_id
stringlengths
17
21
url
stringlengths
32
377
title
stringlengths
2
120
text
stringlengths
100
2.76k
20231101.yo_3996_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88r%C3%B2%20mi%20l%27%C3%B3r%C3%AD%20%E1%BA%B9%CC%81k%E1%BB%8D%CC%81
Èrò mi l'órí ẹ́kọ́
Èrò mi l'órí ẹ́kọ́ (1693) ni ìwé kan tí àmoye omo ilé Gèésì, John Locke kò. Fún ogórun - ọdún kan ó jẹ́ ìwé pàtàkì nípa òrò ẹ́kọ́ ni ilé Britani. A yí padà sí orísirísi èdè pàtàkì ni orílè Yúrópù ni arin ogórun - ọdún èjìdínlógún, bé sí ni òpòlopò omòwe ni orílè Yúrópù ni won tókasí ipa rè ni òrí òrò ẹ́kọ́ ni bé. Okan nínú won ni Jean-Jacques Rousseau.
20231101.yo_3998_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92%E1%B9%A3%C3%B9p%C3%A1
Òṣùpá
Òṣùpá (aami: ) jẹ́ olùyípo (satellite) ilẹ̀-Ayé. Arinidaji jíjìnnà sí láti ilẹ̀-ayé títí dé orí òṣùpá jẹ́ kìlómítà 384,403. Ìwọ̀n ìdábùú òbírí yìí fi ìlọ́pò ọgbọ̀n jù ti ilẹ̀-ayé. Ìlà-àárín òṣùpá jẹ́ kìlómítà 3,474 - tó jẹ́ pé díẹ̀ ló fi jù ọ̀kan nínú mẹ́rin lọ sí ti ilẹ̀-ayé. Èyí sì jẹ́ pé kíkún-inú (volume) òṣùpá jẹ́ ìdá àádọ́ta péré ti ilẹ̀-ayé. Fífà ìwúwosí rẹ̀ jẹ́ ìdá mẹ́fà sí ti ilẹ̀-ayé. Òṣùpá ń yípo ilẹ̀-ayé ní ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọjọ́ 27.3 (1 oṣù; ọjọ́ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé ní wákàtí mẹ́ta).
20231101.yo_4000_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cs%C3%BAl%E1%BA%B9%CC%80%20%C3%92%C3%B2r%C3%B9n
Ìsúlẹ̀ Òòrùn
Ìsúlẹ̀ Òòrùn (solar eclipse) n sele nigbati Òsùpá ba gba arin ile-aye ati oorun koja ti o si di ile-aye loju patapata tabi die lati ri oorun.
20231101.yo_4000_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cs%C3%BAl%E1%BA%B9%CC%80%20%C3%92%C3%B2r%C3%B9n
Ìsúlẹ̀ Òòrùn
Isule oloruka (annular) n sele nigbati osupa ati oorun ba wa ni ori ila kanna ti oorun si han bi oruka.
20231101.yo_4000_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cs%C3%BAl%E1%BA%B9%CC%80%20%C3%92%C3%B2r%C3%B9n
Ìsúlẹ̀ Òòrùn
Isule ajapo (hybrid) n sele larin isule patapata ati oloruka. Nibikan ni ori ile-aye o han bi isule patapata nibomiran bi isule oloruka. Isule ajapo kii fi be sele.
20231101.yo_4000_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cs%C3%BAl%E1%BA%B9%CC%80%20%C3%92%C3%B2r%C3%B9n
Ìsúlẹ̀ Òòrùn
Isule eyidie (partial) n sele nigbati osupa ati oorun ko wa ni ori ila kanna, ti osupa si di oorun loju die.
20231101.yo_4001_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ay%C3%A9
Ayé
Ayé, tàbí Ilé-ayé jẹ́ pálánẹ́ẹ̀tì kẹta ní ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ ọ̀run, ó sì jẹ́ èyí tí ó tóbi jùlo nínú àwọn pálánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ní ilẹ̀ tí ó ṣe é tẹ̀.
20231101.yo_4001_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ay%C3%A9
Ayé
Ilé-ayé jé pálánẹ́ẹ̀tì àkọ́kọ́ tí ó ní omi tó ń sàn ní òde ojú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sìni Ilé-ayé nìkan ni pálánẹ́ẹ̀tì tí a mọ̀ ní àgbáńlá ayé. Ojú-òrun (atmosphere) jẹ́ kìkì nitrogen àti oxygen tí ó ń dà àbò bo ilé-ayé lọ́wọ́ àtaǹgbóná (radiation) tó léwu sí ènìyàn. Bákan náà ojú-òrun kò gba àwọn yanrìn-òrun láàyè láti jábọ́ sí ilé-ayé nípa sísun wọ́n níná kí wọ́n ó tó lè jábọ́ sí ilé-ayé.
20231101.yo_4003_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Pl%C3%A1n%E1%BA%B9%CC%81t%C3%AC
Plánẹ́tì
Pílánẹ́tì gẹ́gẹ́ bí i Ẹgbẹ́ìrẹ́pọ̀ ìmọ̀ Òfurufú Káàkiriayé (IAU) ṣe ṣè'tumọ̀ rẹ̀ jẹ́ ohun òkè-ọrùn tí ó ń yí ìrànwọ́ ká tàbí aloku ọ̀run tí tíwúwosí rẹ̀ jẹ́ kí ó rí róbótó, tí kò tóbi púpọ̀ láti yíyọ́ ìgbónáinúikùn (anthothermonuclear fusion) láàyè nínú rẹ̀, tí ó sì ti gba àwọn oríṣiríṣi ìdènà kúra cartele dé santata lọ́nà tí ó ń gbà kọjá.
20231101.yo_4003_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Pl%C3%A1n%E1%BA%B9%CC%81t%C3%AC
Plánẹ́tì
Gẹ́gẹ́ bí (IAU) ṣe sọ, pílánẹ́tì mẹ́jọ ni wọ́n wà nínú ètò òòrùn. Àwọn nìwọ̀nyìí bí wọ́n ṣe ń jìnnà sí Òòrùn:
20231101.yo_4004_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92r%C3%B9n
Òrùn
Òòrùn ni ìràwọ̀ tó wà láàárín ètò òòrùn. Ilẹ̀-ayé àti àwọn ohun mìíràn (àwọn pílánẹ́ẹ̀tì yoku, oníràwọ̀, olókùúta, òkúta iná àti eruku) wọ́n ń yípo òòrùn, tó ṣe fúnra rẹ̀ nìkan ni ìtóbi 99.8% gbogbo Ètò Òòrùn. Okun láti inú òòrùn gẹ́gẹ́ bíi ooruntitan ń pèsè fún àwọn ohun ẹlẹ́mìí lọ́nà tí a mọ̀ sí ikommolejo (photosynthesis), bẹ́ẹ̀ ni òòrùn ló ń sọ bí ìgbà àti ojú-ọjọ́ ṣe ń rí.
20231101.yo_4006_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8%CC%81l%C3%ADm%E1%BA%B9%CC%80nt%C3%AC%20k%E1%BA%B9%CC%81m%C3%ADk%C3%A0
Ẹ́límẹ̀ntì kẹ́míkà
Ẹ́límẹ̀ntì kẹ́míkà (chemical element) kan tabi ẹ́límẹ̀ntì ni soki ni iru átọ́mù ti nomba atomu re n fi han (iye protoni to wa ninu nukleu re).
20231101.yo_4006_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8%CC%81l%C3%ADm%E1%BA%B9%CC%80nt%C3%AC%20k%E1%BA%B9%CC%81m%C3%ADk%C3%A0
Ẹ́límẹ̀ntì kẹ́míkà
Apere elimenti to gbajumo ni háídrójìn, náítrójìn ati kárbọ̀nù. Ni apapo 118 ni iye awon apilese ti ati se awari won titi de odun 2007, ninu awon eyi 94, eyun plutoniumu ati ni sale lo, wa fun ra ara won ni orile aye.
20231101.yo_4008_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Leonhard%20Euler
Leonhard Euler
Leonhard Euler (April 15, 1707 – September 7, 1783) je onimo isiro ati onimo fisisi omo orile-ede Switzerland ti o gbe gbogbo ojo aye re ni Russia ati Jẹ́mánì.
20231101.yo_4009_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Gb%C3%B2ngb%C3%B2%20al%C3%A1gb%C3%A1ram%C3%A9j%C3%AC
Gbòngbò alágbáraméjì
Ninu imo isiro gbòngbò alágbáraméjì tabi gbongbo ìlọ́poméjì (square root) fun nomba x je nomba r ti yio je tabi pe nomba r ti alagbarameji re (ti a ba so di pupo pelu ara re) je x.
20231101.yo_4078_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Ṣaájú, ó yẹ ki a là á wí pé ohunkóhun tí a bá fi ẹnu bà lábẹ́ àkòrí yìí gbọdọ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìtàn ìwáṣẹ̀. Ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ àwọn ìtàn tó ti pẹ́ púpọ̀, tó sì ń sàlàyé ọ̀pọ̀lọpò ohun tí kò yé ẹ̀dá. Bascom nínú Finnegan (1970:361) ṣe àlàyé nípa ìtàn ìwáṣẹ̀ pe: Myths are prose narratives, which in the society in which they are told are considered to be truthful accounts of what happened in the remote past
20231101.yo_4078_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
(Ìtàn ìwáṣẹ ni àwọn ìtàn àròsọ tí àwọn ènìyàn àwùjọ ní ìgbàgbọ́ pé ó jẹ́ ìtàn òdodo nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́)
20231101.yo_4078_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
kò sí ẹ̀dá alààyè tàbí ibùgbé tí ìtàn ìwáṣẹ̀ kì í dá lé, a sì gbọ́dọ̀ gbà á gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ṣe sọ ọ́ ni nítorí kò sí ẹni tí o lè jẹ́rì í sí i pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojú òun. Finnegan (1970:362) fi ìdí èyí múlẹ̀, ó ní
20231101.yo_4078_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
… they are accepted on faith, they are taught to be believed; and they can be cited as authority in answer to ignorance, doubt, or disbelief. Myths are the embodiment of dogma: they are usually sacred and they are often associated with theology and ritual. Their main characters are animals, deities, or culture heroes whose actions are set in an earlier world, when the earth was different from what it is today, or in another world such as the sky or underworld
20231101.yo_4078_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
(… A gbà wọ́n pẹ̀lú ìgbàgbo, wọ́n jẹ́ ẹ̀kọ́ tó wà láti gbàgbọ́; a lè fi wọ́n ṣe ẹ̀rí àìmọ̀kan, iyèméjì tàbí àìgbàgbọ́. Ìtàn ìwáṣẹ̀ kún fún gbígba ohun kan gbọ́ láìwádìí, ọ̀wọ̀ wà fún wọn, wọ́n ṣáábà máa ń jẹ́ ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti ọ̀nà tí a ń gbà ṣe ẹ̀sìn. Àwọn ẹ̀dá pàtàkì inú wọn ni ẹranko, òrìṣà àti àwọn akọni nínú àṣà tí wọ́n ti kópa tó jọjú ní ayé àtijọ́ tàbí ayé mìíràn gẹ́gẹ́ bí ojú ọ̀run tàbí ìsàlẹ̀ ilẹ̀).
20231101.yo_4078_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Àlàyé rẹ̀ yìí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilé-Ifẹ̀. Ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilé-Ifẹ̀, kì í ṣe ohun à á yọ àdá bẹ́; òdú sì ni, kì í ṣe àìmọ̀ fun oloko. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú Ilẹ̀ Yorùbá ni wọn gbà pé Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn ti lọ, èyí kò sì jẹ́ kí ìtàn ìsẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilé-Ifẹ̀ ṣe àjòjì sí wọn.
20231101.yo_4078_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Oríṣìíríṣìí ìtàn ìwàṣẹ̀ ló wà tó jẹ mọ́ ìṣẹ̀dá Ilé-Ifẹ̀. Ìtàn ti a kà nínú ìwé tí ó sì tún ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí tí a gbà láti ẹnu àwọn abẹ́nà ìmọ̀ wa kò ju ìtàn méjì péré tí í ṣe ìtàn atẹ̀wọ̀nrọ̀ àti ìtàn Mẹ́kà. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé àwọn ìtàn méjì náà ni wọ́n gbajúmọ̀ jù lọ. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìtàn wọ̀nyí, a rí abala tí ó fará pẹ́ òtítọ́, a sì rí èyí tí kò fi gbogbo ara jẹ́ òtítọ́.
20231101.yo_4078_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Nínú ìtàn atẹ̀wọ̀nrọ̀ ni a ti gbọ́ pé láti ìsálú ọ̀run ni Olódùmarè ti rán Odùduwà wá tẹ Ilé ayé dó. Kí Olódùmarè tó ran Odùduwà, ó ti kọ́kọ́ rán Ọbàtálá, ẹni tí àwọn Ifẹ̀ máa ń kì pe:
20231101.yo_4078_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Olódùmarè fún ọbàtálá ní adìyẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún àti erùpẹ̀ pé kí ó lọ fi tẹ Ilé ayé dó. Èèwọ́ Ọbàtálá ni pe kò rú ẹbọ kí ó tó máa bọ̀. Ó pàdé adẹ́mu, Èṣù si jẹ́ kí ó mu ẹmu yó. Ẹmu tó mu yìí mú ki ó sùn lójú ọ̀nà, kò le è lọ mọ́. Nigbà tí Olódùmarè retí rẹ̀ títí tí kò rí i, ó rán Odù tó dá ìwà tí í ṣe Odùduwà. Orìṣà atẹ̀wọ̀nrọ̀ ni Odùduwà nítorí pé ẹ̀wọ̀n ni ó fi rọ̀ wá sí ilé ayé. Abímbọ́lá (1969:26) ṣe ìtọ́kasí èyí nínú Ọ̀yẹ̀kú méjì.
20231101.yo_4078_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Odùduwà àti àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ rọ̀ sí ni wọ́n ń pè ní òkè Ọ̀ràmfẹ̀ lónìí. Níbẹ̀ ni Odùduwà ti rí omi tí ó tẹ́jú lọ, ó sọ adìye yìí sí orí omi yìí, adìyẹ yìí sì bẹ̀rẹ̀ sí tan yanrìn náà títí. A sì sọ ọ́ di ilẹ̀ Ifẹ̀. Èyí ni pé ilẹ̀ ẹ́ fẹ̀. Ibi tí ó tan yanrìn náà de ni òkun, ibi tí Odùduwà wá tẹ̀dó sí ni Ilé-Ifẹ̀. ìdí nìyí tí àwọn Ifẹ̀ ṣe màa ń ki Odùduwà ni:
20231101.yo_4078_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
According to the oral traditional history of Ilé-Ifẹ̀, Odùduwà was instructed to throw with a fowl of five toes to spread the grains of sand with a view to reclain the land from the water
20231101.yo_4078_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
(Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtẹnudẹ́nu ìlú Ilé-Ifẹ̀, Odùduwà gba àṣẹ láti da iyẹ̀pẹ̀ sí orí omi pẹ̀lú adìyẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún kí omi náà le di ilẹ̀)
20231101.yo_4078_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Ní èrò tiwa, ìtàn yìí fara pẹ́ òtítọ́ ní àwọn ọ̀nà kan, ó sì jìnnà sí òtítọ́ ní àwọn ọna mìíràn. Ìdí òtítọ́ rẹ̀ ni pé èdè Ifẹ̀ “ilẹ̀ ẹ́ fẹ̀” hàn nínú orúkọ tí wọn sọ ìlú náà tí í ṣe ilẹ̀ Ifẹ̀ tí ó di Ilé-Ifẹ̀. Bákan náà, èdè wọn hàn nínú orúkọ oyè ọba wọn “Ọọ̀ni”. Àpètán Ọọ̀ni ni “ọni kọ́ ni ilẹ̀”. “Ẹni” ni Ifẹ̀ ń pè ni “Ọni”. Nítorí náà, Ẹni tí ó ni ilẹ̀ wá di Ọọ̀ni ilẹ.
20231101.yo_4078_13
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Ẹ̀wẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọọ́lẹ̀ lo fi ìdí rẹ múlẹ̀ pé Ilé-Ifẹ̀ ni ayé ti bẹ̀rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ Johnson (1921:15) ni:
20231101.yo_4078_14
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
All the various tribes of the Yoruba nation trace their Origin from Oduduwa and the city of Ilé-Ifẹ̀. In fact Ile-Ife is fabled as the spot where God created man white and black and from whence they dispersed all over the earth .
20231101.yo_4078_15
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
(Gbogbo ẹ̀yà Yorùbá lo tọsẹ̀ orírun wọn sí Odùduwà, a tilẹ̀ gbọ́ ọ nínú ìtàn pé Ile-Ifẹ̀ ni Ọlọ́run ti ṣẹ̀dá ènìyàn, yálà funfun tàbí dúdú tí wọ́n sì ti ibẹ̀ fọ́n káàkiri ilé ayé).
20231101.yo_4078_16
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Bákan náà ni Adeoye (1979:28) se àlàyé pé Ilé-Ifẹ̀ ti fi ìgbà kan jẹ́ Olú ìlú fún àwọn ọmọ aládé mẹ́rìndínlógún kó tó di pé wọ́n pínyà.
20231101.yo_4078_17
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Lọ́jọ́ tí wọn yóò sì jáde ní ìta ìjerò ní ibi tí ilé-ifẹ̀ ti wà ní òwúrọ̀ ọjọ́ (ibẹ̀ wà láàrin Ifẹ̀wàrà àti ilé-ifẹ̀ lónìí) lábẹ́ Igi ọdán àti pèrègún, ìta ìjerò yìí ni àwọn ọmọ aládé mẹ́rindínlógún yìí ti pínyà.
20231101.yo_4078_18
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe a rí àwọn ẹ̀rí bì í mélòó kan tí a fi lérò pé òtítọ́ ni ìtàn atẹ̀wọ̀nrọ̀ yìí, síbẹ̀ a kò lè fi gbogbo ara kà á sí òtítọ́ nítorí àwọn ìbéèrè kan wà tí a kò lè rí ìdáhùn fún bí a bá fi ojú ìmọ́ sáyéǹsí wò ó. Àwọn ìbéèrè náà ni pé; Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe kí ènìyàn fi ẹ̀wọ̀n rọ̀ wá si ayé? Ǹjẹ́ a lè da iyẹ̀pẹ̀ sí inú omi kí ó má lọ si ìsàlẹ̀ odò, kí a má ṣẹ̀sẹ̀ wá sọ pé adìyẹ̀? Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ ṣe é ṣe kí adìyẹ kan ṣoṣo tan ilẹ̀ dé gbogbo ayé? Ǹjẹ́ ìwọ̀nba iyẹ̀pẹ̀ díẹ̀ lè tó láti kárí gbogbo ayé? Níwọ̀n ìgbà tí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí bá jẹ́ rárá, a jẹ́ pé ìtàn ìwáṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́rìírí tí a kàn ní láti gbà gbọ́ ni. Ó jìnà sí òtítọ́ púpọ̀.
20231101.yo_4078_19
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ ni wọ́n sọ nípa itan kejì tí í ṣe ìtàn Mẹ́kà pé láti ìlú Mẹ́kà ni Odùduwà ti wá tẹ̀dó sí Ilé-Ifẹ̀. Lára àwọn onímọ̀ náà ni Johnson (1921:384), Owólabí (awy) (1986:2-8). Ní ìlú Mẹ́kà, Odùduwà yapa sí ẹ̀sìn abínibí rẹ̀ tí í ṣe ẹ̀sìn Lámúrúdu baba rẹ̀. Ìyapa yìí mú kí ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ láàrin Odùduwà àti àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí. Bùràímọ̀, ọmọ Odùduwà pàápàá lòdì sí Odùduwà baba rẹ̀ nítorí pé ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ní ṣe. Inú bí Odùduwà, ó sì pàṣẹ̀ pé kí wọ́n sun ọmọ rẹ̀ náà ni ààye. Inú bí awọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí yòókù, wọn gbógun ti Odùduwà. Odùduwà sá àsàlà kúrò ní Mẹ́kà, ó sì tẹ́dò sí Ilé-Ifẹ̀. Ó bá Àgbọnmìrègún tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sẹ̀tílù. Àgbọnmìrègún yìí ló dá ẹ̀sìn ifá silẹ. Ìtàn náà tẹ síwájú láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn ọmọ Yorùbá yòókù ti lọ. Ìtàn yìí fẹ́ dojúrú díẹ̀ nítorí oríṣìíríṣìí ìtàn ni a ń gbọ nípa ìran Yorùbá. Àwọn kan sọ pé Ọ̀kànbí nìkan ni ọmọ Odùduwà tí Ọ̀kànbí sì wá bí àwọn ọmọ méje tí wọ́n jẹ́ ọba Aládé káàkiri ibi tí a lè tọpasẹ̀ àwọn Yorùbá dé lónìí. Àwọn mìíràn gbà pé àwọn méje wọ̀nyí kì í ṣe ọmọ-ọmọ Odùduwà, pé ọmọ Odùduwà gan-an ni wọ́n àti pé kì í ṣe ìyàwó kan ṣoṣo ni Odùduwà ni. Èrò yìí ni Mákindé (1970:8) fi hàn nígbà tí ó sọ pé:
20231101.yo_4078_20
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Among the wives of Odùduwà were Atiba, Omitoto and Olókun. He had children by many of them. The children set up Obaship and Chieftaincy institutions in the various parts of Yorùbá land
20231101.yo_4078_21
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
(Lára àwọn ìyàwó Odùduwà ni Àtìbà, Omìtótó àti Olókun. Púpọ̀ nínú wọn ni ó bí ọmọ fún un. Àwọn ọmọ náà sì gbé ìjọba àti ètò ìṣèlú kalẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Yorùbá).
20231101.yo_4078_22
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Ìtàn tí ó gbà pé Odùduwà ni ó bí àwọn ọmọ méje tó tẹ ilẹ̀ Yorùbá dó sọ pé Olówu ni àkọ́bí Odùduwà. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn, obìnrin ni Olówu. Olówu yìí ni ó gbé àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin wá kí Odùduwà. Odùduwà gbé ọmọ náà lé ẹsẹ̀. Ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ké, ó sì ń fa mọ́ adé orí bàbá ìyá rẹ̀. Odùduwà ṣí adé, ó sì fi lé ọmọ náà lórí, ọmọ náà sì gbàgbé sùn lọ tòun tadé lórí. Èyí mú kí Odùduwà yọ̀ǹda adé fún ọmọ náà nígbà tí ó jí. Bóyá ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń ki àwọn Òwu ní
20231101.yo_4078_23
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Ọ̀ràngún ilé Ìlá, Onísábé ti ilẹ̀ Sábẹ́, Olúpópó tí í ṣe ọba Pópó àti Ọ̀rányàn. Ìtàn tó tọ́ka sí Ọ̀kànbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ kan ṣoṣo tí Odùduwà bí náà gbà pé Ọ̀ràńyàn ni àbígbẹ̀yìn ọ̀kànbí. Nígbà tí bàbá wọn kú. Ọ̀rányàn kò sí nílé, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì pín gbogbo dúkìá bábá wọn mọ́ ọwọ́, ilẹ̀ nìkan ni wọ́n fún un. Ó gba ilẹ̀ tí wọ́n pín fún un, ó sì sọ ọ́ di dandan fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ láti máa san ìsákọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ náà. Èyí mú kí ó di olówó, alágbára àti olókìkí láàrin àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Johnson (1921:8) jẹ́rì í sí èyí pé;
20231101.yo_4078_24
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Ọ̀rányàn was the youngest of Odùduwà’s grandchildren, but eventually, he became the richest and most renowned of them all.
20231101.yo_4078_25
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
A gbọ́ pé ń ṣe ni Ọ̀ràńyàn ń lọ láti ìlú kan sí ibòmíràn tí ó sì ń tẹ ìlú dó bí ó ti ń lọ káàkiri. Lára àwọn ìlú náà ni Ọ̀yọ́-Ilé, Ahoro Òkò, Ìkòyí, Ilé Igbọn, Ìrẹsà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. A gbọ́ ọ bákan náà pé àwọn ọmọ Odùduwà ju méje lọ. Àwọn òpìtàn mìíràn ń fi Aláké Ẹ̀gbá àti Obòkun ti Ìjẹ̀ṣà mọ́ wọn. Oyèbámijí (awy) (1990:4) ni
20231101.yo_4078_26
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Òpìtàn kan náà, Àlùfáà Johnson tún fi yé ni pé Aláké àti Ọwá jẹ́ ọmọ Odùduwà tí wọ́n sì lọ tẹ̀dó sí Aké ní orílẹ̀-Aké àti ní ilẹ̀ Ìjẹ̀sà níbi tí wọ́n wà di òní yìí
20231101.yo_4078_27
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Owólabí (awy) (1986:8) sọ pé bí ìran Yorùbá ṣe wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjírìà ni wọ́n wà káàkiri àgbáńlá ayé bí i ilẹ̀ Sàró, Gánà, Tógò, Bìní, ilẹ̀ Àmẹ́ríkà, Bùràsíìlì, Jàmáíkà àti ogunlọ́gọ̀ erékùsù tí ó wà káàkiri òkun Àtìláńtììkì. Lórí bí àwọn ọmọ Yorùbá ṣe ta gbòǹgbò káàkiri àgbáyé yìí náà ni Akínyẹmí (1991:586) sọ̀rọ̀ lé nígbà tí ó ní:
20231101.yo_4078_28
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Ifẹ̀ ni wọ́n ń pe Yorùbá orílẹ̀ èdè Tógò. Àwọn Yorùbá tó sì wà ní orílẹ̀ èdè Benin pín sí méjì ‘ìdásà’ àti ‘Manígì’. Kì í ṣe orílẹ̀ èdè mẹ́ta yìí nikan ni Yorùbá wà. Àwọn onímọ̀ bíi Abímbọ́lá, Turner àti Watkins ti ṣe áláyè pé àwọn ẹni tí wọ́n kó lọ orílẹ̀ èdè ‘Cuba’, ‘Brazil’ àti America’, wà níbẹ̀ lónìí tí wọn ń gbé èdè àti àsà Yorùbá lárugẹ. Àwọn Yorùbá tó wà ni ‘cuba’ ni wọ́n ń pé ní ‘Lucumi’. Àwọn tó wà ni ‘Brazil’ ni wọ́n ń pè ni ‘Nàgó’.
20231101.yo_4078_29
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, abala kan ìtàn tí ó sọ pé Odùduwà wa láti Mẹ́kà fara pẹ́ òtítọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni apá kan rẹ̀ jìnà sí òtítọ́. A lè ka ìtàn Mẹ́kà yìí sí òtítọ́ nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣìíríṣìí àkọọ́lè ló wà tó tọ́ka sí Odùduwà àti Ilé-Ifẹ gẹ́gẹ́ bí orírun ọmọ Yorùbá tí oríṣìíríṣìí àkọọ́lè sì wà pẹ̀lú pé mẹ́kà ni Odùduwà ti wá sí ifẹ̀, Ìtàn Mẹ́kà jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ju ìtàn atẹ̀wọ̀nrọ̀ lọ tí a ba fojú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn wò ó.
20231101.yo_4078_30
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Tí a bá fi ojú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ìbára-ẹni gbépọ̀ wo ìtàn Mẹ́kà yìí, a kò le kà á sí òtítọ́ rárá. Ìdí ni pé ìrísí àwọn ènìyàn Ifẹ̀ àti ìran Yorùbá lápapọ̀ yàtọ̀ gédégédé si ti awọn ara Mẹ́kà bẹ́ẹ̀ sì ni àṣà àti ìṣe wọn kò bára mu.
20231101.yo_4078_31
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Àkíyèsí mìíràn tí a ṣe ni pé ìtàn yìí sọ pé Odùduwà bá Àgbọnmìrègún ni Ilé-Ifẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Odùduwà bá Àgbọnmìrègún ní Ile-Ifẹ̀, á jẹ́ pé Ilé -Ifẹ̀ ti wà kí Odùduwà tó dé.
20231101.yo_4078_32
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Nínú ìtàn mìíràn, èyí tó fara jọ ìtàn inú Bíbélì, a gbọ́ pé nígbà ti ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀, àgbàrá òjò gbá gbogbo àwọn tó wà láyé nígbà náà lọ, Odùduwà wà lára àwọn tó yè, ìjọba tuntun sì bẹ̀rẹ̀ lábẹ́ àkóso Odùduwà (Fábùnmi 1969:4) jẹ́rìí sí èyí pé:
20231101.yo_4078_33
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
…Odùduwà came neither from the East nor from the West but that he was one of the people who lived before the deluge, and that, after the deluge, he together with his followers and their families, descended unto dry land by means of chain-ropes from their life-boat which anchored on Oke-Ora.
20231101.yo_4078_34
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
(Odùduwà kò wá láti ìlà Oòrun tàbí ìwọ̀ oòrùn, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó wà láyé kí ìkún omi tó dé, àti pé lẹ́yìn ìkún omi, òun pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ àti àwọn ẹbí rẹ̀ fi ẹ̀wọ̀n rọ̀ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ ìyè wọn, èyí tí ó gúnlẹ̀ sí Òkè-Ọ̀ra).
20231101.yo_4078_35
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Èyí pàápàá tún fi òkodoro ọ̀rọ̀ náà hàn pé wọn kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ilé ayé tàbí tẹ ìlú kan dó, àsìkò ìjọba kan sí èkejì ló ń ṣẹlẹ̀.
20231101.yo_4078_36
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Ní ọ̀nà mìíràn, a kò tilẹ̀ gbọ́ nínú ìtàn àwọn Áráàbù pé Odùduwà fi ìgbà kan wà ní Mẹ́kà bẹ́ẹ̀ ni ìṣ̣ẹ̀lẹ̀ yìí ṣe pàtàkì ju pé kí òpìtàn ilẹ̀ Áráábù kankan má mẹ́nu bà á lọ.
20231101.yo_4078_37
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Ct%C3%A0n%20Il%C3%A9-If%E1%BA%B9%CC%80
Ìtàn Ilé-Ifẹ̀
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtakora díẹ̀díẹ̀ wà nínú ìtàn méjèèjì òkè yìí, síbẹ̀ ìtàn méjèèjì ló tọ́ka sí Odùduwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó tẹ Ilé-Ifẹ̀ dó.
20231101.yo_4079_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Charles%20Darwin
Charles Darwin
Charles Darwin jẹ́ onímọ̀ àdáyébá ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (Ọjọ́ kejìlá Oṣù kejì Ọdún 1809 – Ọjọ́ ọkọkàndínlógún Oṣù kẹrin Ọdún 1882) tí ó mú àbá àti òfin tí ó de èrò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ wipé gbogbo ohun ẹlẹ́mí pátá jọ wá láti ọ̀dọ̀ adẹ́dàá kan náà ni...
20231101.yo_4080_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%89mile%20Durkheim
Émile Durkheim
Émile Durkheim (April 15, 1858 – November 15, 1917) je onimo awujo omo ile Fransi ti o ko ipa pataki ninu imo awujo ati imo eda. O ko opolopo iwe lori eko, iwa odaran, esin igbaemi araeni ati lori opolopo eka awujo.
20231101.yo_4081_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Max%20Weber
Max Weber
Maximilian Carl Emil Weber (21 April 1864–14 June 1920) je onimo eto inawole ati onimo awujo omo ile Jẹ́mánì ti a mo gege bi okan ninu awon oludasile eko nipa awujo ati iseijoba igboro.
20231101.yo_4085_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/J%C3%BCrgen%20Habermas
Jürgen Habermas
Jürgen Habermas (abi ni osu June ojo 18, odun 1929 ni ilu Düsseldorf) je amoye ati onimo awujo omo ile Jẹ́mánì nini eka imo oye to je mo agbeyewo ero ati asa amerika lori oyegangan. O gbajumo lati inu ise re lori igboro roboto ti o gbeduro lori ero ise ibanisoro.
20231101.yo_4128_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80d%C3%ACt%C3%BA%20Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Àdìtú Olódùmarè
Ìwé ìtàn-àròsọ yìí wà fún tọmọdé tàgbà lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n mọ èdè Yorùbá kà dáadáa. Òun pẹ̀lú àwọn ìyóòkù rẹ̀ bíi Ògbójú Ọdẹ nínú Igbo Irúnmọlẹ̀, Ìrèké Òníbùdó, Ìrìnkèridò nínú Igbo Elégbèje àti Igbó Olódùmarè, tí D.O Fagunwa kọ jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára ìwé tí àwọn ọmọ Iléẹ̀kọ́ gíga yunifásítì tàbí Iléẹ̀kọ́ àwọn olùkọ́ni fún iṣẹ́ akadá lọ́pọ̀ ìgbà. Iṣẹ́ gbooro lórí ìwé bíi ìtúpalẹ̀, lámèyító, abbl bákan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè lo fún iṣẹ́ àpilẹ̀kọ fún àṣekágbá ẹ̀kọ́.
20231101.yo_4128_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80d%C3%ACt%C3%BA%20Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Àdìtú Olódùmarè
D.O. Fágúnwà (2005) Àdììtú Olódùmarè Ibadan; Evans Brothers (Nigeria publishers) Limited, ISBN 978-126-239-7. Ojú-iwé 148.
20231101.yo_4134_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92g%C3%BAn%20L%C3%A1k%C3%A1ay%C3%A9
Ògún Lákáayé
Ògún nínú ìtàn aròsọ àtẹnu-dẹ́nu ní ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ òrìṣà tó ní agbára lórí ina, irin, ìsọdẹ, ìṣèlú àti ogun.
20231101.yo_4134_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92g%C3%BAn%20L%C3%A1k%C3%A1ay%C3%A9
Ògún Lákáayé
“Ọmọ ti yóò j’aṣàmú, kékeré ló ti ńjẹnu ṣámúṣámú lọ.” Owe àwọn àgbà yìí ló bá ẹni tí ó kọ ìwé yìí mu ọ̀gbẹ́ni Ọlátúbọ̀sún Ọládàpọ̀, nitori àkókò ti o ńkẹ́kọ̀ọ́ ni ilé-ìwé àwọn olùkọ́ ti Lúkù Mimọ́ ni ó kọ ìwé yìí, nílùú Ìbàdàn.
20231101.yo_4134_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92g%C3%BAn%20L%C3%A1k%C3%A1ay%C3%A9
Ògún Lákáayé
Lákòókò yìí, mo ni àǹfàní àti jẹ́ olùkọ́ọ rẹ̀ nínú ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Yorùbá, àti láti tún jẹ́ alábòjútó Ẹgbẹ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá ti Kọ́lẹ́ẹ̀jì náà. Lọ́nà méjèèji yii ni Ọ̀gbẹ́ni Ọládàpọ̀ ti fi ara rẹ̀ hàn bii akọni nínú èdèe Yorùbá. dé ibi pé ni ọdún kẹta rẹ̀ ni Kọ́lẹ́ẹ̀jì, òun ni a fi jẹ alága Ẹgbẹ́ Ìjinlẹ̀ Yorùbá ti Kọ́lẹ́ẹ̀jì náà.
20231101.yo_4134_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92g%C3%BAn%20L%C3%A1k%C3%A1ay%C3%A9
Ògún Lákáayé
Nígbà tí ó sì dip é ki á máa wá eré ti ẹgbẹ́ yóò ṣe ní ọdún 1967, eré tirẹ̀ yii ni a yàn pé ó gbayì jù nínú gbogbo àwọn eré ti a yẹ̀wò nígbà náà. Àwọn ti ó wo eré náà nígbà ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣe é ni Gbọ̀ngàn Sẹ̀ntínárì ní Aké, Abẹ́òkútà àti ni Gbọ̀ngàn Àpèjọ ti Ilé-Ẹkọ́ giga tí ìlú Ayétòrò ni, “àrímá -leèlọ àwò-padà-sẹ́hin” ni eré náà í-ṣe. Eyi ló fún mi ni ìdùnnú láti lè kọ ọ̀rọ̀ àsọsiwájú yìí lórí ìwé ÒGÚN LÁKÁAYÉ. Eré náà kọ́ ènìyàn ni ògidìi Yorùbá. o fi oriṣiriṣI àṣà Yorùbá hàn; ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó kọ́ ènìyàn lọ́gbọ́n lóríṣiríṣi ọ̀nà.
20231101.yo_4134_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92g%C3%BAn%20L%C3%A1k%C3%A1ay%C3%A9
Ògún Lákáayé
Ọlatunbọsun Ọladapọ (1983) Ògún Lákaayé Ibadan; Onibonoje Press and Book Industries (NIG) LTD. Ojú-iwé 138.
20231101.yo_4139_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8%CC%80w%C3%B9%20%C3%80gb%C3%A0
Ẹ̀wù Àgbà
Thomas Mákánjúọlá Ilésanmí (2002) Ẹ̀wù Àgbà Ibadan; University Press PLC Ibadan, ISBN 978-030-823-7 Ojú-iwé 68.
20231101.yo_4232_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Ọọ̀ni ti Ilè-Ifẹ̀ ni orúkọ ọba aládé Ilé-Ifẹ̀ àti olórí nípa tẹ̀mí fún gbogbo ìran Yorùbá. Ipò Ooni ti wà ṣáájú ìjọba Oduduwa, èyí tí àwọn onímọ̀ sọ pé ó ti wà láti bíi sẹ́ńtúrì keje sí kẹsàn-án.
20231101.yo_4232_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Lẹ́yìn ìpapòdà Oduduwa àti ìpàdánù orí-oyè fún Ogun, àwọn ọmọ lẹ́yìn Oduuwa tàn kárí Ile-Ife. Àmọ́ ìtàn mìíràn fi yé wa pé Ogun ló mọ̀ ọ́n mọ̀ rán àwọn ọmọ Oduduwa láti ṣe ìtànkálẹ̀ ìran Yoruba.
20231101.yo_4232_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Lẹ́yìn ìṣèjọba Oduduwa, Obatala tún gorí oyè ní ẹlẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì í pín ètò ìṣèjọba láàárín ìdílé Obatala àti Obalufon títí Oranmiyan fi da ètò náà rú fúngbà díẹ̀. Ìtàn fi yé wa pé Ooni Lajamisan jẹ́ ọmọ Oranmiyan. Àmọ́, ìṣẹ̀ṣe Ife fi hàn pé Lajamisan jẹ́ ìran Oranfe ní tòótọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, Lajamisan ni ó pàpà mú ọ̀làjú wọ Ifẹ̀.
20231101.yo_4232_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Ṣáájú sẹ́ńtúrì ogún, ètò ìṣèjọba ń lọ létòlétò. Àmọ́, pẹ̀lú ọ̀làjú àti ìkónilẹ́rú, ètò náà yí padà, ó sì pín sí ìdílé mẹ́rin, t í ṣe Ooni Lafogido, Ooni Osinkola, Ooni Ogboru àti Ooni Giesi. Ọọ̀ni tó ń jẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni Adéyẹyè Ẹnitàn Ògúnwúsì, Ojaja II (tí a bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹwàá, ọdún 1974).
20231101.yo_4232_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Chief Fabunmi 1975 quotes 7 names for the same period. See column 6. Chief Fabunmi is known for his Historical notes.
20231101.yo_4232_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Prince L. A. Adetunji 1999, pages 70–77. The prince, from the Giesi family, was one of the contenders for the 2015 designation. See column LA.
20231101.yo_4232_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Ologundu 2008, pages 58–59. Lists 48 names, that are the B list, except from Obalufon Alayemore (#5) and Aworokolokin (#12). Moreover, Osinkola (#18) is at #25 (strange place) Araba Adedayo Ologundu was a native of Ile-Ife, Nigeria. See column Og.
20231101.yo_4232_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Lawal 2000, page 21 (nevertheless, this book is Google described as a 19 pages book !). See column LB.
20231101.yo_4232_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Ooni Ojaja II web site, 2016 quotes 51 names. Same as list B, differs only by the diacritics. No references are given. This list was already in use before 2015.
20231101.yo_4232_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%E1%BB%8D%CC%80ni%20If%E1%BA%B9%CC%80
Ọọ̀ni Ifẹ̀
Ìfọbajẹ kì í ṣe isẹ́ tó rọgbọ rárá, ó sì ní àwọn tíwọ́n fi sípò láti máa fọba jẹ. Ìfilélẹ̀ látẹnu àwọn afọbajẹ ní ọdún 1980 lábẹ́ Section 4(2). Ní ọdún 1957, ìfilélẹ̀ tí wọ́n ṣe fún ètò ìfọbajẹ ni:
20231101.yo_4242_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%CC%80y%E1%BB%8D%CC%81t%C3%BAnj%C3%AD
Ọ̀yọ́túnjí
Oyotunji Apejopo awon kan ni yi ti won n gbe ede ati asa Yoruba laruge. Won pe ibi ti won wa ni The kingdom of Oyotunji, Box 51, Yoruba Village, South carolina 29941. Oruko Oba won ni H.R.H. Oba Oseijeman Adefunmi 1. Ile-Ife ni oba yii ti wa gba ade ni ojo karun-un osu kefa, odun 1981 ni aafin Oba Okunade Sijuwade, Olubushe Keji. Eyi si ni igba akoko ti eni ti kii se omo ile Naijiria yoo gba ade ni Ile-Ife. Orisirisi orisa ile Yoruba ni won n bo ni ibi yii.
20231101.yo_4242_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BB%8C%CC%80y%E1%BB%8D%CC%81t%C3%BAnj%C3%AD
Ọ̀yọ́túnjí
C.M. Hunt (1977), "Oyotunji Village: Yoruba Movement in America.", PhD Dissertation, West Virginia University.
20231101.yo_4253_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ew%C3%AC%20Ayaba
Ewì Ayaba
Ewì ayaba jẹ́ ewì tí a mọ̀ mọ́ àwọn ìyàwó ọba nìkan. Ọ̀kan pàtàkì lára ẹ̀yà ewì alohùn ilẹ̀ Yorùbá ni pẹ̀lú. Ààfin ọba ni a ti ń bá ewì ayaba pàdé. Ní pàtàkì jù lọ, ewì obìnrin ni ewì ayaba. Ohun tí à ń sọ ni pé àwọn obìnrin nìkan ló ń kópa nínú àgbékalẹ̀ ewì ayaba.
20231101.yo_4253_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ew%C3%AC%20Ayaba
Ewì Ayaba
Ọjọ́ ewì ayaba ti pẹ́ láwùjọ Yorùbá. Láàrin àwọn Ọ̀yọ́ ni ewì yìí ti wọ́pọ̀ jù lọ. Ìwádìí jẹ́ kí á mọ̀ pé irú ewì yìí náà ń wáyé láàrin àwọn Èkìtì. (Aládésurú, 1985) Orúkọ tí a mọ̀ mọ́ ewì yìí ní agbègbè Èkìtì ni orin olorì. Yálà kí á pe ewì yìí ní “ewì ayaba” tàbí “orin olorì”, sibẹ́ iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe láwùjọ Yorùbá.
20231101.yo_4253_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ew%C3%AC%20Ayaba
Ewì Ayaba
Ìwádìí jẹ́ kí á mọ̀ pé àwọn ayaba kì í gbé ewì yìí jáde kọjá àsìkò ayẹyẹ tàbí ìṣẹ̀ṣe inú ààfin ọba láyé àtijọ́. Lóde òní, ewì ayaba ti ń wáyé nínú ayẹyẹ tó jẹ́ ti ìdílé ọba. Bákan náà, ewì ayaba a tún máa wáyé nínú ayẹyẹ ìlú; tí ọba bá ti wà níbè.̣ Nípa àkíyèsí wọ̀nyìí, a rí i pé ewì ayaba wà fún ọba, ayaba àti ẹbí ọba lápapọ̀.
20231101.yo_4253_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ew%C3%AC%20Ayaba
Ewì Ayaba
Gbogbo ewì alohùn Yorùbá ló ní kókó tí wọ́n má ń dá lé lórí. Lára kókó tí ewì ayaba máa ń dá lé lórí ni ìjúwe àwọn ayaba gẹ́gẹ́ bí i aya aládé, àrẹ̀mọ ọba tàbí abọ́baṣèlú. Ọ̀rọ̀ nípa ìgbésí-ayé ayaba, àti ọba nínú ààfin. Àlèébù to wà nínú ilé ọba. Ìwà òjòwú láàrin ayaba, ìṣàfihàn ipò ọba láàrin ìlú. Orúkọ àdàpè ọba. Ítàn àwọn ọba tó ti jẹ rí. Ọ̀rọ̀ nípa ìdàgbàsókè tó wọ inú ìlú lásìkò ọba kọ̀ọ̀kan. Àkíyèsí nípa ìwà ọba tàbí ìrísí ọba. Ọ̀rọ̀ nípa ọdún àti ìbọ tó ń wáyé láàrin ìlú tó jẹ́ ti ọba Ọ̀yọ́-Ọ̀ṣun. Ìwúre fún ọba àti ẹbí ọba.
20231101.yo_4253_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ew%C3%AC%20Ayaba
Ewì Ayaba
M. O. Oyewale, ‘Àgbéyẹ̀wò Ewì Ayaba láàrin Àwọn Ọ̀yọ́-Ọ̀ṣun’., Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹẹ́meè, DALL, OAU, Ifè, Nigeria.
20231101.yo_4253_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ew%C3%AC%20Ayaba
Ewì Ayaba
Iṣẹ́ yìí ṣe àgbéyẹ̀wò ewì ayaba láàrin àwọn Ọ̀yọ́-Ọ̀ṣun. Ó sì jẹ́ kí á mọ̀ nípa àbùdá ewì ayaba, ìsọwọ́lò-èdè ewì ayaba, ọgbọ́n ìsèré ewì ayaba àti ìwílò rẹ̀ láwùjọ.
20231101.yo_4253_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ew%C3%AC%20Ayaba
Ewì Ayaba
Ọgbọ́n ìwádìí tí a yàn láàyò nínú iṣẹ́ yìí ni gbígba ohùn ewì ayaba sínú fọ́nrán. Àwọn ìlú márùn-ún tí agba ohùn ewì ayaba wọn sínú fọ́nrán ni Òṣogbo, Ẹdẹ, Ìláwó-Èjìgbò, Ìwó àti Ìkòyí. Lẹ́yìn náà, a ṣe àdàkọ ewì wọ̀nyìí, a sì ṣe àtúpalẹ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, a fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ọba ìlú tí a mẹ́nubà yìí lẹ́nu wò. A tún ka àwọn ìwé tó bá iṣẹ́ yìí mu. Tíọ́rí ìbára-ẹni-gbépọ̀ láwùjọ ni a yan láàyò láti fi ṣe àtúpalẹ̀ àkòónú àti ìsọwọ́lò-èdè inú ewì ayaba yìí.
20231101.yo_4253_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ew%C3%AC%20Ayaba
Ewì Ayaba
Ìwádìí lórí iṣẹ́ yìí fi hàn pé ewì ayaba jẹ́ ẹ̀yà lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá tó jẹ́ ti àwọn obìnrin; ní pàtàkì jùlọ ìyàwo ọba olorì ọba tàbí ayaba. A jẹ́ kí ó di mímọ̀ nínú iṣẹ́ yìí pé àwọn ayaba a máa ké ewì wọn yìí láàfin tàbí nínú ayẹyẹ tó kan ọba ìlú dáradára. A sọ nínú iṣẹ́ yìí pé ìsọ̀rí ayaba méjì tí a mọ̀ sí ayaba àgbà àti ayaba kéékèèké ló ń lọ́wọ́ nínú ewì yìí.
20231101.yo_4253_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ew%C3%AC%20Ayaba
Ewì Ayaba
Ní ìkádìí, iṣẹ́ yìí ṣàlàyé pé orin àti ìsàré ni ewì ayaba Ọ̀yọ́-Ọ̀ṣun. Ìwádìí lórí iṣẹ́ yìí sì jẹ́ kí á mọ̀ pé ewì ayaba yìí gbajúgbajà nínú ṣíṣe ìjíyìn nípa ayaba, ọba àti àwọn ìṣèṣe inú àwùjọ kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀ ewì ayaba yìí tún jẹ mọ́ ìwúre fún ọba àti ẹbi ọba
20231101.yo_4320_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%BAy%E1%BB%8D%CC%80l%C3%A9
Olúyọ̀lé
Wọ́n bí Baṣọ̀run Olúyọ̀lé ní Ọ̀yọ́ àtijọ́ sí inú ìdílé Olúkùoyè tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ Àrẹmọbìnrin Àgbọ̀nyín tí ó jẹ́ ọmọ Aláàfin Abíọ́dún nígbà náà . Òun ni ó kọ́kọ́ rí ìlú Ìbàdàn gẹ́gẹ́ bí ìlú olókìkí yàtọ̀ sí ibùdó ogun. Ìdí rèé tí ó fi fi ìdí ìjọba tó gíríkì múlẹ̀ nígbà náà.
20231101.yo_4320_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%BAy%E1%BB%8D%CC%80l%C3%A9
Olúyọ̀lé
Àsìko rẹ̀ ni àwọn ìlú tí wọ́n wà ní abẹ́ Ìbàdàn gbèrú si. Kò kùnà láti gbé iṣẹ́ àgbẹ̀ lárugẹ, bẹ́ẹ̀ ni ó fi ìpìlẹ̀ ọrọ̀ ajé tí ó nípọn múlẹ̀. Ìdí rèé tí a fi ń pe Ìbàdàn ní "ilé Olúyọ̀lé".
20231101.yo_4320_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%BAy%E1%BB%8D%CC%80l%C3%A9
Olúyọ̀lé
Látàrí họ́u họ́ù tí ogun dá sílẹ̀ láàárín àwọn àgbààgbà olóyè ìlú Ọ̀yọ́-ilé láti gorí àpèrè Aláàfin ti Ọ̀yọ́ nígbà náà tí ó ṣófo, èyí ni ó mú kí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ láàárín Aláàfin àti Baṣọ̀run Gáà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ọ̀yọ́ ìgbà náà sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn. Fífọ́nká tí àwọn ọmọ Ọ̀yọ́ fọ́n ká yí, tí wọ́n sì ti lọ tẹ̀dó sí oríṣìíríṣìí ibùgbé tí wọn kò sì fẹ́ san ìsákọ́lẹ̀ fún Ọ̀yọ́ mọ́, àsìkò yìí ni Iba Olúyọ̀lé di lààmì-laaka láàrín àwọn jagunjagun. Ó kọ́kọ́ di ìlúmọ̀ọ́ká látàrí ipa tí ó kó láàárín àwọn ọmọ ogun tí wọ́n borí ogun Òwu, ní èyí tí ó sì mú kí ìjọba ilẹ̀ Ẹ̀gbá àti àwọn ìlú bí Ìbàdàn ó ṣubú. Láti bu ọlá fún pẹ̀lú ipa rẹ̀ láti lè jẹ́ kí ìjọba Ọ̀yọ́ tí ó ti ń dẹnụ kọlẹ̀ ó tún gbìnà yá nínú àwọn ogun tí ó mú Ọ̀yọ́ borí ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú-Rẹ́mọ yí ni ó mú kí wọ́n fi jẹ ''Ààrẹ Àgò ilẹ̀ Ìbàdàn''. Òun náà sì fi ara rẹ̀ jẹ oyè ''Òsì-Kakaǹfò'', tí ó sọ ọ́ di ológun apàṣẹ wàá kẹta fún ilẹ̀ Ìbàdàn.
20231101.yo_4320_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%BAy%E1%BB%8D%CC%80l%C3%A9
Olúyọ̀lé
Akínwùmí Àtàndá (200) Basọ̀run Olúyọ̀lé Ibadan; Rasmed Publications, ISBN 978-8024-75-0. Ojú-iwé 140.
20231101.yo_4364_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Kur%C3%B3w
Kurów
Abule kan ni ila-oorun gusu ile Polandi ni o n je Kurów. O wa laarin Pulawi ati Lubiliini. Ilu ti awon kan jumo da sile ni. Ibe ni won ti n ta awon ounje ti won n pese ni agbegbe re. Awon ile-ise ti won ti n fi awo eran se nnkan wa ni ibe pelu. Ni senturi kerindinlogun, ibe ni awon ti o n se Kafinisiimu (Calvinism) ti maa n pe jo nitori pe ibe ni awon kan ti won n pe 'polish brethren' maa n gbe. nigba ti yoo fi di odun 1660, opolopo ninu awon eniyan ibe ti yi pada si esin arianisiimu (Arianism). Fun ekunrere liri abule kekere yii, wo ohun ti won ko nipa re ni http://en.wikipedia.org/wiki/Kur%C3%B3w ni ede Geesi.
20231101.yo_4410_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cran%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Ìran Yorùbá
Ìran Yorùbá, àwọn ọmọ Yorùbá tàbí Ọmọ káàárọ̀-oòjíire, jé árá ìpinle ẹ̀yà, ní apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Áfríkà. Wọn jé árá ìpin àwọn ìran to pò ju ní orílẹ̀ Áfríkà. Ilẹ̀ Yorùbá ní púpò nínú wọ́n. Ẹ lè ri wọ́n ní ìpínlẹ̀ púpò bíi ìpínlẹ̀ Ẹdó, Ìpínlẹ̀ Èkìtì, ìpínlẹ̀ Èkó, Ìpínlẹ̀ Kwara, ìpínlẹ̀ Kogí, ìpínlẹ̀ Ògùn, Ìpínlẹ̀ Oǹdó, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àti ní ẹ̀yà ila ọ́wọ́ òsi ti ilè Nàìjíríà. Ẹ tún le rí wọ́n ní ìpínlẹ̀ to wa nínú orílẹ̀-èdè Olómìnira Benin (Dahomey), ní orílẹ̀-èdè Sàró (Sierra Leone), àti ní àwọn orílẹ̀-èdè miiran bíi àwọn tí wọ́n pè ní Togo, Brazil, Cuba, Haiti, Amẹ́ríkà ati Venezuela. Àwọn Yorùbá wà l’árá àwọn to tóbí ju ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó le jẹ́ pe àwọn lo
20231101.yo_4410_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cran%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Ìran Yorùbá
Àwọn Yorùbá jẹ́ àwọn ènìyàn kan ti èdè wón pín sí orísirísi. Diẹ̀ lára àwọn ìpínsísọ̀rí àwọn èdè wọn ni a ti ri: "Èkìtì"; "Èkó"; "Ìjèbú"; "Ìjẹ̀ṣhà"; "Ìkálẹ̀"; "Ọ̀yọ́"; "Ẹ̀gbá" àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ìpínsísọ̀rí yí ni a ń pe ní ẹ̀ka èdè tàbí èdè àdúgbò.
20231101.yo_4410_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cran%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Ìran Yorùbá
Ìran Yorùbá je ènìyàn kan tí wọ́n fẹ́ràn láti máà se áájò àti àlejò àwọn ẹlẹ́yà míràn, wọ́n sì ma ń nífẹ́ sí ọmọ'làkejì.
20231101.yo_4410_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cran%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Ìran Yorùbá
Èdè Yorùbá jé èdè ti àwọn ìran Yorùbá ma'ń sọ sí ara wọn. Ójẹ́ èdè to pé jù ni ilẹ́ Yorùbá. Ẹ lè ri èdè yi ni Ilẹ Nàìjíríà, Ilẹ Benin, ati ni Ilẹ Togo. Iye to'n sọ èdè yi ju ni gbogbo ilẹ́ Yorùbá 30 milliọnu lọ.
20231101.yo_4465_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8%CC%80gb%C3%A1%20Ow%C3%B3d%C3%A9
Ẹ̀gbá Owódé
Ìwé Àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá tí Olóyè Olúdáre Ọlájubù jẹ́ Olóòtu, Ojú-iwé 1-11, Ikẹja; Longman Nigeria Limited, 1975.
20231101.yo_4465_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8%CC%80gb%C3%A1%20Ow%C3%B3d%C3%A9
Ẹ̀gbá Owódé
Agbègbè kọ̀ọ̀kan ni ó ní òfin àti àṣà nipa bí ènìyàn ṣe lè ní ilẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ tàbí fún ìgbà pípẹ́. Ní àwọn àgbègbè tí ọ̀làjú ti gòkè ní gbogbo àgbáyé, ilẹ̀ nínú ṣe pàtàkì fún àǹfàní iṣẹ́ẹ jíjẹ, mímu àti òwò nìkan. Ọ̀rọ̀ òṣèlú kò ṣe dandan lóríi rẹ̀ bíkọ̀ṣe nínú àwọn ọ̀ràn tí ó da ìlú méjì pọ̀.
20231101.yo_4465_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%BA%B8%CC%80gb%C3%A1%20Ow%C3%B3d%C3%A9
Ẹ̀gbá Owódé
Láti ilẹ̀ wá láàrín àwọn Yorùbá, ilẹ̀ nínú ṣe pàtàkì fún àǹfàní jíjẹ, mímú àti ti òwò. Láti kọ́lé àti láti ṣe oko ni ó ńmú kí gbogbo ènìyàn ní ìfẹ́ láti ní ilẹ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ ni kókó iṣẹ́ẹ wa, àwọn olóyè tàbí àwọn ọba ìlú tí wọn ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn lábẹ́ ìtọ́júu wọn máa ńní ilẹ̀ tó pọ̀ ní ikáwọ́ọ wọn ju ẹlòmíràn tí ẹbíi rẹ̀ kéré. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tó wà lábẹ́ àṣẹ olóyè kan, tí wọ́n sì ńṣiṣẹ́ sìn í ti pọ̀ tó ni iyì àti ẹ̀yẹẹ rẹ̀ ṣe máa pọ̀ tó láàrín ẹgbẹ́ àti ìlú. Èyí ni ó mú ọ̀rọ̀ àwọn àgbà kan wá tí o sọ pé, ‘Ohun tó wunni ní ńpọ̀ nínú ọrọ̀ ẹni, ológún ẹrú kú, aṣọ ọ rẹ̀ jẹ́ ọkan.” Ọ̀nà tí ìjòyè yìí fi lè di aláṣẹ lórí àwọn irú ènìyàn wọ̀nyí ni nípa fífi ilẹ̀ fún àwọn ẹbí tàbí ìdílée rẹ̀, ìbátan tàbí àlejò fún ọ̀gbìn ṣíṣe àti àwọn nǹkan míràn gbogbo, àti nípa pínpín oriṣiriṣi ẹ̀bún lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láàrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Lílo ilẹ̀ tí a tọrọ yìí lè jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ tàbí fífún láyéláyé. Fún ìdí èyí, a ní láti rí i pé kì í ṣe fún iyì láàrín ẹgbẹ́ tàbí ìlú nìkan ni ó mú kí àwọn ìdílé olóyè kan máa ní ilẹ̀ tó pọ̀, ṣùgbọ́n èyí jẹ́ ọ̀nà láti pín nǹkan jíjẹ, mímú àti ti òwò tí ó wọ́n eyíyìí ni ilẹ̀, ní ọ̀nà ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ orìíṣiríṣi ènìyàn tí ó wà ní ìlú tàbí abúlé. Nítorí náà, bí a bá wò ó láti ìhín lọ, ó ṣe é ṣe kí a sọ̀rọ̀ ilẹ̀ níní láàrín àwọn Yorùbá láti ipa jíjẹ, mímu àti ti òwò. Ṣùgbọ́n a ó mẹ́nu ba díẹ̀ nínú ètò ìlú ṣíṣe àti ẹgbẹ́ kíkó tí ó bá jẹ mọ́ tí ilẹ̀ nínú. ...
20231101.yo_4469_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cranra%E1%BA%B9nil%E1%BB%8D%CC%81w%E1%BB%8D%CC%81
Ìranraẹnilọ́wọ́
Ìwé Àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá tí Olóyè Olúdáre Ọlájubù jẹ́ Olóòtu, Ojú-iwé 1-11, Ikẹja; Longman Nigeria Limited, 1975.
20231101.yo_4469_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cranra%E1%BA%B9nil%E1%BB%8D%CC%81w%E1%BB%8D%CC%81
Ìranraẹnilọ́wọ́
Gẹ́gẹ́ bí gbogbo wá ṣe mọ̀ láti ọjọ́ tí aláyé ti dáyé ni àwọn èèyàn ti ńran ara wọn lọ́wọ́. Bí a ba nsọrọ nipa ọjọ tí alaye ti dáyé àwọn ti nka ìwé Bíbélì lára wa á fẹ́ mú ọkàn wọn lọ si àkókò tó jẹ pe ọkùnrin kan ṣoṣo ló wa lórílẹ̀ èdè ayé yìí, èyí ni Adamu. Mo rò pé a ò mọ gbogbo iṣẹ tó ṣe nínú ọgbà tí ó wà, ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ẹni ti ó mọ oúnjẹẹ́ jẹ nib í èèyan bíi tiwa ni, ó dáni lójú wí pé yíó máa gbìyànjú láti fi ọwọ ká èso igi jẹ ni. Ounjẹ sì nìyí kì í dùn tó bẹ́ẹ̀ tó bá ṣe èèyàn nìkan ṣoṣo ló ńjẹ́ ẹ́ láarọ̀, lọ́sàán àti lálẹ́ láti ọjọ kan dé ọ̀sẹ̀ kan, dé oṣù kan, dé ọdún kan. Itan Bíbélì náà sọ fun wa pé nígbà tí o bùṣe, Olúwa fi olùrànlọ́wọ́ kan jíǹkí rẹ̀, eléyìí náà ni obinrin tí a ńpè ni Éèfà. O dà bí ẹni pe inú ọgbà Ídẹ́nì náà gbádùn si i lẹ́hin tí àwọn méjèèjì ti wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n oríṣi ìrànlọ́wọ́ ti wọ́n rí náà kì í ṣe nkan ti kò ní ní ìfàsẹ̀hìn-in tirẹ̀. Mo fi ìyókù si ọkàn ẹ̀yin tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìwée ti Bíbélì.