_id
stringlengths
17
21
url
stringlengths
32
377
title
stringlengths
2
120
text
stringlengths
100
2.76k
20231101.yo_2542_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
Òwe ni ọ̀kan lára àwọn ọnà-èdè tí àwọn Yorùbá mán ń gbà láti kó ẹwà bá ohùn ènu wọn. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni a le gbà pa òwe:
20231101.yo_2542_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
(a) A le pa òwe gẹ́gẹ́ bí àwọn elédè ti ń pa á tàbí bí gbogbo ènìyàn ti ń pá gan-an. Bí àpẹẹrẹ: Àíyá bẹ́ sílẹ̀ ó bé áré, (igi ọ̀ún ni kò ga).
20231101.yo_2542_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
Lára àwọn èròngbà kan gbòógì tí ìlò èdè Yorùbá yíì ni pé mo fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ èdè Yorùbá lo dáradára nítorí náà a wo ìjúba ni awùjọ Yorùbá, a wo ààtò, Ìtúmọ̀, ìlò, àti àgbéyẹ̀wò àwọn òwe, àkànlò èdè àti ọ̀rọ̀ àmúlò mííràn. A wo èdè àmúlò nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ àti igba ti a ba kọ èdè Yorùbá silẹ. A wo ẹ̀bùn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. A sí wo ìlànà ati òté tó de sísọ̀rọ̀ ni àwùjọ Yorùbá. A wo ìwúrẹ láwùjọ Yorùbá. A wo aáyan àròkọ kikọ. Lábẹ́ àròkọ, a wo arokọ wọ̀nyí: alapejuwe, ajemọroyin, alalaye, alariiyan, ìsòròǹgbèsì, onisiipaya, ajẹmọ́-ìsonísókí-ìwé ati arokọ onileta. A wo bi a ṣe n se agbekale isẹ to da le girama, iwe atumọ, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ, àbọ̀ ìpàdé, ìjábọ̀ ìwádìí, ìwé ìkéde pélébé àti eyí ti a fi n se ìpolongo ti a máa ń tẹ̀ mọ́ ara ògiri. Èdè Yorùbá ni ibamu pẹlu asa obínibí Yorùbá. Ó yẹ kí a mọ ọ̀rọ̀ í dá sí. Ó yẹ ki a mọ ọ̀rọ̀ sọ, ki á si mọ ọ̀rọ̀ ọ́ kọ sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà ti a bá ka ìwé kékeré yìí.
20231101.yo_2542_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
Kí àwọn òyìnbó tó gòkè odò dé, kò sí ètò kíkọ ati kíka èdè Yorùbá. Gbogbo ọ̀rọ̀ àbáláyé tí ó ti di àko sílẹ̀ lóde òní,nínú ọpọlọ́ àwọn baba ńlá wa ni wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Irú àwọn ọ̀rọ̀ àbáláyé báyìí a máa súyọ nínú orin, ewì àti ìtàn àwọn baba wa. Nígbà tí a kọ́ ń pe gbogbo àwọn ẹ̀yà tí èdè wọ́n papọ̀ yìí ní Yorùbá tàbí Yóòbá, wọn kò fi tara tara fẹ́ èyí nítorí pé àwọn ẹ̀yà Yorùbá ìyókù gbà pé àwọn Ọ̀yọ́ nìkan ni Yorùbá. Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run aláwọ̀ funfun tó wá wàásù nípa kírísítì ṣe àkiyèṣí pé èdè wọ́n bá ara wọn mu ni wọ́n bá pè wọ́n ní Yorúbà tàbí Yóòba. Àwọn Yorùbá ti a ko l’éní lo si ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí a sì wá dá padà sí sàró lẹ́hìn tí òwò ẹrú tí tán ni àwọn òyìnbó Ìjọ C.M.S. kọ́kọ́ sọ di onígbàgbọ́.
20231101.yo_2542_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
Àbùdá èdè Yorùbá ni ó máa jẹ́ kí á mọ ohun tí èdè jẹ́ gan-an. Orísirísi ni àwọn àbùdá tí èdè Yorùbá ní. Èdè Yorùbá kógo àbùdá wọ̀nyí já.
20231101.yo_2542_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
(1) Ohun tí a bá pè ní mi gba to aobdubdi lnfjbfi gibh knjèdè gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí a fí ìró èdè gbé jáde. Ìró yìí ni a le pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa. A ó ṣe àkíyèsí pé èyí yàtọ̀ sí pípòòyì, ijó ọlọ́bọ̀ùnbọ̀un, dídún tàbí fífò tata tàbí jíjuwó alákàn sí ara wọn.
20231101.yo_2542_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
(2) Èdè nílò kíkọ́ ọ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó le sọ ọ́. Ó ti di bárakú tàbí àṣà fún wa pé a gbọ́dọ̀ kọ́ ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ni èdè. Àkiyèsí àti ìwádìí yìí ni àwọn eléde gẹ̀ẹ́sì ń gọ́ka sí nígbà tí àwọ́n ba sọ pé “Language is Culturally transmitted”. Ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣè bí tí a kò kọ́ ní èdè, àti àwùjọ jẹ́ kòríkòsùn.
20231101.yo_2542_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
(3) Ìhun ni èdè ènìyàn gùn lé tàbí dálé. Bí a ṣe hun ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú gbólóhùn ṣe pàtàkì kíkà iye ìró èdè nínú gbólóhùn kò fi ibi kankan ní ìtúmọ̀.
20231101.yo_2542_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
Ìyípadà orírsirísi ló le wáyé sí gbólóhùn wọ̀nyí tí yóò sì da ètò wọn ní, síbẹ̀síbẹ̀, yóò ní ìtumọ̀. Irú àbùdá yìí ni onímọ̀ ẹ̀dá-èdè ń pè ní “Structure dependence”.
20231101.yo_2542_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
(4) Gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí a ń pè ní (Fóníìmù {phonemes}). Foniimu yìí sún mọ́ ti àwọn ẹranko ṣùgbọ́n ó sì tún rọ̀ jut i ẹranko lọ. Ó yàtọ̀ láti èdè kan sì òmíràn. Bí a bá mú fóníìmù yìí lọ́kọ̀ọ̀kan. kì í dá ìtumọ̀ ní kó wúlò ìgbà tí a bá kàn án pọ̀ mọ́ fóníìmù mìíràn gan-an ló máa ṣìṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ:- ìró èdè /a/ /b/ /d/ /e/ /ẹ/ kò dá ìtumọ̀ ní, àfi tí abá kàn wọ́n papọ̀ lọ́nà orísirísi. A lè se àkànpọ̀ kí á ri ọ̀rọ̀ bí : abẹ, baba, adé, alẹ́ abbl. Irúfẹ́ àkiyèsí àti ìwádìí yí ni àwọn onímọ̀ ẹ̀dà-èdè ń pe gẹ̀ẹ́sì rè ní “duality” tàbí “double articulation” ìwádìí fihàn pé àwọn ẹyẹ àti ẹranko tí wọ́n ní ìró èdè kò pò, iye èdè tí òkọ̀ọ̀kan ní kò pọ̀ pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ adìyẹ ní ìró èdè bí ogún, ti mààlúù jẹ́ mẹ́wàá ṣùgbọ́n kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ọgbọ̀n.
20231101.yo_2542_13
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
Èdè wúlò fún kí a le bá ara sọ ọ̀rọ̀ léyìí tí gbédìí fún ẹwà akéwì náà. A kò le ṣe kí a má kí ara wa ní orísirísi ọ̀nà bóyá ọ̀rẹ́ sí ọ̀rẹ́, pẹ̀lú orísirísi ẹwà èdè.
20231101.yo_2542_14
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Èdè Yorùbá
Èdè wúlò fún fífi sọ èrò ọkàn wa àti fífi ìtara hàn sí ohun tí a gbọ́ rí tàbí tí ó ṣelẹ̀ sí wa. Reference:
20231101.yo_2543_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Àṣà Yorùbá jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ẹ̀yà [Yorùbá] ń lò láti fi gbé èrò, ìmọ̀, àti ìṣe wọn kalẹ̀ tí ó sì bá àwùjọ wọn mu ọ́nà tí ó gun gẹ́gẹ́. Tàbí kí á sọ wípé Àṣà ni ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ìgbé ayé àwọn ènìyàn kan, ní àdúgbò kan, bẹ̀rẹ̀ lórí èrò, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, ìsẹ̀dá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìṣe, ìrísí, ìhùwàsí, iṣẹ́-ọnà, oúnjẹ, ọ̀nà ìṣe nǹkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kọ̀ọ̀kan padà. Pàtàkì jùlọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, eré ìbílẹ̀, àti iṣẹ́ ìbílẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n kó'ra jọ pọ̀ ń jẹ́ àṣà.
20231101.yo_2543_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá, a ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí a ń mú enu bà ni ìhùwàsí àti ìrísí wa láàrín àwùjọ. Nínú ogún-lọ́gọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe tí ó ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan pàtàkì ni'
20231101.yo_2543_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Àṣà ìkíní nílẹ̀ Yorùbá. Èyí jẹ́ ohun tí gbogbo àwọn ẹ̀yà tí ó kú ní agbáyé fi ma ń ṣàdáyanrí ọmọ káàrọ̀-o kò-jíire bí tòótọ́ ní gbogbo ayé tí wọ́n bá dé
20231101.yo_2543_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Àṣà ìkíni jẹ́ àṣà tí ó gbajúgbajà nílẹ̀ Yorùbá, àṣà yí sì ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà àti àkókò. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí ó ń sẹlẹ̀ ní déédé àsìkò náà. Bí Yorùbá bá jí láàárọ̀, ọmọdé tí ó bá jẹ́ ọkùnrin, yóò wà lórí ìdọ̀bálẹ̀, nígbà tí èyí tí ó bá jẹ́ obìnrin yóò wà lórí ìkúnlẹ̀, wọn a sì kí àwọn òbí wọn tàbí ẹni tí ó bá ti jùwọ́n lọ ní gbogbo ọ̀nà, wọn á máa wípé:
20231101.yo_2543_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Nílẹ̀ Yorùbá, gbogbo àsìkò ni ó ní ìkíni tirẹ̀, ṣùgbọ́n ọmọdé ni ó kọ́kọ́ máa ń kí àgbà. Èyí tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ Yorùbá ní wí pé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò ní ẹ̀kọ́ tàbí, wọ́n kọ́ ọ ní'lé, kò gbà ni.
20231101.yo_2543_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Bí ó bá jẹ́ ìgbà ayẹ̣yẹ bíi ìsìnkú àgbà, nítorí Yorùbá kì í ṣe òkú ọ̀dọ́, ẹhìnkùnlé ni wọ́n máa ń sin òkú ọ̀dọ́ sí. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé, òfò ni ó jẹ́ fún àwọn òbí irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wàyí, bí ó bá jẹ́ òkú àgbà, wọn á ní,
20231101.yo_2543_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Bákan náà, oríṣiríṣì àkókò ni ó wà nínú odún. Àkókó òfìnkìn, Àkókò ọyẹ́, Àkókò oòrùn (Summer), Àkókò òjò, gbogbo wọ̀nyí sì ni àwọn Yorùbá ní bí a ṣe ń kí'ni fún. Ẹ jẹ́ kí á gbẹ́ àṣà ìsìnkú yẹ̀wò.
20231101.yo_2543_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú wípé ó ní àwọn òkú tí Yorùbá máa ń ṣe ayẹyẹ fún, àwọn bíi òkú àgbà, nítorí wọ́n gbà wí pé, olóògbé lọ sinmi ni, àti wí pé, wọ́n lọ'lé. Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọjà ni ayé, ṣùgbọ́n ọ̀run ni ilé.
20231101.yo_2543_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Bí ó bá jẹ́ òkú ọ̀dọ́ tàbí ọmọdé, òkú ọ̀fọ̀ àti ìbànújẹ́ ló jẹ́. Wọ́n á gbà wí pé, àsìkò rẹ̀ kò tíì tó. Yorùbá máa ń ná owó àti ara sí ìsìnkú àgbà, pàápàá bí olóògbé náà bá jẹ́ ẹni tí ó ní ipò àti ọlá nígbà tí ó wà láyé, tí ó sì tún bí ọmọ. Ìsìnkú àwọn wọ̀nyí máa ń lárinrin, ayé á gbọ́, òrun á sì tún mọ̀ pẹ̀lú.
20231101.yo_2543_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Ní ayé àtijọ́, bí aláwo bá kú, àwọn àwọn Olúwo ní ń sìnkú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wọn á pa adìyẹ ìrànà, wọn á sì máa tu ìyẹ́ rẹ bí wọ́n ṣe ń gbé òkú rẹ̀ lọ. Lẹ́yìn tí wọn bá sin òkú tán, àwọn aláwo náà á sun adìye náà jẹ. Ìdí rèé tí Yoòbá fi máa ń sọ wí pè, "Adìyẹ ìrànà kì í ṣ'ọhun à jẹ gbé." Nítorí pé, kò sí ẹni tí kò ní kú.
20231101.yo_2543_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Ọ̀fọ̀ ni ó máa ń jẹ́ tí ìyàwó ilé bá sáájú ọkọ rẹ̀ kú. Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọkọ ló máa ń sáájú aya rẹ̀ kú, kí ìyàwó máa bójú tó àwọn ọmọ. Fún ìdí èyí, bí okùnrin bá kú, àwọn ìyàwó irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ṣe opó pẹ̀lú ìlànà àti àṣà Yorùbá. Ogójì ọjọ́ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n máa ń fi ṣe opó. Lẹ́yìn ìsìnkú, àwọn àgbà ilé ni wọ́n máa pín ogún olóògbé fún àwọn ọmọ rẹ̀, bí ó bá jẹ́ òkú olọ́mọ. Àmọ́ tí kò bá bí’mọ, àwọn ẹbí rẹ̀, ní pátàkì jùlọ, àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ tí ó jù ú lọ ní wọ́n máa pín ogún náà láàárín ara wọn. Ó tún jẹ́ àṣà Yorùbá òmíì kí wọn máa ṣú opó olóògbé fún àwọn àbúrò rẹ̀, láti fi ṣe aya.
20231101.yo_2543_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Ohun tí ó jẹ́ orírun àṣà ni ‘àrà’, ó lè dára tàbí kí ó burú. Ìpolówó Èkìtì – iyán rere, ọbẹ̀ rere; Ìpolówó Oǹdó Ẹ̀gi – (dípò Iyán) ẹ̀bà gbọn fẹẹ. Àṣà Oǹdó ni kí wọ́n máa pe iyán ní ẹ̀bà, nítorí pé èèwọ̀ wọn ni, wọn kò gbọdọ̀ polówó iyán ní àárín ìlú.
20231101.yo_2543_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
(a) Àṣà lè jẹyọ nínú oúnjẹ: Òkèlè wọ́pọ̀ nínú oúnjẹ wa. Àkókó kúndùn ẹ̀bà, Ìlàjẹ fẹ́ràn púpurú, Igbó ọrà kìí sì í fi láfún òṣèré.
20231101.yo_2543_13
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
(b) Àṣà lè jẹyọ nínú ìtọ́jú oyún, aláìsà,òkú; ètò ẹbí, àjọṣepọ̀; ètò ìṣàkóso àdúgbò, abúlé tàbí ara dídá nípa iṣẹ́-ọnà.
20231101.yo_2543_14
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí:
20231101.yo_2543_15
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
(a) Bí àṣà tó wà nílẹ̀ bá lágbára ju èyí tó jẹ́ tuntun lọ, èyí tó wà tẹ́lẹ̀ yóò borí tuntun. Bí àpẹẹrẹ, aṣọ wíwọ̀.
20231101.yo_2543_16
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
(b) Àyípadà lè wáyé bí àṣà tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ bá dógba pẹ̀lú àṣà tuntun, wọ́n lè jọ rìn pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àṣà ìgbéyàwó.
20231101.yo_2543_17
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
(d) Bí àṣà tuntun bá lágbára ju èyí tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, yóò sọ àṣà ti àtẹ̀hìnwá di ohun ìgbàgbé. Bí àpẹẹrẹ, bí a ṣe ń kọ́'lé.
20231101.yo_2543_18
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Èdè àwọn ènìyàn jẹ́ kókó kan pàtàkì nínú àṣà wọn. Kò sí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò nínú àṣà àti èdè. Ìbejì ni wọ́n. Ọjọ́ kan náà ni wọ́n délé ayé nítorí pé kò sí ohun tí a fẹ́ sọ nípa àṣà, tí kì í ṣe pé èdè ni a ó fi gbé e kalẹ̀. Láti ara èdè pàápàá ni a ti lè fa àṣà yọ. A lè fi èdè Yorùbá sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni, a lè fi kọrin, a lè fi kéwì, a lè fi jọ́sìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láti ara àwọn nǹkan tí à ń sọ jáde lẹ́nu wọ̀nyí ni àṣà wa ti ń jẹyọ. Ara èdè Yorùbá náà ni òwe àti àwọn àkànlò-èdè gbogbo wà. A lè fa púpọ̀ nínú àwọn àṣà wa yọ láti ara òwe àti àkànlò èdè.
20231101.yo_2543_19
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3%C3%A0%20Yor%C3%B9b%C3%A1
Àṣà Yorùbá
Nítorí náà, èdè ni ó jẹ́ òpómúléró fún àṣà Yorùbá. Àti wí pé, òun ni ó fà á tí ó fi jẹ́ pé, bí àwọn ọmọ Odùduwà ṣe tàn kálẹ̀, orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n, èdè kan náà ni wọ́n ń sọ níbikíbi tí wọ́n lè wà. Ìṣesí, ìhùwàsí, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀. Fún ìdí èyí, láìsí ènìyàn, kò le è sí àṣà rárá.àsà jẹ́ nnkan gbòógì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ṣùgbọ́n àwọn yorùbá mu ní ọ̀kúnkúndùn kí gbogbo wa sì gbe lárugẹ
20231101.yo_2547_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Sé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “Se bó o ti mọ ẹlẹ́wàà sàpọ́n. Ìwọ̀n eku nìwọ̀n ìtẹ́.” Wọn a sì tún máa pa á lówe pé “ìmọ̀ ìwọ̀n ara ẹni ni ìlékè ọgbọ́n nítorí pé ohun ọwọ́ mi ò tó ma fi gọ̀gọ̀ fà á, í í já lu olúwarẹ̀ mọ́lẹ̀ ni”
20231101.yo_2547_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
áyé òde òní, àwọn ọ̀dọ́ tilẹ̀ máa ń dáṣà báyìí pé “dẹ̀ẹ́dẹ̀ẹ́ rẹ, ìgbéraga ni ìgbérasán lẹ̀.” Wọ́n máa ń sọ èyí fún ẹni tí ó bá ń kọjá ààyè rẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ ọgbọ́n kan se wí pé “ni àtètékọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ wà,” bẹ́ẹ̀ náà ni ètò ti wà fún ohun gbogbo láti ìpilẹ̀sẹ̀ wá. Ètò ní í mú kóhun gbogbo rí rẹ́mú. Ọlọrun ọ̀gá ògo to da ayé. Ó fi ẹranko sígbó {àwọn olóró}. Ó tún fi ẹja síbú. Ó fi àwọn ẹyẹ kan sígbó. Ó fi àwọn mìíràn sílé. Àdìmúlà bàbá tó ju bàbá lọ tún fi ààlà sáààrin ilẹ̀, omi òkun, àti sánmọ̀. Ohun gbogbo ń lọ ní mẹ̀lọ̀-mẹ̀lọ.
20231101.yo_2547_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Bàbá dá àwa ọmọnìyàn kò fi ojú wa sí ìpàkọ́. Kò fi ẹsẹ̀ wa sórí kí orí wá wà lẹ́sẹ̀. Elétò lỌlọ́run gan-an.
20231101.yo_2547_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Kíni ètò? Ètò jẹ̣́ ọ̀nà tí à ń gbà láti sàgbékalẹ̀ ohun kan tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan lójúnà àti mú kí ó se é wò tàbí kó se é rí tàbí kó dùn ún gbọ́ sétí. A sẹ̀dá orúkọ yìí gan-an ni. Ohun tí a tò ní í jẹ́ ètò.
20231101.yo_2547_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Ẹ̀wẹ̀, ìnáwó ni ọ̀nà tàbí ìwà wa lórí bí a se ń náwó. Ohun pàtàkì ni láti sètòo bí a óò se máa ná àwọn owó tó bá wọlé fún wa. Ní àkọ́kọ́ ná, èyí yóò jẹ́ kí á mọ ìsirò oye owó tó ń wọlé fún wa yálà lọ́sẹ̀ ni o tàbí lósù, bí ó sì se lọ́dún gan-an ni.
20231101.yo_2547_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Bákan náà, yóò tún mú kó rọrùn fún wa láti mọ àwọn ọ̀nà tí owó náà ń bá lọ. Síwájú síi, ètò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti le ní ìkọ́ra-ẹni-níjàánu lórí bí a se ń náwó wa.
20231101.yo_2547_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Bí a bá ti mú ìsàkọ̀tún tán, tí a tún mú ìsàkòsì náà, ìsàkusà ni yóò kù nilẹ̀. Tí a bá yọ ti ètò kúrò nínú ojúse ìjọba pàápàá sí ará ìlú, eré ọmọdé ni ìyókù yóò jẹ́. Gbogbo àwọn ẹka ìjọba pátá-porongodo ló máa ń ní àgbẹ́kalẹ̀ ìlànà tí wọn yóò tẹ̀lé lati mọ oye owó ti wọn n reti ati eyi ti wọn óò na bóyá fún odidi ọdún kan ni o tàbí fún osù díẹ̀. Èyí ni wọ́n ǹ pé ní ‘ÈTÒ ÌSÚNÁ’
20231101.yo_2547_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Ìdí nìyí tó fi se pàtàkì fún gbogbo tolórí-tẹlẹ́mù, tòǹga-tòǹbẹ̀rẹ̀ ki kúlukú ní ètò kan gbòógì lọ́nà bí yóò se máa náwó rẹ̀. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, “eku tó bá ti ní òpó nílẹ̀, kì í si aré sá. Bí a bá ti se àlàkalẹ̀ bí a óò se náwo wa yóò dín ìnákùùná kù láwùjọ wa. Ìnáwó àbàadì pàápàá yóò sì máa gbẹ́nú ìgbẹ́ wo wá láwùjọ wa.
20231101.yo_2547_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Mo ti sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀kan nípa àwọn ẹka ìjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀tà orílẹ̀ èdè yìí tí wọ́n máa ń sètò ìnáwó wọn. Àwọn wo ló tún yẹ kó máa sètò ìnáwó? Àwọn náà ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn oníṣòwò, àwọn ọmọ ilé-ìwé, níbi àsẹyẹ.
20231101.yo_2547_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Àwọn òsìsẹ́ ìjọba gbọdọ̀ sètò ìnáwó wọn kó sì gún régé. Ìdí ni pé, èyí ni yóò jẹ́ kí owó osù wọn tó í ná. Ẹni tó ń gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lósù tí kò sì fi òdiwọ̀n sí ìnáwó rẹ̀ nípa títò wọ́n lésẹẹsẹ le máa rówó sohun tó yẹ láàákò tó yẹ nígbà tí ó bá ti náwó rẹ̀ sí àwọn ohun mìíràn tó seése kó nítumọ̀ ṣùgbọ́n tí kì í se fún àkókò náà.
20231101.yo_2547_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Síwájú sí i, àwọn oníṣòwò gbọ́dọ̀ máa sètò to jíire lórí ìnáwó wọn. Nípa ṣíṣe èyí, wọn óò ni àǹfààní láti mọ̀ bọ́yá Ọláńrewájú ni iṣẹ́ wọn tàbí Ọláńrẹ̀yìn. Níbi tí àtúnṣe bá sì ti pọn dandan, “a kì í fòdù ọ̀yà sùn ká tó í nà án ládàá,” wọn kò nì í bèsù bẹ̀gbà, wọn óò sì se àtúnṣe ní wéréwéré. Àwọn ọmọ ilé-ìwé gan-an gbọdọ̀ mọ̀ pé ká sètò ìnáwó ẹni kì í sohun tó burúkú bí ti í wù kó mọ. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ẹ̀kó gíga, béèyàn bá gbowó fún àwọn orísirísi ìnáwó láti ilé lórí ẹ̀kọ́ ẹni, ó seése kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ná ìná-àpà tó bá dé ààrin àwọn ẹlẹgbẹ́ẹ rẹ̀. Irú wọn ló máa ń pe ọ̀sẹ̀ tí wọ́n bá ti ilé lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn dé ní ‘Ọṣẹ ìgbéraga’ Èyí kò yẹ ọmọlúàbí pàápàá. Ó sì ń pè fún àtúnṣe.
20231101.yo_2547_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Ṣíṣe ètò tó gúnmọ́ lórí ọ̀nà tí à ń gbà náwó kò pin sí àwọn ọ̀nà tí mo sàlàyé rẹ̀ sókè yìí. Mo fẹ́ kó ye wá pé a le sètò ìnáwó wa níbi àwọn orísisi ayẹyẹ bí ìsọmọlórúkọ [tàbí ìkọ́mọ́jáde], ìgbéyàwó, oyè jíjẹ, ìṣílé, àti ìsìnkú àgbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi bí a se tó hàn wá ká le mọ ohun tí a óò dágbá lé níbi irúfẹ́ àṣeyẹ tí a bá fẹ́ í ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀ a ò ní í sí nínú àwọn tó máa ń pa òwe tó máa ń mú kí wọn kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn ọ̀rọ̀. Òwe wọn ni, “rán aṣọ rẹ bí o bá se ga mọ.” Èyí tí wọn ì bá fi wí pé “rán aṣọ rẹ bí o bá se lówóo rẹ̀ sí.” Bí ẹni tó ga bá rán aṣọ rẹ̀ ní ‘bóńfò’ bó se lówó mọ ni, kò sì fẹ́ í sàsejù. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ le ti mọ̀ pé alásejù pẹ́rẹ́ ní í tẹ́.
20231101.yo_2547_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cn%C3%A1w%C3%B3
Ìnáwó
Bí a bá wá fẹ́ láti sètò ìnáwó wa, ó yẹ ká mọ̀ pé ìtòṣẹ̀ ló lỌ̀yọ̀ọ́, Oníbodè lo làààfin, ẹnìkan kì í fi kẹ̀kẹ́ síwájú ẹsin. Iwájú lojúgun í gbé. Ìnáwó tó bá ṣe kókó jùlọ tó sì ń bèèrè fún ìdásí ní kíákíá ló yẹ ká fi síwájú bí a se ń tò ó ní ẹsẹẹsẹ. Bí a bá wá kíyèsí pé ètò tí a là sílẹ̀ ti ju agbára wa lọ, ẹ jẹ́ ká fura nítorí pé akéwì kan wí pé:
20231101.yo_2551_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Yorùbá tọ̀ wọ́n ní kí la ó jẹ làgba kí la ó ṣe, abálájọ tí ètò ajé fi mumú láyà gbobgo orílẹ̀ èdè àgbáyé tóó bẹ̀.
20231101.yo_2551_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Gbàrà tí ọ̀nà káràkátà oní-pà ṣí pààrọ̀ tayé ọjọ́ tun ti dotun ìgbàgbé ni ètò ajé ti dotun tó gbòòrò síwájú sí.
20231101.yo_2551_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Awọn ènìyàn wáá bẹ̀rẹ̀ síí ní lo àwọn ohun èlò bíi wúrà àti jàdákà láti máa fii se pàṣípààrọ̀ àwọn ohun tí wọ́n nílò.
20231101.yo_2551_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Eléyìí mú kí káràkátà láàrín-ín ìlú àti orílẹ̀ èdè tún gbináyá síi nígbà tí àwọn kù dìẹ̀ ku diẹ tí ń fa ìdílọ́wọ́ nínú káràkátà onípàṣípàrọ̀ ti kúrò ní bẹ̀.
20231101.yo_2551_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Tí abá kọ́kọ́ gbé ètò ayé ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú yẹ̀ wò fínní fínní, aórìí pe ohun erè oko ló jẹ́ lájorí ọrọ̀ ajé àwọn ènìyàn yìí. Àwọn erè oko wọ̀nyí ni wọ́n si ń fi ń ṣe pàṣípàrọ̀ láti tán àìní ara wọn ṣááju alábàápàbé wọn pẹ̀lú àwọn aláwọ̀ funfun.
20231101.yo_2551_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Ṣíṣa lábàápàdé àwọn aláwọ̀ funfun yìí mú kí àwọn aláwọ̀ dúdú ní àǹfàní àti ṣàmúlò àwọn ohun èlò míràn bíi: Jígí ìwojú, Iyọ̀, ọti líle àti àwọn ohun míràn bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àti ibí yìí ni wọ́n ti kọ́ àṣà lílo àwọn ohun èlò táati dárúkọ ṣáájú yìí dípò pà sí pààrọ̀ tó mú ọ̀pọ̀ wàhálà lọ́ iwọ́. kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀, ìlànà àti máa lo owó wá sí ojútáyé, tí ètò ọrọ̀ ajé sì wá búrẹ́kẹ́.
20231101.yo_2551_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìbúrẹ́kẹ́ ọrọ̀ ajé yìí, ìyípadà díẹ̀ ló dé bá ipò ò ṣì tí àwọn aláwò dúdú yìí ti wà tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ́rí.
20231101.yo_2551_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Kàyéfì ńlá ló jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ àwọn aláwọ̀ funfun yìí tí ń pọ̀ sin i òṣì túbọ̀ ń bá àwọn aláwọ̀ dúdú fínra sí.
20231101.yo_2551_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Kàyéfì ọ̀rọ̀ yìí ò sẹ̀yìn ìwà imúni sìn adáni lóró tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí fimú àwọn gìrìpá tó yẹ kó fi gbogbo ọpọlọ àti agbára wọn ṣiṣẹ́ láti mú ayé ìrọ̀rùn wáá bá ilẹ̀ wọn àti àwọn ènìyàn wọn.
20231101.yo_2551_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Nígbà tó yẹ kí àwọn gìrìpá aláwọ̀ dúdú máa ṣiṣẹ́ idàgbàsókè ní ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìlẹ̀ àwọn aláwọ̀ funfun ni wọ́n wà tí wọ́n ń bá àwọn ènìyàn yìí ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó.
20231101.yo_2551_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Àwọn aláwọ̀ funfun yìí ńlo àwọn aláwọ̀ dúdú láti tún orílẹ̀ èdè ti wọn se, àti láti pilẹ̀ ọrọ̀ ajé tó lààmì láka.
20231101.yo_2551_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Gbogbo ìgbà tí ìmúni lẹ́rú yìí n lọ lọ́wọ́, tí ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ funfun yìí sì ń tẹ̀ síwájú, kò sí ẹyọ iṣẹ́ ìdàgbàsókè kan ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú.
20231101.yo_2551_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Ìgbà tí ìmúnilẹ́rú dáwọ́ dúró, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí ti gòkè àgbà díẹ̀ ń se ni wọ́n tún yára gba ètò ìṣàkóso ìjọba lọ́wọ́ àwọn àláwọ̀ dúdú, tí wọ́n sì sọ pé, ọ̀làjú ni àwọn fẹ́ẹ́ fi wọ àwọn aláwọ̀ dúdú yìí tí ẹ̀wù ìdí nìyí tí àwọn fi tẹ wọ́n lóríba tí àwọn sì fi pá gba ijọba wọn.
20231101.yo_2551_13
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Òtítọ́ tó dájú nip é, àwọn aláwọ̀ funfun yìí ríi pé ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú dára fún àwọn iṣé ọ̀gbìn erè oko kan bíi: kòkó rọ́bà, ẹ̀pà, àti kọfí èyí tí ó wúlò lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ohun èlò àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá tí wọ́n ti dá sílẹ̀.
20231101.yo_2551_14
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Wọ́n wá fi tì pá tì kúùkù sọ̀ ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú di oko Ọ̀gbìn àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò tí àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ti wọn.
20231101.yo_2551_15
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Ipò Ìṣẹ́ àti Ìmúni sìn yìí ni àwọn aláwọ̀ dúdú wà tí tí fi di ìgbà tí wọ́n sọ pé àwọn funfun wọn ní òmìnira.
20231101.yo_2551_16
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Ipò òṣì àti àre tí àwọn aláwọ̀ funfun fi àwọn ènìyàn yìí sí kò jẹ́ kí wọ́n ó lè dá dúró, kí wọ́n sì dáńgbájíá láti máage àwọn ohun ti wọ́n nílò ní ilé iṣẹ́ ìgbàlódé ti wọn fún raa wọn.
20231101.yo_2551_17
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Àwọn aláwọ̀ funfun yìí ló sì wá ń dá iye owó tí ohun erè oko tó ń wá láti ilè àwọn aláwọ̀ dúdú yíò jẹ́, èyí ti ó ń túmọ̀ sí pé, ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí ni dídọ lọ́rọ̀ àti òdìkejì àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú wà.
20231101.yo_2551_18
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Kódà, àwọn orílẹ̀ èdè kan tó ní àwọn ohun àmúṣọrọ̀ kan tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí ò fi bẹ́ẹ̀ ní, bíi epo rọ̀bì ò he è dá ohun kan ṣe lórí ohun àmúṣọrọ̀wọn yìí láì sí ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí níbẹ̀.
20231101.yo_2551_19
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88t%C3%B2%20aj%C3%A9
Ètò ajé
Ọ̀wọ́ àwọn aláwọ̀ funfun ni agbára ètò ọrọ̀ ajẹ́ àgbéyé wà, àwọn ló sì ń pàṣe fún àwọn orílẹ̀ èdè tó kù ní pa ọnà tí wọn yíò gbà ṣe ìjọba àti ọ̀nà tí wọn yíò gbé ọrọ̀ ajé wọn gbà, tí wọ́n bá fẹ́ àjọ ṣepọ̀ dídán mọ́rán pẹ̀lú àwọn.
20231101.yo_2552_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3%C3%A8l%C3%BA
Ìṣèlú
Ìṣèlú tabi òṣèlú ni igbese bi awon idipo eniyan kan se n sepinnu. Oro yi je mimulo si iwuwa ninu awon ìjọba abele.
20231101.yo_2552_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3%C3%A8l%C3%BA
Ìṣèlú
Ní àwùjọ Yorùbá, á ní àwọn ọ̀nà ìsèlú tiwa tí ó dá wa yàtọ̀ sí ẹ̀yà tàbí ìran mìíràn. Kí àwọn Òyìnbó tó dé ní àwa Yorùbá ti ni ètò ìsèlú tiwa tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀. Tí ó sì wà láàárin ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn. Yàtọ̀ sí tí àwọn ẹ̀yà bí i ti ìgbò tí ó jẹ́ wí pé àjọrò ni wọn n fi ìjọba tiwọn ṣe (acephalous) tàbí ti Hausa níbi tí àsẹ pípa wà lọ́wọ́ ẹnìkan (centralization).
20231101.yo_2552_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3%C3%A8l%C3%BA
Ìṣèlú
Ètò òsèlú Yorùbá bẹ̀rẹ̀ láti inú ilé. Eyi si fi ipá tí àwọn òbí ń kò nínú ilé ṣe ìpìlẹ̀ ètò òsèlú wa. Yorùbá bọ̀ wọn ní, “ilé là á tí kó èsọ́ ròdé”.
20231101.yo_2552_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3%C3%A8l%C3%BA
Ìṣèlú
Baba tí ó jẹ́ olórí ilé ni ó jẹ́ olùdarí àkọ́kọ́ nínú ètò ìsèlú wa. Gbogbo ẹ̀kọ́ tó yẹ fún ọmọ láti inú ilé ni yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn. Bí i àwọn ẹ̀kọ́ ọmọlúàbí. Tí èdèàiyèdè bá sẹlẹ̀ nínú ile, bàbá ni yóò kọ́kọ́ parí rẹ̀. tí kò bá rí i yanjú ni yóò tó gbé e lọ sí ọ̀dọ̀ mọ́gàjí agbo-ilé. Agbo-ilé ni ìdílé bíi mẹ́rin lọ sókè tó wà papọ̀ ni ojú kan náà. Wọn kó ilé wọn papọ̀ ní ààrin kan náà. Tí mógàjí bá mọ̀ ọ́n tì, ó di ọdọ olóyè àdúgbò. Olóyè yìí ni ó wà lórí àdúgbò. Àdúgbò ni àwọn agbo-ilé oríṣìíríṣìí tí ó wà papọ̀ ní ojúkan. A tún máa ń rí àwọn Baálè ìletò pàápàá tí wọ́n jẹ́ asojú fún ọba ìlú ní agbègbè wọn. Àwọn ni ọ̀pá ìsàkóso abúlé yìí wà ní ọwọ́ wọn. Ẹjọ́ tí wọn kò bá rí ojúùtú sí ni wọ́n máa ń gbé lọ sí ọdọ ọba ìlú. Ọba ni ó lágbára ju nínú àkàsọ̀ ìsàkóso ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn Yorùbá ka àwọn Ọba wọn sí òrìṣa Ìdí nìyí tí wọn fí máa ń sọ pé:
20231101.yo_2552_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3%C3%A8l%C3%BA
Ìṣèlú
Ọba yìí ní àwọn ìjòyè tí wọn jọ ń ṣèlú. Ẹjọ́ tí ọba bá dá ni òpin. Ààfin ọba ni ilé ẹjọ́ tó ga jù. Ọba a máa dájọ́ ikú. Ọba si le è gbẹ́sẹ̀ lé ìyàwó tàbí ohun ìní ẹlòmíì. Wọ́n a ní:
20231101.yo_2552_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3%C3%A8l%C3%BA
Ìṣèlú
A rí àwọn olóyè bí ìwàrèfà, ní òyọ́ ni a ti ń pè wọ́n ní Ọ̀yọ́-mèsì. Ìjòyè mẹ́fà tàbí méje ni wọn. Àwọn ni afọbajẹ. A rí àwọn ìjòyè àdúgbò tàbí abúlé pàápàá tí ó máa ń bá ọba ṣe àpérò tàbí láti jábọ̀ ìlọsíwájú agbègbè wọn fún un.
20231101.yo_2552_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3%C3%A8l%C3%BA
Ìṣèlú
A tún ń àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó ń dáàbò bo ọba àti ìlú. Àwọn ni wọn ń kojú ogun. Àwọn ni o n lọ gba isakọlẹ fọ́ba. A tún ní àwọn onífá, Babaláwo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
20231101.yo_2552_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3%C3%A8l%C3%BA
Ìṣèlú
Ètò òsèlú wa tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ yìí ni ó mú kí ó sòro fún àwọn òyìnbọ́ láti gàba tààrà lórí wa (Indirect rule). Àwọn ọba àti ìjòyè wa náà ni wọn ń lò láti ṣèjọba lórí wa. Ó pẹ̀ díẹ̀ kí wọ́n tó rí wa wọ.
20231101.yo_2557_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20O
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): O
ọ̀tọ̀tọ̀, n. the whole of anything, entirety, many. ọ̀tọ̀tọ̀ ènìyàn ni ó wá sí orí pápá. (Many people came to the field.)
20231101.yo_2557_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20O
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): O
ọ̀tun, n. or adj. newness, freshness, novelty, new, fresh, recent, novel. ọ̀tun nìwé yìí. This book is new.
20231101.yo_2557_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20O
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): O
ọ̀wàwà, n. an animal resembling the dog, which climbs the tree with its face, downwards, and its hind legs topmost, tree-bear.
20231101.yo_2557_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20O
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): O
ọ̀wẹ̀, n. a club or a company summoned to assist one of their number in manual labour. Mo bẹ wọ́n ní ọ̀wẹ̀ lórí iṣẹ́ oko mi. I asked them for assistance with my farm-work.
20231101.yo_2557_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20O
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): O
ọ̀yà, n. wages, salary, hire, pay, stipend, an animal which is also called ‘Ewújù,’ hedgehog, bush pig. (His wages are ten naira per week.) owó ọ̀yà rẹ̀ jẹ́ náírà mẹ́wàá lọ́sẹ̀.
20231101.yo_2557_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20O
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): O
ọya, n. wife of ṣàngó, to whom the River Niger is dedicated, hence the river is called ‘Odò Ọya’ after her.
20231101.yo_2557_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20O
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): O
ọ̀yàyà, n merry mood and behavious, cheerfulness, vivacity. ọ̀yàyà rẹ̀ ni ó jẹ́ kí ó ní ìfẹ́ sí i. (He was charmed by his vivacity.)
20231101.yo_2557_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20O
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): O
ọyún, ètútú, èétú, n. matter coming out of a sore, purulence, pus. Má ṣe fún oówo láti fi agbára jẹ́ kí ọyún rẹ jáde. Dọ́nt squeeze a boil to force the pus out.
20231101.yo_2558_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pa, verb. (primary idea, “to make to feel, suffers, etc.”, extensively used in composition), to kill, to murder, to put out of existence, to ruin, to stay, to betray to quench fire, to extinguish, to bruise, to rub, to scrub, to cut yam or calabash into halves, to break any hard nut, to peel the bark of a tree, to win a game, to hatch, (eggs), to tell fables, to be intoxicated (as with liquor).
20231101.yo_2558_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pá v.t. to avoid giving occasion for quarrel, to avoid strife. Ó pá èṣù (páàṣù/péèṣù) mọ́ nílẹ̀ (He avoided strife.)
20231101.yo_2558_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
padà san, v.t. to repay, to refund, to retaliate. Wọn yóò padà san owó ìwé náà. (The will refund the cost of the book.)
20231101.yo_2558_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
padà sẹ́yìn, v.i. to turn back, to relapse. Ó padà sẹ́yìn sí àwọn ìwà burúkú rẹ̀ àtijọ́ (He relapsed into his old bad habits.)
20231101.yo_2558_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
padà sí v.t. to resort to, to come back to, to turn upon, to return to. Ó ti padà sí ilé. (He has returned home.
20231101.yo_2558_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pàdé, v.t. to meet with, to come together. Jẹ́ kí á pàdé ní ilé rẹ lálẹ́ (Let us meet at your house tonight.)
20231101.yo_2558_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pàdéminígbọ̀nwọ́, n. (lit. meet me at the elbow) watery sauce. pàdéminígbọnwọ́ ni agbára àwọn òtòsì ká. (poor people can afford only watery source.)
20231101.yo_2558_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pàdẹ, v.t. to expose near the gate of a town or village the garments or other clothes left by a hunter after his death.
20231101.yo_2558_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
padẹmọ́lọ́wọ́, v.t. to hand-cuff; fig to cheat, to swindle. Wọ́n padẹ mọ́ ọn lọ́wọ́ sí ẹ̀yìn rẹ̀. (His hands were handcuffed behind his back.)
20231101.yo_2558_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pàdí, v.t. to be the cause of. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ó pàdí iná náà? (Do you know what caused the fire?).
20231101.yo_2558_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pááfá, páráfà, n. a butcher’s table, board, a long table, a litter. Òun ni ó ni pááfà yẹn. (He owns that butcher’s table.
20231101.yo_2558_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
páfe, pátápátá, adv. altogether, absolutely, entirely, completely. Ó tán páfe. (It is completely finished.)
20231101.yo_2558_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pagi, v.t to lop off the branches and leaves of trees (as by the ‘Orò’) eaten the leaves of a tree. Orò pagi orò has eaten the leaves of the tree.
20231101.yo_2558_13
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pagidarì, interj. an exclamation of surprise, fancy! Pagidarì! Kò tíì wọ ọkọ̀ òfurufú rí. Fancy! She has never been in a plane before.
20231101.yo_2558_14
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pa gììrì, Ta gììrì, v.i. to arouse oneself suddenly, to shudder. Ó pa gììrì nígbà tí ó rí ẹ̀jẹ̀. He shuddered at the sight of blood.
20231101.yo_2558_15
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pàgbẹ́, ṣángẹ̀ẹ́ v.t. to clean a new forest for the purpose of cultivating it for planting yams, corn, etc., to clear the forest. Ó ti pàgbẹ́. He has cleared the forest.
20231101.yo_2558_16
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pagbo, v.i to make or form a ring or circle, to arrange in a circle. Wọ́n pagbo They arranged themselves in a circle.
20231101.yo_2558_17
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pahín payín, v.i to chip off two of the upper front teeth (for fashion), to file teeth. Ó pahín. He filed his teeth.
20231101.yo_2558_18
https://yo.wikipedia.org/wiki/At%C3%BAm%E1%BB%8D%CC%80-%C3%88d%C3%A8%20%28Yor%C3%B9b%C3%A1-G%E1%BA%B9%CC%80%E1%BA%B9%CC%81s%C3%AC%29%3A%20P
Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P
pahím keke, Payín keke, v.t. to gnash the teeth. Yóò máà pahín keke nígbà tí ó bá gbọ́ pé iṣẹ náà kò bó sí i mọ́. (He will be gnashing his teeth when he hears that he lost the contact.