikú jesse ẹgbẹ́ rẹ̀ polongo pé ajíhìnrere gíga jù lọ paul suru maforikan ni aṣáájú ẹ̀mí tuntun ti ìjọ ní ìlòdì sí ìlànà ìtẹ́lọ́rún ní naijiria porto-novo tó jẹ́ olú ilé-ìjọsìn gíga jù lọ yan benoit agbaossi 19312010 láti jẹ olórí ilé-ìjọsìn ẹni tí ó wá yan benoit adeogun ní àkókò tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olùṣọ́-àgùtàn láìpẹ́ kí ó tó kú ní ọdún 2010
|
bosede bukola afolabi bosede bukola afolabi jẹ́ dókítà ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà tó jẹ́ onímọ̀ nípa àìsàn ojú ara àwọn obìnrin òjògbón àti adarí ẹ̀ka àwọn olóyún àti àwọn àìsàn ti ojú ara obìnrin ní ilé ìwòsàn ti yunifásitì ìpínlẹ̀ èkó èkó nàìjíríà òun tún ni ọ̀lùdásílẹ̀ àti alága mrh maternal and reproductive health research collective
|
aderonke kale aderonke kale jẹ́ dókítà ọpọlọ fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ológun nàìjíríà òun ni obìnrin àkọ́kọ́ láti di majo general ẹgbẹ́ ọmọ ológun nàìjíríà ó wà lára àwọn adarí nigerian army medical corps iṣẹ́ rẹ̀ aderonke kale kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó ní kọ́lẹ́jì yunifásitì tí ó padà di yunifásítì ìlú ìbàdàn lẹ́yìn náà kale tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ ọpọlọ ní yunifásitì ti london awòkọ́se òjògbón thomas adeoye lambo ẹni tí ó jẹ́ dókítà ọpọlọ àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ áfríkà ni kale wò kí ó tó fi pinu pé òun fẹ́ di dókítá ọpọlọ ó ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ní britain kí ó tó padà sí nàìjíríà ní odún 1971 ní ọdún 1972 ó dara pọ̀ ẹgbẹ́ ológun nàìjíríà èyí jẹ́ òun tí kò wọ́pọ̀ láàrin àwọn obìnrin ní ìgbà náà pàápàá jùlọ láàrin àwọn obìnrin tí ọwọ́ wọn ti lọ òkè lẹ́nu iṣẹ́ wọn ó padà di majo general nínú iṣẹ́ ológun tí ó tó fẹ̀híntì ní ọdún 1997 ìgbésí ayé rẹ̀ wọ́n bí aderonke kale ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdún 1959 bàbá kale jẹ́ onímọ̀ ògùn òyìnbó ìyá rẹ̀ sì jẹ́ olùkọ́ àwọn méjèèjì sa ipá wọn láti ri wípé kale ni ẹ̀kọ́ tó dájú kale lọ ilé-ìwé primari ní èkó àti zaria kí ó tó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní st anne's school ibadan àti abeokuta grammar school ọmọ ẹ̀yà yorùbá ni aderonke
|
ejegayehu dibaba ethiopian long-distance runner ejegayehu dibaba keneni ni a bini ọjọ kọkan leelogun óṣu march ọdun 1982 si bekoji jẹ elere sisa lóbinrin ilẹ ethiopia àṣèyọri ni ọdun 2003 dibaba kopa ninu ere ti gbogbo ilẹ afirica ti mita ti ẹgbẹrun mẹwa to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura ni ọdun 2004 ejegayehu kopa ninu olympics ti athens ninu mita ti ẹgbẹẹrun mẹwa to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver ni ọdun 2005 dibaba kopa ninu idije agbaye lori ere sisa ti mita ti ẹgbẹrun maarun to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti idẹ ni ọdun 2010 dibaba kopa ninu ere sisa ti kilo mita meje to wayr ni memorial ti peppe greco to si gbe ipo keji ni ọdun 2011 ejegayehu kopa ninu marathon ti chicago pẹlu wakati 22209
|
genzebe dibaba ethiopian middle and long-distance runner genzebe dibaba keneni ni a bini ọjọ kẹjọ óṣu february ọdun 1991 jẹ elere sisa lóbinrin ilẹ ethiopia to da lori arin ati ọna jinjin àṣèyọri ni ọdun 2008 genzebe yege ninu idije agbaye u20 to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver ninu mita ti ẹgbẹrun maarun lati ọdun 2009 de 2017 genzebe kopa ninu idije agbaye to si tun kopa ninu àṣèkagba awọn ere sisa naa ni ọdun 2010 dibaba kopa ninu idije agbaye u20 lẹlẹkeji to si gba wura ni mita ti ẹgbẹrun maarun ni ọdun 2014 dibaba ni a peni elerelobinrin ti laureus fun ọdun naa ni ọdun 2015 dibaba jẹ elere sisa lobinrin ti iaaf agbaye ti ọdun naa ni ọdun 2015 genzebe kopa ninu idije agbaye ti mita ti ẹgbẹrun maarun to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti idẹ ati wura ninu ayẹyẹ naa ni ọdun 2016 genzebe kopa ninu olympics ti rio to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver ni mita ti ẹgbẹrun kan ati aadọrun
|
mare dibaba ethiopian long-distance runner mare dibaba hurrsa ni a bini ọjọ ogun óṣu october ni ọdun 1989 jẹ elere sisa lóbinrin to da lori ọna jinjin àṣèyọri ni ọdun 2007 dibaba kopa ninu idije ti ilẹ ethiopia to si gbe ipo kẹfa ni bi to ti sare fun ọlọpa ti oromia ni ọdun 2008 dibaba kopa ninu idaji marathon ti new delhi to si gbe ipo kẹjọ pẹlu wakati 11028 ni ọdun 2009 dibaba kopa ninu idaji marathon ti delhi to si gbe ipo kẹfa pẹlu wakati 10845 ni óṣu february mare pari pẹlu ipo kẹta ninu idaji marathon ti ras al khaimah ni ọdun 2011 dibaba ṣoju fun órilẹ ede rẹ ninu ere gbogbo ilẹ afirica to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura pẹlu wakati 11047 ni óṣu october ọdun 2011 dibaba kopa ninu marathon ti toronto to si pari pẹlu ipo keji pẹlu wakati 22325 ni ọdun 2012 mare kopa ninu marathon ti ilẹ dubai pẹlu wakati 21952 to si pari pẹlu ipo kẹta ni ọdun 2012 dibaba kopa ninu idaji marathon ti philadelphia to si pari pẹlu ipo keji ni ọdun 2014 mare yege ninu marathon ti ile ifowopamọ ilẹ america ti chicago pẹlu wakati 22537 mare kopa ninu marathon ti idije agbaye to waye ni ọdun 2015 ni ilẹ beijing
|
betta edu betta c edu tí a bí ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ́n oṣù kẹ̀wá ọdún 1986 jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera ara ní ìpínlẹ̀ cross river àti alága ẹgbẹ́ àwọn kọmíṣọ́nà ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà
|
ọjọ́ ìbí ọjọ́ ìbí rẹ ni ìṣè-rántí ọjọ́ tí a bí ọ sáye ọjọ́ ìbí ni ajodun ojo pato ti a bi enikan gẹ́gẹ́ bí arákùnrin simon jacobson ti ṣé lálàyé ó dára kí a máa dunnú fún àwọn ohun ti a jẹ́ láyé àti ohun tí ati gbé ilé ayé ṣe sùgbón kí awá tó leè máa ṣe eléyìí a ní lati kọ́ mó rírì ìbí wa gan an ìbí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀da òhun ni fèrèsè si ìgbé ayé ẹ̀dá lati le ní àbáyọrí ipa rẹ nítorínà ọjọ́ ìbí jẹ́ àkókò kan pàtàkì tó yẹ kí a yà sọ́tọ̀ fún ra ẹni bí ẹní ya ọjọ́ ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè tàbí ọjọ́ tí a ṣẹ̀da ilé-iṣẹ́ kan síbẹ̀ ó kọ ja pé kí a kan gba ẹ̀bùn lásán lọ ó tún jẹ́ àkókò láti rántí awọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó ti ṣelẹ̀ lati ṣe àjọyọ̀ ìdúpẹ́ ati àtún gbéyẹ̀wò bí a ti ṣe nlo ayé wa dáradára si nítorí àkókò àti ìgbà a maá yí áwọn nkan pàtàkì a máa wáyé ní àkókò ọjọ́ ìbí rẹ lọ́dọdún irúfẹ́ okun kan naa tí adẹ́da fi kun ọ yóò tún ru ọ́ sóke ní àkókò yi ojúṣe wa sì ni lati túraká pẹ̀lu a le ṣe èyí nípa jíjọ̀wọ́ ara wa fún adẹ́da wa àti láti lo àwọn ẹ̀bùn ati ohun tí o wà ní ìkáwọ́ wa láti ṣe ara wa ati alabágbé àyíka wa ati gbogbo or=lẹ̀ àgbáye loore bí adẹ́da ti n fẹ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ni a fi n ṣe àjọyọ̀ ìbí fún ra rẹ̀ àti ayọ̀ ìwàláàyè ó sì tún jẹ́ àkókò láti tún inú wa rò lo rii ki ni ìpààlà larin àwọn àṣeyọrí tí atiṣe ati àwọn tí a tún leèṣe ṣé mo n lo àkókò mi dáradára tabi mi ò sí ni ojú ọ̀na gaan tí o yẹ kí o wa bawo ni mo ṣe lee mú èrò àti ìse mi dógba ọjọ́ ìbí tun le mú wa ní àròjinlẹ̀ nípa ohun tí ìbí ènìyàn jẹ́láti rántí ọjo ìbi jẹ́ ànfàní láti pinnu ìbẹ̀ẹ̣̀rẹ̀ ìgbé-ayé tuntun kò ní fiṣe bí ohun kan ti rí lánànan tàbí ní àkòkò díẹ̀ sẹ́hìn gbogbo ìgbà ni a maa ní ore-ọ̀fẹ́ áti tún ìtàn ayé wa kọ ọjọ ìbí a máa tunilára a máa fún ni ni ore-ọ̀fẹ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ ayé ara ẹni kii ṣe ní ti àwọn nkan àfọwọ́bà nìkan sùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ohun tí nṣe tẹ̀mí o lèè kó mọ̀lẹ́bí àti àwọn ojúlùmọ̀ rẹ jọ ní ọjọ́ ìbí rẹ kí ẹ́ jùmò ṣe ìgbéléwò àwọn ohun tí o ṣe ànfàní tí ó sì ṣe pàtàkì kò wá sí ohun tí ó dára tó kí a ṣe ọjọ́ ìbí pẹ̀lú ọkàn ìṣòore tí a bá fẹ́ fi ọkàn ọpẹ́ wa han iba dára kí a ṣe pẹ̀lú ohun àrítọkasí rere kan ni gbatí a kò tilẹ̀ ṣee lana tàbí pe ṣe ni a fi ipá mu wa tàbí pé ẹnìkan ni ó tọ́ka rè síwa sùgbọ́n ti ó jẹ́ ohun tí o wá láti inú ọkan ẹni láti dúpẹ́ ìbí áti ìdásí wa irúfẹ́ nkan bayìi a maa mú inú ẹlẹ́da ẹni dùn èyí gan ni ìríri ótítọ́ pé abíniwáyé
|
michelle abueng michelle abueng tí a bí ní ọjọ́ kẹfà osù kaàrún ọdún 2001 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti orílẹ̀-ède botswana kan tí ó mú ipò iwájú lórí pápá fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù zambia fc yasa fc àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin ti orílẹ̀-ède botswana ó di ẹni tí ẹgbẹ́ zambia yasa queens mọ̀ nígbà tí ó ń gbábọ́ọ̀lù tako zambia ní bi african u-17 women's world cup qualifying tournament ti ọdún 2018 ṣùgbọ́n wọn kò ní àànfàní láti buwọ́ lùú gbígbà wọlé rẹ̀ títí di ọdún 2019 nítorípé ó jẹ́ ọmọdé ní àkókò náà ó mi àwọ̀n pẹ̀lú àmi ayò máàrún nínú eré bọ́ọ̀lù tí ó gbá tako namibia ní bi ìdíje ayẹyẹ ife àgbáyé ti àwọn obìrin u-20 ti ọdún 2020 ó ṣe àkọ́kọ́ ìfarahàn ti òkè-òkun ní bi ìdíje 2019 cosafa women's championship ní ọjọ́ kinní oṣù kẹjọ ọdún 2019
|
nikan gaofetoge lone gaofetoge tí a bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún osù keje ọdún 2001 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti orílẹ̀-ède motswana kan tí ó mú ipò olùgbèjà lórí pápá fún geronah àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ti àwọn obìnrin ti orílẹ̀-ède botswana
|
nondi mahlasela nondi mahlasela tí a bí ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1991 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti orílẹ̀-ède motswana kan tí ó mú ipò iwájú lórí pápá fún prison àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àwọn obìnrin ti orílẹ̀-ède botswana
|
lesego moeng lesego gloria moeng tí a bí ní ọjọ́ kẹta osù kínní ọdún 1998 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti orílẹ̀-ède motswana kan tí ó mú ipò asọ́lé lórí pápá fún bdf àti ẹgbẹ́ àwọn obìnrin orílẹ̀-ède botswana isẹ́ ẹgbẹ́ moeng ti gbábọ́ọ̀lù fún geronah ní botswana isẹ́ òkè-òkun moeng dúró fún botswana ní ìpele àgbà ní àkókò ìdíje cosafa women's championship ti ọdún 2021 àti africa women cup of nation qualification ti ọdún 2022
|
olufunke adeboye olufunke adeboye jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní ẹ̀ka fún ìtàn ní yunifásítì ìlú èkó nàìjíríà òun ni adarí faculty of arts ilé-ìwé náà lọ́wọ́ lọ́wọ́ àwọn ǹkan tí adeboye fẹ́ràn láti ma ṣe ìwádìí nípa ni ìtàn nàìjíríà kí ó ti pé àwọn òyìnbó amúnisìn ko nàìjíríà lẹ́rú nígbà tí wọ́n kọ lẹ́rú àti nípa bí ìjọ pentecostal ṣe gbilẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn africa ìpìlẹ̀ a bí olufunke adeboye orúkọ àbísọ rẹ̀ ni òjó ní ibadan nàìjíríà ó lọ ilé ìwé our lady's girls' high school ile-ife ní ìpínlẹ̀ osun nàìjíríà ní odún 1983 ó lọ yunifásítì ìlú ìbàdàn nàìjíríà níbi tí ó ti gba àmì ẹyẹ bachelor of arts ba masters of arts ma àti dókítàphd nínú ìmò ìtàn ní ọdún 1988 1990 àti 1997 ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi igbákejì olùkọ́ ní yunifásitì ìpínlẹ̀ ogun tí orúkọ rẹ̀ ti yí padà sí olabisi onabanjo university ago iwoye nàìjíríà ní ọdún 1991 ní ọdún 1999 ó lọ sí ẹ̀ka ìtàn ní yunifásitì ìlú èkó gẹ́gẹ́ bi olùkọ́ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń gòkè nínú iṣẹ́ rẹ̀ kí a tó sọ di ọ̀jọ̀gbọ́n ní oṣù kẹta ọdún 2011
|
aisha lawal nigerian actress aisha lawal oladunni jẹ́ òṣèré nàìjíríà òǹkọ̀wé àti òṣèré fíìmù arábìnrin náà ni wọ́n yàn fún àmì ẹ̀yẹ òṣèré tí ó ní ìlérí jùlọ yoruba ní ọdún 2014 city people entertainment awards òṣèré tí ó dára jùlọ nínú ìkópa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú best actress in leading role - yoruba àmì ẹ̀yẹ ní ọdún 2015 best of nollywood awards best indigenous language movie/tv series yoruba ní awards africa magic viewers' choice awards 2016 àti òṣèré tí ó dára jù ti ọdún yoruba àti òṣèré àtìlẹ́yìn dára jùlọ ti ọdún yoruba ní ọdún 2018 city people movie awards </ref> ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ aisha lawal jẹ́ ọmọ bíbí ìlú ìbàdàn ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ní ilẹ̀ nàìjíríà ó sì lọ sí adeen international school àti federal government college ògbómọ̀ṣọ́ aisha lawal ní ìtara láti ṣe ìṣèré láti ìgbà èwe rẹ̀ níbi tí yóò ṣe ní oríṣiríṣi àwọn eré orí ìtàgé lẹ́hìn náà lawal lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga lead city níbití ó ti gba òye ní òfin àti òye kejì ní ìṣàkóso gbogbo ènìyàn public administration iṣẹ́ rẹ̀ aisha lawal lọ sí femi adebayo's j15 school of performing arts láti ọdún 2008 sí ọdún 2010 ó sì kọ́ bí a ṣe lè ṣe eré fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀ ni 'adun-ma-deeke' níbi tí ó ti ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó ó di olókìkí láti ipa rẹ̀ ní 'irugbin' láti ìgbà tí ó ti di olókìkí ó tẹ̀síwájú láti ṣe eré ní àwọn fíìmù tí ó ju ọgọ́rùn-ún lọ ó ti gbé fíìmù tó bí mẹ́wàá jáde gẹ́gẹ́ bí imú níkà àti ọpọ́n ìfẹ́ láìpẹ́ ó ṣàfihàn nínú love castle 2021 àti fíìmù netflix ti kunle afolayan aníkúlápó 2022 bí i olòrì súnkànmí ayé rẹ̀ aisha lawal wá láti ìdílé tí ó ní ọmọ mẹ́ta àti pé òun ni ọmọ kejì ó ti ṣe ìgbéyàwó tí ó sì ti bí ọmọbìnrin kan ó jẹ́ mùsùlùmí
|
christie ade ajayi christie ade ajayi tí a bí ní ọdún 1930 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí ó ń jà fitafita fún kíkó àwọn ọmọdé bí a ti ń kàwé láti ìgbà tí wón ti wà ní ọmọ jòjòló ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ní èdè gẹ̀ẹ́sì fún àwọn ọmọdé àwọn ìwé rẹ̀ sì jẹ́ ìwé nípa nàìjíríà ó tún jẹ́ olùkọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ó s jẹ́ ọmọ àwọn ẹgbẹ́ kọ̀kan tí ó ń bìkítà fún ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdé ìtàn wọ́n bí christie aduke martins ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ọdún 1930 ní ile oluji ìpínlẹ̀ òndó christie ade ajayi tí wón tún le ko bi ade-ajayi lọ sí kudeti girls' school ní ìlú ibadan tí àwọn ènìyàn wá padà mọ̀ sí st anne's school lẹyìn náà ó lọ sí united missionary college ibadan níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ láti di olùkọ́ ó tún tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní froebel institute london àti ní institute of education níbi tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ diploma nínú ìmò títọ́ àwọn ọmọdé ní ọdún 1958 láàrin ọdún 1952 sí 1978 ó kọ́ àwọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé ní nàìjíríà àti ní ilé-ìwé kan ní london níbi tí ó ti di olórí ilé-iwé náà headmistress ó tún tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní san jose state university california ó fẹ́ j f ade ajayi ní ọdún 1956 àwọn méjèèjì sí bí ọmọ márùn-ún
|
ummi ibrahim ummi ibrahim jẹ́ òṣèrébìrin kannywood an hausa language cinema tó di olókìkí nínú fíìmù jinsi níbi tí ó ti ní orúkọ rẹ̀ ní zeezee iṣẹ́ rẹ̀ àríyànjiyàn wà nípa òṣèré náà ní ilé-iṣẹ́ náà bí ó ṣe sọ pé òun lòún ga jùlọ èyí fa ifarapa láàrín àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti ríi kẹ́hìn ní kannywood ní ọdún 2006
|
ọláyẹmí ògúnwọlé
|
jasmine nwajei nigerian basketball playerjasmine nwajei tí a bí ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ọdún 1995 ó jẹ́ ajubọ́ọ̀lù sápẹ̀rẹ̀ tí ikọ̀ first bank bc tí orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó sì jẹ́ ajubọọlu sapẹrẹ tí ikọ̀ nàìjíríà nigerian national team ó ṣojú ikọ̀ nàìjíríà ní 2019 women's afrobasket wagner and syracuse statistics source
|
katherine obiang katherine obiang jé òsèrébìnrin ọmọ orílẹ-èdè nàìjíríà àti cameroon agbóhùn-sáféfé àti olóòtú ètò amóhùnmáwòran lákòókó ó sisé gégé bíi olóòtú ètò amóhùnmáwòrán fun nigerian television authority nta ni am express àti nigeria info 993fm ó bèrè sí ní se eré ó sì n kópa nínu sinimá àgbéléwò ó kópa nínu eré kan tí àkolé rè n jé the women ní odún 2017 ó gba àmì èye ní odún 2017 pèlú kate henshaw àti obidi
|
chioma udeaja chioma udeaja tí a bí ní june 29 1984 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n tó gbá bọ́ọ̀lù náà fún first bank àti ẹgbẹ́ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ọmọbìnrin yìí ni a tún mọ̀ sí elephant girl iṣẹ́ rẹ̀ lágbàáyé ó kópa nínú women's afrobasket tó wáyé ní ọdún 2017
|
mfon udoka nigerian-american basketball player and coach mfon sunday udoka tí a bí ní ọjọ́ kerin-dín-lógún oṣù kẹfà ọdún 1976 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà-amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀rí agbábọ́ọ́lù inú agbọ̀n tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ olùkọni fún ẹgbẹ́ bọ́ọ́lù inú agbọ̀n ti àwọn obìnrin ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà d'tigress tí a bí ní portland oregon udoka parí ilé-ìwé gíga benson polytechnic 1994 ní portland ṣáájú kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga depaul ní chicago illinois láti ọdún 1994 sí ọdún 1998 ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n sí olùkọni àti òṣèré nba tẹ́lẹ̀ ime udoka
|
ifeoma aggrey-fynn ifeoma iphie aggrey-fynn 8 june 1980 2 june 2015 known to most simply as iphie was a ghanaian-nigerian media personality writer and public speaker ìgbé ayé àti ètò ẹ̀kọ́ baba tí ó bí aggrey-flynn jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè ghana nígbà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè nàìjíríà wọ́n bí sílu nàìjíríà ó sí kẹ́kọ̀ọ́ ní orílé èdè nàìjíríà ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyẹ̀ ní fásiti tí ó wà ní ìpínlè ábíá ní orílé èdè nàìjíríà ní bí tí ó gboyẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ lìǹgúsítíkí àti communication iṣẹ́ iṣẹ́ aggrey-fynn ní tí ó jẹ́ igbohunsafefe bẹ̀rẹ̀ bí olùtajà lórí èrò amóhùnmáwòrán tv ní ọdún 2003 lẹ́yìn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn ní ilé iṣé ìbáẹnisọ̀rọ̀ silverbird ní ọdún 2009 ní ó lọ sí ilé iṣẹ́ tí orí rédíò rhythm 957 fm àti silverbird television ní awka níbè ni ó tí ń ṣe sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ lórí rédíò àti àwọn ètò lórí tẹlifísàn tí àwọn bí rhythm soul gospel vibes and e-merge kí ó tó padà lọsí ilé iṣé rhythm 937 fm ní port harcourt ó jẹ́ agbẹnusọ àti agbàlejò fún ètò miss niger delta beauty pageant ní ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ikú olóògbé aggrey-fynn lọsí ábíá lati lọ kí àwọn òbí rẹ̀ ojú ọnà port harcourt tí ó ń gbà bọ̀ nínú ọkọ̀ akérò ní àwọn ọlọ́sà tí dènà tí wọn sì ṣe jàǹbá fún wọn as the driver was driving the gunmen opened fire on the vehicle aggrey-fynn was hit by bullets and died of wounds àwọn mìíràn pé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní ó ń wa ọkọ̀ bọ́ wásí ilé ní ọjọ́ kejì osù kẹfà ọdún 2015 níbi tí ó tí lọsí ábíá láti lọ rí àwọn òbí àti mọ̀lẹ́bí rẹ wọn fẹ́ẹ̀ dé ibè ní àwọn ọlọ́sà dá wọn lọnà tí wọn sì yin ìbon nígbà tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ gbìyànjú láti wakọ̀ ìṣẹlẹ yìí sẹlẹ̀ ní ọwọ́ aago méje ìrọ̀lẹ́ ní agbègbè ilé aggrey-fynn ìbọn tí àwon ọlọ́sà yín ló mú kí aggrey-fynn wà ní agbára ẹjẹ ti wọn sì gbé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ lọ àwọn olùgbé agbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí ṣẹlẹ̀ ní wọ́n gbé aggrey-fynn lọsí ilé ìwòsan níbi tí wọn tí pé ó tí dì àìsí kí ó tó dé ilé ìwòsan
|
sarah ogoke sarah ogoke tí a bí ní ọjọ́ karúndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1990 jẹ́ agbá bọ̀ọ́lù ọwọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti amerika fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ferroviário de maputo àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù owó orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó kópa ní eré ijíde ti àwọn elégbé rẹ̀ obìnrin tí ó wáyé ní odún 2017 àti 2019 ogoke jé ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbá bọ̀ọ́lù ọwọ́ àwọn ọbìnrin tí a mọ̀ sí d'tigress nígbà tí wọ́n kópa ní ìdíje bọ́ọ̀lù owó world cup fiba fún àwọn obìnrin ní ọdún 2018 ìdíje náà wáyé ní tenerife canary islands spain
|
linda ogugua linda ogugua tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹrin ọdún 1978 je agbá-bọọọlu sínú agbọ̀n ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó ń gba fún ẹgbẹ́ women's basketball center ogugua lọ sí fáṣítì ìlú california ní orílè-èdè amẹ́ríkà ódẹ̀ tún gbá bọọọlù pẹ̀lú the nigeria women's national basketball team ní 2004 summer olympics ayé rẹ̀ a bí ogugua sínú ìdílé caroline chinwe àti john brown ogugua ní ìpínlẹ̀ anambra ní orílè-èdè nàìjíríà ni ọjọ́ kejìlá oṣù kẹrin ọdún 1978
|
sadio mane sadio mané tí wọ́n bí ní oṣù kẹrin ọdún 1992 ó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-èdè senegal ó tún jẹ́ agbábọ́ọ̀lù lọ́wọ́ iwájú fún ikọ̀ bayern munich nínú ìdíje bundesliga ó tún gbajú-gbajà àti ọ̀kan lára àwọn agbábọ́ọ̀lù tí ó dára jù lọ ní ilẹ̀ afrika wọ́n mọ̀ ọ́n fún eré-sísá ègé-gígé lórí pápá mane bẹ̀ẹ̀rẹ ère bọ́ọ̀lu àfẹsẹ̀gbá pẹ̀lu ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù metz nínú ìdíje ligue 2 tí ìlú france nígbà tí ó sì fi jẹ́ ọmọ ọdún ọkàn-dín-lógún ṣùgbọ́n ó kúrò nínú ikọ̀ náà tí ó sì dara pò mọ́ ikọ̀ red bull salzburg ní ọdún 2012 pẹ̀lú mílíọ̀nù mẹ́rin euro eléyìí tí ó sì ife ẹ̀yẹ àti kọ́ọ̀pù ẹsẹ̀ kùkú ní ọdún 2013-14 lẹ́yìn ìgbà náà mane lọ sí ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù southampton tí ìlú england pẹ̀lú owó tí ó tó 118m euro tí ó sì gbá àmì ẹ̀yẹ fatest hatrick ní ìṣẹ́jú eerin dín lógo rìn nínú ìdíje náà nígbà tí wọ́n ń kọjú ikọ̀ aston villa
|
mactabene amachree agbábọ́ọ́lù sínú ìwọn fún orílè-èdè naijiria mactabene amachree ọjọ́ ìbí jẹ́ ọjọ́ tí ó gbèyìn oṣù kínní ọdún 1978 ni ìpínlè port harcourt ní orílé èdè nàìjíríà jẹ́ agbábọ́ọ́lù sínú ìwọn fún orílè-èdè nàìjíríà ní ìgbà kàn rí tẹ́lẹ̀ ní ọdún 2001 òun yìí ní obìnrin àkọkọ́ tí ó sì wà láti orílè èdè nàìjíríà láti seré ní wnba amachree jẹ́ ọkàn lára àwọn tí wọn gbà bọ́ọ̀lù tí nigeria women's national basketball team fún ìdíje òlímpíkì ìgbà oòrù ti 2004 ó tún jẹ́ ọmọ ọba ti ẹ̀yà ojuka tí ìlú kalaba ní orílé èdè nàìjíríà
|
itoro umoh coleman american basketball player-coach itoro umoh-coleman ọjọ́ ìbí rẹ̀ ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kejì ọdún 1977 jẹ́ òní ère ìdárayá ọmọ orílẹ̀-èdè amerika àti agbábọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá tẹ́lẹ̀rí fún ẹgbẹ́ wnba ó gbá bọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù clemson tigers ní ìgbà tí ó wà ní ilé-ìwé ó sì jé adarí ẹgbẹ́ náà ní ọdún 2002 atlantic coast conference yan itoro fún '50-year all star women's basketball team' àti fún '25th anniversary tournament' team ìgbé ayé ìbéèrè pẹpẹ a bí ní washington dc umoh-coleman dàgbà ní hephzibah georgia ó lọ sí hephzibah high school ó sì gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá fún ẹgbẹ́ the lady rebels lábẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá wendell lofton ó ka ẹ̀kọ́ gboyè ní ọdún 1995
|
fade ogunro fade ogunro jẹ́ agbóhùn sáfẹfẹ́ ilé isé ìròyìn àti amóhùnmáwòrán olóòtú fíìmù àti aràsọ/amúnidára òun ni olùdásílẹ̀ àti olùdarí ilé isé e bookings africa ilé isé kan fún pèsè kárdì fún lílọ ẹ̀rọ ayélujára ní ilẹ̀ áfríkà ó jẹ́ ọmọbíbí ìpínlẹ̀ ekiti ní apá ilà-oòrùn orílẹ́-èdè nàìjíríà ó ń sọ èdè gẹ̀ẹ́sì èdè faransé àti èdè spéìn
|
zina saro-wiwa zina saro-wiwa tí a bí ní ọdún 1976 port harcourt nigeria jẹ́ olórin fídíò àti onífíìmù tí ó gbé ní brooklyn ó ṣe àwọn fídíò àwọn ìwé àkọọ́lẹ̀ àwọn fídíò orin àti àwọn fíìmù àdánwò saro-wiwa ni olùdásílẹ fíìmù ti ẹgbẹ́ alt- nollywood ìgbìyànjú tí ó ńlò ìtan-àkọọ́lẹ̀ àṣà àti àwọn àpéjọ wíwò ti ilé-iṣẹ́ fíìmù nollywood ṣùgbọ́n fun awọn ajàfẹ́tọ-ènìyàn nípa ètò òṣèlú ó jẹ́ akọ̀ròyìn bbc tẹ́lẹ̀ rí a bí iṣé ọnà rẹ̀ jáde láti inú ìfẹ́ rẹ̀ láti mú ìyípadà bá ojú tí gbogbo àgbáyé fi ń wo áfíríkà nípa lílo fíìmù àwòrán àti oúnjẹ iṣé rẹ̀ pẹ̀lú ni new west african kitchen iṣẹ́ àkànṣe kan níbi tí saro-wiwa ti ṣe àtúnrò nípa onjewiwa iwọ-oorun afirika ayẹyẹ kọ̀ọ̀kan tún ṣe àfihàn àwọn iflarahàn àwòrán fídíò áfíríkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ kékeré kan ní ọjọ́ kejìlólógún oṣù kẹta ọdún 2011 saro-wiwa gba àmì ìdánimọ̀ gẹgẹ bí ọ̀kan nínú àwọn adarí mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ó ga jùlọ ti renaissance afirika nínú ìwé ìròyìn times ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ zina saro-wiwa jẹ́ ọmọ ken ati maria saro-wiwa tí a bí ní port harcourt orílẹ̀-èdè nàíjírìa bàbá rẹ̀ òǹkọ̀wé àti akéwì ken saro-wiwa tó ti di olóògbé di olokiki ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọ-ènìyan ní orílẹ̀-èdè naijiria odun 1995 ni ijọba ologun dájọ́ ikú fún bàbá rè nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndílógún ó dàgbà ní surrey àti sussex ní uk níbití màríà ìyàwó saro-wiwa àti àwọn ọmọ márùn-ún ń gbé ó lọ sí ilé-ìwé àwọn ọmọbìrin aládàáni roedean ní sussex àti yunifasiti ti bristol níbi tí ó ti kawe ní ìmọ̀ lóri ọrọ aje ati ìtàn awujọ arábìnrin ìbejì rẹ̀ jẹ́ oǹkọ̀wé arìrìn-àjò noo saro-wiwa oǹkọ̀wé ti looking for transwonderland ti granta ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ arákùnrin rẹ̀ àgbà ken wiwa ni oǹkọ̀wé ìwé-ìrántí in the shadow of a saint tí random house/vintage
|
sarah imovbioh nigerian basketball playersarah imovbioh jẹ́ ẹni tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlelógùn oṣù karùn-ún ọdún1992ó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfọwọ́gbá tí orílẹ̀-èdè náìjíríà fún peac-pécs àti nigerian national team
|
joanne aluka joanne aluka-white tí a bí ní ọjọ́ kẹríndínlógbọ̀n oṣù kẹrin ọdun 1979 ní jackson mississippi orílẹ̀-èdè amerika jẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá ọmọ orílẹ̀-èdè naijiria àti amẹ́ríkà igbesi aye ibẹrẹ ati ẹkọ wọ́n bí i ní ìpínlẹ̀ mississippi ní orílẹ̀-èdè amẹ́ríkà ó sì gba ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú nàìjíríà lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ o lọ si ile-iwe giga hephzibah ni ipinlẹ amẹrika ti georgia o jẹ ọmọ ile-iwe giga ti aarin tennessee state pẹlu alefa apon ni imọ-iṣe ihuwasi ni ọdun 2001 ati pe o lọ siwaju lati pari alefa titunto si ni iṣe eniyan pẹlu ifọkansi ni isakoso awọn ere idaraya ni 2003 o fẹ fred white ati pe wọn ni awọn ibeji daniel ati gabrielle isẹ́ rẹ̀ aluka dije ni olimpiiki igba ooru 2004 ni athens greece pẹlu ẹgbẹ bọọlu inu agbọn ti orilẹ-ede naijiria lẹhin olimpiiki aluka darapọ mọ ati ṣere fun igba diẹ ni ibinu dallas ni ajumọṣe bọọlu inu agbọn ti orilẹ-ede aluka ni iriri iṣẹ ikẹkọ akọkọ rẹ ni fiu nibiti awọn ojuse rẹ pẹlu iranlọwọ pẹlu igbanisiṣẹ ere lori ilẹ ati ikẹkọ adaṣe bii awọn igbega ati awọn ibudó ṣaaju ki o to lọ si ikẹkọ o kọ iṣẹ rẹ ni ifijišẹ ati ṣere ni aarin tennessee state 1997-2002
|
anita alaire afoke asuoha anita alaire afoke asuoha jẹ́ apanilẹ́ẹ̀rín alámì-ẹ̀yẹ ètò stand up òṣèré olóòtú ètò ìgbáfẹ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára àti atọ́nisọ́nà lórí ọ̀rọ̀ ayé àti ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ jẹ́ real warri pikin ìgbésí ayé rẹ̀ anita asuoha tí a bí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1990 ó sì dàgbà ní ìlú warri ní ìpínlẹ̀ delta orílẹ̀-èdè nàìjíríàbàba rẹ̀ jẹ́ ọmọ ijaw láti ìjọba ìbílẹ̀ burutu ní ìpínlẹ̀ delta nígbà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ urhobo ó jẹ́ ọmọ kẹta nínú ọmọ mẹ́fà ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú political science ní fásitì benson idahosa ìlú benin ní ọdún 2012 ó fẹ́ ọ̀gbẹ́ni victor ikechukwu asuoha ní ọdún 2013 wọ́n sì ní ọmọ mẹ́ta
|
joanne alaku
|
bolanle olukanni orílẹ̀-èdè nàìjíríà isírẹ́lì amẹ́ríkà àti kẹ́ńyà ni wọ́n ti tọ́ bọ́láńlé bọ́láńlé olukanni lọ si st saviour's primary school ní ìlú eko fún ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ó tẹ̀ síwájú lọ sí queens college fún ilé-ẹ̀kọ́ gírámà olukanni tún lọ sí kenya níbití ó ti lọ sírosslyn academy ni nairobi kenya fún apákan ti ilé-ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀ ṣáájú ọdún ìkẹyìn rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ó lọ sí amẹrika àti fún ọdún àgbà rẹ̀ ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ̀ gíga wichita southeast ní wichita kansas níbití ó ti kópa nínú ìdíje ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè àti ìdíje àríyànjiyàn fún èto dramatic interpretation ní ọdún 2007 olukanni gba oyè ìwé-ẹ̀rí básẹ́lọ̀ láti iilé-ẹ̀kọ́ gíga loyola ní chicago pẹ̀lú aléfà méjì - bachelors of arts nínú communications àti international studies ó ti jẹ́ olùgbàlejò lórí ètò àwọn àkókò pẹ̀lú mo lórí dstv ati project fame west africa ó ní iṣẹ́ móhùn-máworan èyiun tv àkọ́kọ́ rẹ̀ bíi agbàlejò kejì lórí ilé-iṣẹ́ mohùn-máwòrán kan fún ètò tí a pè ní àwọn àkókò pẹ̀lú mo” wọ́n yàn-án láti ṣe atọ́kùn ètò yìí pẹ̀lú olùdarí ebonylife tv mo abudu tí ó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ lórí ebonylife tv
|
nyma akashat zibiri nihmatallah akashat zibiri tí wón tún mọ̀ sí nyma jẹ́ agbẹjọ́rò àti olóòtú ètò tẹlifíṣọ̀nù ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olóòtú ètò àràárọ̀ your view lórí tvc ìgbé ayé ó ṣetán nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin láti ilé-ìwé lagos university wọ́n sì pè é wọ nigerian bar aláṣedánwò mùsùlùmí nihmatallah akashat ti sọ ọ́ pé ìborùn mi ni àmì ìdánimọ̀ mi ó ní ìwúrí láti lọ sínú ètò tẹlifíṣọ̀nù nípa pé ó fẹ́ kí mùsùlùmí pọ̀ nínú iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lẹ́yìn tí ó wo ètò your view láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ ó kọ̀wé wọ́n sì gbà á lẹ́yìn ètò ìpolówó tí ó ṣe fún amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olóòtú mùsùlùmí akashat zibiri tẹ̀síwájú nínú ìṣedánwò ìmọ̀ òfin rẹ̀ ni ọdún 2016 ó ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ìṣẹ̀dá ilé ìmọ̀ òfin cynosure practice barristers and solicitors níbi tí ó ti jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olùdarí ní ọdún 2019 wón gbọ́ pé ó gba ẹjọ́ lórí ìgbéyàwó ọmọdé àti ìbálòpọ̀ tí kò tíì ní ìgbéyàwó nínú
|
adora oleh nigerian tv hostadora oleh jẹ́ ọmọ bíbí ìlú bírítìṣì olóòtú telifísàn àti olóòtú àkọ́kọ́ tí mtn project fame èyí tí ó ṣe olóòtú rẹ̀ fún ọdún márùn-ún ni ọjọ́ àìkú 8 oṣù kejìlá ọdún 2013 adora oleh ní ó gba àmì ẹ̀yẹ fún olóòtú obìnrin tó gbajúmò ní nigeria broadcasters awards èyí tí ó wáyé ní ìlú èkó ó jé olóòtú fún ètò ìbáni wírọ̀ rẹ the adora oleh show lóri vox africa a bí adora oleh ní surrey england ó jẹ́ àkọ́bí nínu àwọn ọmọ mẹta tí òbí rẹ bí ó kà ìwé gboyè nínu ìmò òfin ní unifasiti ó sì gba iwe ẹ̀rí ni ìmò òfin ayélujára àti ìgbóhùn sí afẹ́fẹ́ ni london school of journalism ó ṣiṣẹ́ ní mtv base ní ọdún 2002 pẹ̀lú joseph benjamin ó ṣe olóòtú fún project fame west africa èyí tí ó jẹ́ ìdíje orin orí ẹ̀rọ̀ amóhùn-máwòrán fún ọdún márùn-ún ní ọdún 2012 adora farahàn gẹ́gẹ́ bíi olóòtú lórí ètò american tv lóri ìròyìn fox
|
adora oleh
|
ìtọrọ umoh coleman
|
alexander abiodun adebayo bada alexander abiodun adebayo bada ọjọ́ ìbí ní ọjọ́ kẹrin osu kejìlá ọdún 1930- ojọ́ kẹjọ ọdún 2000 jẹ́ olùsọ́-àgùtàn kejì tí ilé ìjósìn tí amò sí celestial church of christ ccc tí ó tẹ̀lẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìjósìn náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ samuel biléhou joseph oschoffa ní oṣù kejìlá ọdún 1985 ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé wọ́n bí bàdà ní ọjọ́ kẹrin osu kejìlá ọdún 1930 baba rẹ̀ jẹ́ baálé tí ìlú àgọ́-ọba ni agbègbè kàn ní abeokuta ó sì jẹ́ olórí ìjọ áfíríkà ní eréko ní ìpínlè èkó àti pé bada dàgbà nínú ṣọ́ọ̀ṣì yìí bàdà losí ilé alákọ́bẹ̀rẹ̀ àti john ní ìlorò ní iléṣà ní 1935 sí 1943 o tún lọsí ilé ẹ̀kọ́ gírámà láti ọdún 1943 sí 1949 ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe ní nigerian breweries tí wọn ń ṣe ọtí ni ọdún 1950 tí wọ́n sì ní ìgbéga sí alábojútó ìṣàkóso ọjà ní ọdún 1952 ìṣe ilé ìjósìn ní àárín ọdún 1952ó pàdé superior ajíhìnrere s o ajáńlekòkò ti ccc ẹnití ó ní ipa púpọ̀ lórí rẹ̀ ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ láti ṣẹṣẹ olúwa kíkún fún ìjọ ó sì di àgbààgbà ní 1954 adarí ní ọdún 1955 tí o sì dì adarí àgbà ní oṣù kejìlá ọdún 1960 àti ajíhìnrere ní ọdún 1964 ó di ajíhìnrere àgbà ní ọjọ́ kerìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1972 àti pé ní ojú karúndílógbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1980 ajíhìnrere tí ó ga jùlọ òun sì ní àkọkọ́ tí ó dé ipò náà èyí tí ó túmọ sí pé ipò rẹ súńmọ́ ipò tí pastor samuel ọ̀sọfà wà nígbà tí osofa kú ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹsán ọdún 1985 nínú ìṣẹ̀lẹ ìjàmbá ọkọ́ láì sí arópò kan kan tàbí ọmọ tí yóò jogún rẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọlẹyìn rẹ̀ ní en fi dí olórí èyí tí ó yọrí sí ìjà òfin tí ó wáyé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sibẹsibẹ ìgbimọ alàkóso àti àwọn olùfọkàntàn kéde pé bàdà ni olùsọ́-àgùtàn tuntun àti aṣáájú ẹ̀míi ní àpéjọ ọdọọdún ccc ní ọjọ́ karúdínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1985 wøn fí sí orí ipò náà ní ọjọ́ karúdínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1985 ní orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti ccc ní ìmẹ̀kọ ní ìpínlè ògùn ní orílé èdè nàìjíríà ó sì ṣe aṣáájú ìjọ náà fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó tẹ̀ lé e bàdà jáde láyé ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹsán ọdún 2000 ni ilé ìwòsan greenwich ní london lèyìn tí wọn gbé wá sí orílè èdè nàìjíríà fún ayẹyẹ ìsìnkú ní oṣù kokàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 2000 ní ìlú celestial ní ìmẹ̀kọ gómìnà olúsẹ́gun ọ̀sobà ló sojú ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí olúsẹ́gun ọbásanjọ́ níbi ayẹyẹ ìsìnkú náà àwọn ìyàwó àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ-ọmọ ní bàdà filẹ́ lọ philip hunsu ajose lọ́ rọ́pò rẹ̀ ẹní tí a yàn sípò aṣáájú ìjọ ní ọjọ́ kejì oṣù kẹwàá ọdún 2000
|
seye kehinde oluseye olugbemiga kehinde 21 osù kẹrin 1965 jẹ akọ̀ròyìn oríẹ-ède naijiria ti o jẹ olùdásílẹ̀ city people group limited igbesi aye ibẹrẹ a bí kẹ́hìndé ni ipinle iṣara ogun ni naijiria bí o tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí rẹ méjèèjì jẹ òṣìṣẹ́ ìjọba ó ní ìwé ẹ̀rí nínú ṣíṣe àti ìfiròyìn lédè ó sì gba ìwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ ìtàn àti ìmọ̀ ìṣèlú ní yunifásítì obafemi awolowo ó sì tún gba ìwé ẹ̀rí nysc ní kwara state polytechnic o bẹ̀rẹ̀ si ṣiṣẹ́ bi akọ̀ròyìn níbi tí ó jẹ oníròyìn ni newswatch olùrànlọ́wọ́ ile-ikawe ni 1986 àti pé ó tún ṣiṣé pẹ̀lú iroyin atẹle herald ni 1988 ìwé ìròyìn confidential inu inu bi akọroyin agba ni 1989 ó jẹ́ olórí international desk ní ọdún 1990 ó sì jẹ́ àgbà òǹkọ̀wé ni tribune ni 1991 ó si i ṣiṣẹ́ pẹ̀lú african concord gẹ́gẹ́ bi òǹkọ̀wé oṣiṣẹ láti ọdún 1991 títí dé ìgbà ifẹhinti rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ní ọdún 1992 nígbà tí aare ibrahim babangida ṣe atunda african concord press wọn sì pe e sí african guardian gẹ́gẹ́ bí olóòtú ìrànlọ́wọ́ nibẹ ni ó ṣiṣẹ́ láti ọdún 1992 si ọdún 1994 ó tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iwe irohin thenews gẹ́gẹ́ bi olóòtú àgbà àti olóòtú àgbà ní ìwé ìròyìn tempo tẹ́lẹ̀ ní ọdún 1995 ki o to o bẹrẹ si n ṣeto ìwé ìròyìn the city people magazine ó tún wa láàrin ẹgbẹ́ ìdásílẹ̀ ti pm news
|
sarah imovbioh
|
fade ogunro
|
linda ogugua
|
sarah ogoke
|
katherine obiang
|
tirunesh dibaba ethiopian long-distance runner tirunesh dibaba ni a bini ọjọ akọkọ óṣu june ọdun 1985 jẹ elere sisa lóbinrin to dalo ri ọna jinjin ati ere ti oju ona oke okun àṣèyọri tirunesh kopa ninu ere olympic to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura lẹẹmẹta ni ọjọ kẹfa ósu june ọdun 2008 dibaba kopa ninu ere ti bislett to waye ni oslo ti mita ẹgbẹrun maarun pẹlu wakati 141115 ni ọdun 2008 tirunesh kopa ninu olympics ti summer ti mita ẹgbẹrun mẹwa pẹlu wakati 295466 ni ọdun 2008 dibaba ni iaaf sọ ni elere sisa ti ọ̀dun naa ni ọdun 2010 dibaba kopa ninu idije ti ilẹ afirica ti mita ti ẹgbẹrun mẹwa pẹlu wakati 315139 to waye ni nairobi ni ọdun 2012 dibaba kopa ninu olympics ti summer ti london pẹlu wakati 302075 ti mita ẹgbẹrun mẹwa ni ọdun 2013 tirunesh kopa ninu idije agbaye ti mita ẹgbẹrun mẹwa to waye ni moscow ni ọdun 2014 tirunesh kopa ninu marathon ti london to si pari pẹlu ipo kẹta pẹlu wakati 22035 ni ọdun 2016 dibaba kopa ninu olympics ti summer ni rio de janeiro ni mita ẹgbẹrun mẹwa ni óṣu august dibaba kopa ninu idije agbaye ti london ti mita ẹgbẹ̀run mẹwa to si gba ami ẹ̀yẹ ti ọla ti silver pẹlu iṣẹju aya 4637 ni ọdun 2017 dibaba kopa ninu marathon ti chicago to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti wura pẹlu wakati 21830 ni óṣu september ọdun 2018 dibaba kopa marathon ti berlin pẹlu wakati 21855 to si pari pẹlu ipo kẹta ni óṣu october ọdun 2018 dibaba kopa ninu idaji marathon ti delhi to si pari ipo kẹfa ni óṣu january ọdun 2023 tirunesh kopa ninu idaji marathon ti houston to si pẹ̀lu wakati 7135
|
dera dida ethiopian long-distance runner dera dida yami ni a bini ọjọ kẹrin dinlọgbọn óṣu october ọdun 1996 jẹ elere sisa lobinrin ti ilẹ ethiopia to da lori ọna jinjin àṣèyọri ni ọdun 2017 dera kopa ninu idije agbaye lori ere sisa ti mita ti ẹgbẹrun mẹwa pẹlu wakati 315175 ni ọdun 2019dera gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver ninu idije agbaye ti iaaf to waye ni aarhus denmark ni ọdun 2019 dera ami ẹyẹ ti ọla ti idẹ ninu ayẹyẹ ti mita ẹgbẹrun mẹwa
|
dihininet demsew jara dihininet demsew jara ni a bini ọjọ kaarun leelogun óṣu september ọdun 1994 jẹ elere sisa lóbinrin to da lori ayẹyẹ oju ọna aṣèyọri ni ọdun 2009 demsew kopa ninu marathon ti alaafia kosice to si pari pẹlu ipo karun pẹlu wakati 24803 ni ọdun 2016 demsew ṣoju fun órilẹ ede rẹ ninu idaji idije ti marathon ti agbaye ti iaaf to si gba ami ẹyẹ ti ọla ti silver to si gbe ipo kẹjọ ni ọdun 2019 demsew kopa ninu marathon ti alaafia to si gbe ipo karun pẹlu wakati 24803
|
etenesh diro ethiopian long-distance runner etenesh diro neda ni a bini ọjọ kẹwa óṣu may ọdun 1991 jẹ elere sisa lobinrin ti órilẹ ede ethiopia aṣèyọri etenesh kopa ninu olympics ti 2012 ati 2016 lori mita ti ẹgbẹrun mẹta ti steeplechase ni ọdun 2012 diro kopa ninu àṣekagba ere olympic to waye ni london pẹlu ipo kẹfa pẹlu wakati 91989 ni ọdun 2013 diro kopa ninu idije agbaye ti mita ẹgbẹrun mẹta to si pari pẹlu ipo kaarun pẹlu wakati 91697 ni ọdun 2017 etenesh kopa ninu idije agbaye ti london ti mita ẹgbẹrun mẹta to si pari pẹlu ipo keje pẹlu wakati 92246
|
lishan dula lishan dula gemechu ni a bini ọjọ kẹ̀ta dinlọgbọn óṣu february ọdun 1987 jẹ elere sisa lóbinrin ti órilẹ́ ede ethiopia arabinrin naa da lori ọna jinjin to ṣoju fun bahrain àṣèyọri ni ọdun 2012 dula kopa ninu marathon ti olympics ti summer pẹlu wakati 23620
|
iyàrá ìdáná iyàra ìdáná jẹ́ ibi tí a tí n pèlò tí a sì ti n dáná se oúnjẹ yàra ìdáná jẹ́ ibìkan tí ayàsọ́tọ̀ nínú ilé ìgbé fun iṣé oúnjẹ sísè lóríṣíríṣi yàra ìdáná jẹ́ ibi tí a tí n pèlò tí a sì ti n dáná se oúnjẹ nítorí áwọn ohun èlò ìdána tí ó póríṣíríṣi tí an ṣe àmúlò àti pẹ̀lú onírurú ènìyàn tí o ń wọ iyàrá ìdáná mú kí ó jẹ́ ibi tí ó léwu láti ìgbà púpọ̀ sẹ́hìn ni yàrá ìdáná ti jẹ́ ibi ti àwọn ẹbí ti n darapọ̀ ṣe ọ̀yàyà láti ìgbà púpọ̀ sẹ́hìn ni àwọn ènìyàn ti mọ rírì àti máa ṣe àyípadà àwon nkan àmúlò tàbí ilé ìdáná gan fún ra rẹ̀ ní mímọ pàtàkì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ti àwọn yàrá tókù ní ìrísí tí yio mù rọrùn lati ṣe àmúlò bí ó ti yẹ ṣíṣe ágbéyẹ̀wò yàrá ìdáná ìgbálódé jẹ́ ohun tí o n gbajú-gbajà si ní ojoojújmọ́ sùgbón o ṣe pàtàkì kí a ni lọ́kan láti ṣe ní ọ̀nà tí yoo fi mú kí iṣẹ́ ìdáná rọrùn ju ìgbà àtijọ́ lọ ṣíṣe idanilẹkọ bí a ti ṣe nlo àwọn ohnu èlò ilé ìdáná àti ilé ìdáná gan fúnrarẹ̀ yio jẹ́ kí iṣẹ́ ilé ìdáná wúni lórí àtipé àdìnkù yio bá ìjàmbá tí ó ṣééṣe kí ó ṣẹlẹ̀ nínú ilé ìdáná
|
list of articles created from the 7th of april to the 30th of april april 2023 list of articles i created and edited on yoruba wikipedia from april 7th - april 30th 2023 list of articles created aisha lawal ummi ibrahim mfon udoka
|
yàrá ìdáná
|
ibiyinka a fuwape ibiyinka a fuwape tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kejìlá ọdún 1962 jẹ́ ọ̀mọ̀wé àti ọ̀jọ̀gbọ́n físísì ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni ẹni èkejì láti di adarí yunifásitì michael and cecilia ibru yunifásitì aládàáni kan ní nàìjíríà ìpìlẹ̀ a bí ibiyinka fuwape ní ìpínlẹ̀ èkó ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kejìlá ọdún 1962 sínú ìdílé david ademokun ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní reagan memorial baptist girls primary school yaba ìpínlẹ̀ èkó ibẹ̀ ni ó ti parí ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní methodist girls high school níbi tí ó ti gba ìwé ẹrí o level kí ó tó tẹ̀síwájú ní queen's college yaba láàrin ọdún 1979 to 1981 ní ọdún 1984 ó gba àmì-ẹ̀yẹ bachelor of science bsc nínú ìmọ̀ físísì yunifásítì ìlú ìbàdàn ó sì ṣin ilẹ̀ bàbá rẹ̀ láàrin ọdún 1984 sí 1985 ní yunifásitì kan náà ó gba àmì-ẹ̀yẹ master of science msc ní ọdún 1986 àti àmì ẹyẹ dókítàphd nínú ìmọ̀ físísì ní ọdún 1989
|
richard brook
|
dupsy abiola modupeola dupsy abiola tí a bí ní oṣù kẹta ọdún 1982 jẹ́ agbẹjọ́rò àti oníṣòwò obìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti ilẹ̀ọba aṣọ̀kan ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdarí international airlines group iag òun tún ni ọ̀lùdásílẹ̀ àti adarí intern avenue ìpìlẹ̀ wọ́n bí dupsy abiola ní london orílẹ̀-èdè england òun ni ọmọ olóyè mko abiola àti dele abiola òkan lára àwọn ìyàwó olóyè bàbá rẹ̀ jẹ́ gbajúmọ̀ oníṣòwò àti onìfifúnni ìyá dupsy tọ dàgbà pẹ̀lú àwọn ọmọ márùn-ún míràn ní àríwá london ìdílé rẹ̀ baba dupsy ẹni tí ó jẹ́ aare ona kakanfo àwọn ènìyàn yoruba kẹrìnlá di ọkàn lára àwọn tó bẹ̀rẹ̀ si ń jà fún ètọ́ àwọn ará ìlú àti fún ìjọba tiwa tiwa ó díje fún ipò ààrẹ nàìjíríà ó sì jáwé olúborí nínú ìbò náà nínú oṣù kẹfà ọdún 1933 lẹ́yìn ǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ ìjọba kò láti fi ìjọba lé mko lọ́wọ́ wọ́n padà ti olóyè abiola mó ilé wọn kò sì jẹ́ kí ó fojú kan ìdílé rẹ̀ àtìmọ́lé rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àwọn bi akọ̀wé àjọ un kofi annan - gbìyànjú láti wá ọ̀nà àti tú olóyè sílẹ̀ mko kú ní ọjọ́ tí wọ́n gbèrò láti tu sílẹ̀ ní ọjọ́ keje oṣù keje ọdún 1998 nígbà tí dupsy jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún
|
gbadebo rhodes-vivour use both this parameter and |birth_date to display the person's date of birth date of death and age at death -->|death_place=|death_cause=|body_discovered=|resting_place=|resting_place_coordinates=|burial_place=|burial_coordinates=|monuments=|nationality=nigerian|other_names=|siglum=|citizenship=|education=*bachelor of architecture
|
ashley battle ashley battle ti won bi ni ojo kokanlelogbon osu karun un odun 1982 jẹ akosemose agba boolu alapere eni ti o dara po mo iko agba boolu alapere seattle storm ọdun 2005 o bawon gba ifesewonse meji ki o to di pe won yọkuro o wa darapo mo new york liberty fun idije saa 2006 titi di 2009 o bawon kopa ninu idije ti boolu alapere awon obinrin ti ile-eko agba ti university of connecticut
|
chinyere kalu chinyere kalu mfr orúkọ àbísọ rẹ̀ ni onyenucheya jẹ́ obìnrin ọmọ orílẹ̀-edè nàìjíríà àkọ́kọ́ láti di awakọ̀ èrò ojú òfuurufú àti obínrin àkọ́kọ́ láti wa ọkọ̀ ojú òfurufú ní orílẹ̀-ede nàìjíríà ayé rẹ̀ ó jẹ́ ọmọ bíbí akwete ijoba ìbílẹ̀ ìwọ oòrùn ukwa ní ìpínlẹ̀ ábíá ìwọ oòrùn nàìjíríà kalu dàgbà lábé ìtọ́jú ìyá rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwọn òbí rẹ̀ yapa àwòkọ́se aunti rẹ̀ lówò tí ó fi wọ inú isẹ́ wíwà ọkọ̀ ojú òfuurufú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mọ aunti rẹ̀ fún lílọ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn ó lọ sí ilé-ìwé anglican girls grammar school yaba ìpínlẹ̀ èkó fún ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ kí ó tó kọ́ nípa wíwà ọkọ̀ ojú òfuurufú ti aládàáni àti fún àwọn èrò ní ọdún 1978 ní ilé-ìwé nigerian college of aviation technology zaria ó padà tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú si ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé fún ẹ̀kọ́ ìmò ojú òfuurufú ní ilẹ̀ọba aṣọ̀kan àti ní orílẹ̀ èdè amerika kí ó tó gba ìwé ẹrí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi awakọ̀ ojú òfuurufú ní ọjọ́ ogún oṣù karùn-ún ọdún 1981 ní ilé-ìwé nigerian college of aviation technology
|
blessing liman blessing liman tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ọdún 1984 jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ajagun ojúòfurufú nàìjíríà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ́ gẹ́gẹ́ bi ọkàn lára àwọn obìnrin awa ọ̀kọ̀ ojú òfuurufú ti ológun tí ó dára jùlọ ní nàìjíríà ayé rẹ̀ wọ́n bí blessing liman ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdún 1984 ní zangon kataf ìpínlẹ̀ kàdúná agbègbè apáàríwá nàìjíríà ní oṣù keje ọdún 2011 ó fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí dídára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ológun ofuruufu ti nàìjíríà wọ́n sì gbá wọlé ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kejìlá ọdún 2011 ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2012 ó di obìnrin àkọ́kọ́ láti di ajagun ojú òfuurufú ní nàìjíríà lẹ́yìn àmì-ẹ̀yẹ tí air marshal mohammed dikko umar fun
|
hadiza lantana oboh hadiza lantana oboh ọdún 1959 sí 1998 jẹ́ awakọ̀ ojú òfuurufú ọmọ-orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun nìkan ni obìnrin tí ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi awakọ̀ ojú òfuurufú fún ilé ìṣẹ́ nigeria airways wọ́n ṣekú pá ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kejì ọdún 1998 àwọn afunrasí nínú ọ̀rọ̀ náà jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ nínú ilé rẹ̀ tí wón jà lólè ayé rẹ̀ oboh ti ń wa ọkọ̀ òfuurufú fún ilé ìṣe míràn fún ọ̀pọ̀ ọdún kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣiṣẹ́ fún ilé isẹ́ nigeria airways ikú rẹ̀ hadiza lantana oboh jẹ́ ọmọ ọdún kàndínlógójì nígbà tí wọ́n ṣekú pá àwọn ọlọ́pá rí òkú rẹ̀ ní ihò tí wón da ìgbẹ́ sí lẹ́yìn tí wọ́n ká atọjú ọgbà rẹ̀ níbi tí ó ti ń gbìyànjú láti ta àwọn ǹkan ìní hadiza àwọn ọlọ́pá gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ilé hadiza kí wọ́n tó fi wọ́nlẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ yí ṣálọ
|
kalifọ́rníà
|
adeola ogunmola showemimo adeola sowemimo jẹ́ awakọ̀ ọ̀furufú ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà iṣẹ́ rẹ̀ adeola bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní sunrise aviation academy ní orílẹ̀ èdè amerika níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 2011 àwọn àṣeyọrí ní ọdún 2019 ó di obìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àkọ́kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú qatar airways ní ààrin ìwọ̀ òórùn àgbáyé ibí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro ti wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin tí wọ́n fẹ́ di awakọ̀ ojú ọ̀furufú òun tún ni obìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà láti wa ọkọ̀ òfuurufú boeing 787 dreamliner fún qatar airways
|
tosin ajibade nigerian writer and blogger tosin olorisupergal ajibade oluwatosin ajibade tí a bí ní ọjọ́ kẹta-dín-lógún oṣù kejì ọdún 1987 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí a mọ̀ fún ojú òpó wẹ́ẹ̀bù eré ìdárayá àti ìgbésí ayé rẹ̀ olorisupergalcom àti láìpẹ́ ààyè ayélujára tirẹ̀ tosinajibadecom ó tún jẹ́ olùṣètò 'new media conference ' tí ó ń wáyé ní ọdọọdún ní nàìjíríà ẹ̀kọ́ rẹ̀ tosin ajibade gba òye ti 'bachelors' nínú ètò ìṣirò láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ èkó lẹ́hìn náà ó gba ìwé-ẹ̀rí ní 'media enterprise' láti ilé-ìwé ti 'media and communications' ilé-ẹ̀kọ́ gíga fásítì pan-atlantic nàìjíríà iṣẹ́ ayélujára tosin ajibade jẹ́ mímọ̀ fún ìgbésí ayé rẹ̀ àti ojú òpó wẹ́ẹ̀bù eré ìdárayá olorisupergalcom ní nàìjíríà àti ẹ̀dá south africa kan tosin bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ bí àtẹ̀jáde ní ọdún 2009 ó ṣẹ̀dá búlọ́ọ̀gì rẹ̀ ní ọdún 2010 ní ọdún 2011 wọ́n gbà á wọlé ní blackhouse media gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso wẹ́ẹ̀bù wọn ṣùgbọ́n ó fi sílẹ̀ ní ọdún 2012 láti dojúkọ́ búlọ́ọ̀gì ní àkokò tí ó bẹ̀rẹ̀ ní búlọ́ọ̀gì rẹ̀ ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ tó níṣe pẹ̀lú ẹ̀rọ ayélujára púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí the net ng acada magazine àti laff mattaz ti gbenga adeyinka the 1st ní ọdún 2014 tosin ajibade ti wà ní àkójọ láàrín àwọn ọgọ̀run àwọn obìrin ynaija tí ó ní ipa jùlọ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti pé búlọ́ọ̀gì rẹ̀ ni a kà lónìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn olókìkí àti gbajúmọ̀ jùlọ ní nàìjíríà ó jẹ́ olùṣètò ti àpéjọ 'new media conference' tí ó wáyé ní ọdọọdún ní ọdún 2015 2016 2017 2018 àti 2019 àtojọ náà fojú sí àwọn agbára ẹ̀rọ ayélujára tuntun pàápàá ní àwọn 'online/digital possibilities àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ ajibade ti lo búlọ́ọ̀gì rẹ̀ láti pe àkíyèsí sí àwọn ọ̀rọ̀ àwùjọ pàápàá bí ó ṣe kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin àpẹẹrẹ tí ó hàn gbangba ni ìtàn ikọlù ìbálòpọ̀ ti ilé-ìwé queen's college kan ọmọ ilé-ìwé èkó nípasẹ̀ olùkọ rẹ̀ tí ó gbé jáde àti pé nítorí náà ìròyìn náà dé gbogbo etí ó sì gba àkíyèsí àwọn aláṣẹ tí ó yẹ àmì-ẹ̀yẹ àti yíyán ní ọdún 2015 tosin jẹ́ orúkọ nínú àtòjọ ọgọ́run àwọn obìnrin tí ó ní ipa jùlọ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà nípasẹ̀ ynaija ní ọdún 2016 ó gba ààmì-ẹ̀yẹ àwọn ẹ̀bùn future awards ti áfíríkà fún new media àtẹ̀jáde iṣẹ́ tosin ajibade jẹ́ òǹkọ̀wé ìwé méjì láti social misfit sí social media hero 2018 and the influencer blueprint 2020 àti the influencer blueprint
|
angela emuwa angela olufunmilayo emuwa jẹ́ adarí àwọn oníròyìn ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ alága punch media foundation tí àwọn ìgbìmọ̀ punch nigeria limited yàn ní ọdún 2018 lẹ́yìn ikú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ gbadebowale wayne aboderin ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2018 kí wọ́n tó yàn án sípò gẹ́gẹ́ bí alága ó ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà ní ọdún 1994 ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi olùdarí tí kì í ṣe aláṣẹ ilé-iṣẹ́ náà
|
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.