_id
stringlengths
17
21
url
stringlengths
32
377
title
stringlengths
2
120
text
stringlengths
100
2.76k
20231101.yo_2709_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%92gb%C3%B3j%C3%BA%20%E1%BB%8Cd%E1%BA%B9%20n%C3%ADn%C3%BA%20Igb%C3%B3%20Ir%C3%BAnm%E1%BB%8Dl%E1%BA%B9%CC%80
Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀
Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Sóyinká ṣe ògbufọ̀ ìwé ìtàn àròsọ Ògbójú Ọdẹ nínú Igbo Olódùmarè sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Like Igbo Olodumare, it was adapted for the stage, in both English and Yoruba.
20231101.yo_2710_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Igb%C3%B3%20Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Igbó Olódùmarè
Eléyìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìtàn àròso tí D.O. Fagunwa kọ. Ó sọ ìtàn Olówó-ayé àti ìrìnàjò rẹ̀ ní Igbó olódùmarè. Ó sọ bí ó ṣe dé ọ̀dọ̀ bàbá-onírùngbọ̀n yẹnkẹ àti bí ó ṣe rí òpin Òjòlá-ìbínú
20231101.yo_2710_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Igb%C3%B3%20Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Igbó Olódùmarè
D.O. Fagunwa (1950), Igbó Olódùmarè. Nelson Publisher Ltd in association with Evans Brothers (Nigeria) Publishers Ltd; Ìbàdàn, Nigeria. ISBN 978-126-241-9. Ojú-ìwé 165.
20231101.yo_2729_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Emere
Emere
Ọlátìńwò Adéagbo Fátokí (1991) Emèrè. Ìbàdán, Nigeria: Heineman Educational Books Nig. PLC. ISBN 978-129-234-2. Ojú-ìwé 53.
20231101.yo_2729_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Emere
Emere
Ohun tó gbé mi dé ìdí à ń kọ ìwé yìí ni ìgbàgbọ́ àti ihà tí àwọn ènìyàn kọ sí àwọn ọmọ tí à ń pè ní Emèrè.
20231101.yo_2729_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/Emere
Emere
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rí àwọn ọmọ wọ̀nyìí gẹ́gẹ́ bí Àbíkú, Ẹlẹ́gbẹ́, Ọ̀gbáńje, Ọmọ Ìyanu, Abáfẹ́fẹ́rìn-ọmọ Ẹlẹ́mìíkẹ́mìí-ọmọ àti Adíwọ̀n-ọmọ. Àwọn orúkọ wọ̀nyìí fi hàn pé ìṣòro ńlá wà láti dá Emèrè mọ̀. Lọ́wọ̀ọ́ ìgbà tó sì jẹ́ pé a ko le fi Ògún rẹ̀ gbárí pé Emèrè nìyìi, mo wá lọ sí Àròjinlẹ̀ ọkàn, mo pe kọ́lọ́fín ọpọlọ jáde, mo wá rí i pé Emèrè jẹ́ Àjíǹde-òkú tó ń pọ́n ọ̀bẹ sùn, tó tún fapò rọrí. Gbogbo ara ni wọ́n fi ṣe agbára. Ẹ̀mí àìrí tó sì ń bá wọn lò jẹ́ èyí tó ṣòro láti ṣàpèjúwe. Ọmọ kàyéfì ni Emèrè. À ní Àdánwò-ọmọ ni wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dúró fún tibi-tire tó bá bá àwọn lọ́kọláyà tó bá lùgbàdì wọn.
20231101.yo_2729_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/Emere
Emere
Ní ti agbára, wọ́n ní agbára ju Àjẹ́ àti Oṣó lọ. Ẹ̀yìn Ìyà mi, apani-má-hàá-Ogún, ìbà! Pẹ̀lú fàájì ni Emèrè ṣe ń wọ inú obìnrin-kóbìnrin. Taa ni yóò yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò? Wọ́n ní agbára láti yí padà tàbí taari ọmọ inú aboyún jáde nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lo ààyè ibẹ̀. …
20231101.yo_2733_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1h%C3%A1r%C3%A1%C3%ACn%C3%AC
Báháráìnì
Bahrain tabi Ile-Oba Bahrain Ní ọdún 1995, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé orílẹ̀-èdè yìí tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta àti ààbọ̀ (555,000). Èdè Lárúbááwá (Arabic) ni èdè ìjọba ní ibẹ̀. Àwọn èdè kan tún wà tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Àwọn èdè náà ni fáàsì (farsi) tí àwọn tí ó ń sọ ó ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́ta (48, 000); Úúdù (Urdu) tí àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) àti àwọn èdè fílípíìnì (Phillipine) mìíràn tí àwọn tí ó ń sọ wọ́n tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbayì ní ilẹ̀ yìí sí i gẹ́gẹ́ bí èdè òwò àti èdè ìṣe àbẹ̀wò sí ìlú (tourism).
20231101.yo_2734_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%E1%BB%8Dn%20B%C3%A0h%C3%A1m%C3%A0
Àwọn Bàhámà
Àwọn Bàhámà () tabi lonibise bi Orílẹ̀-èdè Àjọni ilẹ̀ awọn Bàhámà, je orile-ede elede Geesi to ni awon erekusu 29, 661 cays, ati 2,387 erekusu kekere 2,387 (apata). O budo si inu Okun Atlantiki ni ariwa Kuba ati Hispaniola (Dominiki Olominira ati Haiti), ariwaiwoorun awon Erekusu Turks ati Caicos, ati guusuilaorun orile-ede Awon Ipinle Aparapo ile Amerika (nitosi ipinle Florida). Apapo iye aala ile re je 13,939 km2 (5,382 sq. mi.), pelu idiye olugbe to to 330,000. Oluilu re ni Nassau. Bi jeografi, awon Bahama wa ni asopo erekusu kanna bi Kuba, Hispaniola (Dominiki Olominira ati Haiti) ati Awon Erekusu Turks ati Caicos.
20231101.yo_2734_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%E1%BB%8Dn%20B%C3%A0h%C3%A1m%C3%A0
Àwọn Bàhámà
Awon onibudo ibe tele ni awon Taino ti Arawaka, awon Bahama ni ibi ti Columbus koko gunle si ni Ile Aye Tuntun ni 1492. Botilejepe awon ara Spein ko se amunisin awon Bahama, won ko awon Lucaya abinibi ibe (eyi ni oruko ti awon Taino Bahama unpe ara won) lo si oko eru ni Hispaniola. Lati 1513 de 1650 enikankan ko gbe ori awon erekusu yi, ko to di pe awon olumunisin ara Britani lati Bermuda tedo si erekusu Eleuthera.
20231101.yo_2735_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A1l%C3%ADn%C3%AD%C3%ACs%C3%AC
Bálíníìsì
Ọmọ ẹgbẹ́ ẹbí èdè Austronesian ni èdè yìí. Àwọn tí ó n sọ ọ́ fẹ́rẹ́ẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́rin (3.8 million) ní erékùsù Báálì (Bali) ní In-indoníísíà (Indonesia). Àkọtọ́ Bálíníìsì àti ti Rómáànù (Balinese and Roman alphabet)ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀.
20231101.yo_2736_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20B%C3%A0l%C3%B3%E1%B9%A3%C3%AC
Èdè Bàlóṣì
Ọmọ ẹgbẹ́ èdè tí a ń pé ní Iranian ni Bàlúṣì. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tọ́ mílíọ̀nù márùn-ún. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ọ́ yìí ni ó wà ní Pakísítáánì (Pakistan) ní Bàlúṣísítáànì (Baluchistan). Baluclistan yìí ni ìpínlẹ̀ (province) tí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn jùní pakcstan. Àwọn tí ó ń sọ èdè yìí ní Baluchistan tó mílíọ̀nù (Iran), Afuganíísítáànù (Afghanistan) àti In-índíà (India). Àkọtọ́ Lárúbáwá (Arabic) ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àjọ kan wà tí wọ́n ń pè ní Baluchi Academy tí ó ń ń sí pé àkọsílẹ̀ èdè yìí páye.
20231101.yo_2737_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/B%C3%A0l%C3%BA%E1%B9%A3%C3%AC
Bàlúṣì
Ọmọ ẹgbẹ́ èdè tí a ń pé ní Iranian ni Bàlúṣì. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tọ́ mílíọ̀nù márùn-ún. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ọ́ yìí ni ó wà ní Pakísítáánì (Pakistan) ní Bàlúṣísítáànì (Baluchistan). Baluclistan yìí ni ìpínlẹ̀ (province) tí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn jùní pakcstan. Àwọn tí ó ń sọ èdè yìí ní Baluchistan tó múlíọ̀nù (Iran), Afuganíísítáànù (Afghanistan) àti In-índíà (India). Àkọtọ́ Lárúbáwá (Arabic) ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àjọ kan wà tí wọ́n ń pè ní Baluchi Academy tí ó ń ń sí pé àkọsílẹ̀ èdè yìí páye.
20231101.yo_2738_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%E1%BB%8Dn%20%C3%A8d%C3%A8%20Balto-S%C3%ADl%C3%A0f%C3%B9
Àwọn èdè Balto-Sílàfù
Ẹgbẹ́ àwọn èdè tí wọ́n ní Baltic ati Slavic ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n wá ń pe àwọn méjèèjì papọ̀ ní Balto-Slavic. Ọmọ ẹgbẹ́ ni àwọn èdè wọ̀nyí jẹ́ fún àwọn ẹ̀yà èdè (branch) tí a ń pè ní Indo-European (In-indo-Yùrópíànù). Àwọn tí ó ń sọ Baluto-Sìláfíìkì yìí tí mílíọ̀nù lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn (300 million people). Eléyìí tí ó ju ìlàjì lọ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni ó ń sọ èdè Rọ́síà (Russian)
20231101.yo_2738_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%E1%BB%8Dn%20%C3%A8d%C3%A8%20Balto-S%C3%ADl%C3%A0f%C3%B9
Àwọn èdè Balto-Sílàfù
Èdè àìyedè díẹ̀ wà lórí pé bíyá ibi kan náà ni gbogbo àwọn èdè yìí ti ṣẹ̀ tàbí pé nítorí pé wọ́n jọ wà pọ̀ tí wọ́n sì jọ ń ṣe pọ̀ ló jẹ́ kí ìjọra wà láàrin wọn.
20231101.yo_2739_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asamiisi
Asamiisi
Ara ẹgbẹ́ ti ìlà-oòrùn àwọn èdè Indo-Aryan (Indo-Aryan languages ni Assamese. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ to mílíọ̀nù mẹ́rìnlá àbọ̀ (14.5 million). Orílẹ̀-èdè Asam ni wọ́n ti ń sọ èdè yìí jù. Ìlà-oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè India ni Asam wà. Àwọn tí ó ń sọ èdè Assamese yìí tún wà ní Bhutan àti Bangladesh. Àkọtọ́ Bengah ni wọ́n fi ń kọ Assamese sílẹ̀. Ìbátan sì ni òun àti èdè Bengah:
20231101.yo_2740_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Arm%C3%A9n%C3%AD%C3%A0
Èdè Arméníà
Èdè Arméníà jẹ́ ọ̀kan lára èdè Indo-European (Indo-Ùrópóàànù) kan ni eléyìí. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíònù méje. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ ní orílẹ̀-èdè Armenia jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (3.6 million). Wọ́n tún ń sọ ọ́ ní Turkish Armenia. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní Europe (Úróòpù), Àmẹ́ríkà (USA) àti ààrin gbungbun ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East) náà ń sọ èdè náà.
20231101.yo_2740_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Arm%C3%A9n%C3%AD%C3%A0
Èdè Arméníà
Èdè Armenia àtijọ́ (Classical Armenian tí wọ́n ń pè ní Grabar ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ lítíréṣọ̀ sílẹ̀ ní gbogbo àgbáyé. Wọ́n kọ ọ́ ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì karùn-ún lẹ́yìn ikú Jésù Kírísítì Èdè Grabar yìí ni wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí èdè ẹ̀sìn fún àwọn ijọ ilẹ̀ Armenia òde òní,
20231101.yo_2740_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Arm%C3%A9n%C3%AD%C3%A0
Èdè Arméníà
Lẹ́tà álúfábẹ́ẹ̀tì méjìdínlógòjì ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀. St Mesrop ni ó ṣẹ̀dá álúfábẹ́ẹ̀tì yìí.
20231101.yo_2740_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20Arm%C3%A9n%C3%AD%C3%A0
Èdè Arméníà
Oríṣìí méjì ni ẹ̀yà èdè yìí ni ayé òde òní. Ọ̀kan nit i apá Ìlà oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní, ìpínlẹ̀ Yeravan. Òun ni wọ́n ń lò ní orílẹ̀-èdè Armenia. Èkejì nit i Ìwọ̀-oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Islanbul. Eléyìí ni wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Turkey.
20231101.yo_2741_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Arm%C3%A9n%C3%AD%C3%A0
Arméníà
Arméníà (; , siso Hayastan, ), fún iṣẹ́ọba bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Arméníà (Հայաստանի Հանրապետություն, Hayastani Hanrapetut’yun, ), je orile-ede oke-ile ti ile yika ni agbegbe Kafkasu ni Eurasia. O budo si oritameta Apaiwoorun Asia ati Apailaorun Europe, o ni bode mo Turki ni iwoorun, Georgia ni ariwa, de facto Nagorno-Karabakh Republic alominira ati Azerbaijan ni ilaorun, ati Iran ati ile Azerbaijani Nakhchivan ni guusu.
20231101.yo_2742_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Arg%E1%BA%B9nt%C3%ADn%C3%A0
Argẹntínà
Argẹntínà Nínú ètò ìkànìyàn 1995, iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà (Argentiana) lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógójì àti àti ààbọ̀ (46 245 668). Èdè Pànyán-àn ni èdè tí wọ́n fi ń ṣe ìjọba ní ibẹ̀. Àwọn èdè mìíràn tí wọ́n tún ń sọ ní orílè-èdè yìí lé ní ogún. Lára àwọn ogún èdè yìí ni àwọn èdẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Àmẹ́rídíánà (Ameridian Languages) wà. Ara àwọn èdè.
20231101.yo_2742_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Arg%E1%BA%B9nt%C3%ADn%C3%A0
Argẹntínà
Àwọn èdè tí ó tún wà lára ogún yìí ni èdè tí àwọn tí ó wá se àtìpó ń sọ. Lára wọn ni èdè Ítílì (Ìtahàn) àti Jámánì (Herman). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbilẹ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè fún òwò àgbáyé àti èdè àwọn tí ó ń ṣe àbẹ̀wò wá sí ibẹ̀ (International trade and tourism). Wọ́n ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí pẹ̀lú èdè Pànyán-àn.
20231101.yo_2743_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20%C3%81r%C3%A1m%C3%A1%C3%ACk%C3%AC
Èdè Árámáìkì
Èdè Árámáìkì je ara èdè Sèmítíìkì (Semitic). Àwon tí ó ń so èdè yìí tó egbèrún lónà igba ní Ìráànù (Iran) àti Ìráàkì (Iraq) pèlú òpòlopò àwon mìíràn tí wón tún ń so ó ní Ààrin gbùngbùn ìlà-òòrùn àgbáyé (Middle tast). Láti séńtúrì kefà ni wón ti ń fi Árámáìkì àtijó (Classical Aramaic) ko nnkan sílè ní Ààrin gbingbein ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East). Hébéérù ni ó wá gba ipò rè gégé bí èdè tí àwon júù ń so.
20231101.yo_2743_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20%C3%81r%C3%A1m%C3%A1%C3%ACk%C3%AC
Èdè Árámáìkì
Èka-èdè ìwò-oòrùn èdè yìí (Western dialect) ni èdè tí Jéésù Kristì àti àwon omo èyìn rè ń so. Èka-èdè kán tí ó wá láti ara èka-èdè yìí ni wón sì ń so ní àwon abúlé kan ní ilè Síríà àti Lébánóònù.
20231101.yo_2743_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20%C3%81r%C3%A1m%C3%A1%C3%ACk%C3%AC
Èdè Árámáìkì
Ní nnkan bíi séńtúrì kéje ni èdè Lárúbáwá gba ipò èdè Árámáìkì. Èka-èdè apá ìwo-oòrùn èdè yìí tí a ń pè ní Síríàkì (Syricac) ni àwon ìjo Àgùdà ará fíríàkì (Syriac Catholic) ń lò.
20231101.yo_2743_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20%C3%81r%C3%A1m%C3%A1%C3%ACk%C3%AC
Èdè Árámáìkì
Álúfábéètì méjìlélógún ni èdè yìí ní. Èdè yìí sì se pàtàkì nítorí pé láti ara rè ni Hébéérù, Lárúbáwá àti àwon èdè mìíràn ti dìde.
20231101.yo_2745_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20L%C3%A1r%C3%BAb%C3%A1w%C3%A1
Èdè Lárúbáwá
Ara èdè Sẹ̀mítíìkì ni èdè Àrábíìkì (Arabic (Èdè Lárúbááwá)). Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíọ̀nù lọ́nà igba gẹ́gẹ́ bí èdè abíníbí ní àríwá Aáfíríkà àti ìlà-oòrùn-gúsù Eésíà (Asia). Àìmoye ènìyàn tí a kò lè fi ojú da iye wọn ni ó ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì, ìyẹn èdè àkọ́kún-tẹni ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀sìn Mùsùlùmú ti gbilẹ̀. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní pàtàkì ní ilẹ̀ faransé náà máa ń sọ èdè yìí.
20231101.yo_2745_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20L%C3%A1r%C3%BAb%C3%A1w%C3%A1
Èdè Lárúbáwá
Ibi tí àwọn tí ó ń sọ èdè yìí pọ̀ sí ju ni Algeria, Egypt, Iraq, Morocco, Saudi Arabia, Sudan, Syria, Tunisia àti Yeman. Àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ kan wà tí ó jẹ́ ti apá ìwọ̀-oòrùn tí àwọn kan sì jẹ́ ti ìlà-oòrùn. Èdè tí a fi kọ kọ̀ráànù sílẹ̀ ni a ń pè ní ‘Classical’ tàbí ‘Literary Arabic’. Èdè mímọ́ ni gbogbo mùsùlùmú àgbáyé tí ó tó ẹgbẹ̀rún ó lé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ní àgbáyé (1, 100 million) nínú ètò ìkànìyàn 1995 ni ó mọ èdè ‘Classical Arabic’ yìí.
20231101.yo_2745_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20L%C3%A1r%C3%BAb%C3%A1w%C3%A1
Èdè Lárúbáwá
Olórí ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá wà tí ó sún mọ́ èyí tí wọ́n fi kọ Kọ̀ráànù. Eléyìí ni wọ́n fi ń kọ nǹkan sílẹ̀. Òun náà ni wọ́n sì máa ń lo dípò àwọn ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ẹ̀ka-èdè lárúbáwá yìí ni wọ́n kò gbọ́ ara wọn ní àgbóyé.
20231101.yo_2745_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20L%C3%A1r%C3%BAb%C3%A1w%C3%A1
Èdè Lárúbáwá
Méjìdínlọ́gbọ̀n ni àwọn álúfábẹ́ẹ̀tì èdè Lárúbááwá. Apé ọ̀tún ni wọ́n ti fi ń kọ̀wé wá sí apá òsù Yàtọ̀ sí álúfásẹ́ẹ̀tì ti Rómáànù, ti Lárúbáwá ni àwọn ènìyàn tún ń lò jù ní àgbáyé. A ti rí àpẹẹrẹ pé láti nǹkan bíi sẹ́ńtérì kẹ́ta ni a ti ń fi èdè Lárúbáwá kọ nǹkan sílẹ̀. Nígbà tí ẹ̀sìn mu`sùlùmí dé ní sẹ́ńtúrì kéje ni òkọsílẹ̀ èdè yìí wá gbájúgbajà. Wọ́n tún wá jí sí ètò ìkọsílè èdè yìí gan-an ní séńtúrì kọ́kàndínlógún nígbà tí ìkọsílẹ̀ èdè yìí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. Ìwọ̀-oòrùn Úróòpù. Ní pele-ń-pele ni èdè yìí pín sí (ìyẹn ni pé eléyìí tí olówó ń sọ lè yàtọ̀ sí ti tálíkà tàbí kí ó jẹ́ pé eléyìí tí obìnrin ń lò lè yàtọ̀ sí ti ọkùnrin).
20231101.yo_2746_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%81nt%C3%ADg%C3%BA%C3%A0%20%C3%A0ti%20B%C3%A0rb%C3%BAd%C3%A0
Ántígúà àti Bàrbúdà
Ántígúà àti Bàrbúdà (; Spani fun "atijo" ati "onirungbon") je is a twin-orile-ede erekusu-meji larin Omi-okun Karibeani ati Okun Atlantiki. O ni erekusu meji ninla ti awon eniyan ungbe be, Ántígúà ati Bàrbúdà, pelu awon erekusu kekeke melo kan (bi awon Erekusu Great Bird, Green, Guinea, Long, Maiden ati York).
20231101.yo_2748_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80ng%C3%B3l%C3%A0
Àngólà
|native_name =República de Angola (Portuguese) Repubilika ya Ngola (Kikongo, Kimbundu, Umbundu)
20231101.yo_2748_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80ng%C3%B3l%C3%A0
Àngólà
|national_anthem = Angola Avante!<small>(Portuguese)''Rìnsó ÀngólàForward Angola!</small>
20231101.yo_2748_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80ng%C3%B3l%C3%A0
Àngólà
|ethnic_groups = 37% Ovimbundu25% Ambundu13% Bakongo22% ará Áfríkà míràn2% Mestiço1% ará Europe
20231101.yo_2748_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80ng%C3%B3l%C3%A0
Àngólà
}}Àngólà, lóníbiṣẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Àngólà''' (, ; Kikongo, Kimbundu, Umbundu: Repubilika ya Ngola), jẹ́ orílẹ̀-èdè kan ní apágúsù Áfríkà tó ní bodè mọ́ Namibia ní gúsù, Orílẹ̀-èdè Olómìnira Olóṣèlú ilẹ̀ Kóngò ní àríwá, àti Zambia ní ilàòrùn; ìwọ̀òrùn rẹ̀ bọ́ sí etí Òkun Atlántíkì. Luanda ni olúìlú rẹ̀. Ìgbèríko òde Kàbíndà ní bodè mọ́ Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Kóngò àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira Olóṣèlú ilẹ̀ Kóngò.
20231101.yo_2748_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80ng%C3%B3l%C3%A0
Àngólà
Àngólà di ileamusin Portugal ni 1884 leyin Ipade Berlin. O gba ilominira ni odun 1975 leyin ogun itusile. Ko pe leyin ilominira ni ogun abele sele lati 1975 de 2002. Àngólà ni opo alumoni ati petroliomu, be sini okowo re ti ungbera soke pelu iwon eyoika meji lati odun 1990, agaga lateyin igba ti ogun abele wa sopin. Sibesibe opagun ijaye si kere gidigidi fun opo alabugbe, be sini ojo ori ati iye ọ̀fọ̀ ọmọwọ́ ni Angola je awon eyi to buru julo lagbaye.
20231101.yo_2749_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80nd%C3%B3r%C3%A0
Àndórà
Àndórà tabi fun iseoba o je Ilẹ̀-Ọmọba Andorra, bakanna won tun mo si Ilẹ̀-Ọmọba àwọn Àfonífojì ilẹ̀ Àndórà (Principality of the Valleys of Andorra) je orílẹ̀-èdè aláfilẹ̀yíká ni apa guusuiwoorun Europe.
20231101.yo_2749_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80nd%C3%B3r%C3%A0
Àndórà
Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn tí ó ń gbé Àndórà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì-dún-láàádọrin (68,000). Àwọn èdè tí ó jẹ́ ti ìjọba níbẹ̀ ni Kàtáláànù tí ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ń sọ (60%) àti èdè faransé. Wọ́n tún ń sọ Kàsìtílíànù ti àwọn Pànyán-àn-àn gan-an fún òwò àgbáyé àti láti fi bá àwọn tí ó bá wá yẹ ìlú wọn wo sọ̀rọ̀ .
20231101.yo_2751_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Am%C3%B3r%C3%A1%C3%ACt%C3%AC
Amóráìtì
''Amorite'' je Èdè Sẹ̀mítíìkì (Semitic) kan ni Amóráìtì (Amorite) tí wọ́n ń sọ ní agbègbè àríwá Síríà (Syria) òde òní ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sí ẹgbẹ̀rún kan àbọ̀ ṣáájú ìbí Kírísítì. Díẹ̀ ni a mọ̀ nípa èdè yìí nítorí pé láti inú orúkọ ènìyàn àti àwọn àkọ́sílẹ̀ díẹ̀ tí a rí tí wọ́n opẹ́ sí ara òkúta nìkan ni a mọ̀ nípa èdè yìí
20231101.yo_2752_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8%20%C3%80mh%C3%A1r%C3%ADk%C3%AC
Èdè Àmháríkì
Amhariki Èdè Sẹ̀mítíìkì (Semitic) kan ni eléyìí tí nǹkan bú mílíọ̀nu márùndínlógún ń sọ gẹ́gẹ́ bí èdè àkọ́kọ́ ní Ethopia (ìtópíà). Níbẹ̀, wọ́n ń lò ó gẹ́gẹ́ bí tí ìjọba ń mú lò. Àwọn bú mílíọ̀nù márùn-ún ni ó ń sọ èdè yìí ní agbègbè Ethiopia nígbà tí ̣ àwọn ọ̀pọ̀lọpò mílíọ̀nù mìíràn ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì àkọ́kúntẹnu ní Ethiopia àti Sudan (Sùdáànù). Láti nǹkan bíi sẹ́ńtúrì kẹrìnlá (14th Century) ni èdè yìí ti ní àkọsílẹ̀. Àkọtọ́ Amharic ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àkọtọ́ yìí ní Kóńsónáǹtì mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ẹ̀dà méjeméje. Ẹ̀dà kóńsónáǹtì tí ènìyàn yóò mú lò dúró lóró fáwẹ̀lì tí kóńsónáǹtì náà yóò bá jẹ yọ. Àbá ti ń wáyé nípa pé kí àtúnṣe wà fún àkọtọ́ yìí. Àwọn kan sì ti kóra wọn jọ fún ìpolongo láti sọ èdè yìí di àjùmọ̀lò (Standardisc).
20231101.yo_2753_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80ng%C3%BA%C3%ADll%C3%A0
Àngúíllà
Anguilla Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn ènìyàn tó wa ní Anguilla jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje àti ọgọ́rùn-ún (7,100). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń sọ níbẹ̀. Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni wọ́n ń sọ èdè Kirió tí wọ́n gbé ka èdè Gẹ̀ẹ́sì (English based Creole). Kirió yìí ni ó wọ́pọ̀ jù ní Áńtílẹ́ẹ̀sì (Lesser Antilles)
20231101.yo_2780_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Olódùmarè
Olódùmarè Káàkìri àgbáyé ni a ti mò pé olódùmarè wà, eni tí ó dá ayé àti òrùn àti ohun gbogbo ti ń be nínú won òyígíyigí oba àìrí arínú-róde Olùmòràn Òkàn, alèwílèse, alèselèwí, Oba atélè bí eni téní, Oba atésánmo bí eni téso, Oba lónìí, Oba lóla, Oba títí ayé àìnípèkun, Olówó gbogbogbo tí ń yomo rè nínú òfin, Oba Olójú lu kára bí ajere, Oba onínú fúnfún àti béè béè lo.
20231101.yo_2780_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Olódùmarè
Èyí ni pe oríkì Olódùmarè pọ̀ lọ jáǹtìrẹrẹ, bí a bá sì gbọ́ tí àwọn Yorùbá bá sọ pé ‘orí mi o tàbí olọ́jọ́ ọ̀ní o, Olódùmarè ni wọ́n ń pè ní orí, èyí tí ó dúró fún ẹlẹda orí àti ọlọ́jọ́ òní tí ó dúró fún ẹ̀ni tí ó nì ọjọ́ òní. Tàbí nígbà mìíràn tí àwọn Yorùbá bá rí Ohun tí ó ya ni lẹ́nu wọn á ní ‘Bàbá ò’ èyí tí ó dúró fún Olódùmarè.
20231101.yo_2780_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Olódùmarè
Àwọn ọmọ ènìyàn gbà wí pé ọlọ́run tóbi ju gbogbo ẹ̀dá lọ ó sì jẹ ẹni tí wọ́n gbọ́dọ̀ má a bọlá fún, èrò ọkàn àwọn Yorùbá ni pé ọlọ́run tàbí olódùmarè tóbi púpọ̀, ó sì ju ẹnikẹ́ni lọ àti nítorí èyí kò yẹ kí wọ́n máa dárúko mọ́ ọ lórí bí wọ́n ti ń ṣe sí ẹgbẹ́ àti ọ̀gbà wọn, láti bu ọlá fún-un àti láti fi ìtẹríba wọn hàn fún un wọ́n ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ pè é, wọn a ní ẹlẹda, èyí ní ẹni tí ó dá ọ̀run, àti ayé, òyígíyigì, èyí ni ẹni tí ó tóbi tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò sí ohun tí a lè fi wé. Ọba àwámárìdí, èyí ni ẹni tí a kò lè rí ìdí iṣẹ́ rẹ̀, Alábàláṣe, èyí ni ẹnì tí ó ni àbá àti àṣẹ, Bàbá, èyí ni baba gbogbo ẹ̀dá inú ayé, Ọ̀gá ògo; èyí ni ẹni tí ó ni ọ̀run èyí tí ó jẹ́ ògo ẹ̀dá tàbí nígbà mìíràn a lè túmọ̀ rẹ̀ sí ẹni tí ògo tàbí ìgbéga ẹ̀dá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, Atẹ́rẹrẹkáríaye, èyí ni ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní gbogbo ayé ní ìkáwọ́ rẹ̀, ẹlẹ́mìí, èyí ni ẹni tí ó ni ẹ̀mí ẹ̀dá.
20231101.yo_2780_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Olódùmarè
Bí a bá tún gbó nígbà mìíràn tí àwọn àgbàlagbà ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘Èdùàrè tàbí wọ́n ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘olú’ olódùmarè kan náà ni wọn ń tọ́ka sí. Àwọn àgbàlagbà a máa sọ pé:
20231101.yo_2780_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Olódùmarè
Ohun tí àkọlé yìí ń tọ́ka sí ni pé ohun tí ọmọ Èdùàrè, èyí tí ó dúró fún olódùmarè bá ti ṣe àṣegbé ni ìgbà gbogbo là ń gbọ́ tí àwọn àgbàlagbà máa ń sọ pé “ẹni olúwa dá kò ṣe é fara wé”. Ohun tí wọn ń tọ́ka sí nínú gbólóhùn yìí nip é ẹni tí Olú, èyí tí ó dúró fún olódùmarè “bá ti dá àyànmọ́ kan mọ́ ẹnìkan, a kò lè fara wé irú ẹ̀nìyàn bẹ́ẹ̀.
20231101.yo_2780_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Olódùmarè
Àwọn àkíyèsí tí a lè rí tọ́ka sí ni pé ọ̀pọ̀ ìtàn ìwásẹ̀ ni ó sọ bí Olódùmarè ṣe sẹ̀dá ayé àti ọ̀run, Yorùbá gbàgbọ́ pé ọ̀run ni olódùmarè wà, tí ó ti ń ṣe àkóso ayé àti ọ̀run, èrò Yorùbá ni pé kò sí ohun tí a ‘lè fi wé olódùmarè nítorí àwọn àwẹ̀mọ́ tàbí abuda rẹ tó tayọ àwa ẹ̀dá lọ fún àpẹẹrẹ a lè pe olódùmarè báyìí pé ‘Ẹlẹda, Ẹlẹ́mìí, Ọlọ́run Ọba ní í fọ́n èjí iwọ́rọ́ iwọ́rọ̣́, òun ló ni ọ̀sán àti òru dọ́jọ́ òní, òní ọmọ Ọlọ́fin, Ọ̀la ọmọ Ọlọ́fin, Ọ̀tunla ọmọ Ọlọ́fin, ìrènì ọmọ Ọlọ́fin, ọ̀rúnní ọmọ Ọlọ́fin, Yorùbá máa ń sọ pé ìṣẹ́ Ọlọ́run tóbi tàbí àwámárìdí ni iṣẹ́ Ọlọ́run, Ọ̀rúnmìlà fẹ̀yìntì ó wò títí o ní “ẹ̀yín èrò okun, ẹ̀yin èrò ọsa, ǹ jẹ́ ẹ̀yin ò mọ̀ pé iṣẹ́ Olódùmarè tóbi: A tún lè sọ pé Ọba Ọ̀run ọ̀gá Ògo, atẹ́rẹrẹ káyé ẹlẹ́ní àtẹ́ẹ̀ká, Ọba ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í yẹ̀, alábà láṣẹ̀ á tun le pe ni alágbára láyé àti lọ́run.
20231101.yo_2780_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Olódùmarè
Adùn ún ṣe bí ohun tí olódùmarè lọ́wọ́ sí, aṣòro o ṣe bí ohun tí olódùmarè kò lọ́wọ́ sí, Alèwílèṣe, Aṣèkanmákù. Ìgbà mìíràn a tún lè sọ pé ọlọ́run nìkan ló gbọ́n, ó rí ohun gbogbo, ó sì lè ṣe ohun gbogbo, Arínúróde Olùmọ̀ràn ọkan, Yorùbá sọ pé “Amòòkùn ṣolè bí Ọba ayé kò ri, Ọba ọ̀run ń wò ó, èyí túmọ̀ sí wí pé kò sí ohun tí a ṣe ní ìkọ̀kọ̀ tí Olódùmarè kò rí, kedere ni lójú Olódùmarè, àwọn òrìṣà ló máa ń jẹ àwọn arúfin ní ìyà ṣùgbọ́n Olódùmarè ló máa ń dájọ́ fún wọn, fún àpẹẹrẹ ní ìgbà kan gbogbo òrìṣa fẹ̀sùn kan ọ̀rúnmìlà níwájú olódùmarè lẹ́yin tí tọ̀tún tòsì wọ́n rojọ́ olódùmarè dá ọ̀rúnmìlà láre, odù ifá kan jẹri sí eléyìí, odù náà lọ báyìí “Ọ̀káńjùa kì í jẹ́ ka mọ nǹkan pínpín, Adíá fun odù. Mẹ́rìndín lógún níjọ́ ti wọn ń jìjà àgbà relé olódùmarè, nígbà tí àwọn ọmọ ìrúnmọlẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún tán ń jìjà ta ni ẹ̀gbọ́n ta ni àbúrò láàárin ara wọn, wọ́n kẹ́jọ́ lọ sódọ̀ olódùmarè, níkẹyìn, olódùmarè dá ẹjọ́ pé èjìogbè ni àgbà fún àwọn odù yókù. Yorùbá gbàgbọ pé onídàjọ́ òdodo ni olódumarè, ìdí nìyí tí Yorùbá fi ń sọ pé ọlọ́run mú u tàbí ó wà lábẹ́ pàṣán ‘Olódùmarè. Òyígíyigì ọba Ọta àìkú fẹ̀rẹ̀kufẹ̀, a kì í gbọ́kú Olódùmarè.
20231101.yo_2780_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Olódùmarè
Tí a bá tún wo Ọ̀kànrànsá (odù ìfa) òun náà tún sọ pe olódùmarè kì í ku, fún àpẹẹrẹ, Odù ọ̀kànrànsá yìí sọ pé:
20231101.yo_2780_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ol%C3%B3d%C3%B9mar%C3%A8
Olódùmarè
Olódùmarè náà ni Ọba àìrí, àwámárìdí Yorùbá tún gbà pé ó jẹ Ọba mímọ́ tí kò léèérí, alálà funfun òkè. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé bí àwọn áńgẹ́lì tí jẹ́ Olùrànláwọ́ fún Olódùmarè lóde ọ̀run ni àwọn òrìṣà náà jẹ́ aṣojú rẹ̀ lóde ìṣálayé, àwọn òrìṣà wọ̀nyí jẹ́ alágbàwí àwọn ènìyàn níwájú olódùmarè. A gbọ́ wí pé ìbáṣepọ̀ wà láàárin àwọn òrìṣà tàbí òòṣà ilẹ̀ Yorùbá àti Olódùmarè, àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pe òòṣà wọ̀nyí nì wọ́n lè rán sí olódùmarè yálà láti tọrọ nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀ tàbí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ohun ribiribi tí ó ṣe fún wọn. Erò yìí hàn nínú òwe Yorùbá kan pé “ẹni mojú ọwá là ń bẹ̀ sọ́wá, olójú ọwá kan kò sí bíkòṣe ayaba”. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ pé bí a bá fẹ́ kí Ọba ṣe ohun kan fún ni a ó bẹ ayaba sí i, ipò alágbàwí láàárin àwọn abòòṣà àti olódùmarè ni àwọn òòṣà wà.
20231101.yo_2782_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Ẹbí èdè Khoisan yìí ni ó kéré jù lọ nínú àwọn ẹbí èdè gbogbo tí ó wà ní Áfíríkà. Gẹ́gẹ́ bí Greenberg (1963a) ti sọ, ó ní àwọn ni wọ́n dúró fún èyí tí ó kéré jù lọ nínú èdè Áfíríkà.
20231101.yo_2782_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
A mu orúkọ yìí jáde láti ara orúkọ ẹgbẹ́ Khoi-Khoi ti Gusu ilẹ Afirikà (South Africa) àti ẹgbẹ́ san (Bushmen) ti Namibia. A máa ń lo orúkọ yìí fún Oríṣìíríṣìí àwọn ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ pé àwọn gan-an ni wọ́n kọ́kọ́ jẹ́ olùgbé ilẹ̀ south Africa kí awọn Bantu tó wá, kí àwọn òyìnbó ilẹ̀ Gẹẹsi (Europe) sì tó kó wọn lẹ́rù.
20231101.yo_2782_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Oríṣìíríṣìí àwọn onímọ̀ ni wọn ti siṣẹ lórí orúkọ yìí – Khoisan.Tan Gùldemann ati Rainer Vossen ṣàlàyé nínú iṣẹ́ rẹ̀ pé Leonardt Schulze 1928 ni o mu orúkọ yìí jáde láti ara Hottentot’ tí o túmọ̀ sí Khoi ti o sì tún túmọ̀ sí ‘person’ (ènìyàn) àti ‘san’ tí ó túmọ̀ sí ‘forager’. Lẹ́yìn èyí ni onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá àṣà, ìgbàgbọ́ àti ìdàgbàsókè ọmọnìyàn, anthropologist Schapera (1930) tún wá fẹ̀ orúkọ yìí lòjù sẹ́yìn nípasẹ̀ ‘Hottentot’àti ‘Bushman’ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà, (racia) àṣà (cultural) àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè. (Linguistic).
20231101.yo_2782_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Àwọn orúmọ̀ mìíràn tí wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kẹta ti wọ́n tún siṣẹ́ lé orúkọ yìí lórí ni Kolnler (1975, 1981) sands (1998) àti Traill (1980, 1986). Wọn pinnu láti lo orúkọ náà Khoisan gẹ́gẹ́ bí olúborí fún àwọn èdè tí kìí ṣe ti Bantù tí kì í sì í ṣe èdè Cushitic.
20231101.yo_2782_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Àwọn onímọ̀ akíọ́lọ́jì fi han wí pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fa ọdún sẹ́yìn ni awọn ènìyàn Khoisan ti fara hàn. Èyí fi han pé lọ́dọ̀ àwọn àgbà láèláè nìkan ni a ti lè máa gbọ́ èdè Khoisan nìkan báyìí.
20231101.yo_2782_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Bí èdè Khoisan tilẹ̀ farajọra nínú ètò ìró, gírámà tirẹ̀ yàtọ̀ gédégbé. Àìsí àkọ́sìlẹ̀ ìtàn àwọn èdè wọ̀nyí mú kí o nira díẹ̀ láti sọ ìfarajọra awọn èdè yìí sí ara àti sí àwọn èdè adúláwọ̀ tí ó kù.
20231101.yo_2782_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Lóde àní, Ilẹ̀ (South Western Africa) gúsu-ìwọ̀ òòrùn Áfíríkà títí dé àginjù kàlàhárì (Kalaharì Desert), láti Angola de South Africa àti ní apákan ilẹ̀ Tanzania nìkan ní wọ́n ti ń sọ èdè Khoisan. Edè Hadza àti Sandawe ní ilẹ̀ Tanzania ni a sáábà máa ń pè ní Khoisan ṣúgbọ̀n wọ́n yàtọ̀ nípa ibùgbé àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè sí ara wọn. A wá lè sọ pé nínú gbogbo èdè àgbáyé, èdè Khoisan wà lára àwọn èdè tí àwọn onímọ́ èdè kò kọbiara sí tí a kò sì kọ́ ẹ̀kọ́ nípa rẹ̀.
20231101.yo_2782_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Èdè Khoisan yìí gẹ́gẹ́ bí a ti sọ síwájú ń dín kù síi lójoojúmọ́ ni. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ń di ohun ìgbàgbé. Ohun tí ó fa èyí ni pé àwọn tí wọ́n ń sọ àmúlùmálà èdè Khoisan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè mìíràn tí ó gbilẹ̀ ní agbègbè wọn; wọ́n sì dẹ́kun kíkọ́ àwọn ọmọ wọn ní èdè abínibí wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn èdè wọ̀nyí ni kò ní àkọ́silẹ̀ kankan tí ó sì fíhàn pé sísọnù tí àwọn èdè wọ̀nyí sọnù, kò lè ní àtúnṣe.
20231101.yo_2782_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Ó jẹ́ ohun tí ó nira díẹ̀ láti sọ pé iye àwọn ènìyàn kan pàtó ni wọ́n ń sọ èdè Khoisan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí àwọn Òyìnbó tó gòkè bọ̀, a kò sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo àkókò tí àwọn Òyìnbó ń ṣètò ìjọba, bẹ́ẹ̀ sì tún ni pé ìwọ̀nba la lè sọ mọ nípa ohun ti ó ń ṣẹlẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àkọsílẹ̀ fi hàn pé, ní bíì ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, iye nọ́nbà tí wọ́n kọ sílẹ̀ kò ṣeé tẹ̀lé mọ́; àkọsílẹ̀ sọ wí pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà Igba (120,000 – 200,000) ni wọn, ṣùgbọ́n èyí ti di ohun àfìsẹ́yìn bí eégún fí aṣọ. Wọn kò tó bẹ́ẹ̀ mọ́.
20231101.yo_2782_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Àwọn èdè Khoisan kò ṣàì ní ìfarajọra nínú ètò ìrò. Ó dá yàtọ̀ gédégbè sí àwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà yòókù, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè tí ó nira.
20231101.yo_2782_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Ọ̀pọ̀ àwọn èdè Khoisan wònyí ni ó ń lo fáwẹ́lì márùn ún - /i/, /e/, /a/, /o/, /u/ tí a sì lè pè pẹ̀lú àwọn oríṣìí àbùdá wọ̀nyìí bíi, ìránmú, (nasalization) ìfi káà-ọ̀fun-pè (pharyngealization) ati oríṣìí àmúyẹ ohùn bíi mímí ohun (breathy voice) ati dídún ohùn (Creaky voice) tí yóò sì mú bí i oríṣìí ìró fáwẹ́lì bí i ogójì jáde.
20231101.yo_2782_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Kílíìkì ni a ń pe àwọn kọ́ńsónáǹtì wọn; títí kan àwọn àfeyínpè (dential), àfèrìgìpè, (alveolar), afàjàfèrìgìpè (alveo-palatal), afẹ̀gbẹ́-ẹnu-pè (lateral) àti kílíìkì afètèpè (bilabial Chick). Sandawe àti àwọn Hadza tí ilẹ̀ Tanzania ń lo àfeyínpè (dental ) afèrìgìpè (alveolar) àti kílíìkì afẹ̀gbé-ẹnu-pè (lateral clicks). Pẹ̀lú gbogbo àhesọ ọ̀rọ̀ títí di àkókò yìí orísun kílíìkì èdè Khoisan kò tíì yéni.
20231101.yo_2782_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
- Kílíìkì Afèrìgìpè – Ó máa ń dún bí ìgbà tí a bá ṣí ìdérí ìgò nípa gbígbé ahọ́n sí ẹ̀yìn eyín iwájú.
20231101.yo_2782_13
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
- Kílíìkì Afètépè máa ń dún nípa kíkanra ètè méjèèjì, tí a sì tún sí i sílẹ̀ ní kíá, gẹ́gẹ́ bí ìró ìfẹnukonu ni èyí ṣe máa ń dún.
20231101.yo_2782_14
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kílíìkì wọ̀nyí ló lè ní Kíkùnyùn-ùn, (Voicing) ríránmú (nasality), “aspiration” ati “ejection”. Láti le mú kí á ní àgbéjáde oríṣìíríṣìí kílíìkì. Àwọn orísìíríṣìí kílíìkì wọnyi ló mú kí èdè Khoisan yàtọ̀. Àpẹẹrẹ nínú èdè Nama, Ogún ni kílíìkì tí wọ́n ń lò nígbà tí wọ́n n lo mẹ́tàlélógọ́rin nínú ède Kxoe tí ó jẹ́ ọ̀kan lára èdè Khoisan. Ní àfíkún, àádọ́rùn-ún ònírúrú kóńsónáǹtì kílíìkì ni wọ́n n lo ni Gwi tí òhun náà jẹ́ ọ̀kan lára èdè Khosian wọ̀nyí. Àpẹẹrẹ Kílíìki Nama
20231101.yo_2782_15
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Gbogbo àwọn kóńsónáǹtì Kílíìkì àti èyí tí kìí ṣe kílíìkì ló máa ń fara hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tí fáwẹ́lì sì máa ń tẹ̀lé e. Ìwọ̀nba kóńsónáǹtì bí àpẹẹrẹ /b/, /m/, /n/, /r/, àti /l/ ló lè jẹ yọ láàrín fáwẹ́lì, díẹ̀ sì lè farahàn ní ẹ̀yìn ọ̀rọ̀.
20231101.yo_2782_16
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Àwọn èdè Khosan máa ń sàfihàn oríṣìíríṣìí ìró ohùn, bí àpẹẹrẹ, Jul’hoan ní ipele ohun àárún oríṣìí mẹ́rùn, ó sì ní ipele ohun òkè kan.
20231101.yo_2782_17
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Ìsọ̀rí mẹ́ta ni ọ̀rọ̀ arúkọ Khoisan pín sí; bí a bá wòó, nípasẹ̀ jẹnda, akọ, abo àti àjọni ni ò pín sí. Nínú Kxoe, fún àpẹẹrẹ, jẹ́ńdà nínú ọ̀rọ̀-orúkọ aláìlẹ́mìí tún máa ń ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìríṣí, bi àpẹẹrẹ, akọ ní í ṣe pẹ̀lú gígùn, tí tò si tóbi, nígbà tí abo ní í ṣe pẹ̀lú nǹken kúkúrú, gbígbòòrò tí kó sì tóbi òríṣìíríṣìí mọ́fíímù ni wọ́n fi ń parí òkọ̀ọ̀kan àwọn jẹ́ńdà wọ̀nyí.
20231101.yo_2782_18
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Àbùdá gírámà tí ó sáábà máa ń jẹ yọ nínú àwọn èdè Khoisan ni lílo ọ̀rọ̀-iṣe àkànmónúkọ (verb compound) nígbà tí èdè Gẹ̀ẹ́sì ń lo ọ̀rọ̀ atọ́kùn tàbí ọ̀rọ̀-iṣe kan (single verb) Àpẹẹrẹ
20231101.yo_2782_19
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Ẹ̀rún ni a máa ń lò láti fi àsìko hàn nínú èdè KhoeKhoe àti nípa lílo àfòrò ẹyin nínú ede Kxoe, Buga ati //Ani Ninú àwọn èdè Kalahari East Kxoe, Àfòmọ́ ẹ̀yìn ló ń fi ìṣẹ̀lẹ̀ ti o ti Koja hàn (Past Tense), ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ tí ó lòdì ati jẹ̀rọ́ndì hàn nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ti ọjọ́ iwájú ń lo Ẹ̀rún. Bẹ́ẹ̀ náà lọmọ́ sorí nínú èdè Naro, G//ana, G/ui àti ‡Haba.
20231101.yo_2782_20
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Mana nìkan ni ó ń lo ibá ìṣẹ̀lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìṣẹ̀dá (Morphological Category) ó sì ya ibá ìṣẹ̀lẹ̀ aṣetán sọ́tọ̀ sí àìṣetán
20231101.yo_2782_21
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Ẹ̀rún tàbí àfòmọ́ ẹ̀yìn ni wọn n lo fún ìyísódì (Khoekhoe tam; G//ana G/ui àti ‡Haba tàmátema) n lò ẹ̀rún fún ìyísódì nígbà tí (kxoe //Am. Buya-bé) n lo afọmọ ẹyin, nígbà mìíràn wọ́n n lo méjèèjì.
20231101.yo_2782_22
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Ètò ọ̀rọ̀ tí àwọn èdè Khoisan ti à ń sọ wọ̀nyí máa ń lò ni (Svo-Subject-Verb-Object) Olùwà ọ̀rọ̀-ìṣe àti àbọ̀ tàbí (Sov-Suject-Object-verb).
20231101.yo_2782_23
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Àfihàn ìgbésí ayé àwọn olùṣọ èdè Khoisan ni ọ̀rọ̀-èdè (Vocabulary) wọn jẹ́. Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn olùṣọ èdè wọ̀nyí ń gbé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀dá mìírà, èyí mú kí wọ́n ní àwọn ọ̀rọ̀-èdè tí ó súnmọ́ ọdẹ ṣíṣe, ẹranko, Kóríko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
20231101.yo_2782_24
https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu
Koisaanu
Ọ̀pọ̀ àwọn èdè wọ̀nyí ni kò ni àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n Nama ati Naro ni àkọsílẹ̀ àti ohun èlò ìkọ́ni. Nama ní pàtàkì ti wà ní àkọsílẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.
20231101.yo_2812_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilorin
Ilorin
Ilorin ni olu-ilu Ìpínlẹ̀ Kwara ní ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà. Gégé bi abayori ìkà ènìyàn odun 2006 ní Nàìjíríà, ìlú Ilorin ní olùgbé 777,667, èyí mú kí ó jẹ́ ìlú keje tí ó ní olùgbé jùlo ní Nàìjíríà.
20231101.yo_2813_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/Kazimierz%20Nowak
Kazimierz Nowak
Kazimierzu Nowaki (lati Ọdún 1897 títí di Osu Òwàrà Ọjọ kétàlá Ọdún 1937 je ọmọ Ìuí Polandi ti Ọjẹ arińninajo Oníweroým ati aya woran ti a bi ni ilu Stiryi.
20231101.yo_2813_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/Kazimierz%20Nowak
Kazimierz Nowak
Lehin Ogun àgbáyé alakọkọ ogbe ni ilu Poznani lati ọdún 1931 títí di ọdún 1936 Orin, ogun kẹkẹ jake jado ilu Aláẁọ dúdú. Orin irinajo ti oto egberun lọ́na ogoji kilomita (40.000 km). Owun ni eni akọkọ ti okọkọ ṣẹ́iru nkan bayi.
20231101.yo_2813_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/Kazimierz%20Nowak
Kazimierz Nowak
O ti kọ iṣẹ yi si inu iwe ti a pe orukọ rẹ ni Rowerem i pieszo przez Czarny Ląd (Kẹkẹ ati ẹsẹ jake jado ilẹ aláẁọ dúdú).
20231101.yo_2821_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/L%C3%ADt%C3%ADr%C3%A9%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%80
Lítíréṣọ̀
Eléyìí náà kò ṣàì ní orírun tirẹ̀ láti inú èdè Látìn “LITERE” Èyí ni àwọn gẹ́ẹ́sì yá wọ inú èdè wọn tí wọ́n ń pè ni lete rature”
20231101.yo_2821_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/L%C3%ADt%C3%ADr%C3%A9%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%80
Lítíréṣọ̀
Ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ máa ń yípadà láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yà ènìyàn kan sí èkejì láti ìgbà dé ìgbà. Lítíréṣọ̀ kò dúró sójú kan.
20231101.yo_2821_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/L%C3%ADt%C3%ADr%C3%A9%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%80
Lítíréṣọ̀
“Àkójọpọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ní èdè kan tàbí òmíràn tó jásí ewì, ìtàn àlọ́, ìyànjú, eré onítàn, ìròyìn àti eré akọ́nilọ́gbọ́n lórí ìtàgé”
20231101.yo_2821_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/L%C3%ADt%C3%ADr%C3%A9%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%80
Lítíréṣọ̀
Tí a bá wo òde òní, ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ tún yàtọ̀, fún àpẹẹrẹ a máa ń ṣàkíyèsí ìlò èdè tí wọ́n fi kọ ìwé kan yàtọ̀ sí èyí, a tún ka lítíréṣọ̀ kùn iṣẹ́ òǹkọ̀wé alátinúdá tàbí iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìlò ojú inú gẹ́gẹ́ bí ewì, ìtàn àròkọ àti eré oníṣe. A ó sì rí i pe awẹ́ tàbí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ tí a mẹ̀nubà wọ̀nyí kó púpọ̀ nínú ìmọ̀ ìgbé ẹ̀dá láwújọ (folklore) mọ́ ara, yálà, a kọ, ọ́ sílẹ̀, a rò ó sọ tàbí a ṣe é léré yàtọ̀ fún àwọn àkọọ́ lẹ̀ iṣẹ́ ọwọ́.
20231101.yo_2821_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/L%C3%ADt%C3%ADr%C3%A9%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%80
Lítíréṣọ̀
Lítírésọ̀ tún jẹ́ irúfẹ́ àkọọ́lẹ̀ tó ní àbùdá ẹ̀mí gígùn, ó máa ń fi ìṣẹ̀ṣe àti àṣà àgbáríjọ àwọn èèyàn kan hàn.
20231101.yo_2821_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/L%C3%ADt%C3%ADr%C3%A9%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%80
Lítíréṣọ̀
Kí òǹkọ̀wé kan tó lè se iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeyanjú, irúfẹ́ oǹkọ̀wé náà gbọ́dọ̀ ni àtinúdá àtinúdá yìí pẹ̀lú ohun gan-an tí ó ń ṣelẹ̀ láwùjọ ni yóò wá sọ di ọ̀kan nínú iṣẹ́ rẹ̀.
20231101.yo_2821_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/L%C3%ADt%C3%ADr%C3%A9%E1%B9%A3%E1%BB%8D%CC%80
Lítíréṣọ̀
Nípa yíyẹ lítíréṣọ̀ wò, à ní láti wo ẹ̀hun ìpìlẹ̀ ìtumọ̀, èyí ni wíwo gbogbo nǹkan tí ó wà láwùjọ yẹn olápapọ̀ láì dá ọ̀kan sí.
20231101.yo_2829_0
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ojúlówó àwọn ọmọ Yorùbá ni ilẹ̀ Yorùbá òde-òní ìjẹ̀sa jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ojúlówó ọmọ Yorùbá tí kò se fí ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìtàn àwọn Yorùbá. Oríìsíìsí ìtàn ni a sì gbọ́ nípa orírun Ìjẹ̀sà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó Yorùbá kó dà a ti lè gbọ́ wí pé olórí àwọn Ìjẹ̀sà jẹ òkan lára àwọn ọmọ méjèje tí Odùduwà bí.
20231101.yo_2829_1
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ni a gbọ́ nípa ìsẹ̀dálẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ó sì dàbí ẹni pé o sòro díẹ̀ láti sọ pe ọ̀kan ni fìdí múlẹ̀ jùlọ.
20231101.yo_2829_2
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Lára ìtàn tí a gbọ́ ni wí pé ó jẹ́ àsà fún àwọn ènìyàn jàkànjàkàn láti wá bá Ajíbógun ní ibùdó rẹ̀, àwọn ènìyàn wònyí ni à ń pè ní “Ìjọ tí a sà”. Ní ìtẹ̀síwájú, ìtàn sọ fún wa wí pé òjígírí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ò bá Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀. Òjígírí yìí kan náà ló jẹ́ ọwá sí ìlú Ìpólé. Bákanna ni ìtàn sọ pé òjígírí ló jẹ Ògbóni sí ìlú ti Ìjẹ̀bú-jẹ̀sà. A sì tún gbọ́ wí pé nígbà tí Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀, ilé-Ìdó ni o kọ́kọ́ dúró sí láti ilè Ìdó yi ló ti lọ sin òkú ọlọ́fin (Odùduwà) ní ilé-ifẹ̀, lẹ́yìn èyí ni a gbọ́ wí pé ìgbàdayé ni Ajíbógun padà sí, tí ó sì kú síbẹ̀. Ọ̀kà-òkìlè tí ó jẹ́ daodu fún Ajíbógun ni ó jẹ Ọwá sí ìlú- Ìlówá ti oun naa si sun ibẹ̀, bakanna ni Ọbarabara tí a mọ̀ sí Olokun. Esin ló je Ọwá sí Ìpólé. Ọwalusẹ ní ẹnití ó jẹ Ọwá àkọ́kọ́ sí ìlú Ilesà ti o nì.
20231101.yo_2829_3
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Bakanna ni a tún rí ìtàn míràn tó sọ fún wa nípa Ọwá Obòkun ti ilẹ̀-Ìjẹ̀sà wí pé nígbà tí Odùduwà tó n se bàbá fún (Ajíbógun) dàgbà ti ojú rẹ fọ̀ ni ifá Àgbọ̀níregùn ní kí wọn lo bu omi òkun wá kí ojú Odùduwà bàbá wọn lè là. Báyìí ní ó wá pe àwọn ọmọ rẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọkan èjèejì wí pé ki wọn lọ bu omi lókun wá fún ìtọ́jú ojú òhun, sùgbọ́n èyí Ọwá re ló gbà láti lọ bu omi òkun naa wá. Nígbà tí ó ń lọ bàbá rẹ fun ní idà tí á mọ̀ sí idà ìsẹ́gun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára, a gbọ́ wí pé nígbà tí o n lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro àti ìdàmú ló bá pàdé ni ojú ọ̀nà rẹ sùgbọ́n o sẹ́gun wọn pẹ̀lú idà ìsẹ́gun ọwọ́ rẹ, sùgbọ́n kí ó tó dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti sọ ìrètí nù èrò yìí ló mú kí bàbá rẹ gan-an pàápàá sọ ìrètí nù, èrò yìí ló mú kí bàbá pín gbogbo ogún àti àwọn ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ (Owá)
20231101.yo_2829_4
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ènìyàn àti bàbá wí pé ó lè padà dé mọ́. nígbà tí o dé wọn fi omi òkun fọ ojú bàbá wọn ó sì là padà, lẹ́yìn èyí ló wá bi bàbá lérè wí pé àwọn ẹ̀gbọ́n oun ń kọ́ bàbá sì sàlàyé fún pe ò ń rò pé kò lè padà wá sí ilé mọ́ àti wí pé ò ń ti pín gbogbo ogún fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Ajíbógun bínú gidi, ó wá bèèrè wí pé kí ni ogún ti oun báyìí, bàbá rẹ ni kò sí nkan-kan mọ́ àfi idà Ìsẹ́gun tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nìkan ló kù, inú bí Ajíbógun ó fa idà yọ láti fi ge bàbá rẹ̀, sùgbọ́n idà bá adé ò sí ge jọwọjọwọ ìwájú adé naa, lẹ́yìn èyí ní bàbá rẹ̀ gbé adé naa fún, nítorí pé ó se akin àti akíkanjú ènìyàn, sùgbọ́n bàbá rẹ sọ fun wí pé láti òní lọ kò gbọdọ̀ dé adé tí ó ní jọwọjọẁ létí mọ́, àti ìgbàyí ló ti di èwọ̀ fún gbogbo ọwá tí ó bá jẹ ni ILÉSÀ.
20231101.yo_2829_5
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Ìtàn míràn ni pé, lẹ́yìn ìgbàtí Ajíbógun ti parí isẹ́ ti bàbá ran tán ni o kúrò ni ilé-ifẹ̀ láti lọ se ìbẹ̀wò sí ìlú àwọn bàbá rẹ. lára àwọn ìlú tí Àjíbógun gba kọ já ni Osu àti àwọn ìlú míràn, a gbọ́ wí pé, Ọ̀kà-òkìle tí ó jẹ́ dáódù fúnAjíbógun ní ó jẹ Owari si ìlú Ìpólé tì wọn ń sì ń pé ni Owari. Ìtàn sọ fún wa wí pé Ìpólé yìí ní Ọ̀kà-òkìle jẹ Owa ti rẹ si sùgbọ́n oun àti àwọn ará ìlú ko gbọ ara wọn yé rárá nítorí agbára tí ó ní, sùgbọ́n o selẹ̀ wí pé ọ̀tẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀sì ni pọ̀ si láàrín àwọn ará ìlú pẹ̀lú ọba, ọ̀tẹ̀ yìí ló fa Ìjà tí ó pín ìlú sí méjì. lára àwọn tí ó kọ́ ara jọ ni wọ́n sọ gbólóhùn kan pé “Ìn jẹ́ asá” tí ó túmọ̀ sí pé “ Ẹjẹ́ ká sá “ èyí ní wọ́n yípadà sí Ìjẹ̀sà, àwọn wọ̀nyí ni wọn lo tẹ ìlú Ilésà gan-gan dó. Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ìlú Ilésà dó ni àwọn olóyè ti wọ́n kúrò ni ìlú Ìpólé pé ara wọn jọ pé ó yẹ kí àwọn ni ọba, wọ́n wa pa ìmọ̀ pọ̀ pé kí wọn lọ mú Ọwalusẹ ti se àbúrò Ọ̀kà-òkìle kí o jẹ́ ọba wọn, wọ́n se bẹ lọ́ọ̀tọ́ Owálusẹ si jẹ ọba àkọ́kọ́ ní ìlú Ilésà. Ìgbàtí tí Ọ̀kà-òkìle gbọ́ ní Ìpólé o ránsẹ́ sí Owalusẹ pé kí ó wá. Ọwálúsẹ̀ si se bẹ gẹ́gẹ́, ìgbàtí ó dé ọ̀dọ̀ Ọ̀kà-òkìle naa idà si etí Ọwálùsẹ̀, etí kàn si jábọ́, ìgbàtí Ọwálùsẹ padà sí Ilésà oun à ti Ọwá (Ọ̀kà-òkìle) kò rí ara wọ́n, àti ìgbàyí nì Oka- okule tí gẹ́gùn pé gbogbo ọdún tí wọ́n bá fẹ se ni ilésà wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ se ti Ìpólé títí di àsìkò yìí. Lẹ́yìn gbogbo rògbòdìyàn yìí ni Ọ̀kà-òkìle (Owá) pinu láti ba gbogbo ará Ìpólé se ìpàdé pọ̀, ohun tí o sẹ lẹ ni Ìpàdé ni pé Ọ̀kà-òkìle se àlàyé pé oun fẹ́ férakù láàrín wọn (fẹ́ kú) ó fún wọn ni osù mẹ́ta, lẹ́yìn osù kan ará ìlú lọ ba pé sé kò fẹ́ wo ilé mọ ilè mọ ni, sùgbọ́n ojú ti fẹ́ ma ti Owari nítorí òrọ̀ òhún ti di yẹ̀yẹ́ láàárín ìgboro.
20231101.yo_2829_6
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Ìgbà tí ó di ọjọ́ tí ó fẹ́ wọ ilẹ̀ ó jẹ́ àárín òru bí owari se wọ ilẹ̀ ni gbogbo ìgboro dàrú nítorí gbiri gbiri tí wọn gbọ́ wọ́n sáré kiri, kò pé ní àwọn kan ri tí wọn si fi ariwo bọ ẹnu pé owá ti rì ò, Owá ti rì ò, èyí ní wọn yí padà tí ó di Owárì. Àfin tí o rì ni à ń pè ní Ùpàrà Owárì. Ìdí sì ni yìí tí Ọwá kò gbọ́dọ̀ fi dé ibẹ̀ títí di àsìkò yìí.
20231101.yo_2829_7
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Ìlú mẹ́ta ló kúrò ni Ìpólé, lára wọn ni Ìpólé, Ìjakuro àti Ẹ̀fọ̀n Aláayè. Ìdí nì yí tí wọn má ń sọ pé
20231101.yo_2829_8
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ó wà ní abẹ́ Ìjẹ̀sà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ni a lè rí tọ́kasí lábẹ́ wọn. Lára àwọn ìlú wọ̀nyí ní a tí rí ìlú ńláńlá àti kékeré.
20231101.yo_2829_9
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Orísìrísì oyè ló wà ní ilé lólọkàn ò jọ kan. Pàápàá ní ìlú Ilésà gangan, bẹ́ pẹ̀lú ní àwọn oyè míràn tún wà ní ààrín àdúgbò. Bákan náà ni wọ́n ń jẹ àwọn oyè bi baálẹ̀, lọ́jà ni àwọn ìlú kékèké abẹ́ wọn. lára àwọn oyè pàtàkì tí ó wà ní ìlú ilésà gangan ní wọ̀nyí.
20231101.yo_2829_10
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Tí a bá wo ètò òsèlú tàbí ètò ìse ìjọba ilé ìjẹ̀sà a ó ri wí pé ó jé ètò ìsè ìjọba ti o dára. Nítorí pé, ọba ló jẹ́ olórí fún gbogbo Ìlú ti o maa n pa àsẹ bákan naa ní wọn ní àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ìjòyè. Lára àwọn oyè àdúgbò ni tí a rí olórí ọmọ, ọ̀wábùsuwà, lọ́tún, losì, Ìyá-lóbìrin, àti olórí àdúgbò gangan tí wọn maa n fi orúkọ àdúgbò pè bi àpeere:- bàbá lanaye ni àdúgbò Ànáyè, bàbá luroye ni àdúgbò Ìróyè abbl.
20231101.yo_2829_11
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan yi ló jé olórí fún àwọn ará àdúgbò wọn tí yoo si máà se ìsàkóso àdúgbò naa. Àwọn olórí yìí naa tún ni àwọn àsọmọgbè kọọkan pẹ̀lú isé olúkálukú. Ìyálóbìnrin wà fún ọ̀rọ̀ àwọn obinrin ni àdúgbò, bàbá lórí ọmọ wa fún ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́. Ti ọ̀rọ̀ kan ba selè láàrín àwọn ọ̀dọ̀ tàbí làáárín àgbà tí ó wà ní àdúgbò. Wọn á gbé ejó naa lọ si ilé bàbá lórí ọmọ tí bàbá lórí ọmọ bá parí ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n a tari rẹ̀ si olórí-àdúgbò àti àwọn ìjòye rẹ tí àwọn ìjòyè àti olórí àdúgbò naa kò bá rí ọ̀rọ̀ náà yanjú wọ́n a gbé o di ọ̀dọ̀ ọwá (Ọba wọn) àti àwọn Ìjòyè rẹ fún ejò dídá. Ọ̀dọ̀ Ọwá yìí ni ẹjọ́ gbígbé kiri parí sí. Tí a bá wá ri ẹjọ́ tí Ọwá kò le parí wọn a ní kí oníjà méjì naa lọ búra ní ẹ̀yìnkùlé Ọwá, níbíyi ènìyàn kò le se èké kí o lọ búra ní bẹ̀ nítorí kò sí ohun tí a sọ tí kò ní selẹ̀.
20231101.yo_2829_12
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cj%E1%BA%B9%CC%80%E1%B9%A3%C3%A0
Ìjẹ̀ṣà
Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àsà ni ilẹ̀ Yorùbá lónìí, a ó ri wí pé kò sí ojùlówó ọmọ Yorùbá tí kò ní àsà, àmọ́ àsà wá le yàtọ̀ láti ibìkan sí ibòmíràn. Lára àwọn ojúlówó ọmọ Yorùbá tí ó ní àsà ni a ti rí àwọn Ìjẹ̀sà. Tí a bá sì ń sọ̀rọ̀ nípa àsà, àsà jẹ́ ohun tí agbègbè kan ń se yálà nínú Ìwà wọn, ẹ̀sìn wọn, tàbí nínú Ìsesí wọn.