_id
stringlengths 17
21
| url
stringlengths 32
377
| title
stringlengths 2
120
| text
stringlengths 100
2.76k
|
---|---|---|---|
20231101.yo_2438_39
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prosecute, v.t. lépa, bá rojọ́, pè lẹ́jọ́, pẹjọ́ (The police decided not to prosecute) Àwọn ọlọ́pàá pinnu láti má pẹjọ́.
|
20231101.yo_2438_40
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prosecution, n. ìbárojọ́, ìpèlẹ́jọ́ (Prosecution for a first minor offence rarely leads to imprisonment.) Ìpèléjọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́ṣẹ̀ tí kò le kìí sábàá mú ẹ̀wọ̀n dání.
|
20231101.yo_2438_41
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prosecutor, n. abánirojọ́, apenilẹ́jọ́, agbẹ́jọ́rò. (He is the state prosecutor.) Òun ni agbẹjọrò ìjọba.
|
20231101.yo_2438_42
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prospect, n. ìfi ojú sí ọ̀nà, híhàn, ìwò, ìrí si ìrètí ohun rere. (There is a reasonable prospect that his debts will be paid.) Ìfi ojú sọ́nà tí ó mọ́gbọ́n dání wà pé àwọn gbèsè rẹ̀ yóò di sísan.
|
20231101.yo_2438_43
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prosper, v.t and i. ṣe rere, ṣe aásìkí, lọ déédéé fún, lọ déédéé. (The economy prospered under his administration.) Ètò ọrọ̀ ajé ń lọ déédéé ní abẹ́ àkóso rẹ̀.
|
20231101.yo_2438_44
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prosperity, n. àlàáfíà, aásìkí (The country is enjoying a period of prosperity.) Ilẹ̀ náà ń gbádùn àkókò àláàfíà.
|
20231101.yo_2438_45
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prostitute, v.t. tà fún ìwà búburú, lò ní ìfẹ́kúùfẹ́ (He prostitude his honour.) Ó ta ọ̀wọ̀ rẹ̀ fún ìwà búburú.
|
20231101.yo_2438_46
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prostitution, n. ìfi àgbèrè àti páńṣágà ṣ òwò ṣe, fífi àgbèrè àti páńṣágà ṣe òwò ṣe. (Prostitution is bad.) Ìfi àgbèrè àti páńṣágà ṣe òwò ṣe kò dára.
|
20231101.yo_2438_47
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prostrate, adj. ní idọ̀ọ̀bálẹ̀ (He stumbled over Ade’s prostrate body.) Ó kọsẹ̀ lára ara Adé tí ó wà ní ìdọ̀ọ̀bálẹ̀.
|
20231101.yo_2438_48
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prostrate, v.t. dábùúlẹ̀, dọ̀ọ̀bálẹ̀, dojúbolẹ̀. (The slaves prostrated before their master.) Àwọn ẹrú náà dọ̀ọ̀bálè níwájú ọ̀gá wọn.
|
20231101.yo_2438_49
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prostration, n. ìdáàbúlẹ̀, láìní agbára, ìdọ̀ọ̀bálẹ̀ (They were carried off in a state of prostration.) Wọ́n gbé wọn lọ ní ipò ìdọ̀ọ̀bálẹ̀.
|
20231101.yo_2438_50
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
protect, v.t. dáàbò bò (Troops have been sent to protect them.) Wọ́n ti fi àwọn ológun ránṣẹ́ láti dáàbò bò wọ́n.
|
20231101.yo_2438_51
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
protege, n. ẹni tí ó wà ní abẹ́ ìtọ́jú ẹlòmíràn. (He is a protégé of the musician.) Abẹ́ ìtọ́jú olórin náà ni ó wà.
|
20231101.yo_2438_52
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
protract, adj. fà gùn, mú pẹ́ (It was caused by his protracted visit.) Àbẹ̀wò rẹ̀ tí ó fà gùn ni ó fà á.
|
20231101.yo_2438_53
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
provide, v.t. and i. pèsè sílẹ̀, pèsè. (We provided the hungry children with rice and vegetables.) A pèsè ráìsì àti ẹ̀fọ́ fún àwọn ọmọ tí ẹbi ń pa.
|
20231101.yo_2438_54
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
providence, n. ìpèsè sílẹ̀ Ọlọ́run fún àwọn èdá Rẹ̀ , Ọlọ́run (Bí Onípèsè) (He trusts in providence.) Ó ní ìgbékẹ̀le nínú ìpèsè sílẹ̀ Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀
|
20231101.yo_2438_55
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
provident, adj. ní ìpèsè tẹ́lẹ̀, aroti ọ̀la, mojú owó, ìpèsè sílẹ̀ de ọ̀la (Our school has a provident.) ìpèsè sílẹ̀ de ọ̀la.
|
20231101.yo_2438_56
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
province, n. ìgbèríkọ, ojú iṣẹ́, agbègbè. (Nigeria was divided intoprovinces.) Wọ́n pín Nàìjíríà sé agbègbè.
|
20231101.yo_2438_57
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
provincial, adj. ti agbègbè ìlú (The provincial government has many school.) Ìjọba ti agbègbè ilú náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ẹ̀kọ́
|
20231101.yo_2438_58
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
provision, n. oúnjẹ, èpèsè tẹ́lẹ̀, èsè. (I took with me a day’s provision.) Mo mú oúnjẹ fún ọjọ́ kan dání.
|
20231101.yo_2438_59
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
provocation, n. ìmúbínú, ìrusókè, ìtọ́, fórífọ́rí, ìrunú, ìfitínà. (She bursts into tears at the slightest provocation.) Lẹ́yìn ìfìtínà kékeré ẹkun ni ó máa ń bú sí.
|
20231101.yo_2438_60
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prowess, n. ìgbóyà, ìláyà, (He was praised for his sport prowess.) Wọ́n yìn ún fún ìgbóyà rẹ̀ nípa eré ìdárayá.
|
20231101.yo_2438_61
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prowl, v.t. and. i. rìn kiri wá ohun ọdẹ, rìn kiri láti wá ẹran fún pípa jẹ., (The lion prowled through the forst.) Kìnìrún náà ń rin kiri inú igbó láti wá ẹran fún pípa jẹ.
|
20231101.yo_2438_62
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
proximity, n. itòsí, etí (The proximity of the school to our house makers it very popular.) Itòsí ilé wa tí ilé-ẹ̀kọ́ náà wá jẹ́ kí ó lókìkí.
|
20231101.yo_2438_63
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
proxy, n. ìrọ́pò, ìdúró fún, ìgbọ̀wọ́, ìfènìyàn-ṣènìyàn. (It was a proxy vote.) Ìbò ìdúró fún mi ni.
|
20231101.yo_2438_64
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
prune, v.t. rẹ́ lọ́wọ́, rẹ́wọ́, ké kúrò, wọ́n kúrò, gbà lọ́wọ́. (prune out unnecessary details.) Ké àwịn àlàyé tí kò wúlò kúrò.
|
20231101.yo_2438_65
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
publication, n. ìkéde, ìtẹ̀wé sóde. ìtẹ̀wé jáde, ìtèjáde. (He talked about the publication of his first book.) Ó sọ̀rọ̀ nípa ìtẹ̀jáde ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́.
|
20231101.yo_2438_66
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
publish, v.t. sọ di mímọ̀, kédée, fi lọ̀, tẹ ìwé fún títà. (They published Yorùbá books.) Wọ́n tẹ àwọn ìwé Yorùbá fún títà.
|
20231101.yo_2438_67
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
pulpit, n. àga ìdúró wàásù. (The plan was condemned from the pulpit.) Wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ẹ̀rò náà láti orí àga ìdúró ìwàásù.
|
20231101.yo_2438_68
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
pump, v.t. fà sókè, fà sínú, fa afẹ́fẹ́ sí. (The engine was used for pumping water out of the well.) Wọ́n ń lo ẹ̀rọ náà láti fa omi sókè láti inú kànga.
|
20231101.yo_2438_69
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
punctilious, adj. Kíyè sí nǹken kínníkínní (He was a punctilious host.) Olùgbàlejò tí ó máa ń kíyè sí nǹken kínníkínní ni.
|
20231101.yo_2438_70
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
punish, v.t. je. Níyà, ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ (He was punished for coming to school late.) Wọ́n jẹ ẹ́ níyà fún pípẹ́ dé ilé-ẹ̀kọ́.
|
20231101.yo_2438_71
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
pupil, n. ọmọ ilé-ẹ̀kọ́, akẹ́kọ̀ọ́ (How many pupils does the school have?) Akẹ́kọ̀ọ́ mélòó ni ilé-ẹ̀kọ́ náà ní?
|
20231101.yo_2438_72
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
pupil-Teacher, n. tíṣà kékeré tí ó ń kọ́ iṣẹ́ lábẹ́ẹ tíṣà àbà. (He is a pupil-teacher.) Tíṣà kékeré tí ó ń kọ́ iṣẹ́ lábẹ́ẹ tíṣà àgbà ni.
|
20231101.yo_2438_73
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
purchase, v.t. rà (They purchased the land for N 100,000.) Wọ́n ra ilẹ̀ náà ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà.
|
20231101.yo_2438_74
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
purchase, n. ohun tí a rà. (He filled his car with his purchases.) Ó kó àwọn ohun tí ó rà kún inú káà rẹ̀
|
20231101.yo_2438_75
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
pure, adj. mọ́, dá ṣáká, funfun ní ìwà. (He bought a bottle of pure water.) Ó ra ìgò omit í ó mọ́ kan.
|
20231101.yo_2438_76
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
purification, n. ìwẹ̀nùmọ́ (He bought a water purification plant.) Ó ra ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ omi.
|
20231101.yo_2438_77
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
purify, v.t. wẹ̀ mọ́, sọ di mímọ́ (One tablet will purify the water in 10 minutes.) lògùn oníhóró ken yóò sọ omi yẹn di mímọ́ ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá.
|
20231101.yo_2438_78
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
purloin, v.t. jí jalè, (We purloined a couple of old computers from work.) A jí àwọn kọ̀ǹpútà mélòó kan tí o ti ogbó láti ibi iṣẹ́
|
20231101.yo_2438_79
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
purpose, n. ète, èrò, ohun tí a ń lépa. (Our campaign’s main purpose is to raise money.) Ète ìpolongo wa ni láti kó owó jọ
|
20231101.yo_2438_80
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
purposeless, adj. àṣedànù, láìní àǹfààní, láìní ète, láìní ìpinnu, aláìní àǹfààní. (It was a purposeless destruction.) Ìparun aláìní àǹfààní ni.
|
20231101.yo_2438_81
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC-Yor%C3%B9b%C3%A1%29%3A%20P
|
Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P
|
pursuit, n. ìlépa, ìtẹ̀lẹ́ (She traveled to ìbàdàn in pursuit of heppiness.) Ó rin ìrìnàjò lọ sí ìbàdàn fún ìlépa ìdùnnú.)
|
20231101.yo_2439_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%B9%A2%C3%A0ng%C3%B3
|
Ṣàngó
|
Òrìṣà Ṣàngó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn òrìṣà tí àwọn Yorùbá ń bọ. Ṣàngó jẹ́ òrìsà takuntakun kan láàárín àwon òrìsà tókù ní ilẹ̀ Yorùbá. Ó jẹ́ orisà tí ìran rẹ̀ kún fún ìbẹ̀rù, Ìrísí, ìṣe àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ pàápàá kún fún ìbẹ̀rù nígbàtí ó wà láyé nítorípé ènìyàn la gbọ́ pé Ṣàngó jẹ́ tẹ́lẹ̀ kí ó tó di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Ìtàn sọ wí pé ọmọ Ọ̀rányàn ni ṣàngó ń ṣe àti pé Ọya, Ọ̀ṣun àti Ọbà ni wọ́njẹ́ ìyàwó rẹ̀.
|
20231101.yo_2439_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%B9%A2%C3%A0ng%C3%B3
|
Ṣàngó
|
Ìhùwàsí búburú ati dídá wàhalá ati ìkọlura pẹ̀lú ìjayé fàmílétè-kí-n-tutọ́ pọ̀ lọ́wọ́ ṣàngó g̣ẹ́gẹ́ bí Ọba tó bẹ́ẹ̀ títí ó fi di ọ̀tẹ́yímiká, èyí jásí wí pé tọmọdé tàgbà dìtẹ̀ mọ́ ọ. Wọ́n fi ayé ni í lára. Ó sì fi ìlú Ọ̀yọ́ sílẹ̀ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ó pokùnso sí ìdí igi àyàn kan lẹ́bà ọ̀nà nítòsí Ọ̀yọ́ nígbàtí Ọya: Ìyàwó rẹ̀ kan tókù náà sì di odò.
|
20231101.yo_2439_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%B9%A2%C3%A0ng%C3%B3
|
Ṣàngó
|
Ọgbọ́n tí àwọn ènìyàn ṣàngó tókù dá láti fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà nípa títi iná bọlé wọn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sọ ṣàngó di òrìṣà tí wọ́n ń bọ títí dòní tí wọ́n sì ńfi ẹnu wọn túúbá wí pé ṣàngó kò so: Ọba koso.
|
20231101.yo_2439_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%B9%A2%C3%A0ng%C3%B3
|
Ṣàngó
|
Oríṣiríṣi orúkọ ni a mọ ṣàngó sí nínú èyí tí gbogbo wọn sì ní ìtumọ̀ tàbí ìdí kan pàtó ti a fi ńpè wọ́n bẹ́ẹ̀. Àwọn orúkọ bíi ìwọ̀nyìí:
|
20231101.yo_2439_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%B9%A2%C3%A0ng%C3%B3
|
Ṣàngó
|
Olójú Orógbó: nítorípé orógbó ni obì tirẹ̀, òun ni ó sì máa ń ṣàfẹ́ẹ́rí nígbà ayé rẹ̀. Orógbó náà sì ni a máa ń lo ní ojúbọ ṣàngó títí di òní.
|
20231101.yo_2439_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%B9%A2%C3%A0ng%C3%B3
|
Ṣàngó
|
Jàkúta: gẹ́gẹ́ bí òrìṣà tí ń fi òkúta jà (ẹdùn àrá). Irúfẹ́ òkúta kékẹrẹ́ kan tí ó máa sekúpa ènìyàn nípasẹ̀ ṣàngó
|
20231101.yo_2439_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%E1%B9%A2%C3%A0ng%C3%B3
|
Ṣàngó
|
Èbìtì-káwó-pònyìn-soro: Irúfẹ́ Òrìṣà tí ó jẹ́ wí pé ìṣọwọ́-sekúpa asebi rẹ̀ máa ńya ènìyàn lẹ́nu gidigidi.
|
20231101.yo_2458_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Kí ni Sińtáàsì? Síńtáàsì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀ka gírámà èdè tí ó ní í sè pèlú bi a se ń so òrò pọ̀ tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Nínú ìdánilékòó yìi, a ó máa m ẹ́nu ba ohun tí a ń pè ni òfin. Ìtumò òfin gégé bí a se lò ó ni àwon ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yii yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun tí elédè sọ jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón èyí kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn lè mu emu yó ti yóò máa so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti otí bá dá ní ojú rè, yóò sọ òrò ti ó mógbón lówó.
|
20231101.yo_2458_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Nínú ìdánilékòó yìí, a ó ménuba ohun tí a ó pè ní ofin. Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan.bí àpẹẹrẹ re, eni tí ó bá gbó Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà,
|
20231101.yo_2458_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nipé ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu.
|
20231101.yo_2458_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin tíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé àtéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé àtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé.
|
20231101.yo_2458_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Méjèèjì ni ó bá òfin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé àtéwógbà, èkejì kò jé àtéwógbà. Èyé kò ni nǹken kan án se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófinmu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú ìdánilékòó yìí.
|
20231101.yo_2458_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Ó ye kí á tún pe àkíyèsí wa sí tip é àbínibí ni èdè o. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó ọ. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àbínibí ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè, ó ti wà lára re. Kò sì si èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so.
|
20231101.yo_2458_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
(2) Òrò àti Àpólà: Òrò ti a bat ò pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b).
|
20231101.yo_2458_7
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn.
|
20231101.yo_2458_8
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
3. Gírámà ti a ó lò: Gírámà ìyidà onídàro ti Chomsky ni a ó mú lò nínú isé yìí. Ohun tí ó fà á ti a ó fi mú gíràmà yìí lò nip é ó gbìyànjú láti sàlàyé ìmò àbinibí elédè nípa èdè rè. Gírámà yìí sàlàyé gbólóhùn oónna, gbólóhùn ti ó jé àdàpè ara won abbl. Gírámà yìí yóò lo òfin ti ó níye láti sàlàyé gbólóhùn tí kò niye.
|
20231101.yo_2458_9
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5).
|
20231101.yo_2458_10
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí:
|
20231101.yo_2458_11
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS
|
20231101.yo_2458_12
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Ayọ̀ Bámgbóṣé (1990), fonọ́lọ́jí àti Gírámà Yorùbá. Ìbàdàn, Nigeria: University Press Limited. ISBN 978 249155 1. 239 pp.
|
20231101.yo_2458_13
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Láti ìgbà tí Ìgbìmọ̀ Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ Ẹ̀kọ́ (N.E.R.C.) ti gbé ìlànà ẹ̀kọ́ Yorúbá fún ìlò -ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdírì jáde ni ó ti di dandan láti wá ìwé tí yó ṣe àlàyé yékéyéké lórí àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ yọ nínú ìlànà ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Ìrírí wa nipé àti akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ni ó máa ń ni ìṣòro lórí iṣẹ́ tí ó bá èdè yàtọ̀ sí lítíréṣọ̀. lọ Ìdí nìyí tí a fi ṣe ìwé yìí lórí èdè, tí a sì lo ìmọ̀ ẹ̀dà-èdè láti fi ṣàlàyé àwọn orí-ọ̀rọ̀ fonọ́lọ́jì àti gíràmà.
|
20231101.yo_2458_14
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdírì àti ti olùkọ́ni, láìmẹ́nuba àwọn olùkọ́ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, ni wọ́n ti ń lo ìwé Èdè Ìperí Yorùbá tí N.E.R.C. tẹ̀ jáde ní ọdún 1984, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Bámgbóṣé sì ṣe olótùú rẹ̀. ìwé Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ kejì lórí lílo èdè-ìperí Yorùbá nítorí pé a ṣe àlàyé àwọn èdè-ìperí tí ó bá ẹ̀dá-èdè lọ dáadáa; a sì lo àpẹẹrẹ oríṣiríṣi láti fi ìtumọ̀ wọn hàn kedere. Nípa lílo ìwé yìí, èdè-ìperí á kúrò ní àkọ́sórí nìkan: kódà, á á di ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ mọ̀ dénú, tí wọ́n sì lè ṣàlàyé rẹ̀ fún ẹlòmíràn.
|
20231101.yo_2458_15
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi tí mo ṣe Olóòtú ìwé Èdè-Ìperí Yorùbá náà ni mo kọ ìwé tuntun yìí. Mo sì kọ ọ́ ní ọ̀nà tí yó rọrùn fún akẹ́kọ̀ọ́ láti kà nítorí pé nípa ìrírí púpọ̀ tí mo tin í nípa kíkọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀dá-èdè Yorùbá, mo mọ ọgbọ́n tí a lè fi ṣe àlàyé àwọn orí-ọ̀rọ̀ tí ó díjú lọ́nà tí yó lè fi tètè yé ni.
|
20231101.yo_2458_16
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
A dá ìwé yìí sí ọ̀nà mẹ́ta. Apá kìíni ni Fonọ́lọ́jì, Apá kejì ni Gírámà. Apá kẹta sì ni Ìdánwò Èwonìdáhùn. Nínú apé kìíní àti apá kejì, a pín àwọn orí-ọ̀rọ̀ sí abẹ́ orí kọ̀ọ̀kan nínú èyí tí a ṣe àlàyé àti ìtúpalẹ̀ orí-ọ̀rọ̀, tí a sì lo àpẹẹrẹ oríṣiríṣi láti fi ìdí ìtúpalẹ̀ náà gúnlẹ̀ dàadáa. Lẹ́yìn èyí ni a fi ìdánrawò kádìí orí kọ̀ọ̀kan. Orí mẹ́rìnlá ni ó wà ní abẹ́ Fonọ́lọ́jì, tí méjìdínlógún sì wà lábẹ̀ Gírámà. Ó ṣeé ṣe fún olùkọ́ láti fa ẹ̀kọ́ méjì mẹ́ta yọ láti ara ori kọ̀ọ̀kan. A sì tún lè lo orí kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àtúnyẹ̀wò iṣẹ́ tí a ti ṣe kọjá lorí orí-ọ̀rọ̀. Ní apá kẹta ìwé yìí, a fi ìdánwò èwonìdáhùn mẹ́rin nínú èyí tí ìbéèrè méẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wà nínú ìkọ̀ọ̀ken ṣe àpẹẹrẹ irú ibéèrè ti a lè ṣe fún gírámà àti fonọ́lọ́jì Yorùbá. Irú àpẹẹrẹ ìdánwò báyìí yóò wúlò fún àwọn tí ó ń sẹ́ẹ̀tì ìdánwò àti fún àwọn olùkọ́ pẹ̀lú. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pàápàá yó lè lo ìdánwò yìí gẹ́gẹ́ bí àfikún fún ìdánrawò tí ó wà lẹ́yìn orí kọ̀ọ̀kan.
|
20231101.yo_2458_17
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/G%C3%ADr%C3%A1m%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Gírámà Yorùbá
|
Mo ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ láti ran ara wọn lọ́wọ́ nínú ẹ̀kó Yorùbá. Ọ̀nà tí wọ́n sì lè fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí wọn lo ìwé tí yó mú kí ẹ̀kọ́ Yorùbá rọrùn fún wọn láti kọ́. Ìwé tí ó lè ṣe èyí ni ìwé tuntun yìí. Ìwé náà sì lè fún wọn ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún ẹ̀kọ́ Yorùbá ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga.
|
20231101.yo_2462_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/S%C3%A1d%C3%AD%C3%ACk%C3%AC
|
Sádíìkì
|
Omo ebi kan ni eleyii je fun ebi ede ile Aafirika kan ti oruko re n je Afro-Asiatic (Afuro-Esiatiiki). Awon ede ti o wa ninu Chadic yii to ogojo (160) awon ti o si n so awon ede wonyi to ogbon milionu. Awon ti o n so o bere lati iha ariwa Ghana (Gana) titi de aarin gbungbun Aafirika. Hausa ni gbajumo ju ninu awon ede ti o wa ni abe ipin Chadic. Oun nikan ni o wa ninu ipin yii ti o ni akosile ti o peye. Lara awon ede miiran ti o wa ni ipin yii a ti ri Anga, Kotoko ati Mubi.
|
20231101.yo_2463_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80k%C3%B3l%C3%AC
|
Àkólì
|
Acholi tabi Akoli jẹ́ èyà kan ní apá àríwá ilẹ̀ Uganda àti ní apá gúúsù ilẹ̀ Sudan. Èdè wọn ni Èdè Akoli.
|
20231101.yo_2497_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/El%C3%A9d%C3%B9m%C3%A0r%C3%A8
|
Elédùmàrè
|
Elédùmarè Yorùbá gbàgbọ́ wípé elédùmàrè ni ó dá ayé àti ọ̀run pẹ̀lú gbogbo ohun tí ń bẹ nínú wọn. Yorùbá sì gbàgbọ́ wí pé kò sí ohun tí elédùmarè kò lẹ se, òhun ni wọ́n fí ń ki elédùmarè wí pé
|
20231101.yo_2497_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/El%C3%A9d%C3%B9m%C3%A0r%C3%A8
|
Elédùmàrè
|
Bí a bá ti ojú inú wò ó á ri wí pé àwọn oríkì yìí fib í olódùmarè se jẹ́ hàn láwùjọ Yorùbá. Ohun tí a ń so ni wí pé ọ̀pọ̀ ìtàn iwásẹ̀ ló sọ wípé bi olódùmarè se dá ayé àti ọ̀run. Èrò Yorùbá ni pé kọ̀ síohun ti a lẹ̀ fi wé elédùmarè nitorí àwọn àwòmọ́ tàbí àbùdá rẹ̀ tó tayọ awari ẹ̀dá. Fún àpẹẹrẹ, ẹlédàá, àlẹ̀mí, oun ló ni ọsán àti òru, ọlọ́jọ́ òní, òní ọmọ ọlọ́rin ọ̀la ọmọ ọlọ́run ọ̀tunla ọmọ ọlọrin, ìrèmi ọmọ ọlọrin, òrún ni ọmọ ọlọ́rin.
|
20231101.yo_2497_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/El%C3%A9d%C3%B9m%C3%A0r%C3%A8
|
Elédùmàrè
|
Yorùbá máa ń sọ wí pé iṣẹ́ ọlọ́run tóbi tàbí àwámárídì ni iṣẹ́ olódùmarè. ọ̀rúnmìlà lọ́ fẹ̀yìntì, ó wo títítítí ó ní ẹ̀yin èrò òkun, ero ọ̀sà ǹ jẹ́ ẹ̀yin ò mọ̀ wí pé iṣẹ́ elédùmarè tòbí.
|
20231101.yo_2497_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/El%C3%A9d%C3%B9m%C3%A0r%C3%A8
|
Elédùmàrè
|
Olódùmarè gẹ́gẹ́ bí alágbaára láyé àti lọ́run a dùn ń se bí ohun tí elédùmarè lọ́wọ́ sí a sòro se bí ohun tí elédùmarè kò lọ́wọ́ sí, a lèwí lese, asèkanmákù, ohun tí Yorùbá rò nípa elédùmarè ni wí pé kò sí nǹkan tí kò le se àti wí pé ohunkíhun tí ó bá lọ́wọ́ sí ó di dandan kí ó jẹ́ àseyọrí àti àseyege. Ní ọ̀nà míràn Yorùbá tún gbàgbọ́ wí pé ọlọ́run nìkan ni ó gbọ́n, ìdí ni ìyí tí Yorùbá fi máa ń sọ ọmọ wọn ní Ọlọ́rungbọn elédùmarè rí óhun gbogbo, ó sì mọ ohun gbogbo arínúríde, olùmọ̀ràn ọkàn. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé ojú ọlọ́run ni sánmọ̀ Yorùbá sọ wí pé amùokùn sìkà bí ọba ayé kòrí o, Ọba ọ̀rùn ń wò ọ́, ki ni ẹ̀ ń se ní kọ̀kọ̀ tí ojú ọba ọ̀run kò tó. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé elédùmarè ni olùdájọ́ ìyẹ ni wí pé elédùmarè ni adájọ́ tó ga jù láyé àtọ̀run, òun ni ọba adákẹ́ dájọ́, àwọn òrìṣà ló, máa ń jẹ àwọn orúfin níyà ṣùgbọ́n ọlọrun ló ń dájọ́. Bí àpẹẹrẹ ní ìgbnà kan láyé ọjọ́un àwọn òrìṣà fẹ̀sùn kan ọ̀rúnmìlà níwájú elédùmarè, lẹ́yìn tí tọ̀tún tòsì wọn rojọ́ tán elédùmarè dá ọ̀runmìlà láre. Odù ifá kan ọ báyìí wí pé Ọ̀kánjúà kìí jẹ́ kí á mọ nǹkanán-pín, adíá rún odù mẹ́rìndínlógún níjọ́ tí wọ́n ń jìjà àgbà lọ ilé elédùmarè, nìgbà tí àwọn ọmọ irúnmọlẹ̀ mẹ́rìndínlógún ń jìjà tani ẹ̀gbọ́n tan i àbúrò, wọ́n kí ẹjọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ elédùmarè, níkẹyìn elédùmarè dájọ̀ wí pé èjìogbè ni àgbà fún àwọn Odù yókù. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé onídájọ́ ododo ni elédùmarè ìdí nì yí tí Yorùbá fi máa ń sọ wí pé ọlọ́run mún-un tàbí ó wa lábẹ́. Pàsán ẹlẹ́dùmarè
|
20231101.yo_2497_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/El%C3%A9d%C3%B9m%C3%A0r%C3%A8
|
Elédùmàrè
|
Ní ọ̀nà míràn Yorùbá gbàgbọ́ wípé ọta àìkú ni elédùmarẹ̀ Yorùbá máa ń sọ wípé rẹ̀rẹ̀kufẹ̀ a kì í gbọ́ ikú elédùmarè. Ẹsẹ ifá kan ìyẹn ni ogbè ìyẹ̀fún sọ fún wa wí pé: -
|
20231101.yo_2497_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/El%C3%A9d%C3%B9m%C3%A0r%C3%A8
|
Elédùmàrè
|
Ní àkótán Yorùbá gbàgbọ́ wí pé ọba tó mọ́ Ọba tí je ni èérí ni elédùmarè ń se. Òun ni àwọn Yorùbá ń pè ní alálàfunfun ọ̀kàn àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wí pé bí àwọn ángẹ́lù ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ọ̀rùn bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn òrìṣà jẹ́ orùrànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ayé. Awọn òrìṣà wọ̀nyí sì ni wọ́n jẹ́ alágbàwí fún àwọn ènìyàn lọ́dẹ̀ elédùmarè.
|
20231101.yo_2506_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%C3%B9j%E1%BB%8D
|
Àwùjọ
|
Ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Kò sí ẹ̀dá alààyè tó dá wà láì ní Olùbátan tàbí alájogbé. Orísirísi ènìyàn ló parapọ̀ di àwùjọ-bàbá, ìyá, ará, ọ̀rẹ́, olùbátan ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ìyá ṣe ń bí ọmọ, tí bàbá ń wo ọmọ àti bí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ ṣe ń báni gbé, bẹ́ẹ̀ ni ìbá gbépọ̀ ẹ̀dá n gbòòrò si. Gbogbo àwọn wọ̀nyí náà ló parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá. Àti ẹ̀ni tí a bá tan, àti ẹni tí a kò tan mọ́, gbogbo wa náà la parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá.
|
20231101.yo_2506_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%C3%B9j%E1%BB%8D
|
Àwùjọ
|
Ní ilẹ̀ Yorùbá ati níbi gbogbo ti ẹ̀dá ènìyàn ń gbé, ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ṣe pàtàkì púpọ̀. Bí ẹnìkan bá ní òun ò bá ẹnikẹ́ni gbé, tí kò bá gbé nígbó, yóó wábi gbàlọ. Ṣùgbọ́n, àwa ènìyàn lápapọ̀ mọ ìwúlò ìbágbépọ̀. Orísirísi àǹfàní ni ó wà nínú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá.
|
20231101.yo_2506_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%C3%B9j%E1%BB%8D
|
Àwùjọ
|
Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn bá n gbé papọ̀, ó rọrùn lati jọ parapọ̀ dojú kọ ogun tàbí ọ̀tẹ́ tí ó bá fẹ́ wá láti ibikíbi. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àjòjì ọwọ́ kan ò gbẹ́rù dórí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ló ṣe rí fún àwùjọ-ẹ̀dá. Gbígbé papọ̀ yìí máa ń mú ìdádúró láì sí ìbẹ̀rù dání nítorí bí òṣùṣù ọwọ̀ ṣe le láti ṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwùjọ tó fohùn ṣọ̀kan. Èyí jẹ́ oun pàtàkì lára ànfàní tó wa nínú ìṣọ̀kan nínú àwùjọ-ẹ̀dá. Nídà kejì, bí ọ̀rọ̀ àwùjọ-ẹ̀dá ba jẹ́ kónkó-jabele, ẹ̀tẹ́ àti wàhálà ni ojú ọmọ ènìyàn yóó máa rí. Nítorí náà, ó dára kí ìṣọ̀kan jọba ni àwujọ-ẹ̀dá.
|
20231101.yo_2506_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%C3%B9j%E1%BB%8D
|
Àwùjọ
|
Ìdàgbàsókè tí ó máa ń wà nínú àwùjọ kò sẹ̀yìn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bí àti ránmú un gángan ò ti sẹ̀yìn èékánná. Ó yẹ kí á mò pé nítorí ìdàgbàsókè ni ẹ̀dá fi ń gbé papọ̀. Bí igi kan ò ṣe lè dágbó ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnìkan ò lè dálùúgbé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló máa ń dá Ọgbọ́n jọ fún ìdàgbàsókè ìlú. Bí Ọgbọ́n kan kò bá parí iṣẹ́, Ọgbọ́n mìíràn yóó gbè é lẹ́yìn. Níbi tí orísirísi ọgbọ́n bá ti parapọ̀, ìlọsíwájú kò ní jìnnà si irú agbègbè bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ànfàní tó wà ní àwùjọ-ẹ̀dá tí kò sì ṣe é fi sílẹ̀ láì mẹ́nu bà.
|
20231101.yo_2506_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%C3%B9j%E1%BB%8D
|
Àwùjọ
|
Nínú ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá, a tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìsòro tó ń kojú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá. Kò ṣe é ṣe kó máa sì wàhálà láwùjọ ènìyàn. A kò lè ronú lọ́nà kan ṣoṣo, nítorí náà, ìjà àti asọ̀ máa ń jẹ́ àwọn nǹkan tí a kò lè ṣàì má rì í níbi ti àwọn ènìyàn bá ń gbé. Wàhálà máa ń fa ọ̀tẹ̀, ọ̀tẹ̀ ń di ogun, ogun sì ń fa ikú àti fífi dúkàá sòfò. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ara àwọn ìṣòro tó n kojú àwùjọ-ẹ̀dá. Kò sí bí ìlú tàbí orílè-èdè kan kò se ní ní ọ̀kan nínú àwọn àwọn ìṣòro wọ̀nyí.
|
20231101.yo_2506_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%C3%B9j%E1%BB%8D
|
Àwùjọ
|
Ṣùgbọ́n, a gbódò mọ̀ wí pé awọn ànfàní àti awọn ìṣòro wọ̀nyí ti wà láti ìgbà pípé wá. Tí a bá wo àwọn ìtàn àtijọ gbogbo, a ó ri pé gbogbo àwọn nǹkan wònyí kò jẹ́ tuntun. Ọgbọ́n ọmọ ènìyàn ni ó fi ṣe ọkọ̀ orí-ìlẹ, ti orí-omi àti ti òfúrifú fún ìrìnkèrindò tí ó rọrùn. Àwùjọ-ẹ̀dá ti ṣe àwọn nǹkan dáradára báyìí náà ni wọ́n ń ṣe àwọn ohun tí ó lè pa ènìyàn lára. Fún àpẹẹrẹ, ìbọn àti àdó-olóró. Àwọn ohun ìjà wọ̀nyí ni wọ́n lò ní ogun àgbájé kìnní tí o wáyé ní Odun 1914 sí 1918 àti ti èkejì ní odún 1939 sí 1945. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ti wà tí ó sì tún wà síbè di òní.
|
20231101.yo_2506_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%C3%B9j%E1%BB%8D
|
Àwùjọ
|
Lákòótán, ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ tó lárinrin. Ohun kan tí a gbọ́dọ̀ mọ̀ nip é, kò ṣe é ṣe kí ẹ̀dá máa gbe ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Ìdí ni pé gbígbé papọ̀ pẹ̀lú ìsọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ló lè mú ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbà-sókè wá
|
20231101.yo_2533_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92gb%C3%B3m%E1%BB%8D%CC%80%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%81
|
Ògbómọ̀ṣọ́
|
Ogunlọlá jẹ ọdẹ, ògbótari, tí ó mọ̀n nípa ọdẹẹ síse ó féràn láti máa lọ sísẹ́ Ọdẹ nínú igbó ti a máa ni ìlú Ògbómòsọ́ tí à pè ní igbó ìgbàlè, ṣùgbọ́n ọkùnrin yii ti o jẹ ogunlọlá ṣe Baale àdúgbọ̀ tí ó Ogunlọlá gbé nígbà nàá. Baale o ríi wí pe Ogunlọlá gbé àdùtú àrokò náà lọ sí ọ̀dọ̀ Aláàfin. Aláàfín àti àwọn emẹ̀wà rẹ̀ yìí àrokọ̀ náà títí, wọ́n sì mọ̀ ọ́ tì. Pẹ̀lú líhàhílo, ìfòyà, aibalẹ ọkàn nípa OGUN Ọ̀GBÒRỌ̀ tí ń bẹ ló de Ọ̀yọ́, kò mú wọn ṣe ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ Ogunlọlá, wọ́n si fi í pamọ́ si ilé olósì títí wọn yóò fi ri ìtumọ̀ sí àrokò náà.
|
20231101.yo_2533_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92gb%C3%B3m%E1%BB%8D%CC%80%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%81
|
Ògbómọ̀ṣọ́
|
Ní ọjọ́ kan, Ogunlọlá ń sẹ ọdẹ nínú igbó ìgbàlè-àdúgbò i bi tí Gbọ̀ngàn ìlú ògbímòṣọ́ wà lonìí. Igbó yìí, igbó kìjikìji ni, ó ṣòro dojúkọ̀ kí jẹ́ pé ọdẹ ní ènìyàn, kó dà títí di ìgbà tí ojú tí là sí i bí ọdun 1935, ẹ̀rù jẹ́jẹ́ l’o tún jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú láti wọ̀ ọ́ ńitorí wí pé onírúurú àwọn ẹnranko búburú l’ó kún ibẹ̀. Àní ni ọdún 1959, ikooko já wo Ile Ògúnjẹ́ ńlé ni ìsàlè-Àfọ́n gẹ́gẹ́ bi ìròyìn, ikooko já náà jáde láti inú igbó ìgbàlè yìí ni àwọn ALÁGỌ̀ (àwọn Baálè tí wọ́n ti kú jẹ rí ní ògbómọ̀ṣọ́, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹsin-ìbílẹ̀) máà ń gbé jáde nígbà tí ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń ṣe ọdun Ọ̀LẸ̀LẸ̀. Láti pa á mọ́ gẹ́gẹ́ bi òpẹ títí di òní, nínú Gbọ̀ngàn Ògbómòṣọ́ ní àwọn Alágà náà ń ti jáde níwọ̀n ìfbà tí ó jẹ́ wí pé ara àwọn igbí ìgbàlè náà ní ó jẹ́. Ogunlọlá kó tí í tin jìnnà láti ìdí igi Àjàbon (ó wá di òní) tí ó fi ń ri èéfín. Èéfín yìí jẹ́ ohun tí ó yá à lẹ́nu nítorí kò mọ̀ wí pé iru nǹkan bẹ́ẹ̀ wà ní itòsí rẹ̀ Ogunlọlá pinnu láti tọ paṣẹ̀ èéfín náà ká má bá òpò lọ sílé Olórò, àwọn ògbójú ọdẹ náà rí ara wọn, inú swọn sí dùn wí pé àwọn jẹ pàdé. Orukọ àwọn tí wọ́n jẹ pàdé awa wọn náà ní:- AALE, OHUNSILE àti ORISATOLU. Lẹ̀yìn tí wọn ri ara wọn tan, ti wọn si mọ ara wọn; wọ́n gbìdánwò láti mọ ibi tí Olukaluku dó sí ibùdó wọn.
|
20231101.yo_2533_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92gb%C3%B3m%E1%BB%8D%CC%80%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%81
|
Ògbómọ̀ṣọ́
|
Nínú gbogbo wọn Ogunlọla níkan l’ó ni ìyàwó. Wọ́n sì fi ìbùdó Ogunlọlá ṣe ibi inaju lẹ́yìn iṣe oojọ wọn. Lọ́rùn-ún-gbẹkun ń ṣe ẹ̀wà tà, ó sí tún ń pọn otí ká pẹ̀lú; ìdí niyìí tí o fi rọrun fún àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ Lọ́rùn-un-gbẹ́kún láti máa taku-rọ̀sọ àti lati máa bá ara wọn dámọ̀ràn. Bayíí, wọ́n fí Ogunlọla pamọ́ sí ọ̀dọ̀ Olósì. Ìtàn fi yé wa wí pé Ọba Aláàfin tí ó wà nígbà náà ni AJÁGBÓ. Rògbò dèyàn àti aápọn sì wà ní àkókò ti Ogunlọlá gbé aro ko náà lọ si Ààfin Ọba; Ogun ni, Ogun t’ó sì gbóná girigiri ni pẹ̀lú-Orúkọ Ogun ni, Ogun náà ni OGUN Ọ̀GBỌ̀RỌ̀. Nínú ilé tí a fi Ogunlọla. sí, ni ó ti ráńṣe sí Aláàfìn wí pé bí wọ́n bá le gba òun láàyè òun ní ìfẹ́ sí bí bá wọn ní pa nínú Ogun ọ̀gbọ̀rọ̀ náà. Ẹni tí a fi tì, pàrọwà fún Ogunlọla nítorí wí pé Ogun náà le púpọ̀ àti wí pé kò sí bí ènìyàn tilẹ́ lé è ní agbára tó tí ó le ṣégun ọlọ̀fè náà. Wọn kò lée ṣe àpèjúwe ọ̀lọ̀té náà; wọ́n sá mọ̀ wí pé ó ń pa kúkúrú, ó sí ń pa gigun ni.
|
20231101.yo_2533_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92gb%C3%B3m%E1%BB%8D%CC%80%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%81
|
Ògbómọ̀ṣọ́
|
Aláàfin fún Ogunlọlá láṣẹ láti rán rán òun lọ́wọ́ nípa Ogun ọ̀gbọ̀rọ̀ náà. Aláàfín ka Ogunlọlá sí ẹni tí a fẹ́ sun jẹ, tí ó fi epọ ra ara tí o tún sún si ìdìí ààro, ó mú isẹ́ẹ sísun Yá ni. Alaafin súre fún Ogunlọlá. iré yìí ni Ogunlọla bà lé. Ogunlọlá dójú Ogun, ó pitu meje tí ọdẹ pa nínú igbo ó sẹ gudugudu meje Yààyà mẹ́fà. Àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ fi ibi ọta gunwa sí lórí igin han atamatane Ogunlọlá, Ogunlọá sì “gán-án-ní” rẹ̀. Nibi ti ọta Alaafin yìí tí ń gbiyanju láti yọ ojú síta láti ṣe àwọn jagun-jagun lọ́sé sé ọfà tó sì loro ni ọlọ̀tẹ̀ yìí ń ló; mó kẹ̀jẹ̀ ní Olọ̀tẹ̀ kò tí ì mórí bọ́ sínú tí ọrun fi yo lọ́wọ́ Ogunlọlá; lọrun ló sí ti bá Olọ̀tẹ̀; gbirigidi la gbọ to Ọlọ̀tè ré lulẹ lógìdo. Inú gbogbo àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ sì dún wọ́n yọ sẹ̀sẹ̀ bí ọmọdé tí seé yọ̀ mọ̀ ẹyẹ. Ogunlọlá o gbé e, o di ọ̀dọ̀ Aláàfin; nígbà yìí ni Aláàfin to mo wí pé Ẹlẹ́mọ̀sọ̀ ni ń ṣe alèṣà lẹ́yìn àwọn ènìyàn òun.
|
20231101.yo_2533_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92gb%C3%B3m%E1%BB%8D%CC%80%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%81
|
Ògbómọ̀ṣọ́
|
Bayìí ni Ogunlọlá ṣe àseyorí ohun ti ó ti èrù jẹ̀jẹ̀ sí ọkan àyà àwọn ara ilu ọ̀yọ́. Aláàfin gbé Oṣiba fún Ogunlọlá fún iṣé takun-takun tí ó ṣe, o si rọ̀ ó kìí ó dúró nítòsi òun; ṣùgbọ́n Ogunlọlá bẹ̀bẹ̀ kí òun pasà sí ibùdó òun kí ó ó máa rańsẹ sí òun. Báyìí Aláàfin tú Ogunlọlá sílẹ̀ láàfín nínú ìgbèkùn tí a fii sí kò ní jẹ́ àwáwí rárá láti sọ wí pé nínú ìlàkàkà àti láálàà tí Ogunlọlá ṣe ri ẹ̀yín Ẹlẹ́mọsọ ni kò jọ́ sí pàbó tí ó sí mú orukọ ÒGBÓMỌ̀SỌ́ jade. Erédì rẹ nìyìí Gbara tí a tú Ogunlọla sílẹ̀ tán pẹ̀lu asẹ Alaafin tí ó sì padà si ibùdó rẹ̀ nì ìdí igi Àjàgbọn ni bí èrò bá ń lọ́ tí wọn ń bọ́, wọn yóò máa se àpèjuwe ibudo Ogunlọlá gẹ́gẹ́ bíí Bùdó ò-gbé-orí-Ẹlẹmọsọ; nígbà tí ó tún ṣe ó di Ògbórí-Ẹlẹmọ̀ṣọ́ kó tó wà di Ògbẹ́lẹ́mọ̀sọ́; ṣùgbọ́n lónìí pẹ̀lú Ọ̀làjú ó di ÒGBÓMỌ̀SÓ
|
20231101.yo_2533_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92gb%C3%B3m%E1%BB%8D%CC%80%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%81
|
Ògbómọ̀ṣọ́
|
Baálẹ̀ ni Olórí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́. Nínú ìlànà ètò ìjọba, agbára rẹ̀ kò jut i ìgbìmọ̀ àwọn ìjòyè ìlú rẹ̀ lọ. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti ṣe àlàyé wipe irú ètò báyìí wà láti rí pé Baálẹ̀ tàbí Ọba kò tàpá sí àwọn ìgbìmọ̀ ìjòyè kí gbogbo nǹkan lè máa lọ déédéé ni ìlú. Irú ètò yìí yàtọ púpọ̀ sí ìlànà ètò Ìjọba àwọn ìlú aláwọ̀-funfun ninú eyi ti àṣẹ láti ṣe òfin wà lọ́wọ́ ilé aṣòfin, tí ètò ìdájọ́ wà lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ ìjọba. Ẹkìínní kò gbọ́dọ yọ ẹnu sí iṣẹ́ èkejì, oníkálukú ló ni àyè tirẹ̀. Ní ti ètò ìjọba Yorùbá, Ọba atì àwọn ìjòyè ńfi àga gbá’ga ni nínú èyí tí ó jọ pé ìjà le ṣẹlẹ̀ láàrin wọn bi ọ̀kan bá tayọ díẹ̀ sí èyí. Ohun tí ó mu un yàtọ̀ ni wípé Ṣọ̀ún, baba ńlá ìdílé àwọn Baálẹ̀, dé sí ibi tí ó di Ògbómọ̀ṣọ́ lónìí lẹ́hìn tí àwọn mẹ́ta ti ṣaájú rẹ̀ dé ibẹ̀. Nipa akíkanjúu rẹ̀ ló fi gba ipò aṣíwájú lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ yókù. Akẹ́hìndé sì di ẹ̀gbọ́n lati igba yi lọ títí di òní, àwọn baálẹ ti a ti jẹ ní Ògbómọ̀ṣọ́ kò jẹ́ kí àwọn ìdílé ẹni mẹ́ta ti o ṣaáju Ṣọ̀ún dé ìlú jẹ oyè pàtàkì kan. Ẹ̀rù mbà wọ́n pé ìkan nínú àwọn ọmọ ẹni mẹ́ta yìí lè sọ wípé òun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe Olórí ìlú. Nitorina ni o fi jẹ́ pé àwọn ìjòyè ìlú tí o mbá Baálẹ̀ dámọ̀ràn láàrin àwọn ẹni tí ó dé sí ìlú lẹ́hìn Ṣọhún ní a ti yan wọ́n. Síbẹ̀ náà, Baálẹ̀ kan kò gbọdọ̀ tàpá si ìmọ̀ràn àwọn ìjòyè ìlú, pàápàá nínú àwọn ọrọ tí ó jẹ mọ iṣẹ̀dálẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì jù ní nǹkan ọgọ́rùn ọdún sí àkókò ti a ńsọ nípa rẹ̀ yìí. Àwọn ópìtàn ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ sọ pé gbogbo àwọn Baálẹ̀ ti wọn tàpá si ìmọ̀ràn ìjòyè ìlú ni Aláàfin rọ̀ lóyè. Abẹ́ Aláàfin ni Ògbómọ̀ṣọ́ wà ní ìgbà náà....
|
20231101.yo_2540_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92mu%C3%B2-%C3%92k%C3%A8-%C3%88k%C3%ACt%C3%AC
|
Òmuò-Òkè-Èkìtì
|
Ìlú Òmùò-Òkè Èkìtì jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó wà ní apá Ìlà oòrùn Èkìtì ni Òmùò òkè wà. Ìjọba ìbílẹ̀ ìlà Oòrùn ni ìpínlẹ̀ Èkìtì ni Òmùò-òkè tẹ̀dó sí. Òmùò-òkè tó kìlómítà méjìlélọ́gọ́ọ̀rin sí Adó-Èkìtì tí ó jé olú-ìlú ìpínlẹ̀ Èkìtì. Òmùò-òkè ni ìpínlẹ̀ Èkìtì parí sí kí a tó máa- lọ sí ìpìnlẹ̀ Kogi. Ìdí nìyí tí ó fi bá àwọn ìlú bí i, Yàgbà, Ìjùmú, Ìyàmoyè pààlà. Bákan náà ni ó tún bá Erítí Àkókó pààlà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìwádìí fihàn wí pé àwọn ìlú bí Ejurín, Ìlíṣà, Ìṣàyà, Ìgbèṣí, Àhàn, Ìlúdọ̀fin, Orújú, Ìwòrò, Ìráfún ni ó parapọ̀ di Òmùò òkè, Ọláitan àti Ọládiípò (2002:3) Iṣẹ́ òòjọ́ wọn ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò ṣíṣe. Ìdí ti wọn fi ń ṣe iṣẹ́ òwò ni wí pé, Òmùò òkè ni wọn ti máa ń kò ẹrù lọ sí òkè ọya. Ẹ̀ka èdè Òmùò-òkè yàtọ̀ sí Òmùò kọta Òmùò Ọbádóore. Òmùò Èkìtì jẹ́ àpapọ̀ ìlú mẹ́ta.
|
20231101.yo_2540_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92mu%C3%B2-%C3%92k%C3%A8-%C3%88k%C3%ACt%C3%AC
|
Òmuò-Òkè-Èkìtì
|
Èdè Òmùò-òkè farapẹ́ èdè Kàbbà, Ìgbàgún àti Yàgbàgún ni ìpinlẹ̀ Kogi. O ṣe é ṣe kí èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí Òmùò-òkè ló bá ìpínlẹ̀ Kogí pààlà. Bákan náà ni àwọn ènìyàn Òmùò-òkè máa ń sọ olórí ẹ̀ka èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì ni pàápàá àwọn tó mọ̀ọ̀kọ̀-mọ̀ọ́kà.
|
20231101.yo_2540_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92mu%C3%B2-%C3%92k%C3%A8-%C3%88k%C3%ACt%C3%AC
|
Òmuò-Òkè-Èkìtì
|
Ìtàn àgbọ́sọ ni ó rọ̀ mọ́ ìtàn ìsẹ̀dálẹ̀ ìlú Òmùò-òkè gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ni àwọn ilẹ̀ Yorùbá káàkiri. Ilé-Ifẹ̀ ni orírun gbogbo ilẹ̀ Yorùbá bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí ní Òmùò-òkè.
|
20231101.yo_2540_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92mu%C3%B2-%C3%92k%C3%A8-%C3%88k%C3%ACt%C3%AC
|
Òmuò-Òkè-Èkìtì
|
Olúmoyà pinnu láti sá kúró ni Ifẹ̀ nítorí kò faramọ́ ìyà ti wọn fi ń jẹ́ ẹ́ ni Ifẹ̀. Kí ó tó kúró ni Ilé-Ifẹ̀, ó lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Ifá. Àyẹ̀wò tí ó lọ ṣe yìí fihàn wí pé yóò rí àwọn àmì mẹ́ta pàtàkì kan ni ibi ti ó máa tẹ̀dó sí. Ibi tí ó ti rí àwọn àmì mẹ́ta yìí ni kí ó tẹ̀dó síbẹ̀.
|
20231101.yo_2540_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92mu%C3%B2-%C3%92k%C3%A8-%C3%88k%C3%ACt%C3%AC
|
Òmuò-Òkè-Èkìtì
|
Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rìn títítí ni ó wà dé ibi ti ifá ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un. Nígbà ti ó rí odò, ó kígba pé “Omi o” ibi ni orúkọ ìlú náà “Òmùwò” ti jáde. Òmùwò yìí ni ó di Òmùò-òkè títí di òní.
|
20231101.yo_2540_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92mu%C3%B2-%C3%92k%C3%A8-%C3%88k%C3%ACt%C3%AC
|
Òmuò-Òkè-Èkìtì
|
Olúmoyà rìn síwájú díẹ̀ kúró níbí odó yìí pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó dé ibìkan, ibi yìí ni òun àti àwọn tí ó ń tẹ̀le kọ́ ilé si. Ibi ti ó kọ́ ilé sí yìí ni ó pè ni “Ìlẹ́mọ” Orúkọ ilé yìí “Ìlẹ́mọ” wà ni Òmùò òkè títí di òní. Olúmoyà gbọ́rọ̀ sí ifá lẹ́nu, ó sọ odò náà ni “Odò-Igbó” àti ibi ti ó ti rí ẹsẹ̀ erin ni “Erínjó”. Akíkanjú àti alágbára ọkùnrin ni Olúmoyà ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ. ó kọ ilẹ òrìṣà kan tí ó pè orúkọ òrìṣà yìí ni “Ipara ẹ̀rà”. Ibi yìí ni wọn ti máa ń jáwé oyè lé ọba ìlú náà. Báyìí ni Olúmoyà di olómùwò àkọ́kọ́ ti ìlú Òmùwò tí a mọ̀ sí Òmùò-òkè ní òní.
|
20231101.yo_2540_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92mu%C3%B2-%C3%92k%C3%A8-%C3%88k%C3%ACt%C3%AC
|
Òmuò-Òkè-Èkìtì
|
Ìtàn yí ò kì ńṣe ìtàn ìlú Omuo òkè ní ẹkùn rẹ rẹ. Ìlú Omuo òkè ni o jẹ ìlú kan tí wọn lé kúrò ní orí ilé tiwọn tẹ̀dó sì ni agbegbe iyagba ni Ìpínlẹ̀ Kogi. Lílé tí wọn le wọn yí ni ó ṣokùnfà bí wọn ṣe wá si'lu Omuo Ekiti nígbà náà. Èyí lomu ki wọn tán ọba tí ó wà lórí ìtẹ́ nígbà náà àti àwọn ìjòyè Omuo Ekiti. Bayi ni àwọn ìgbìmò wọ̀nyí fún àwọn ará ìyá yí ni ilẹ̀ tí o kọ́ gun sí ìlú ilamoye ni ìpínlè Kogi (ibiyi ni Omuo npeni igun {Edge}). Olomuo igbana ni o sọ fún wọn pé Omuo Oke níwọ̀n ó máa jẹ. SÍHÀBÀ ni orúkọ oyè tí Olomuo ìgbàanì fún ẹni tí yio dúró gẹ́gẹ́ bíi olórí fún wọn. Àdúgbò (Quarters) ni Omuo Oke je n'ilu Omuo.
|
20231101.yo_2540_7
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92mu%C3%B2-%C3%92k%C3%A8-%C3%88k%C3%ACt%C3%AC
|
Òmuò-Òkè-Èkìtì
|
Ilisa, Iworo, Ijero, Ahan, Edugbe, Ekurugbe, Omodowa, Ehuta, Ìloro, Oruju, Oya, Kota, Oda odò, Araromi, Ahan Ayegunle, Òmùò-òkè.
|
20231101.yo_2542_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Èdè Yorùbá
|
Èdè Yorùbá Ni èdè tí ó ṣàkójọpọ̀ gbogbo ọmọ káàárọ̀-oò-jíire bí, ní apá Ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní Ìwọ̀-Oòrùn aláwọ̀-dúdú fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ bi èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn olùsọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà ni Ìpínlẹ̀ Ẹdó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ìpínlẹ̀ Èkó, àti Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ẹ̀wẹ̀ a tún rí àwọn orílẹ̀-èdè míràn bí Tógò apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, Ghana, Sierra Leone,United Kingdom àti Trinidad, gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ wọ̀nyí, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibẹ.
|
20231101.yo_2542_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Èdè Yorùbá
|
Èdè Yorùbá jẹ́ èdè kan ti ó gbalẹ̀ tí ó sì wuyì káàkiri àgbáyé. Ìtàn sọ fún wa pé ìbátan Kwa ní èdè Yorùbá jé, kwa jẹ́ ẹ̀yà kan ní apá Niger-Congo. A lè sọ pé àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Yorùbá yàtọ̀ sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lé ní Ọgbọ̀n mílíọ̀nùn tàbì jù bẹ́ẹ̀ lọ.
|
20231101.yo_2542_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
|
Èdè Yorùbá
|
Èdè Yorùbá gbajú-gbájà ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti káàkiri àgbánlá ayé lápapọ̀. Àwọn nǹkan tí ó ń gbé èdè Yorùbá níyì tí ó fi di àrí má leè lọ àti àwòpadà sẹ́yìn nìwọ̀yín:
|
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.